ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/22 ojú ìwé 31
  • A Pa Dà sí Ẹsẹ̀ Àárọ̀ Nínú Bíbá Ibà Jà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Pa Dà sí Ẹsẹ̀ Àárọ̀ Nínú Bíbá Ibà Jà
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Lílo Àpò Ẹ̀fọn
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà
    Jí!—2015
  • Ayé Kan Níbi Tí Kò Ti Ní Sí Àrùn
    Jí!—2004
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Ọjọ́ Pẹ́ Táráyé Ti Ń Gbógun Ti Àrùn
    Jí!—2004
Jí!—1997
g97 7/22 ojú ìwé 31

A Pa Dà sí Ẹsẹ̀ Àárọ̀ Nínú Bíbá Ibà Jà

Pẹ̀lú bí gbogbo ayé ti darí àfiyèsí sí àwọn ogun abẹ́lé, ìwà ọ̀daràn, àìríṣẹ́ṣe, àti àwọn rògbòdìyàn míràn, agbára káká la fi ń gbọ́ nípa àwọn tí ibà ń pa ní àkókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ ń gbọ́ ìròyìn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ pé, síbẹ̀síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì lára gbogbo àwọn olùgbé ayé lónìí ni wọ́n wà lábẹ́ ewu ibà, tí nǹkan bí 300 mílíọ̀nù sí 500 mílíọ̀nù ènìyàn sì ń dùbúlẹ̀ àìsàn ibà lọ́dọọdún, tí èyí sì ń sọ ibà di “èyí tí ó tàn kálẹ̀ jù lọ lára gbogbo àrùn ilẹ̀ olóoru àti ọ̀kan lára èyí tí ń fa ikú jù lọ.” Báwo ló ti jẹ́ aṣekúpani tó?

Ibà ń pa ẹnì kan láàárín 20 ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan. Fígọ̀ náà ń ga pelemọ dé iye tí ó lé ní mílíọ̀nù 1.5 ènìyàn tí ń kú lọ́dọọdún—tí ó dọ́gba pẹ̀lú iye gbogbo àwọn olùgbé Botswana ní Áfíríkà. Mẹ́sàn-án lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ikú mẹ́wàá tí ibà ń fà ló ń ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè olóoru Áfíríkà, tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń kú jẹ́ ọmọ kéékèèké. Ní àwọn ilẹ̀ America, àjọ WHO ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ibà gíga jù lọ ní àgbègbè Amazon. Ìpagbórun àti àwọn ìyípadà míràn nínú àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ti ní ìyọrísí ibi tí ń pọ̀ sí i ní ti àwọn tí ibà pa ní apá yẹn nínú ayé. Ní àwọn ibì kan ní àwọn àwùjọ tí ń gbé inú igbó Amazon ní Brazil, ìṣòro náà ti wá le gan-an débi pé ó ti ṣe àwọn tí ó lé ní 500 lára 1,000 olùgbé ibẹ̀.

Yálà ní Áfíríkà ni tàbí ní àwọn ilẹ̀ America, Éṣíà, tàbí ibòmíràn, àwùjọ àwọn tí wọ́n tòṣì jù lọ ni ibà máa ń kọ lù. Àjọ WHO sọ pé, àwọn ènìyàn wọ̀nyí “kò fi bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní àtirí ìpèsè ìlera, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lè pèsè ààbò ara ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ fúnra wọn àwọn sì ni wọ́n jìnnà jù lọ sí ìṣètò kíkápá ìṣẹ̀lẹ̀ ibà.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ipò aburú tí àwọn aláìní wọ̀nyẹn wà kò ṣàìnírètí. TDR News, lẹ́tà ìròyìn kan lórí ìwádìí àrùn ilẹ̀ olóoru sọ pé, ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, ọ̀kan lára àwọn ìgbésẹ̀ tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ láti dènà ìṣekúpani ibà ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó lọ́pọ̀lọpọ̀. Kí ni orúkọ agbẹ̀mílà yẹn? Àpò ẹ̀fọn tí a da oògùn ẹ̀fọn sí lára.

Àǹfààní Lílo Àpò Ẹ̀fọn

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lílo àpò ẹ̀fọn jẹ́ ojútùú pípadà sí ẹsẹ̀ àárọ̀, Dókítà Ebrahim Samba, olùdarí ọ́fíìsì àjọ WHO ní Áfíríkà, wí fún Panos Features, lẹ́tà ìròyìn kan tí ó jẹ́ ti Àjọ Panos, pé, àwọn ìgbìyànjú láti dán bí àwọn àpò ẹ̀fọn náà ṣe gbéṣẹ́ tó wò, nínú ìjà tí a ń bá ibà jà, ti fi “àbájáde tí ń rùmọ̀lára sókè gan-an” hàn. Fún àpẹẹrẹ, ní Kenya, lílo àwọn àpò ẹ̀fọn tí a da oògùn tí kò lè ṣèpalára fúnni sí lára ti dín àròpọ̀ àwọn tí ń kú láàárín àwọn ọmọdé tí wọn kò tí ì pé ọdún márùn-ún kù ní ìdámẹ́ta, kì í ṣe àwọn tí ibà ń pa nìkan. Ní àfikún sí gbígba ẹ̀mí là, “àwọn àpò ẹ̀fọn lè dín ẹrù ìnira tó wà lórí ìpèsè ìlera kù tegbòtigaga” nítorí pé ìwọ̀nba àwọn aláìsàn díẹ̀ ni yóò ní láti gba ìtọ́jú àìsàn ibà nílé ìwòsàn.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò tí ì yanjú ìṣòro kan: Ta ni yóò sanwó àwọn àpò ẹ̀fọn náà? Nígbà tí a ní kí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ṣètìlẹ́yìn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn fà sẹ́yìn. Kò yani lẹ́nu, fún àwọn ènìyàn tí ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tí ń ná owó tí kò tó dọ́là 5 (ti U.S.) lórí àbójútó ìlera ènìyàn kọ̀ọ̀kan lọ́dún, kódà àpò ẹ̀fọn kan—yálà ó ní oògùn ẹ̀fọn tàbí kò ní—jẹ́ afẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ìgbésẹ̀ ìdènà àrùn yí yóò ti ná ìjọba ni owó tí kò tó iye tí wọn óò fi wo àwọn aláìsàn ibà, àwọn ògbógi nínú àjọ UN sọ pé, “yóò jẹ́ ọ̀nà ṣíṣún owó ìjọba tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ná, láti pín àwọn àpò ẹ̀fọn tí wọ́n da oògùn ẹ̀fọn sí lára, kí wọ́n sì fowó ṣètìlẹ́yìn.” Ní gidi, fún àwọn ìjọba, pípèsè àpò ẹ̀fọn lè jẹ́ ọ̀nà kan láti ṣúnwó ná. Síbẹ̀síbẹ̀, fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tálákà ọmọ abẹ́ ìjọba wọn, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ—ó jẹ́ ọ̀nà láti gba ẹ̀mí wọn là.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

CDC, Atlanta, Ga.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́