ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/22 ojú ìwé 14-16
  • Àrùn Àtọ̀sí Ajá—Òpin Rẹ̀ Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Àtọ̀sí Ajá—Òpin Rẹ̀ Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àyípoyípo Ìgbésí Ayé Kòkòrò Àrùn Náà
  • Àwọn Ojútùú àti Ìṣòro
  • Kí Ni Ìrètí fún Ọjọ́ Ọ̀la?
  • Bí Àìsàn Ibà Bá Ń ṣe Ọmọ Rẹ
    Jí!—2003
  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Kòkòrò Àfòmọ́!
    Jí!—1999
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà
    Jí!—2015
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
Jí!—1997
g97 2/22 ojú ìwé 14-16

Àrùn Àtọ̀sí Ajá—Òpin Rẹ̀ Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

LÁÌKA àwọn ìtẹ̀síwájú kíkàmàmà ní ti ìṣègùn àti sáyẹ́ǹsì sí, ìran ẹ̀dá ènìyàn kò lè yanjú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro rẹ̀ àtayébáyé. Èyí jẹ́ òótọ́ nípa àwọn ìsapá láti ṣẹ́pá àrùn àtọ̀sí ajá.

Ó jọ pé a ní gbogbo ohun tí a nílò láti kojú àrùn náà lárọ̀ọ́wọ́tó. Àwọn dókítà mọ gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé kòkòrò àrùn tí ń fà á. Ó rọrùn láti ṣàwárí àrùn náà. Àwọn egbòogi gbígbéṣẹ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti fi wò ó sàn. Àwọn aṣáájú ìjọba ń hára gàgà láti gbé ìsapá láti dènà rẹ̀ lárugẹ. Síbẹ̀, kò sí òye kankan pé òpin àrùn tí ń pọ́n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lójú ní Áfíríkà, Éṣíà, Caribbean, Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, àti Gúúsù America yìí ti sún mọ́lé.

Àrùn àtọ̀sí ajá ti gbógun ti ènìyàn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn ẹyin tí a sọ di aláìlè-yípadà tí a rí nínú àwọn ara òkú dídì ní ilẹ̀ Íjíbítì fẹ̀rí hàn pé àrùn náà bá àwọn ará Íjíbítì fínra nígbà ayé àwọn fáráò. Ọgbọ̀n ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àrùn kan náà ń gbógun ti Íjíbítì, ó ń ba ìlera àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́. Ní àwọn abúlé kan níbi Ìyawọ̀kun Náílì, ìpín 9 lára 10 àwọn ènìyàn ní àrùn náà.

Íjíbítì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè 74 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí àrùn àtọ̀sí ajá ti jẹ́ tìbílẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí iye tí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbé jáde, 200 mílíọ̀nù ènìyàn ló ní àrùn náà kárí ayé. Lára àwọn 20 mílíọ̀nù tí tiwọn le jù, nǹkan bí 200,000 ń kú lọ́dọọdún. Lára àwọn àrùn tí kòkòrò àrùn ń fà ní ilẹ̀ olóoru, a gbọ́ pé àrùn àtọ̀sí ajá ló gbapò kejì tẹ̀ lé ibà ní ti iye àwọn tí ó ti ràn àti ìpalára tí ó ń ṣe fún àwùjọ àwọn ènìyàn àti ọrọ̀ ajé.

Àyípoyípo Ìgbésí Ayé Kòkòrò Àrùn Náà

Lílóye àrùn àtọ̀sí ajá, àti títipa bẹ́ẹ̀ mọ bí a ṣe lè dènà rẹ̀, kí a sì wo ẹni tí ń ṣe sàn, túmọ̀ sí lílóye kòkòrò àrùn tí ń fà á. Kókó pàtàkì kan nìyí: Kí kòkòrò àrùn yí lè máa wà nìṣó láti ìran dé ìran, ó nílò ẹ̀dá alààyè méjì, nínú èyí tí yóò ti máa jẹ, tí yóò sì máa dàgbà. Ọ̀kan ni ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú kan, bí ènìyàn; èkejì sì ni ìgbín inú omi aláìníyọ̀.

Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nìyí. Nígbà tí ẹnì kan tí ó ní kòkòrò àrùn náà lára bá tọ̀ tàbí yàgbẹ́ sínú omi ọ̀gọ̀dọ̀, adágún, odò kékeré, tàbí odò ńlá kan, yóò tú àwọn ẹyin kòkòrò àrùn náà sílẹ̀—ó lè pọ̀ tó mílíọ̀nù kan lóòjọ́. Àwọn ẹyin wọ̀nyí kéré ju ohun tí a lè rí láìlo awò tí ń sọhun kékeré di ńlá. Nígbà tí àwọn ẹyin náà bá dénú omi, wọn yóò pa, wọn yóò sì tú àwọn kòkòrò àrùn náà dà sílẹ̀. Àwọn kòkòrò àrùn náà yóò fi irun gán-gàn-gán ara wọn lúwẹ̀ẹ́ lọ sọ́dọ̀ ìgbín inú odò aláìníyọ̀, wọn yóò sì kó sínú rẹ̀. Inú ìgbín náà ni wọn ń pamọ jọ sí fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí méje tí ó tẹ̀ lé e.

Bí wọ́n bá ti ń jáde lára ìgbín náà, wọ́n ní wákàtí 48 péré láti wọ ara ènìyàn tàbí ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú mìíràn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò kú. Bí àwọn kòkòrò àrùn náà bá ti so mọ́ irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ tí ó wọ inú omi náà, wọn yóò dá ihò sí ara rẹ̀, wọn yóò sì kọjá sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Èyí lè fa ara yíyún díẹ̀ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kì í sábà sí àmì kankan tí yóò fi mọ̀ pé nǹkan kan ti wọlé sí òun lára. Nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ náà, kòkòrò àrùn ọ̀hún yóò wá ọ̀nà lọ sí òpójẹ̀ tí ń lọ sínú àpòòtọ̀ tàbí sínú ìfun, ìyẹn sinmi lórí irú ọ̀wọ́ kòkòrò àrùn tó jẹ́. Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, àwọn kòkòrò àrùn náà yóò dàgbà di akọ tàbí abo aràn tí ó gùn tó mìlímítà 25. Lẹ́yìn tí wọ́n bá dà pọ̀, abo náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í tú ẹyin jáde sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ẹni náà, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ parí àyípoyípo tí ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹni àkọ́kọ́ tọ̀ tàbí yàgbẹ́ sómi.

Nǹkan bí ìdajì àwọn ẹyin náà ní ń bá ìyàgbẹ́ (ní ti àrùn àtọ̀sí ajá inú ìfun) tàbí ìtọ̀ (ní ti àrùn àtọ̀sí ajá inú ìtọ̀) jáde lára ẹni tí ó ní in. Àwọn ẹyin yòó kù ń wà nínú ara nìṣó, wọ́n sì ń ba àwọn ẹ̀yà ara pàtàkì-pàtàkì jẹ́. Bí àrùn náà ṣe ń gbilẹ̀ sí i, ẹni náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ara gbígbóná kọjá ààlà, ikùn wíwú, àti ìṣẹ̀jẹ̀ láti inú. Níkẹyìn, àrùn náà lè fa jẹjẹrẹ àpòòtọ̀ tàbí àìgbéṣẹ́ ẹ̀dọ̀ki tàbí ti kíndìnrín. Àwọn kan tí ó ní àrùn náà ń di aláìlèbímọ tàbí alárùn ẹ̀gbà. Àwọn mìíràn ń kú.

Àwọn Ojútùú àti Ìṣòro

Láti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn náà, ó kéré tán, a lè ṣe nǹkan mẹ́rin. Bí a bá gbé èyíkéyìí lára àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí kárí ayé, àrùn náà yóò kásẹ̀ nílẹ̀.

Ìgbésẹ̀ kíní ni láti pa gbogbo ìgbín inú omi. Àwọn ìgbín ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè kòkòrò àrùn náà. Láìsí ìgbín, kì yóò sí àrùn àtọ̀sí ajá.

Ìsapá gidi náà ti jẹ́ pípèsè májèlé tí ó lágbára tó láti pàgbín, ṣùgbọ́n tí kò ní bàyíká jẹ́. Ní àwọn ọdún 1960 àti 1970, àwọn ìgbìdánwò láti pàgbín ti yọrí sí pípa gbogbo ohun alààyè nínú àwọn omi púpọ̀ rẹpẹtẹ. Ní Ibùdó Ìwádìí Theodor Bilharz ní Íjíbítì, a ti gbìdánwò láti ṣàwárí oògùn apàgbín tí kò ní ṣèpalára fún àwọn ohun alààyè míràn. Dókítà Aly Zein El Abdeen, ààrẹ ibùdó náà, sọ nípa irú oògùn bẹ́ẹ̀ pé: “A óò dà á sómi tí a fi ń fọ́n irúgbìn, tí àtènìyàn àtẹranko ń mu, tí àwọn ẹja sì ń gbé inú rẹ̀, nítorí náà, ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú hán-únhán-ún pé kò ní nípa lórí èyíkéyìí nínú àwọn wọ̀nyí.”

Ìgbésẹ̀ kejì ni pípa àwọn kòkòrò àrùn náà tí ó ti wà lára ènìyàn. Títí di agbedeméjì àwọn ọdún 1970, àwọn egbòogi tí ń ní ipa búburú àìròtẹ́lẹ̀, tí ó sì ń fa ìṣòro púpọ̀, ni a fi ń ṣètọ́jú rẹ̀. Nígbà púpọ̀, ìṣètọ́jú náà máa ń ní gbígba àwọn ọ̀wọ́ abẹ́rẹ́ tí ń roni lára kan nínú. Àwọn kan ráhùn pé ìwòsàn náà burú ju àrùn gan-an lọ! Láti ìgbà náà wá, àwọn egbòogi tuntun bíi praziquantel, tí wọ́n lágbára lórí àrùn àtọ̀sí ajá ti wà, ìwọ̀nyí sì ṣeé ti ẹnu lò.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn egbòogi wọ̀nyí ti kẹ́sẹ járí ní lílò wọ́n dánra wò ní Áfíríkà àti Gúúsù America, iye owó wọn ni ìṣòro pàtàkì ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àjọ WHO kédàárò ní 1991 pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn náà jẹ́ tìbílẹ̀ wọn kò lè dáwọ́ lé ètò kíkápá [àrùn àtọ̀sí ajá] lọ́nà gbígbòòrò nítorí iye owó gọbọi tí ìṣètọ́jú náà ń náni; iye owó egbòogi náà fúnra rẹ̀ pọ̀ ju iye owó tí ọ̀pọ̀ jù lọ ilé iṣẹ́ àbójútó ìlera ní ilẹ̀ Áfíríkà ń wéwèé láti ná lọ́dún lọ.”

Kódà, níbi tí egbòogi náà ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó aláìsàn náà lọ́fẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kì í lọ gbàtọ́jú. Èé ṣe? Ìdí kan ni pé iye ènìyàn tí àrùn náà ń pa kéré ní ìfiwéra, nítorí náà, àwọn ènìyàn kò kà á sí ìṣòro gbígbópọn. Ìdí mìíràn ni pé àwọn ènìyàn kì í sábà mọ àwọn àmì àrùn náà. Ní àwọn apá kan ilẹ̀ Áfíríkà, títọ ẹ̀jẹ̀ (ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àmì àrùn náà) wọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kà á sí apá kan ìdàgbà di géńdé.

Ìgbésẹ̀ kẹta ni ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn ẹyin náà dénú omi. Bí a bá kọ́ àwọn ilé ìyàgbẹ́ láti dènà bíba àwọn odò kékeré àti ọ̀gọ̀dọ̀ àdúgbò jẹ́, tí gbogbo ènìyàn bá sì ń lò wọ́n, ewu níní àrùn àtọ̀sí ajá lè dín kù.

Ìwádìí kárí ayé fi hàn pé àrùn náà lọ sílẹ̀ gidigidi nígbà tí a pèsè omi ẹ̀rọ àti ilé ìyàgbẹ́, àmọ́ àwọn ìpèsè wọ̀nyí kò mú ìdènà dájú. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ Alan Fenwick, tí ó ti fi àkókò tí ó lé ní 20 ọdún wádìí àrùn àtọ̀sí ajá, sọ pé: “Ẹnì kan ṣoṣo péré ti tó láti ṣe ẹ̀gbin sódò, kí ó sì tanná ran àyípoyípo náà.” Ewu tí ó tún wà ni ti ọ̀nà ìṣànyàgbẹ́dànù tí ó lè bẹ́, kí ó sì da ìyàgbẹ́ tí àrùn náà wà sí orísun omi.

Ìgbésẹ̀ kẹrin ni ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn ènìyàn máa wọnú omi tí kòkòrò àrùn náà bá wà. Èyí pẹ̀lú kò rọrùn tó bí ó ti lè jọ lójú. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn adágún, àwọn odò kékeré, àti odò ńlá tí a ti ń pọnmi mímu ni a ń lò fún wíwẹ̀, bíbomirin ohun ọ̀gbìn, àti fífọ aṣọ pẹ̀lú. Ojoojúmọ́ ni àwọn apẹja ń fi tomi ṣe. Nínú ooru mímúná ilẹ̀ olóoru, àgbájọ omi kan lè jẹ́ ibi ìlúwẹ̀ẹ́ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ọmọdé.

Kí Ni Ìrètí fún Ọjọ́ Ọ̀la?

Kò sí iyè méjì pé àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ń sakun taápọntaápọn láti gbógun ti àrùn àtọ̀sí ajá, wọ́n sì ti tẹ̀ síwájú lọ́nà kíkàmàmà. Àwọn olùwádìí tilẹ̀ ti ń sakun láti ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí rẹ̀.

Síbẹ̀síbẹ̀, ìfojúsọ́nà láti kásẹ̀ àrùn náà nílẹ̀ kò dán mọ́rán. Dókítà M. Larivière sọ nínú ìwé ìròyìn ìṣègùn ilẹ̀ Faransé náà, La Revue du Praticien, pé: “Láìka àwọn àṣeyọrí náà sí . . . , kò jọ pé àrùn náà fẹ́ kásẹ̀ nílẹ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdènà àti ìwòsàn lè ṣeé ṣe fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan, a lè ṣàìrí ojútùú kárí ayé kan fún àrùn àtọ̀sí ajá títí tí ayé tuntun ti Ọlọ́run yóò fi dé. Bíbélì ṣèlérí pé, “ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.”—Aísáyà 33:24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Nígbà tí àwọn ènìyàn bá wọ omi tí ó ti deléèérí, wọ́n lè kó àwọn àfòmọ́ tí ń fa àrùn àtọ̀sí ajá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́