Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Nov. 1
“Ǹjẹ́ o rò pé bí ọkọ àti aya bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò, ìdè ìgbéyàwó wọn á túbọ̀ lágbára sí i? [Ka Jóòbù 31:1. Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ran ọkọ àti aya lọ́wọ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn.” Sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 18.
Ilé Ìṣọ́ Dec. 1
“Lásìkò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ronú nípa Jésù. Ipa wo lo lè sọ pé Jésù ní lórí ẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. [Ka 1 Pétérù 2:21.] Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà wa á túbọ̀ dára sí, a ó sì túbọ̀ máa láyọ̀. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.”
Jí! Oct.–Dec.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn látinú onírúuru ẹ̀sìn ló ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an. Àmọ́, báwo ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe Rẹ̀? Kíyè sí ohun tí Jésù sọ ní Jòhánù 4:24. [Kà á.] Ojú ìwé méjì péré ni àpilẹ̀kọ yìí fi ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ lórí ìbéèrè náà, Irú ẹni wo ni Ọlọ́run?” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 16 àti 17 hàn án.
“Ǹjẹ́ o mọ Àdúrà Olúwa dáadáa? Ó wà ní Mátíù 6:9-13. Ǹjẹ́ o kíyèsí ohun tí ẹsẹ kẹwàá sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú kó ṣeé ṣe? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 7 nínú ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí ayé yìí ṣe máa rí tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé.”