Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Nov. 15
“Pẹ̀lú bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbòde kan yìí, àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Kí nìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ tiraka láti máa ṣe ohun tó tọ́?’ Ṣó ti ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. [Ka Òwe 2:21, 22.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí pàtàkì jù lọ tó fi yẹ kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́.”
Ile Iṣọ Dec. 1
“Ṣó o rò pé àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì yìí ti ń nímùúṣẹ lónìí? [Ka Mátíù 24:11, kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ kan tó ti tàn kálẹ̀. Ó tún fi hàn bá a ṣe lè máa ṣọ́ra káwọn olùkọ́ èké má bàa rí wa tàn jẹ.”
Jí! Oct.-Dec.
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni téèyàn ẹ̀ kan ò kú rí nínú wa. Ṣó o rò pé nǹkan kan wà tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti kú? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí dáhùn ìbéèrè yẹn. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tó ń tuni nínú tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí.” [Ka Jòhánù 5:28, 29. Kó o wá fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 24 hàn án.]