Ẹyẹ Tí Ó Dánìkan Wà Jù Lọ Lágbàáyé
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ BRAZIL
BÍ O bá rò pé òwìwí alámì tóótòòtó lára àti apárí igún wà nínú ewu, o kò tí ì gbọ́ ọ̀ràn ti ayékòótọ́ Spix. Ẹyẹ ilẹ̀ Brazil yìí fúnni ní ojú ìwòye tuntun pátápátá nípa èrò “àwọn irú ẹ̀yà tí a wu léwu.” Bí ó ti wù kí ó rí, láti fún ọ ní ìsọfúnni kíkún nípa ẹyẹ tí ó dánìkan wà jù lọ lágbàáyé yìí, a óò bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún.
Nígbà náà lọ́hùn-ún, George Marc Grav, ọmọ ilẹ̀ Netherlands, tí ó fi Brazil ṣe ilé, ni ó kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ wíwà àti àpèjúwe ẹyẹ yìí. Láìpẹ́-láìjìnnà, àwọn ènìyàn àdúgbò bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní ararinha azul, tàbí ayékòótọ́ kóńkó aláwọ̀ búlúù—orúkọ tí ó ṣe sàn-án àmọ́ tí ó bá a mu gẹ́lẹ́. Ẹyẹ náà ní àwọ̀ búlúù àti eléérú díẹ̀. Ó gùn tó sẹ̀ǹtímítà 55, títí kan ìrù rẹ̀ tí ó gùn ní sẹ̀ǹtímítà 35, òun tún ni ayékòótọ́ aláwọ̀ búlúù tí ó kéré jù lọ ní Brazil.
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè náà, Carlos Yamashita, ògbógi tí ó mú ipò iwájú jù lọ nípa àwọn odídẹrẹ́ ní Brazil, ṣàlàyé pé: “Nígbà tí ó di 1819, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbé orúkọ ẹ̀yẹ náà tí a fàṣẹ sí jáde: Cyanopsitta spixii.” Cyano túmọ̀ sí “búlúù,” psitta sì túmọ̀ sí “odídẹrẹ́.” Spixii wá ń kọ́? Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè náà ṣàlàyé pé, àyẹ́sí ni àfikún yẹn jẹ́ fún onímọ̀ nípa àbá-èrò-orí àdánidá tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany náà, Johann Baptist Spix. Òun ni ẹni tí ó kọ́kọ́ ṣèwádìí lórí irú ẹ̀yà yìí níbi tí a ṣẹ̀dà rẹ̀ sí, ní ibi itọ́ odò kan tí àwọn igi díẹ̀ tò sí ní ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Brazil.
Ìwuléwu Náà Bẹ̀rẹ̀
Òtítọ́ ni pé ayékòótọ́ Spix kò tí ì fìgbà kan kún ojú ọ̀run rí. Àní ní ìgbà ayé Spix alára, gbogbo iye tí a ṣírò wọn sí ni 180, ṣùgbọ́n láti ìgbà yẹn wá, ipò wọn ti tún burú sí i. Àwọn olùgbé agbègbè náà pa ọ̀pọ̀ lára igbó tí àwọn ẹyẹ náà ń gbé rún nígbà tí yóò fi di ìdajì àwọn ọdún 1970, ayékòótọ́ Spix tí ó kù láyé kò tó 60. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn kò dára, ìwuléwu náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.
Ohun tí àwọn olùgbé agbègbè náà kò ṣe fún odindi ọ̀rúndún mẹ́ta ni àwọn pẹyẹpẹyẹ gbìyànjú láti ṣe ní ìwọ̀n ọdún bíi mélòó kan—wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa gbogbo àpapọ̀ ayékòótọ́ Spix tí ó wà tán. Ní ọdún 1984, kìkì 4 lára 60 ẹyẹ náà ló kù nínú ìgbẹ́, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ìgbà náà, àwọn ọlọ́sìn ẹyẹ ti ṣe tán láti san “iye owó èyí-ló-kẹ́yìn”—ohun tí ó tó 50,000 dọ́là fún ẹyẹ kan. Abájọ tí ìwé ìròyìn Animal Kingdom fi kéde ní oṣù May 1989 pé, ó ti tó ọdún kan sẹ́yìn tí àwọn olùwádìí ti rí àwọn ẹyẹ tí ó kẹ́yìn nínú àwọn ẹyẹ yìí tí ń fò lójú sánmà. Ní oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, wọn ròyìn pé àwọn pẹyẹpẹyẹ ti mú gbogbo àwọn ẹyẹ tí ó kù tán. Ìwé ìròyìn Animal Kingdom sọ pé, ayékòótọ́ Spix ti gba “ẹ̀yẹ ìkẹyìn.”
Ìyàlẹ́nu àti Ìrètí
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè kò tí ì dákẹ́ sísọ̀rọ̀ nípa ìpaláparun ayékòótọ́ Spix tí àwọn ènìyàn tí ń gbé àdúgbò agbègbè tí ẹyẹ náà ń gbé fi sọ pé àwọn ti rí ẹyẹ ararinha azul kan. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló tún ròyìn pé àwọn rí i. Ó ha lè jẹ́ pé ẹyẹ kan tún wà tí kò tí ì kú bí? Kí wọ́n baà lè ṣèwádìí nípa rẹ̀, ní ọdún 1990, àwọn olùṣèwádìí márùn-ún di ohun èèlò ìdẹ̀gbẹ́ wọn, awò awọ̀nàjínjìn, àti àwọn ìwé ìkóǹkansí wọn, wọ́n sì mórí lé agbègbè ayékòótọ́ Spix náà.
Lẹ́yìn wíwá gbogbo agbègbè náà fínnífínní fún nǹkan bí oṣù méjì láìsí àṣeyọrí kankan, àwọn olùwádìí náà rí ògìdìgbó àwọn ẹyẹ papagaios maracanãs aláwọ̀ ewé kan, tàbí ayékòótọ́ Illinger, àmọ́ wọ́n ṣàkíyèsí ohun kan tí ó ṣàjèjì. Ọ̀kan lára ògìdìgbó àwọn ẹyẹ náà yàtọ̀—ó tóbi ju àwọn yòókù lọ, ó sì ní àwọ̀ búlúù. Òun ni ó jẹ́ èyí tí ó gbẹ̀yìn lára àwọn ayékòótọ́ Spix tí ó wà nínú ìgbẹ́! Wọ́n ṣàkíyèsí rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan, wọ́n sì rí i pé ẹyẹ Spix, tí ó ní ànímọ́ kíkẹ́gbẹ́rìn, ń tẹ̀lé àwọn ẹyẹ Illinger lẹ́yìn kí ó má baà ṣe òun nìkan, kí ó sì lè rí alábàákẹ́gbẹ́. Ní báyìí, àwọn ẹyẹ aláwọ̀ ewé náà kò kọ kí ojúlùmọ̀ wọn aláwọ̀ búlúù tí kò jáwọ́ títẹ̀ lé wọn yìí di ọ̀rẹ́ àwọn—àmọ́ ṣe wọn yóò gbà kí ó gun àwọn? Bí ì báà ti wù kí ó jẹ́, àwọn ẹyẹ Illinger mọ ààlà wọn tí ó bá di ọ̀ràn fífi ìgbatẹnirò hàn!
Nígbà tí ọ̀ràn ti dà báyìí, tí wọ́n ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ayékòótọ́ Spix máa ń kúrò lọ́dọ̀ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́rọ̀ lójoojúmọ́, tí yóò sì fò lọ sórí igi níbi tí òun àti èkejì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí ó jẹ́ ayékòótọ́ Spix tí máa ń sùn pa pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún—ìyẹn jẹ́ títí di ọdún 1988 tí àwọn pẹyẹpẹyẹ gbá alábàárìn rẹ̀ àtọjọ́mọ́jọ́ mú, tí wọ́n sì tà á sí oko òǹdè. Láti ìgbà náà, ó máa ń dá sùn síbẹ̀—ìṣù ìyẹ́ aláwọ̀ búlúù tí ó wà lórí ẹ̀ka igi gíga kan, tí kò ní èso lórí. Ní báyìí, àyàfi tí iṣẹ́ ìyanu kan bá ṣẹlẹ̀, kò ní pẹ́ tí ayékòótọ́ Spix tí ó kẹ́yìn, tí ó mọ bí ó ṣe lè là á já nínú ìgbẹ́ yóò fi re ibi tí ẹyẹ dodo aláìsí rè—àyàfi tí ẹnì kan bá bá a wá abo tí ó bá a dọ́gba. Èrò náà di ohun tí gbogbo ènìyàn ń rò, nígbà tí ó sì dí ọdún 1991, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò Projeto Ararinha-Azul (Ètò Ayékòótọ́ Spix). Kí ni ète rẹ̀? Láti lè dáàbò bo akọ rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó kù láyé, láti lè wá abo fún un, láti mú kí wọ́n gun ara wọn, kí wọ́n sì retí pé wọn yóò pa ọmọ jọ sí agbègbè náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó ha ń rí bí wọ́n ṣe rò ó bí?
Wọ́n ti ní ìlọsíwájú. Ilé Ìfìwéránṣẹ́ Brazil mú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ẹyẹ tí ó wà nínú ewu jù lọ náà wá sí ojútáyé nípa ṣíṣe sítám̀pù kan jáde ní orúkọ rẹ̀. Ní àkókò kan náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ta àwọn 8,000 olùgbé Curaçá, ìlú kan tí ó wà nítòsí ibi tí ẹyẹ náà ń gbé Bahia ní ìhà àríwá, lólobó, láti lè ti ayékòótọ́ Spix kan ṣoṣo tí ó kù lẹ́yìn. Pẹ̀lú bí àwọn ará ìlú ṣe ń ṣọ́ ẹyẹ “wọn,” tí wọ́n pè ní Severino, ọwọ́ ṣìnkún lè tẹ àwọn pẹyẹpẹyẹ. Ètò yìí ti ń láṣeyọrí. Severino ṣì ń fò káàkiri ní àyíká wọn. Wọ́n tún ti yanjú ìṣòro tí ó tún wà pẹ̀lú—láti rọ àwọn tí ń sin ẹyẹ, kí wọ́n fi ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ mẹ́fà tí wọ́n kó sínú àgò, tí wọ́n ṣì wà láàyè ní Brazil sílẹ̀. (Wo àpótí.) Ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹyẹ náà gbà, nígbà tí ó sì di oṣù August 1994, wọ́n gbé abo ẹyẹ kékeré kan, tí àwọn pẹyẹpẹyẹ mú nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọmọ ẹyẹ, lọ sí Curaçá, kí wọ́n lè tú u sílẹ̀, kí ó sì máa gbé ní ibùgbé tí Ọlọrun ṣẹ̀dá rẹ̀ sí.
Gbígbọnranù àti Wíwárarí
Wọ́n fi abo ayékòótọ́ Spix yìí sí ilé ẹyẹ ńlá kan tí ó wà ní àyíká ibi tí akọ ẹyẹ náà wà, wọ́n sì ń fún un ní oúnjẹ tí àwọn ìran rẹ̀ máa ń jẹ. Láti lè jẹ́ kí ó gbọnranù fún irú ìgbésí ayé tí a ṣẹ̀dá rẹ̀ sí, àwọn tí ń tọ́jú rẹ̀ kò jẹ́ kí ó jẹ èso igi sunflower mọ́—oúnjẹ tí ó máa ń jẹ tẹ́lẹ̀ nígbà tí ó wà nínú àkámọ́—wọ́n sì ń fún un ní èso igi ahóyaya àti àwọn èso ẹlẹ́gùn-ún lára tí ó máa ń hù nínú ìgbẹ́ ní àdúgbò náà. Kò pẹ́ tí ó fi mọ́ ọn lára.
Eré ìmáragbóná ojoojúmọ́ tún jẹ́ apá mìíràn lára ètò dídá ẹyẹ náà lẹ́kọ̀ọ́—ó sì nídìí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ríretí pé kí ẹyẹ tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú àgò ṣara gírí, lójoojúmọ́, lọ́nà kan náà pẹ̀lú èkejì rẹ̀ tí ó kúndùn fífò 50 kìlómítà lóòjọ́ dà bíi kí ènìyàn máa retí kí ẹni jọ̀bọ̀tọ̀ kan sáré bẹ́mìídíje. Nítorí náà, kí wọn baà lè mú kí iṣan rẹ̀ lágbára, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọn ń bojú tó ẹyẹ náà fún un ní ìṣírí láti máa fò yíká ilé ẹyẹ náà bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.
Kò pẹ́ tí Severino fi wá ilé ẹyẹ náà rí. Gbàrà tí ó rí abo náà, ó han gooro, ó pè é, ó sì sún mọ́ ilé ẹyẹ náà ní nǹkan bí 30 mítà. Marcos Da-Ré, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ níbi ètò náà, sọ pé: “Abo náà” dáhùn, ó sì “fi ìdùnnú hàn” nígbà tí ó rí àlejò rẹ̀ akọ. Ó sọ pé, ayọ̀ rẹ̀ “mú kí a ní ìrètí.”
Olùkọ́ àti Bàbá . . .
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọjọ́ tí à ń wí dé: wọ́n ṣí ilẹ̀kùn ilé ẹyẹ náà sílẹ̀. Lẹ́yìn tí abo náà pa rìdàrìdà fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, ó fò jáde, ó sì bà sórí igi kan tí ó fi bíi 300 mítà jìnnà sí ilé ẹyẹ náà. Ṣùgbọ́n ibo ni Severino wà? Ó wà ní nǹkan bí 30 kìlómítà sí i, tí ó tún ń lé àwọn ayékòótọ́ Illinger kiri. Kí lò dé tí ó fi sá lọ? Bí ó ṣe rí nìyí, lẹ́yìn tí ó ti dúró ní àyíká abo fún ọ̀pọ̀ oṣù, nígbà tí àkókò gígùn dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹyẹ tí ó yẹ kí ó ṣe ìyàwó rẹ̀ ṣì wá nínú àkámọ́. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, Da-Ré, sọ àsé pé, bóyá ó rò pé “ẹyẹ maracanã tí kò sí lákàámọ́ sàn ju ẹyẹ ararinha tí ó wà lákàámọ̀ lọ.” Ní ọ̀tẹ̀ yìí, àìpadàsẹ́yìn Severino mú àṣeyọrí wá. Abo ayékòótọ́ Illinger kan juwọ́ sílẹ̀, ó sì gbà kí ó jẹ́ ẹnì kejì òun.
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àkókò gígùn kọjá lọ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè retí pé Severino yóò dáwọ́ eré oge rẹ̀ dúró, tí yóò sì padà sí ibi ibùgbé rẹ̀, tí yóò wá ayékòótọ́ Spix tí ó ti ń fò kiri nísinsìnyí rí, tí yóò sì mú un gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn wọ́n retí pé kí ó máa ṣe ojúṣe méjì—olùkọ́ àti bàbá. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun nìkan ni kìkì ayékòótọ́ Spix tí ó kù lágbàáyé tí ó mọ̀ bí a ṣeé lè là á já nínú ìgbẹ́, ó ní láti kọ́ ẹnì kejì rẹ̀ bí ó ṣe lè wá oúnjẹ àti ibùgbé, kí ó sì máa wà láàyè lọ ní ọ̀kan lára àwọn agbègbè tí ó jẹ́ aṣálẹ̀ jù lọ ní Brazil.
. . . Àti Ẹni Ìtàn
Nítorí náà, nígbà tí àkókò gígùn bá tún bẹ̀rẹ̀, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè tí ń ṣiṣẹ́ nípa Ètò Ayékòótọ́ Spix lérò pé Severino yóò pa títẹ̀lé àwọn ayékòótọ́ Illinger tì, yóò sì pọkàn pọ̀ sórí wíwá ihò igi kan tí ó lè dà bí ilé fún ẹnì kejì rẹ̀. Bí gbogbo nǹkan bá ń lọ bí ó ti yẹ, abo ayékòótọ́ Spix yóò yé ẹyin kékeré méjì, nígbà tí ó bá sì tó bí oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, Severino yóò máa kọ́ àwọn ẹyẹ mẹ́ta ní ọgbọ́n ọ̀nà lílà á já. Nǹkan yóò ha já sí báyìí bí?
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, Yamashita, sọ pé: “A kò lè mọ ìdáhùn náà nísinsìnyí, àmọ́, ètò yìí lè jẹ́ kìkì ọ̀nà kan láti má ṣe jẹ́ kí ayékòótọ́ Spix tí ń gbé inú ìgbẹ́ di èyí tí ó run nínú ìtàn.” Ó kù sọ́wọ́ Severino nísinsìnyí láti lò àǹfààní tí ó ní, kí ó sì wá nǹkan ṣe. Bí síso wọ́n pọ̀ yìí bá ṣiṣẹ́, àwọn olùfẹ́ ìṣẹ̀dá—àti àwọn ayékòótọ́ Illinger—yóò fọkàn balẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Ẹyẹ Tí Ó Wà Nínú Àkámọ́
Ohun tí a ṣírò sí 30 ayékòótọ́ Spix ní ń gbé nínú àkámọ́. Ohun tí ó ju 12 lọ lára àwọn ẹyẹ Brazil yìí ni àwọn ọlọ́sìn ẹyẹ tí ó wà ní Philippines ń sìn, wọ́n ṣì ń gbé ní orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Asia síbẹ̀. Èyí tí ó kù lára àwọn ẹyẹ tí a kó sínú àkámọ́ náà ń gbé ní Brazil, Spain, àti Switzerland. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo àwọn ẹyẹ yìí ni kò ní ànímọ́ kan tí ó jẹ́ pé kìkì Severino ló ní—bí à ṣeé gbé inú ìgbẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
A pa á mọ́ —ó kéré tán lórí sítám̀pù
[Credit Line]
Empresa Brasileira de Correios e Telégrafos