Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Dec. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn áńgẹ́lì kéde lọ́jọ́ tí wọ́n bí Jésù. [Ka Lúùkù 2:14.] Ǹjẹ́ o rò pé lóòótọ́ ni àlàáfíà ń bọ̀ wá jọba lórí ilẹ̀ ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bí Jésù ṣe máa mú kí àlàáfíà jọba lórí ilẹ̀ ayé.”
Jí! Oct.-Dec.
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sẹ́ni tí kì í wo tẹlifíṣọ̀n. Ṣùgbọ́n ṣó o rò pé ó yẹ ká fiyè sí iye àkókò tá à ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Òwe 14:15.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká gbéṣirò lé àkókò tá à ń lò nídìí ẹ̀, ó sì fún wa láwọn àbá tá ò fi ní máa wò ó ju bó ṣe yẹ lọ.”
Ile Iṣọ Jan. 1
“Ǹjẹ́ dúkìá rẹpẹtẹ la fi ń mọ ẹni táyé yẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 1 Tímótì 6:9, 10.] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ pé ó burú kéèyàn lówó, síbẹ̀ ó jẹ́ ká mọ̀ pé ọrọ̀ kọ́ la fi ń mọ̀ báyé bá yẹ èèyàn. Ìwé ìròyìn yìí sọ bó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
Jí! Jan.-Mar.
“Ṣó o rò pé ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí máa ṣẹ lóòótọ́? [Ka Aísáyà 33:24. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí ìmọ̀ ìṣègùn ti gbé ṣe, ó sì sọ bí àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì ṣe máa ṣẹ.”