Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Dec. 15
“Nírú àkókò yìí nínú ọdún, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú nípa ìbí Jésù. Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé irú ìdílé wo ló ti dàgbà? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Lúùkù 2:51, 52.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ wíwúlò tá a lè rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa bá a ṣe tọ́ Jésù dàgbà.”
Ilé Ìṣọ́ Jan. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ lójú méjèèjì pé kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ o rò pé ọjọ́ kan á jọ́kan tí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí á nímùúṣẹ? [Ka Sáàmù 46:9. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò bí èyí ṣe máa rí bẹ́ẹ̀ àti ìdí tá a fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ayé kan tí kò ti ní sí ogun.”
Jí! Jan. 8
“Gbogbo wa là ń fẹ́ pé kí ayé àwọn ọmọ wa dùn kó sì lárinrin. Kí lo rò pé àwọn ọmọdé nílò jù láti kojú ayé oníwàhálà táà ń gbé lónìí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 22:6.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò ohun tí àwọn ọmọdé nílò àti bí àwọn òbí ṣe lè ṣe é fún wọn.”
Jí! Jan. 8
“Jákèjádò ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ló ní ìṣòro tó ń nípa lórí ìmọ̀lára, irú bí àárẹ̀ ọkàn àti àárẹ̀ ọpọlọ. Ẹlẹ́dàá wa bìkítà púpọ̀ púpọ̀ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. [Ka Sáàmù 34:18.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bí àwọn tí ìṣòro yìí ń bá fínra ṣe lè rí ìrànwọ́ gbà. Ó tún sọ nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe pé láìpẹ́ gbogbo àìsàn pátá ló máa di àwátì.”