ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 9/15 ojú ìwé 12-15
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà
  • Jí!—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 KÍ NI ÀÌSÀN IBÀ?
  • 2 BÁWO NI IBÀ ṢE Ǹ WỌNÚ ARA ÈÈYÀN?
  • 3 BÁWO LO ṢE LÈ DÁÀBÒ BO ARA RẸ?
  • A Pa Dà sí Ẹsẹ̀ Àárọ̀ Nínú Bíbá Ibà Jà
    Jí!—1997
  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Kòkòrò Àfòmọ́!
    Jí!—1999
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Àrùn Àtọ̀sí Ajá—Òpin Rẹ̀ Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—2015
g 9/15 ojú ìwé 12-15

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà

Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé lọ́dún 2013, ohun tó lé ní 198,000,000 èèyàn ni àìsàn ibà ṣe. Nínú wọn, nǹkan bíi 584,000 ni àìsàn náà pa. Èyí tó ju 465,000 nínú wọn ló sì jẹ́ ọmọdé tí kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún. Àìsàn ibà wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tó ọgọ́rùn-ún [100] kárí ayé, èyí fi hàn pé nǹkan bíi 3,200,000,000 èèyàn ló wà nínú ewu àìsàn ibà.

1 KÍ NI ÀÌSÀN IBÀ?

Kòkòrò àrùn kan ló ń fa ibà. Ibà sì máa ń fa àwọn àárẹ̀ bí ara gbígbóná, òtútù, kéèyàn máa làágùn, ẹ̀fọ́rí, ara ríro, kí èébì máa gbé èèyàn tàbí kéèyàn tiẹ̀ máa bì pàápàá. Àwọn àárẹ̀ yìí sábà máa ń fara hàn láàárín ọjọ́ méjìméjì sí mẹ́tamẹ́ta. Ohun tó máa ń pinnu èyí ni irú kòkòrò àrùn ibà tó wọnú ara àti ìgbà téèyàn ní àìsàn náà kẹ́yìn.

2 BÁWO NI IBÀ ṢE Ǹ WỌNÚ ARA ÈÈYÀN?

  1. Tí abo ẹ̀fọn kan tí wọ́n ń pè ní Anopheles bá jẹ èèyàn, ńṣe ló máa ń pọ àwọn kòkòrò àrùn kan tí wọ́n ń pè ní Plasmodia sínú ara ẹni náà.

  2. Àwọn kòkòrò àrùn yìí máa wá lọ kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀dọ̀, wọ́n á sì máa pọ̀ sí i níbẹ̀.

  3. Tí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀dọ̀ táwọn kòkòrò àrùn yìí kó sí bá bẹ́, ńṣe ni wọ́n á tú àwọn kòkòrò àrùn náà jáde. Àwọn kòkòrò àrùn yìí á wá lọ kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa, wọ́n á sì tún máa pọ̀ sí i níbẹ̀.

  4. Tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa táwọn kòkòrò àrùn yìí kó sí bá bẹ́, ńṣe làwọn náà máa tú àwọn kòkòrò àrùn náà jáde. Àwọn kòkòrò àrùn yìí á wá lọ máa kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa míì, wọ́n á sì máa pọ̀ sí i.

  5. Bí àwọn kòkòrò àrùn yìí á ṣe máa kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa lọ nìyẹn. Gbogbo ìgbà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa bá bẹ́ ni ẹni náà á máa nímọ̀lára àárẹ̀ tí ibà ń fà.

3 BÁWO LO ṢE LÈ DÁÀBÒ BO ARA RẸ?

Tó o bá ń gbé níbi tí ẹ̀fọn pọ̀ sí . . .

  • Lo nẹ́ẹ̀tì apẹ̀fọn. Àmọ́ rí i dájú pé

    • nẹ́ẹ̀tì náà ní oògùn ẹ̀fọn lára.

    • kò fàya, kò sì ní ihò tí ẹ̀fọn lè gbà wọlé.

    • o ki nẹ́ẹ̀tì náà bọ abẹ́ bẹ́ẹ̀dì dáadáa, kò máa baà ní àlàfo èyíkéyìí.

  • Máa lo oògùn ẹ̀fọn déédéé.

  • Tó bá ṣeé ṣe, fi nẹ́ẹ̀tì sí ojú wíńdò àti ẹnu ọ̀nà. Kó o sì tan ẹ̀rọ amúlétutù tàbí fáànù, torí kò ní jẹ́ káwọn ẹ̀fọn máa fò káàkiri.

  • O lè wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àmọ́ tó bo gbogbo ara.

  • Yẹra fún àwọn ibi tí ẹ̀fọn máa ń pọ̀ sí, irú bí ibi tí omi dárogún sí.

  • Tí ẹ̀fọn bá jẹ ẹ́, tètè lọ tọ́jú ara rẹ.

Tó o bá fẹ́ lọ sí ìlú tí ẹ̀fọn pọ̀ sí . . .

Ẹnì kan lè kó àìsàn ibà tí ẹ̀fọn tó ti ní kòkòrò àrùn tó ń fa ibà bá jẹ ẹ́. Lọ́wọ́ kejì, ẹ̀fọn tí kò ní kòkòrò àrùn ibà lè kó o látara èèyàn tó ti ní àìsàn náà lára. Tí ẹ̀fọn náà bá wá jẹ ẹlòmíì, ó máa kó àìsàn ibà ran ẹni náà

  • Kọ́kọ́ wádìí nípa bí àdúgbò náà ṣe rí kó o tó lọ. Torí pé irú kòkòrò àrùn ibà tó wọ́pọ̀ ní àdúgbò kan lè yàtọ̀ síbòmíì, èyí ló sì máa pinnu irú oògùn ibà tó o máa lò níbẹ̀. Bákan náà, ó máa dáa kó o bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ kó lè ṣàlàyé ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn nítorí ìlera rẹ.

  • Tó o bá dé àdúgbò náà, rí i dájú pé o tẹ̀ lé àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, èyí tá a dìídì ṣe fún àwọn tó ń gbé ní àdúgbò tí ẹ̀fọn pọ̀ sí.

  • Tí ẹ̀fọn bá jẹ ẹ́, tètè tọ́jú ara rẹ. Torí pé, ó lè tó ọ̀sẹ̀ kan sí ọ̀sẹ̀ mẹ́rin lẹ́yìn tí ẹ̀fọn jẹ ẹ́ kó o tó mọ̀ pé o ti ní àìsàn ibà.

OHUN TÓ O TÚN LÈ ṢE

  1. Máa jàǹfààní lára àwọn ètò tí ìjọba ṣe fún ìtọ́jú ìlera.

  2. Ra oògùn níbi tí wọ́n ti ń ta ojúlówó. (Téèyàn bá lo ayédèrú oògùn, kò ní jẹ́ kí àìsàn náà lọ bọ̀rọ̀, kódà ó lè pààyàn.)

  3. Jẹ́ kí àyíká ilé rẹ wà ní mímọ́ nígbà gbogbo.

Tó bá jẹ́ àdúgbò tí àwọn ẹ̀fọn pọ̀ sí lò ń gbé tàbí tó o ti gbé ibẹ̀ rí, tètè tọ́jú ara rẹ tó o bá kíyèsí àwọn nǹkan yìí . . .

  • Ara gbígbóná

  • Òógùn

  • Òtútù

  • Ẹ̀fọ́rí

  • Ara ríro

  • Kó máa rẹ̀ èèyàn

  • Kí èébì máa gbéni

  • Kéèyàn máa bì

  • Ìgbẹ́ gbuuru

Tí èèyàn kò bá tọ́jú ara rẹ̀, àìsàn ibà lè mú kí ẹ̀jẹ̀ gbẹ lára, èyí sì lè la ẹ̀mí lọ. Torí náà, tètè wá ìtọ́jú kí àìsàn náà tó wọ̀ ẹ́ lára, ní pàtàkì àwọn ọmọdé àtàwọn aláboyún.a

a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i lórí kókó yìí, yìí, wo Jí! November 2011, ojú ìwé 24-25, àti Jí! November 2009, ojú ìwé 26-29 ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

ǸJẸ́ O MỌ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ní ilẹ̀ áfíríkà, àìsàn ibà máa ń pa ọmọ kan ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan

  • Àìsàn ibà kì í lọ bọ̀rọ̀ lára àwọn ọmọdé àtàwọn aláboyún.

  • Ní ilẹ̀ Áfíríkà, àìsàn ibà máa ń pa ọmọ kan ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan.

  • Àwọn míì máa ń kó àìsàn ibà látinú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà sí wọn lára, àmọ́ ìyẹn kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́