Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Nov. 15
“Ọ̀pọ̀ ló ń ṣe kàyéfì nípa báwọn ìṣòro tó ń yọ aráyé lẹ́nu ṣe dà bíi pé ó ń burú sí i dípò kó máa dín kù. Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí ronú lórí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ló fà á tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀? [Ka Ìṣípayá 12:9. Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn ọ̀nà àrékérekè tí Èṣù ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, ó sì tún sọ ohun tá a lè ṣe tí kò fi ní rí wa mú.”
Ile Iṣọ Dec. 1
“Nígbà táwọn èèyàn bá gbọ́ ‘Amágẹ́dọ́nì,’ ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń rò pé ìpakúpa ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. [Fi àpótí tó wà lójú ìwé 3 hàn án.] Ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé ọ̀kan lára ohun táá ṣe wá láǹfààní jù lọ bó bá ṣẹlẹ̀ ni Amágẹ́dọ́nì? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.” Ka 2 Pétérù 3:13.
Jí Dec. 8
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tí gbogbo èèyàn á jẹ́ ní àjẹtẹ́rùn wà, síbẹ̀ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ mílíọ̀nù èèyàn ni kì í rí oúnjẹ jẹ kánú. Ǹjẹ́ ìyẹn ò ṣèèyàn ní kàyéfì? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí ọ̀ràn ìṣòro àìróúnjẹ jẹ tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, èyí tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú ńlá. Ó tún jíròrò ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé ayé kan ń bọ̀ tí kò ti ní sí pé ebi ń pààyàn.” Ka Sáàmù 72:16a.
“Mo fẹ́ láti sọ fún ọ nípa àkókò kan tí kálukú á ní ibùgbé tó dáa. Etí wo ló ń gbọ́ ọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò rílé gbé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka, Aísáyà 65:21, 22.] Ìwé ìròyìn ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lórí àwọn ohun tó ń fa àìrílégbé. Ó sì tún ṣàlàyé ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà mú ìlérí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí ṣẹ.”