ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/1 ojú ìwé 2-4
  • Eeṣe Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Tóbẹ́ẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Eeṣe Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Tóbẹ́ẹ̀?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Bikita!
  • Ìgbà Wo Ni Kòkòrò Oyin Kì Í Ṣe Kòkòrò Oyin?
    Jí!—1997
  • Sísin Kòkòrò Oyin—Ìtàn “Aládùn” Kan
    Jí!—1997
  • Oyin Ẹ̀bùn Iyebíye Fáwa Ẹ̀dá
    Jí!—2005
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/1 ojú ìwé 2-4

Eeṣe Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Tóbẹ́ẹ̀?

WO irẹwẹsi oju ọmọ kan ti ebi npa. Wo ara rẹ ti o ti rù kan egungun ati ikun rẹ̀ rogodo. Ronu nipa aini kanjukanju rẹ̀ fun ounjẹ, ki o si ṣakiyesi abọ́ ofifo ti ó gbe lọwọ. Boya iya rẹ̀ nwo o pẹlu awọn ẹyinju ti o ti kó wọnu, oju oun funraarẹ yaworan ipo ainireti ti o kun fun aniyan. Lẹhin naa gbiyanju lati maṣe fi ibanujẹ rẹ han—bẹẹni, ki o si sapa lati maṣe sunkun.

Iran yii ni a nri leralera ni araadọta ọkẹ igba ni ẹkùn ilẹ ti ìyàn ti kọlu ti o gbooro tó 2.3 million ibusọ níbùú ati lóòró ti a mọ si Sahel. Ó gbooro kọja 3,000 ibusọ la guusu Africa ni Aṣálẹ̀ Sahara já, lati Senegal ni Etikun Atlantic si Ethiopia ni Okun Pupa. Dajudaju, ìyàn tun ti halẹmọ ogunlọgọ eniyan ni awọn ilẹ miiran. Ajọ Ilera Agbaye rohin pe nǹkan bii 1.1 aadọta ọkẹ lọna ẹgbẹrun awọn eniyan yika aye ni nṣaisan lọna ti o lewu tabi jiya lọwọ àìjẹunrekánú.

Dajudaju, ebi jẹ kiki iha kan ninu ijiya eniyan. Eniyan nsọ ilẹ-aye di eléèérí, gbogbo wa si ni ó nnipa le lori. Awọn eto igbekalẹ oṣelu fojurere wo aiṣedajọ ododo ati ogun ti nmu inira ati iku wa sori ọpọlọpọ. Eeṣe ti Ọlọrun fi faaye gba iru awọn nǹkan bẹẹ? O ha bikita nipa wa bi?

Ọlọrun Bikita!

Ẹlẹdaa wa bikita nipa wa. Ọpọlọpọ ẹ̀rí ni o wà fun eyi ati fun agbara rẹ̀ lati mu awọn nǹkan ṣiṣẹ papọ fun rere wa ati fun iṣọkan ninu gbogbo iṣẹda rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, wo aworan kokoro oyin ti nṣebẹwo sọdọ itanna ododo igi eleso kan ti o wà nihin in. Kokoro oyin naa gbarale itanna ododo naa fun omi adidun ti o nilo fun iṣaraloore. Lọwọ keji ẹwẹ, igi naa gbarale lẹ́búlẹ́bú ododo ti ara kokoro oyin naa kó lati ara iru igi kan naa. Ni ọna yii, itanna ododo naa ni a fi lẹ́búlẹ́bú ododo yí lara ki eso baa le sọ. Kii ṣe gbogbo igi eleso ni a nsọ di eleso ni ọna yii, ṣugbọn Ọlọrun ti ṣeto dajudaju fun ifọwọsowọpọ ara ọtọ ninu ọran yii. Iṣoore rẹ si farahan ninu eso ti a le jẹ pẹlu igbadun ki a si janfaani.

Kokoro oyin naa funraarẹ jẹ apakan ọ̀wọ́ awọn kokoro oyin ti a ṣeto daradara ti iye wọn ju 30,000 lọ. Awọn kan ńṣọ́ ile oyin nigba ti awọn miiran ńsọ ọ́ di mímọ́ tonitoni tabi fẹ́ atẹgun sii. Sibẹ awọn miiran ntọju omi adidun ati lẹ́búlẹ́bú ododo, fi ounjẹ bọ́ awọn ìdin oyin, tabi wá awọn orisun omi adidun titun kiri. Ọlọrun funraarẹ ti ṣeto awọn ọran tóbẹ́ẹ̀ debi pe a njanfaani nigba ti iru awọn kokoro oyin bẹẹ ba pese adidun ati oyin ti nṣaraloore ti o dunmọni lẹnu.

Iṣẹ iyanu ifọwọsowọpọ laaarin awọn kokoro oyin ati eweko ati laaarin awọn kokoro naa funraawọn wulẹ jẹ ẹ̀rí kanṣoṣo péré ninu ọpọlọpọ pe Ẹlẹdaa naa lagbara lati mu ki awọn ohun alaaye fọwọsowọpọ pẹlu araawọn lọna pipe. Fun idi yẹn “Ọlọrun kii ṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alaafia.” (1 Kọrinti 14:33) Eeṣe, nigba naa, ti oun fi yọnda ki araye wà ninu iru aisi iṣọkan bẹẹ, pẹlu ibanujẹ ti o nyọrisi fun ọpọlọpọ tobẹẹ? Bi Ọlọrun ba bikita nipa wa, eeṣe ti oun fi duro pẹ́ tobẹẹ lati ṣatunṣe ipo yii? Nitootọ, eeṣe ti Ọlọrun fi mú suuru tóbẹ́ẹ̀?

Ọrọ Ọlọrun, Bibeli, dahun iru awọn ibeere bẹẹ. Iwe pipẹtẹri yii sọ fun wa pe Jehofa Ọlọrun ti mú suuru fun idi rere kan. Ki ni idi yẹn? Bawo si ni suuru Ọlọrun yoo ti pẹ́ pupọ sii tó?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Fọto ẹhin iwe: Frilet/Sipa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́