Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Nov. 15
“Gbogbo wa la fẹ́ káyé wa dùn bí oyin, kó sì nítumọ̀. Ṣó o gbà pé ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ló ń fúnni láyọ̀? [Ka Mátíù 5:3, kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí ayé wa ṣe lè dùn bí oyin bá ba ń jọ́sìn Ọlọ́run tọkàntọkàn.”
Ile Iṣọ Dec. 1
“Kí ni ìdáhùn ẹ sí ìbéèrè yìí? [Ka ìbéèrè tó wà ní ẹ̀yìn ìwé ìròyìn yìí, kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ohun tó wu Ọlọ́run ni pé kí gbogbo èèyàn wà níṣọ̀kan. [Ka Sáàmù 46:8, 9.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa bí gbogbo èèyàn ṣe máa wà ní ìṣọ̀kan.”
Jí! Oct.–Dec.
“Ṣé o rò pé àwọn ọmọ òde òní wà nínú ewu tó ju tàwọn ọmọ àtijọ́ lọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ gbà pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní ló wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. [Ka 2 Tímótì 3:1-5.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun táwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe.”
“Gbogbo wa la léèyàn tó ti ṣaláìsí rí. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé o rò pé wọ́n ń wò wá látòde ọ̀run? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ nígbà tí Lásárù kú. [Ka Jòhánù 11:11.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ipò táwọn òkú wà, bóyá wọ́n ń gbé níbòmíì ni àbí ńṣe ni wọ́n ń sinmi títí dìgbà àjíǹde.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 30 hàn án.