Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Dec. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń hùwà rere tí wọ́n sì máa ń ṣàánú ọmọnìkejì wọn nígbà ọdún. Ṣó o rò pé ayé á sàn jù báyìí lọ bó bá jẹ́ pé ojoojúmọ́ làwọn èèyàn ń ṣàánú ọmọnìkejì wọn? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 1 Pétérù 3:8.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ṣàánú, ó sì mẹ́nu kan díẹ̀ lára ọ̀nà téèyàn lè gbà máa ṣàánú.”
Ile Iṣọ Jan. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Bí àpẹẹrẹ, fetí sí àdúrà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó yìí tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. [Ka Mátíù 6:9, 10.] Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ ohun tí Ìjọba náà jẹ́ àti ìgbà tó máa dé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn náà.”
Jí! Oct.–Dec.
“Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí má máa dá àwọn ọmọ wọn dá ohun tí wọ́n bá ń ṣe, kí wọ́n mọ àwọn ọ̀rẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa bá wọn dá sí iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún wọn láti ilé ìwé. Ǹjẹ́ o mọ̀dí tó fi yẹ káwọn òbí máa ṣe bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Òwe 14:15.] Ìdí ni pé bọ́mọdé bá tiẹ̀ láṣọ bí àgbà, kò lè lákìísà bí àgbà, ìyẹn ló máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe láti tàn wọ́n jẹ. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bó o ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ.”
“Àwọn òbí kan máa ń rò pé àwọn ọmọ á máa bẹ̀rù àwọn láìyẹ báwọn bá ń lo àṣẹ àwọn gẹ́gẹ́ bí òbí. Kí lèrò ẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tí Bíbélì ní káwọn òbí máa ṣe fáwọn ọmọ wọn rèé. [Ka Òwe 29:17.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 23 nínú ìwé ìròyìn yìí jẹ́ káwọn òbí mọ bí wọ́n ṣe lè máa lo àṣẹ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí láì le koko ju bó ṣe yẹ lọ.”