Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Nov. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ kí ara àwọn dá ṣáṣá kí ẹ̀mí àwọn sì gùn. Ṣùgbọ́n ká ní ó ṣeé ṣe, ṣé wàá fẹ́ wà láàyè títí láé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Jòhánù 17:3.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìlérí ìyè ayérayé tó wà nínú Bíbélì. Ó tún sọ bí ìgbésí ayé ṣe máa dùn tó nígbà tí ìlérí yẹn bá ṣẹ.”
Ile Ìṣọ́ Dec. 1
“Ohun kan tí àwa ẹ̀dá èèyàn fi yàtọ̀ sí àwọn ẹranko ni pé a mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ohun búburú ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe. Kí lo rò pé ó fa èyí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Jeremáyà 17:9 tàbí Ìṣípayá 12:9.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè mọ ohun tó tọ́ àti bá a ṣe lè máa ṣe é.”
Jí! Dec. 8
“Láti nǹkan bí ogún ọdún wá, ìmọ̀ àwọn oníṣègùn nípa àrùn éèdì àti bí wọ́n ṣe lè tọ́jú rẹ̀ ti jinlẹ̀ sí i. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ò tíì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa àrùn yìí. [Fi àpótí tó ní àkọlé náà “Àwọn Èrò Èké Nípa Àrùn Éèdì” han onílé, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn.” Ka Diutarónómì 6:6, 7.
“Òótọ́ ni pé aráyé ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ, síbẹ̀ èyí ò lè rọ́pò báwa èèyàn ṣe ń bá ara wa ṣọ̀rẹ́. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé bí ayé ṣe ń yí padà lónìí lè máà jẹ́ kó rọrùn fún àwọn èèyàn láti ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 18:24.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi, kí ọ̀rẹ́ wa má sì já.”