Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Dec. 15
“Lọ́dọọdún, tó bá ti di àsìkò yìí, onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà ṣèrántí ibi Jésù kárí ayé. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbà tí Bíbélì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí Jésù, ó sọ pé ìṣàkóso Jésù ni yóò mú kí àlàáfíà tí kò lópin wà? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Aísáyà 9:6, 7.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àlàáfíà yẹn ṣe máa dé orí ilẹ̀ ayé.”
Ile Ìṣọ́ Jan. 1
“Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹ̀sìn àgbáyé ló ń kọ́ àwọn èèyàn pé ó yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. [Ka Mátíù 22:39.] Àmọ́, kí lo rò pé ó fà á tó fi jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn ló ń fa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ogun àti rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ láyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí dáhùn ìbéèrè kan lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn ni pé, Ǹjẹ́ ìsìn lè mú kí aráyé ṣọ̀kan?”
Jí! Jan. 8
“Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé ohun tó gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn jù lọ lónìí ni bí ìrísí wọn ṣe rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn ewu téèyàn lè kó sí tó bá jẹ́ kí ẹwà gba òun lọ́kàn. Ó tún sọ bí ẹwà tó ṣe pàtàkì jù lọ ṣe níye lórí tó.” Ka 1 Pétérù 3:3, 4.
“Báwo lo ṣe máa dáhùn ìbéèrè yìí? [Ka ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ńṣe làwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé túbọ̀ ń dín kù sí i ṣá. Síbẹ̀, kíyè sí ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí. [Ka Sáàmù 104:5.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa mú kí ilẹ̀ ayé wa yìí padà di bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ láìpẹ́.”