Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Nov. 15
“Àwọn kan máa ń ronú pé kò pọn dandan kéèyàn máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ilé ìjọsìn kan kó tó lè sin Ọlọ́run. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. [Ka Ìṣe 17:24.] Kí ni ète tó yẹ kí àwọn ilé ìjọsìn wà fún nígbà náà? Ìwé ìròyìn yìí pèsè ìdáhùn tó bá Ìwé Mímọ́ mu.”
Ilé Ìṣọ́ Dec. 1
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹnì kankan tí ìṣòro owó kì í bá fínra lóde òní. Ìṣòro ọ̀hún kò yọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì pàápàá sílẹ̀ o, nítorí bí wọ́n ṣe ń bẹ̀bẹ̀ fún owó ti wá ń di lemọ́lemọ́ báyìí. Ṣé ìyẹn máa ń kó ìdààmú bá ọ? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka 1 Tẹsalóníkà 2:9.] Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa èyí.”
Jí! Dec. 8
“Nítorí ìbẹ̀rù àwọn apániláyà, ọ̀pọ̀ ló ń ṣe kàyéfì bóyá èèyàn ṣì lè wọ ọkọ̀ òfuurufú láìsí ìbẹ̀rù. Kí lo rí sí èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò sẹ́nì kankan tó bọ́ lọ́wọ́ jàǹbá àìròtẹ́lẹ̀. [Ka Oníwàásù 9:11.] Àmọ́ ṣá o, ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ ohun tó o lè ṣe láti túbọ̀ bọ́ lọ́wọ́ ewu tó o bá ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òfuurufú, àti láti túbọ̀ mú kí ìrìn àjò náà tù ọ́ lára.”