Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Dec. 15
“Ní àkókò tá a wà yìí nínú ọdún, ọ̀pọ̀ máa ń ronú nípa ìbí Jésù. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye wà tá a lè rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìbí rẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà tọ́ka sí ojú ìwé 5, kó o sì ka 2 Tímótì 3:16.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí.”
Ilé Ìṣọ́ Jan. 1
“Nígbà tí èèyàn ẹni bá kú tàbí tó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, a sábà máa ń ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú nǹkan yìí?’ Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti béèrè irú ìbéèrè yẹn rí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ìyọ́nú fún àwọn ẹni tó ń fara da ìnira èyíkéyìí. [Ka Aísáyà 63:9a.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò fi òpin sí ìnira.”
Jí! Jan. 8
“Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ kí ìjọba máa ṣèdíwọ́ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ká ní irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ mọ́ bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìsìn ńkọ́, gẹ́gẹ́ bí ibi tá a fẹ́ kà yìí ti fi hàn? [Ka Ìṣe 28:30, 31.] Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n gbé ìbéèrè yìí wá síwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. A rọ̀ ọ́ pé kó o kà nípa kókó yìí nínú ìtẹ̀jáde Jí! yìí.”