Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Dec. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe ń fi àkókò ọdún ṣòwò. Ǹjẹ́ o rò pé ohun tó yẹ kí wọ́n fi àkókò yẹn ṣe ni wọ́n fi ń ṣe? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bí àwọn àṣà tó ń wáyé lákòókò ọdún ṣe ń yí padà bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ó sì tún jíròrò bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run àti Kristi bó ṣe yẹ.” Ka Jòhánù 17:3.
Ile Iṣọ Jan. 1
“Ẹ̀dá èèyàn lágbára láti ṣe nǹkan tó dáa, àmọ́ ìwà ibi tí wọ́n sábà máa ń hù láyé yìí ò ṣeé fẹnu sọ. Ǹjẹ́ ó ti fìgbà kan rí ṣe ọ́ bíi kó o mọ ohun tó fà á? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdáhùn tó wà nínú Bíbélì. Ó tún ṣàlàyé bí rere á ṣe borí ibi bó pẹ́ bó yá.” Ka Róòmù 16:20.
Awake! Jan.–Mar.
“Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti fìgbà kan ronú nípa bi ayé ṣe máa rí ní nǹkan bí ogún tàbí ọgbọ̀n ọdún sí àsìkò tá a wà yìí? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 119:105.] Bíbélì tànmọ́lẹ̀ sí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ká lè mọ ohun tó wà níwájú wa. Ìwé ìròyìn yìí ṣe àyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó fi ibi tá a wà nínú ìṣàn àkókò hàn àti ìdí tá a fi lè máa retí ọjọ́ ọ̀la tó sàn jù.”
“Ní nǹkan bí ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún sẹ́yìn, àjàkálẹ̀ àrùn kan pa èèyàn tó pọ̀ gan-an láàárín oṣù mẹ́fà péré ju iye tí àrùn éèdì pa láàárín ọdún mẹ́rìnlélógún lọ. Àwọn kan ní àrùn yìí tíì burú jù nínú ìtàn. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa àrùn gágá rí. [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bóyá irú ẹ̀ tún lè ṣẹlẹ̀. Ó tún ṣàlàyé ohun tó máa mú ká nírètí.” Ka Aísáyà 33:24.