ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/22 ojú ìwé 11-13
  • Irù—Ṣé Ègún Ló Jẹ́ fún Áfíríkà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irù—Ṣé Ègún Ló Jẹ́ fún Áfíríkà?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Máa Ń Mu Ẹ̀jẹ̀
  • Ó Ń Pa Àwọn Ẹranko
  • Ó Ń Pa Ènìyàn
  • Ọ̀rọ̀ Ìgbèjà
  • Bí Eṣinṣin Ìgbẹ́ Ṣe Máa Ń Dábírà Tó Bá Ń Fò
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀
    Jí!—2003
  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Kòkòrò Àfòmọ́!
    Jí!—1999
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/22 ojú ìwé 11-13

Irù—Ṣé Ègún Ló Jẹ́ fún Áfíríkà?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

KÒ TÍ ì pẹ́ tí a kó dé agbègbè àrọ́ko kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Igbó ilẹ̀ olóoru yí wa ká. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, ìyàwó mi wọ iyàrá ìmúra, ó sì kígbe pé: “Eṣinṣin ẹfọ̀n wà nínú iyàrá yìí!”

Kòkòrò náà fò jáde nínú iyàrá ìmúra, ó sì wọ ilé ìwẹ̀. Mo nawọ́ mú agolo oògùn ẹ̀fọn, mo sì gbá tọ̀ ọ́, bí mo ti pa ilẹ̀kùn dé. N kò rí kòkòrò náà. Lójijì, ó fò wá síbi ojú mi. Ó ń fò lù mí! Mo fẹ́ fi ọwọ́ gbá a, àmọ́ n kò rí i pa. Ó fò fẹ̀rẹ̀ lọ sójú fèrèsé. Nẹ́ẹ̀tì kò jẹ́ kí ó lè sá lọ. Kòkòrò náà gẹ́ sára rẹ̀.

Mo ṣọ́ kòkòrò náà, mo sì fín oògùn ẹ̀fọn lù ú. Bí ó ti sábà máa ń rí, tí a bá fín oògùn ẹ̀fọn lu kòkòrò yòówù kí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ yẹn, ojú ẹsẹ̀ ni yóò pa á. Kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti kòkòrò yìí. Ó gbéra, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn yùnmùyùnmù kiri inú ilé ìwẹ̀.

Eléyìí mà le o! Mo ní ìdánilójú pé oògùn ẹ̀fọn náà yóò ṣiṣẹ́ rẹ̀, kòkòrò náà yóò sì já bọ́ sílẹ̀ láìpẹ́. Àmọ́ kò já bọ́. Ìgbà tí ó tún gẹ́, mo fín in lù ú lẹ́ẹ̀kejì. Ó tún gbéra.

Irú àǹjàn-ànnú kòkòrò wo lèyí? Fífín tí mo fín in lẹ́ẹ̀mejì sí i ló pa á nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Mo gbé ìgò mi sójú, mo sì fara balẹ̀ yẹ kòkòrò náà wò. Ó tóbi ju eṣinṣin lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tóbi tó eṣinṣin ẹfọ̀n. Àwọn ìyẹ́ rẹ̀ bo ẹ̀yìn rẹ̀, èyí sì mú kí ó túbọ̀ ṣù mọ́ra ju eṣinṣin lásán lọ. Ọ̀pá gígùn sọọrọ kan yọ jáde láti ibi ẹnu rẹ̀.

Mo ké sí ìyàwó mi pé: “Kì í ṣe eṣinṣin ẹfọ̀n leléyìí. Irù ni o.”

Ìrírí mi náà tẹ ìṣòro ti gbígbìyànjú láti pa kòkòrò náà run pátápátá ní Áfíríkà mọ́ mi lọ́kàn, ilẹ̀ tí ó jẹ́ ilé rẹ̀ tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ 11.7 mílíọ̀nù kìlómítà níbùú lóròó, àyè ilẹ̀ tí ó tóbi ju ti United States lọ. Kí ló dé tí àwọn ènìyàn fi fẹ́ láti pa á run pátápátá? Ẹ̀sùn mẹ́ta ni wọ́n fi kàn án. Ẹ̀sùn kíní:

Ó Máa Ń Mu Ẹ̀jẹ̀

Oríṣi ẹ̀yà 22 irù ló wà. Ìhà gúúsù Aṣálẹ̀ Áfíríkà ni gbogbo wọn fi ṣelé. Àtakọ àtabo wọn máa ń fi ìwàǹwára mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹ̀dá eléegun lẹ́yìn, ní fífa ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ tí ó jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta ìtẹ̀wọ̀n ara wọn bí wọ́n bá jẹni lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

Wọ́n máa ń jẹun lára ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko tí ń jẹko—ìyẹn àwọn ẹran ìbílẹ̀ Áfíríkà àti àwọn tí wọn kì í ṣe ti ibẹ̀. Wọ́n máa ń jẹ ènìyàn pẹ̀lú. Wọ́n máa ń jẹni wọnú ara jinlẹ̀jinlẹ̀, ní yíyára fa ẹ̀jẹ̀ lọ́nà tí ó máa ń roni lára. Ó máa ń yúnni, ó sì máa ń tani bákan náà. Ojú ibẹ̀ máa ń lé.

Àwọn irù mọ iṣẹ́ wọn dájú ṣáká. Wọn kì í fi àkókò ṣòfò láti máa fò yíká orí ẹni. Wọ́n lè máa fò bọ̀ lọ́dọ̀ ẹnì kan bí ọta, kí wọ́n sì kóra ró, kí wọ́n sì rọra gẹ́ si ojú rẹ̀, tí ẹni náà kò sì ní mọ̀. Wọ́n lè dà bí olè; lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o lè má mọ̀ pé wọ́n ti jí ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ fà àyàfi lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ tán—nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó kù fún ọ láti ṣe ni láti yẹ ìpalára náà wò.

Wọ́n sábà máa ń lọ síbi tí aṣọ kò bá bò nínú ara. (Ó jọ pé wọ́n fẹ́ràn ẹ̀yìn ọrùn mi!) Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń fẹ́ láti rá lọ sókè ṣòkòtò tàbí apá ṣẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n tó ti ẹnu bọ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ kan. Tàbí bí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè jẹni taṣọtaṣọ—ìyẹn kì í ṣe ìṣòro fún kòkòrò tí ó lè gún awọ yíyi àgbáǹréré wọlé.

Àwọn ènìyàn fẹ̀sùn kan irù pé kì í ṣe pé ó gbọ́n féfé nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ alálùmọ̀kọ́rọ́yí. Nígbà kan tí mo gbìyànjú láti fi oògùn ẹ̀fọn pa ìkan, ó fò wọ iyàrá ìmúra mi, ó sì sá pamọ́ sára aṣọ ìlúwẹ̀ẹ́ mi. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, nígbà tí mo gbé aṣọ náà wọ̀, ó jẹ mí lẹ́ẹ̀mejì! Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, irù kan sá pamọ́ sínú àpamọ́ ìyàwó mi. Ó mú àpamọ́ náà lọ sí ọ́fíìsì kan, nígbà tí ó sì tọwọ́ bọ inú rẹ̀, kòkòrò náà gé e jẹ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ni ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fò kiri inú ilé náà, tí ó sì fa ìdàrúdàpọ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ inú ọ́fíìsì náà. Gbogbo ènìyàn ló dá iṣẹ́ dúró láti gbìyànjú láti fi nǹkan lù ú pa.

Nítorí náà, ẹ̀sùn àkọ́kọ́ tí wọ́n fi kan irù ni pé mùjẹ̀mùjẹ̀ tí ń jẹni lọ́nà tí ń fa ìrora ni. Ẹ̀sùn kejì:

Ó Ń Pa Àwọn Ẹranko

Oríṣi àwọn irù kan máa ń gbé àrùn kan tí àwọn kòkòrò àfòmọ́ tín-íntìn-ìntín tí ń jẹ́ trypanosome máa ń fà kiri. Tí irù bá fa ẹ̀jẹ̀ ẹranko tí ó ní àrùn náà, ó máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ tí ó ní kòkòrò àfòmọ́ mì. Èyí yóò wá dàgbà, yóò sì di púpọ̀ nínú kòkòrò náà. Bí kòkòrò náà bá jẹ ẹranko mìíràn, àwọn kòkòrò àfòmọ́ yóò lọ sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ẹranko náà láti ara kòkòrò náà.

Trypanosomiasis ni àrùn náà ń jẹ́. Èyí tí ó máa ń ṣe àwọn ẹranko ni a ń pè ní nagana. Kòkòrò àfòmọ́ nagana máa ń ṣara rindin nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ìbílẹ̀ Áfíríkà, pàápàá jù lọ ẹtu, ẹfọ̀n, túùkú, gìdìgìdì, reedbuck, àti àwọn ìmàdò. Kòkòrò àfòmọ́ náà kì í pa àwọn ẹranko wọ̀nyí.

Àmọ́ àwọn kòkòrò àfòmọ́ náà máa ń pa àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọn kì í ṣe ti ìbílẹ̀ Áfíríkà—ràkúnmí, ajá, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ewúrẹ́, ẹṣin, ìbákasíẹ, ọ̀dá-màlúù, ẹlẹ́dẹ̀, àti àgùntàn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn National Geographic sọ, àrùn nagana ń pa mílíọ̀nù mẹ́ta màlúù lọ́dọọdún.

Àwọn tí ń da màlúù, bí àwọn ènìyàn ẹ̀yà Masai ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa pẹ́ àwọn agbègbè tí àwọn irù pọ̀ sí gan-an sílẹ̀, àmọ́ ọ̀dá àti àìsí koríko kì í jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Lákòókò ọ̀dá kan tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí, àwọn kòkòrò náà ń pa ọ̀kọ̀ọ̀kan lára 600 màlúù tí àwọn ìdílé mẹ́rin kan kó pọ̀ sójú kan lóòjọ́. Lesalon, àgbàlagbà nínú ìdílé kan lára wọn, sọ pé: “Onígboyà ènìyàn ni àwa Masai. A ń fi ọ̀kọ̀ pa kìnnìún, a sì ń gbéjà ko ẹfọ̀n tí ń kù gìrì. A ń fi òlùgbóńdóró lu ejò mamba dúdú pa, a sì ń gbógun ti erin tí inú ń bí. Àmọ́ ní ti orkimbai [irù] ńkọ́? Kò sí ohun tí a lè ṣe.”

Àwọn oògùn tí a lè fi wo àrùn nagana wà, àmọ́ àwọn ìjọba kan fàyè gba lílò wọ́n kìkì lábẹ́ àbójútó olùtọ́jú ẹranko. Ìyẹn ní ìdí tí ó dára, níwọ̀n bí kì í ti í ṣe pé ṣíṣàìlo egbòogi náà tó lè fi àwọn ẹranko náà sínú ewu nìkan ni àmọ́, ó lè ṣèmújáde àwọn kòkòrò àfòmọ́ tí oògùn kò ràn. Ó lè ṣòro fún ẹni tí ń da màlúù nínú igbó láti rí olùtọ́jú ẹranko tí yóò tọ́jú ẹran rẹ̀ tí ń kú lọ lásìkò.

A ti fìdí ẹ̀rí àwọn ẹ̀sùn méjì àkọ́kọ́ tí a fi kan irù múlẹ̀ láìsí àríyànjiyàn—ó máa ń mu ẹ̀jẹ̀, ó sì máa ń tan àrùn kan tí ó máa ń pa àwọn ẹranko kálẹ̀. Àmọ́ ó ṣì tún kù. Ẹ̀sùn kẹta:

Ó Ń Pa Ènìyàn

Àrùn trypanosome ti nagana kì í kọ lu ènìyàn. Àmọ́ irù máa ń gbé irú àrùn trypanosome mìíràn láti ara ènìyàn kan sí òmíràn. Oríṣi àrùn trypanosomiasis yìí ni a ń pè ní àrùn sunrunsunrun. Má ṣe rò pé ẹnì kan tí ó ní àrùn sunrunsunrun wulẹ̀ máa ń sùn jù ni. Àrùn náà kì í ṣe ti oorun aládùn. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára àìlera, àárẹ̀, àti ibà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn ni títòògbé jù, ibà líle, ìrora oríkèé ara, ìwúlé àwọn iṣan ara, àti ìwúlé ẹ̀dọ̀ òun ọlọ inú. Nígbà tí ó bá wọra tán, bí àwọn kòkòrò àfòmọ́ náà bá ṣe ń wọnú ìgbékalẹ̀ iṣan ọpọlọ, ẹni tí àìsàn náà ń ṣe máa ń ní àìṣiṣẹ́ geerege ọpọlọ, gìrì, dídá kú, àti ikú.

Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn sunrunsunrun ṣọṣẹ́ púpọ̀ ní kọ́ńtínẹ́ǹtì Áfíríkà. Láàárín 1902 sí 1905, àrùn náà pa nǹkan bí 30,000 ènìyàn nítòsí Adágún Victoria. Ní àwọn ẹ̀wádún tí ó tẹ̀ lé e, àrùn náà ràn dé Cameroon, Gánà, àti Nàìjíríà. Ní ọ̀pọ̀ abúlé, ìlàta àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni ó ràn, tí èyí béèrè fún kíkó àwọn ènìyàn lọ́pọ̀ yanturu kúrò ní ọ̀pọ̀ àfonífojì odò. Àwùjọ àwọn olùtọ́jú aláìsàn tí ń káàkiri tọ́jú ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn. Ẹ̀yìn àwọn ọdún 1930 ni àjàkálẹ̀ náà tó kójú kúrò nílẹ̀, tí ó sì parẹ́.

Lónìí, àrùn náà ń pọ́n nǹkan bí 25,000 ènìyàn lójú lọ́dọọdún. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ, ó lé ní 50 mílíọ̀nù ènìyàn ní orílẹ̀-èdè 36 ní gúúsù Aṣálẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n wà nínú ewu kíkó àrùn náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àrùn sunrunsunrun ń fa ikú bí a kò bá tọ́jú rẹ̀, àwọn egbòogi wà láti tọ́jú rẹ̀. Láìpẹ́ yìí ni wọ́n gbé egbòogi tuntun kan tí ń jẹ́ eflornithine jáde fún títọ́jú àrùn náà—àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lẹ́yìn 40 ọdún.

Ó ti pẹ́ tí ẹ̀dá ènìyàn ti ń gbógun ti irù àti àrùn tí ó ń gbé kiri. Ní 1907, Winston Churchill kọ̀wé nípa ìgbétásì kan láti mú irù kúrò pátápátá pé: “A hun nẹ́ẹ̀tì gbàràmù kan, láti ṣẹ́pá ìrànkálẹ̀ irù.” Ní bíbojú wẹ̀yìn, ó hàn gbangba pé “nẹ́ẹ̀tì gbàràmù” tí Churchill ń sọ ní àwọn ihò ńláńlá. Ìwé Foundations of Parasitology sọ pé: “Títí di báyìí, gbogbo 80 ọdún tí a ti fi ń gbìyànjú àtimú irù kúrò pátápátá kò ní ipa púpọ̀ kan lórí ìrànkálẹ̀ irù.”

Ọ̀rọ̀ Ìgbèjà

Eléwì ọmọ ilẹ̀ America, Ogden Nash, kọ̀wé pé: “Nínú ọgbọ́n Ọlọrun ló ti ṣẹ̀dá kòkòrò, ó sì gbàgbé láti sọ ìdí tí ó fi ṣẹ̀dá rẹ̀ fún wa.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni pé Jehofa Ọlọrun ni Olùṣẹ̀dá ohun gbogbo, dájúdájú, kì í ṣe òtítọ́ pé ó máa ń gbàgbé nǹkan. Ó ti gbà wá láyè láti wádìí nǹkan púpọ̀ fúnra wa. Nígbà náà, ti irù ńkọ́? Ohun kan ha wà tí a lè sọ nípa aṣeburúkú tí a rí gbangba yìí láti gbèjà rẹ̀ bí?

Bóyá ìgbèjà tí ó lágbára jù lọ títí di báyìí ni pé ipa rẹ̀ nínú pípa àwọn màlúù run ti ṣiṣẹ́ láti dáàbò bo igbó tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ Áfíríkà wà. Àwọn agbègbè títóbi ní Áfíríkà jọra pẹ̀lú àwọn pápá tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn United States—ilẹ̀ náà fúnra rẹ̀ dáńgájíá láti gba àwọn ẹran ọ̀sìn. Àmọ́, ọpẹ́lọpẹ́ irù, àwọn kòkòrò àfòmọ́ trypanosome tí kì í pa àwọn ẹran ìbílẹ̀ tí ń jẹko, máa ń pa àwọn ẹran ọ̀sìn.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé bí kì í bá ṣe ti irù ni, tipẹ́tipẹ́ ni à bá ti fi agbo àwọn màlúù rọ́pò ọ̀pọ̀ jaburata igbó tí àwọn ẹran ìgbẹ́ wà ní Áfíríkà. Willie van Niekerk, afinimọgbó nínú igbó ẹran ìgbẹ́ kan ní Botswana, sọ pé: “Mo fọwọ́ sí wíwà irù. Bí a bá mú irù kúrò, àwọn màlúù yóò ya bò wá, àwọn màlúù sì ni ajanilólè ilẹ̀ ní Áfíríkà, tí ń fọ́jú kọ́ńtínẹ́ǹtì yìí pọ̀ di ààtàn ńlá kan.” Ó fi kún un pé: “Ó yẹ kí àwọn kòkòrò náà máa wà nìṣó.”

Ó dájú pé, gbogbo ènìyàn kọ́ ló fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìyẹn. Àríyànjiyàn náà kò ṣe púpọ̀ láti yí ojú ìwòye ọkùnrin kan tí ń rí i tí àwọn ọmọ rẹ̀ tàbí màlúù rẹ̀ ń jìyà àrùn trypanosomiasis padà. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì yí ojú ìwòye àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ènìyàn Áfíríkà nílò màlúù láti bọ́ ara wọn padà.

Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí iyè méjì pé ohun púpọ̀ ṣì wà láti kọ́ nípa ipa tí irù ń kó nínú ìṣẹ̀dá. Bí ó tilẹ̀ jọ pé àwọn ẹ̀sùn tí a fi kàn án lágbára, bóyá ó ti yá jù láti dájọ́.

Bí a ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kòkòrò, ọ̀kán ti fò wọnú iyàrá báyìí. Ẹ jẹ́ kí n lọ wò ó kó má lọ jẹ́ irù ni.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]

Irù: ©Martin Dohrn, The National Audubon Society Collection/PR

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́