Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Nov. 15
“Láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ayé wa yìí á di Párádísè. Àmọ́, lónìí, àwọn kan ń ṣe kàyéfì pé ó lè jẹ́ ìparun ló máa gbẹ̀yìn ayé ọ̀hún. Kí lèrò tìẹ nípa ibi táyé yìí ń lọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa èyí. [Ka Sáàmù 37:11.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé síwájú sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ayé wa yìí.”
Ilé Ìṣọ́ Dec. 1
“Lóde ìwòyí, àwọn èèyàn kan ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìgbàgbọ́ mọ́ nínú Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ohun tó fa èyí ni pé wọn kò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tí ń da ọkàn wọn láàmú. Díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè náà nìyí. [Fún un ní àpẹẹrẹ kan látinú àpótí tó wà ní ojú ìwé 6.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò ohun kan tó ṣe pàtàkì bí a bá fẹ́ ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.” Ka Fílípì 1:9.
Ji Dec. 8
“Ṣé o lérò pé ìgbà kan ń bọ̀ tí aráyé á gbádùn àwọn ipò tó dà bí èyí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ níhìn-ín? [Ka Aísáyà 14:7, kí o sì jẹ́ kó fèsì.] Ìsọfúnni wíwúlò tó lè ṣe wá láǹfààní bí a ṣe ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run wà nínú ìwé ìròyìn yìí.” Fi àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Lo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?” hàn án.