ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 6/8 ojú ìwé 18-19
  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Kòkòrò Àfòmọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Kòkòrò Àfòmọ́!
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdènà Sàn Ju Ìwòsàn Lọ
  • Àrùn Àtọ̀sí Ajá—Òpin Rẹ̀ Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?
    Jí!—1997
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà
    Jí!—2015
  • Ṣé Nítorí Àtiṣoge Nìkan Ni?
    Jí!—2004
  • Ọ̀nà Márùn-ún Láti Mú Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Sunwọ̀n sí I
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 6/8 ojú ìwé 18-19

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Kòkòrò Àfòmọ́!

LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ HONDURAS

BÍ O ṣe jí ni ẹ̀dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rìn ẹ́. Ó sì ti rẹ̀ ọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ikùn rẹ ti tóbi díẹ̀ sí i. Ṣé àmì pé o ti lóyún lèyí ni? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ ilẹ̀ olóoru tàbí ibi tó sún mọ́ ilẹ̀ olóoru lo ń gbé, ó lè jẹ́ irú kòkòrò àfòmọ́ inú ìfun kan ló ń yọ ẹ́ lẹ́nu. Kí ni àwọn kòkòrò àfòmọ́ inú ìfun, báwo lo sì ṣe lè mọ̀ tí àwọn àlejò àpàpàǹdodo wọ̀nyí bá ti fi inú rẹ ṣelé?

Ká sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn, kòkòrò àfòmọ́ jẹ́ ẹ̀dá alààyè kan tó ń rí nǹkan ṣara rindin lára tàbí nínú ẹ̀dá alààyè tó wà. Oríṣi kòkòrò àfòmọ́ inú ìfun méjì tó wà jẹ́ ẹ̀yà protozoan, ìyẹn sì ní amoeba, àti aràn nínú. Bí wọ́n ṣe ń ṣèpalára fún ẹni tí wọ́n wà lára rẹ̀ tó sinmi lórí irú àwọn kòkòrò àfòmọ́ tó jẹ́, bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, ọjọ́ orí ẹni tí wọ́n wà lára rẹ̀ àti bí ara rẹ̀ ṣe yá gágá tó.

Fún àpẹẹrẹ, abo aràn lè yín ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ẹyin lóòjọ́. Àmọ́, àwọn ẹyin náà gbọ́dọ̀ dàgbà nínú iyẹ̀pẹ̀ kí wọ́n lè wà láàyè. Iye aràn tí ẹnì kan ní lára sinmi lórí iye ẹyin tàbí kògbókògbó rẹ̀ tó wà láàyè tí ó wọ ara ẹnì kan. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni aràn bíi mélòó kan máa ń fi ara wọn ṣelé tí wọn kò sì ní mọ̀. Ṣùgbọ́n tí aràn bá pọ̀ gan-an nínú, wọ́n lè dí ènìyàn nífun.

Àwọn àmì àrùn wíwọ́pọ̀ díẹ̀ tó máa ń bá àfòmọ́ inú ikùn rìn ni inú dídunni, ìrìndọ̀, kí oúnjẹ má wuni í jẹ, ikùn wíwú, àárẹ̀, àìdà oúnjẹ tó ti gbẹ̀kan, ìgbẹ́ gbuuru, tàbí inú kíkún. Fífọn, àìlèsùn wọra, ara yíyúnni, mímí gúlegúle, àti ibà pẹ̀lú lè jẹ́ àmì pé kòkòrò àfòmọ́ wà nínú ẹni. Dájúdájú, àwọn àmì àrùn wọ̀nyí lè jẹ́ àmì tí ń bá ọ̀pọ̀ àrùn mìíràn rìn. Ṣùgbọ́n bí a bá ṣàyẹ̀wò ìgbẹ́ nígbà bíi mélòó kan, a lè mọ̀ bóyá kòkòrò àfòmọ́ wà nínú ẹnì kan.

Ó pọndandan láti ṣe àwárí tó péye. Fún àpẹẹrẹ, bí a bá rí aràn àti oríṣi àwọn kòkòrò àfòmọ́ mìíràn nínú rẹ̀, a ní láti kọ́kọ́ wá oògùn tí yóò pa aràn náà. Èé ṣe? Nítorí pé àwọn oògùn kan kì í pa aràn ṣùgbọ́n ó kàn lè rùn sí wọn, kí wọn sì kóra lọ sí inú ẹ̀yà ara mìíràn, wọn óò sì ṣèpalára tó burú.

Ìdènà Sàn Ju Ìwòsàn Lọ

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí ti fi hàn pé lílo oògùn jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí a lè gbà pa àwọn kòkòrò àfòmọ́, ó sàn jù kí a máà jẹ́ kí ó ràn wá rárá. Nítorí náà, báwo ni o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àfòmọ́?

Ìmọ́tótó ni ààbò tó dára jù lọ. A kò gbọ́dọ̀ máa ṣí ìgbẹ́ sílẹ̀ láìbò ó. Ilé ìyàgbẹ́ gbọ́dọ̀ jìnnà dáadáa sí orísun omi. A kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ìdọ̀tí tí ń jáde lára ènìyàn ṣe ajílẹ̀. Ìmọ́tótó tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu pọndandan pẹ̀lú. Láfikún sí i, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọdé máa jẹ ìdọ̀tí. Bí a bá rí i pé ọmọ kan ní àwọn kòkòrò àfòmọ́ lára, yóò bọ́gbọ́n mu kí a lọ ṣàyẹ̀wò ara olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé tó kù.

Bákan náà ni a ní láti ṣọ́ra nípa èèlò oúnjẹ tí a ń rà àti bí a ṣe ń sè é. Gbìyànjú láti ra àwọn èèlò tí a kórè láti àwọn agbègbè tí a mọ̀ pé ó mọ́ tónítóní. A gbọ́dọ̀ se ẹran kó jinná dénú dáadáa. Má ṣe máa jẹ ẹran tútù. A gbọ́dọ̀ ṣan èso àti ewébẹ̀ tí a kì í sè kí a tó jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n ṣọ́ra kí o máà tún lo omi tí o fi ṣàn án nítorí ó lè ti léèérí nínú.

Kí a se omi mímu dáadáa. Tí omi náà bá tutù, a lè jẹ́ kí atẹ́gùn fẹ́ sí i kí ó lè dára lẹ́nu. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn asẹ́ tí a ń lò nínú ilé kò lè mú gbogbo kòkòrò àfòmọ́ kúrò. Bí àwọn omi àrọtà ṣe mọ́ sí sinmi lórí bí ìmọ́tótó tí a fìṣọ́ra ṣe níbi tí wọ́n ti ṣe é ṣe pọ̀ tó.

A ní láti túbọ̀ ṣọ́ra nípa rírìnrìn àjò àti jíjẹun níta. Àwọn ohun mímu tí a rọ sínú ìgò tí a sì kó sínú páálí sábà máa ń dára fún mímu bí a kò bá kó omi dídì sínú rẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn kòkòrò àfòmọ́ kan ti máa ń la ipò títutùnini já, omi dídì kò mọ́ ju omi lásán lọ. Bóyá wàá fẹ́ láti ṣọ́ra fún àwọn oúnjẹ tí àwọn tí ń kiri oúnjẹ ládùúgbò ń tà. Ọ̀pẹ̀yìnbó tàbí watermelon tí a ti gé lè fani mọ́ra, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà omi tí wọ́n fi wọ́n ọn—tí omi náà ti lè ní èérí nínú—ló ń jẹ́ kí ojú ẹ̀ dára. Ṣọ́ra, ṣùgbọ́n má ṣe bẹ̀rù jù tí o kò fi ní máa gbádùn ìrìn àjò rẹ. Nípa lílo ìṣọ́ra bó ti yẹ, wàá lè ṣe púpọ̀ láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àfòmọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ìmọ́tótó ni ààbò tó dára jù lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Omi dídì kò mọ́ ju omi lásán lọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Oríṣi kòkòrò àfòmọ́ méjì tó wà ni “amoeba” àti aràn

[Credit Line]

DPDx, the CDC Parasitology Website

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́