ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/8 ojú ìwé 20-23
  • Kíkojú Ìkọlù Ìpayà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkojú Ìkọlù Ìpayà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Ń Fa Ìpayà?
  • Orísun Ìpayà
  • Ó Ha Ṣeé Wò Sàn Bí?
  • Ìṣòro Tẹ̀mí Ha Ni Bí?
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Bí Wọ́n Ṣe Borí Jìnnìjìnnì Tó Bá Wọn Nígbà Táwọn Apániláyà Yin Bọ́ǹbù
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/8 ojú ìwé 20-23

Kíkojú Ìkọlù Ìpayà

Robert jókòó tìdẹ̀ratìdẹ̀ra nínú ọ́fíìsì rẹ̀. Lójijì ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yára lù kìkì. Ó jókòó sára lójijì bí òógùn ti ń dà níwájú orí rẹ̀. Ó dá Robert lójú pé àrùn ọkàn ló ń ṣe òun! Ó ki tẹlifóònù mọ́lẹ̀. Ó ń mí pàkà bí ó ti ń wí pé: “Ohun bíbanilẹ́rù kan ń ṣe mí. Ó jọ pé mo fẹ́ dá kú!”

ÌRÍRÍ ìkọlù ìpayà tí Robert kọ́kọ́ ní nìyí. Ó bani nínú jẹ́ pé kò mọ sórí èyí. Ohun kan náà tún ṣẹlẹ̀ sí i ní ilé àrójẹ kan àti ní ibùdó ìtajà kan. Ìpayà náà tilẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wò. Láìpẹ́ láìjìnnà, ilé nìkan ni ibi “ààbò” tí Robert ní. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sorí kọ́. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo tilẹ̀ ti ronú pípa ara mi.”

Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ni Robert ṣèèṣì rí àpilẹ̀kọ inú ìwé agbéròyìnjáde kan tí ó sọ nípa ìpayà àti ìbẹ̀rùbojo. Ohun tí ó kọ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

Kí Ló Ń Fa Ìpayà?

Ìhùwàpadà ara lọ́nà títọ́ sí ewu ní ń jẹ́ ìpayà. Finú wòye pé o ń ré òpópónà kan kọjá. Lójijì ni o ṣàkíyèsí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ó dojú kọ ọ́ bí ó ti ń sáré bọ̀. Ìyípadà ojú ẹsẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí àti ti kẹ́míkà nínú ara rẹ yóò jẹ́ kí o lè sáré bẹ́ dànù síbi ààbò.

Àmọ́ wá finú wòye ìmọ̀lára ìpayà yìí kan náà láìsí okùnfà kankan tí ó hàn sóde. Dókítà R. Reid Wilson sọ pé: “Ìkọlù ìpayà máa ń wá nígbà tí ìpayà bá tan ọpọlọ jẹ láti ronú pé ewu kan rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ká sọ pé o wà láàárín ilé ìtajà wóróbo kan, tí o kò sì fara gbún ẹnikẹ́ni. Àfi bìrí. Ìyípadà Pàjáwìrì náà ṣẹlẹ̀. ‘Ìkìlọ̀ ró! Gbogbo ìgbékalẹ̀ ẹ̀yà ara gbaradì fún ogun!’”

Kìkì àwọn tí wọ́n ti nírìírí irú ìkọlù bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lè lóye lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa bí ó ṣe le tó. Ìwé ìròyìn American Health ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìgbérasọ omi ìsúnniṣe adrenaline tí ó kù gìrì kọjá lára rẹ fún ìṣẹ́jú márùn-ún tàbí wákàtí kan tàbí ọjọ́ kan, yóò sì lọ kíákíá àti lọ́nà àràmàǹdà tí ó gbà wá, yóò sì sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀, tí a tán lókun, tí ó sì ń fòyà ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e.”

Orísun Ìpayà

Ìpayà sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù ìgbà ìdàgbà di géńdé, ó sì ń ṣẹlẹ̀ sí obìnrin púpọ̀ ju ọkùnrin lọ. Kí ló ń fà á? Kò sí ìdáhùn pàtó. Àwọn kan sọ pé àwọn tí ó máa ń ṣe ní ìtẹ̀sí sí i lọ́nà ti ẹ̀dá nítorí àìṣedéédéé nínú ìgbékalẹ̀ ìpẹ̀ka ọpọlọ. Àwọn púpọ̀ lérò pé a lè jogún ipò yìí, nígbà tí àwọn mìíràn sì sọ pé àwọn kókó abájọ tí ń ṣokùnfà másùnmáwo ló ń yí ìṣiṣẹ́ ọpọlọ padà.

Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn ìrírí oníhílàhílo bí ogun, ìfipábánilòpọ̀, tàbí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, ló máa ń mú ìkọlù náà wá. Ìwádìí kan fi hàn pé iye ìpín ọ̀rún àwọn tí ìbátan kan ti bá ṣèṣekúṣe rí, tí wọ́n ní àrùn ìpayà, fi ìlọ́po 13 ju ti àwọn tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ sí. Ní tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkọlù ìpayà àti àwọn àmì míràn ti jẹ́ ìṣòro ńlá pátápátá ní tiwọn, wọ́n tún lè jẹ́ ohun tí òǹkọ̀wé E. Sue Blume pè ní “irin àgbá kẹ̀kẹ́ tí bíbá ìbátan ṣèṣekúṣe kún ìgbátí rẹ̀.”

Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo ìpayà ni hílàhílo máa ń fà. Àmọ́, Dókítà Wayne Kritsberg kìlọ̀ pé bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, “títọ́jú ìpayà—dípò wíwo hílàhílo gidi náà sàn—kò ní yanjú ìṣòro náà pátápátá. Yóò wulẹ̀ dà bíi lílo egbòogi ikọ́ fún òtútù àyà.”

Ó Ha Ṣeé Wò Sàn Bí?

A lè mú ìpayà wá sábẹ́ àkóso. Ìtọ́jú wíwà nínú ipò náà ti ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ àwọn tí ìbẹ̀rù ìpayà ti dá jókòó sílé. Nínú ìtọ́jú yìí, wọ́n fi agbàtọ́jú sínú ipò tí ó máa ń bẹ̀rù náà, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti wà níbẹ̀ títí ìpayà yóò fi pòórá. Àwọn tí wọ́n ní àrùn ọkàn, ikọ́ fée, ọgbẹ́ inú, ìwúlé ìfun ńlá, tàbí àwọn àrùn jíjọra gbọ́dọ̀ rí dókítà kí wọ́n tó gbìyànjú ọ̀nà ìtọ́jú yìí.

A lè lo ìlànà ìséraró láti dín ìkórajọ hílàhílo kù.a A jíròrò díẹ̀ lára wọn nínú àpótí náà, “Àwọn Ìlànà Ìmúrọlẹ̀.” Àmọ́, má ṣe dúró di ìgbà tí ìpayà náà yóò bẹ̀rẹ̀. Yóò dára jù lọ láti lo àwọn ìlànà yìí lákòókò tí hílàhílo kò tí ì di púpọ̀. Bí a bá ti mọwọ́ wọn dáadáa, wọ́n lè bu ìkọlù tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ kù tàbí kí wọ́n dènà rẹ̀.

Ìpayà máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ níbi tí a bá ti ń rin kinkin mọ́ ìjẹ́pípé àti èrò àìtẹ́gbẹ́. Ẹnì kan tí ó ń ṣe sọ pé: “Nígbà tí mo ń ní ìkọlù hílàhílo, Ọ̀gbẹ́ni Èrò Òdì ṣàkóso ìgbésí ayé mi. Mo sọ fún ara mi pé nítorí pé mo ní hílàhílo, n kò tẹ́gbẹ́, àwọn ènìyàn kò sì nífẹ̀ẹ́ mi.” Yíyí irú ẹ̀mí ìrònú bẹ́ẹ̀ padà lè dín hílàhílo tí ń ṣamọ̀nà sí ìpayà kù.b

Ó ṣàǹfààní gidigidi láti finú han ọ̀rẹ́ tí a gbẹ́kẹ̀ lé nípa hílàhílo. Sísọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lè ran ẹni tí ń ṣe lọ́wọ́ láti fìyàtọ̀ sáàárín àwọn ìṣòro tí a ní láti forí tì àti àwọn ìṣòro tí a lè yanjú. A kò ní gbójú fo àdúrà dá. Orin Dafidi 55:22 sọ pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Oluwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.”

Dípò pé ìṣòro ńlá kan ṣoṣo ló ń fa ìpayà, ó sábà máa ń jẹ́ ìkójọ rẹpẹtẹ àwọn wàhálà kéékèèké, tí ó dà bí èyí tí kò já mọ́ nǹkankan—bí ipa ìgbékiri ìgbì mànàmáná kan ṣe lè jó fíùsì tí a bà lo àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ tí ó pọ̀ jù lórí rẹ̀. Ojútùú kan jẹ́ láti máa ṣàkọsílẹ̀ ìṣòro kọ̀ọ̀kan sórí káàdì atọ́ka kan, kí a sì to káàdì náà láti orí ìṣòro tí ó kéré jù lọ dórí èyí tí ó le jù lọ. Yanjú wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Kíkọ àwọn wàhálà rẹ sílẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kà wọ́n sí ohun tí o lè kojú, tí o sì lè yanjú dípò ohun tí o bẹ̀rù, tí o sì ń yẹra fún.

Àwọn kan ti rí ìrànwọ́ gbà nípa lílo àwọn egbòogi ẹ̀rọ̀ hílàhílo tàbí ẹ̀rọ̀ ìdààmú ọkàn. Bí ó ti wù kí ó rí, ó bójú mu láti lo ìṣọ́ra. Agbaninímọ̀ràn Melvin Green sọ pé: “N kò lérò pé lílo egbòogi nìkan ni ojútùú rẹ̀. Ó yẹ kí a lò ó gẹ́gẹ́ bí àfikún nígbà tí a bá ń wá ojútùú ni. . . . Egbòogi lè jẹ́ kí o máa bá ìgbésí ayé lọ, ìyẹ́n sì lè fún ọ ní àǹfààní láti wá àwọn ìrànlọ́wọ́ mìíràn láti kojú àwọn okùnfà ìbẹ̀rùbojo, kí o sì ṣiṣẹ́ sípa rírí ìwòsàn.”

Ìṣòro Tẹ̀mí Ha Ni Bí?

Brenda sọ pé: “Ńṣe ni mo rò pé kò yẹ kí àwọn Kristian máa ní ìkọlù hílàhílo nítorí Jesu sọ pé ‘ẹ máṣe ṣàníyàn láé.’ Mo parí èrò pé ó ní láti jẹ́ pé ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Ọlọrun kò tó ni.” Síbẹ̀, àyíká ọ̀rọ̀ Jesu nínú Matteu 6:34 fi hàn pé ọ̀rọ̀ nípa àrùn ìpayà kọ́ ló ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tẹnu mọ́ ewu inú ṣíṣàníyàn nípa àwọn ohun ti ara ju tẹ̀mí lọ.

Ní tòótọ́, kódà àrùn yìí lè pọ́n àwọn tí wọ́n fi ire tẹ̀mí sí ipò kíní lójú, bí ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí nípa obìnrin kan láti Finland ṣe fi hàn.

“Èmi àti alájọṣiṣẹ́ mi, àwa méjèèjì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa, ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ẹnu-ọ̀nà-dé-ẹnu-ọ̀nà. Lójijì, òòyì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi. Ìrònú mi lọ fee. Kò jọ pé ohunkóhun jẹ́ gidi, ẹ̀rù sì ń bà mí pé mo lè ṣubú. Lẹ́nu ọ̀nà tí ó tẹ̀ lé e, pátápátá ni iyè mi fò lọ kúrò nínú ìjíròrò tí ń lọ lọ́wọ́.

“Ìrírí adaniláàmú yìí ṣẹlẹ̀ ní 1970. Àkọ́kọ́ lára ọ̀wọ́ ìkìmọ́lẹ̀ ṣíṣàjèjì tí yóò pọ́n mi lójú fún ẹ̀wádún méjì tí ń bọ̀ ni. Léraléra ni mo máa ń bá ara mi nínú rúdurùdu, tí n kò ní lè ronú kedere. Òòyì yóò máa kọ́ mi, ọkàn mi yóò sì máa yára lù kìkì. Ọ̀rọ̀ yóò máa kọ́ mi lẹ́nu tàbí kí n tilẹ̀ gbàgbé wọn pátápátá.

“Ọ̀dọ́, olókunra, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó sì láyọ̀ ni mí nígbà náà. Ẹ wo bí mo ti nífẹ̀ẹ́ láti máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti lóye Bibeli tó! Àmọ́, ìkọlù yìí kò dábọ̀ nínú pípọ́n mi lójú. Mo ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀ sí mi?’ Onímọ̀ ètò iṣan ara kan ṣàwárí pé ohun tí ń ṣe mí ni wárápá onígbà díẹ̀. Mo lo egbòogi tí ó júwe fún mi fún ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà. Síbẹ̀, mo ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ipa rẹ̀ fi kéré tó bẹ́ẹ̀. Mo wá gbà pé mo wulẹ̀ ní láti fara mọ́ ipò tí mo wà, kí n sì máa forí tì í ni.

“Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo wá mọ̀ pé wárápá kọ́ ló ń ṣe mí, àti pé egbòogi tí wọ́n júwe fún mi kò ṣiṣẹ́. Kódà, rírìn léraléra lọ sí àwọn ibi tí mo mọ̀ dunjú jẹ́ iṣẹ́ tí kò ṣeé gbé dá. Mo máa ń fòyà pípàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà tí mo ń gbà. Ó máa ń gba gbogbo okun inú mi láti lọ sí àwọn ìpàdé Kristian. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń jókòó fi ọwọ́ lẹ́rán, níbi tí mo ti ń làágùn, tí òòyì ń kọ́ mi, tí ọkàn mi ń yára lù kìkì, tí orí mi sì ṣófo. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo ara mi yóò le koránkorán, tí àwọn iṣan ara mi yóò sì le tantan. Nígbà kan, mo ti mọ́kàn pé n óò kú.

“Iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ṣèrànwọ́ láti gbé mi ró, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyanu ńlá ló jẹ́ pé mo tilẹ̀ lè máa bá a lọ. Dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli máa ń mú mi pòrúurùu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan débi tí alájọṣiṣẹ́ mi fi máa ń bá dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ. Lótìítọ́, ìwàásù wa jẹ́ iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe àti ní paríparí rẹ̀, Ọlọrun ní ń mú kí ó dàgbà. (1 Korinti 3:6, 7) Àwọn ẹni bí àgùtàn ń gbọ́, wọ́n sì ń dáhùn padà láìfi ààlà tí olùkọ́ lè dé pè.

“Ní ọjọ́ kan ní March 1991, ọkọ mi fi ìwé kan tí ó sọ nípa àrùn ìpayà hàn mí. Àwọn àmì tí ó ṣàpèjúwe jọ tèmi gẹ́lẹ́! Mo ka ohun púpọ̀ sí i, mo lọ sí àwọn ibi àwíyé, mo sì ṣe àdéhùn láti rí ògbóǹtagí kan lórí kókó náà. Lẹ́yìn ẹ̀wádún méjì ni wọ́n wá mọ ìṣòro mi. Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbádùn tán!

“A lè ran ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n ní àrùn ìpayà lọ́wọ́ nípa lílo ìtọ́jú tí ó bá a mu. Àwọn ọ̀rẹ́ lè jẹ́ ìtìlẹ́yìn gíga bí wọ́n bá lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn. Dípò dídi ẹrù ẹ̀bi lé ẹni tí nǹkan ń ṣe náà, alájọṣiṣẹ́ tí ń fòye mọ̀ yóò mọ̀ pé kì í ṣe pé ẹni tí àrùn ìpayà ń ṣe náà ń mọ̀ọ́mọ̀ tàdí mọ́lé ni.—Fi wé 1 Tessalonika 5:14.

“Bí mo ti ń ronú wẹ̀yìn wo 20 ọdún tí ó ti kọjá, inú mi dùn pé jálẹ̀ gbogbo rẹ̀, mo ṣì ń lè máa bá a lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún náà. Ó ti jẹ́ ìbùkún tí ó tóyeyẹ dáradára fún ìjàkadì náà. Lákòókò kan náà, mo mọ̀ pé, bíi ti Epafroditu, àwọn kan ní láti fi àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan sílẹ̀ nítorí àìlera. Irú àwọn wọ̀nyẹn kò já Jehofa kulẹ̀. Kò retí ju ohun tí ẹnì kan lè fi sílẹ̀ lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu lọ.

“Níní àrùn yìí lára ti kọ́ mi láti má ṣe ka ara mi sí pàtàkì jù. Ó ti jẹ́ kí n lè bá àwọn mìíràn tí ipò wọ́n ní ààlà kẹ́dùn. Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jehofa. Jálẹ̀ gbogbo ìrírí agboni jìgìjìgì mi, léraléra ni mo ti rí i gẹ́gẹ́ bí ojúlówó orísun okun àti ìtùnú.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Kristian máa ń yẹra fún àwọn ìlànà tí ó kan ìmúniníyè tàbí ìmúra ẹni níyè. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìdánrawò aṣeéfojúrí àti aláṣàrò kan wà tí kò kan sísọ iyè dòfo tàbí fífi sílẹ̀ sábẹ́ àkóso ẹlòmíràn. Yálà a fẹ́ tàbí a kò fẹ́ láti gba àwọn ìtọ́jú yìí jẹ́ yíyàn ara ẹni.—Galatia 6:5.

b Fún ìsọfúnni nípa yíyí àwọn èrò òdì pada, wo Jí!, October 8, 1992, ojú ewé 3 sí 9, àti October 22, 1987, ojú ewé 7 sí 16.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn Ìlànà Ìmúrọlẹ̀

Mú mímí rọlẹ̀. Ìmígúlegúle sábà máa ń bá ìpayà rìn. Láti mú mímí rẹ dẹwọ́, gbìyànjú ìdánrawò yìí: Dakùn délẹ̀. Ka ení, èjì, títí dé ẹẹ́fà, bí o ti ń mí sínú; ka ení, èjì, títí dórí ẹẹ́fà bí o ti ń mí síta. Lẹ́yìn náà, gbìyànjú irú mímí dẹ́lẹ̀délẹ̀ kan náà ní ìjókòó. Lẹ́yìn náà, gbìyànjú rẹ̀ lórí ìdúró. Mí délẹ̀ láti abonú kí o sì máa ṣe ìdánrawò èyí lójoojúmọ́ títí tí yóò fi mọ́ ọ lára. Àwọn kan máa ń jàǹfààní nípa fífinú wòye àwọn àyíká ẹlẹ́wà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìdánrawò yìí.

Mú ìrònú rọlẹ̀. ‘Bí mo bá ṣubú lulẹ̀ ń kọ́?’ ‘Bí kò bá sí ẹnì kankan nítòsí ti yóò ràn mí lọ́wọ́ ń kọ́?’ ‘Bí èémí mi bá dúró ń kọ́?’ Àwọn èrò alájàálù máa ń fún ìpayà lókun. Níwọ̀n bí àwọn èrò wọ̀nyí ti sábà máa ń jẹ́ nípa àgbákò ọjọ́ iwájú tàbí àwọn ìkọlù tí ó ti kọjá, gbìyànjú pípọkàn pọ̀ sórí ipò lọ́ọ́lọ́ọ́. Dókítà Alan Goldstein sọ pé: “Dídarí àfiyèsí sí ipò lọ́ọ́lọ́ọ́ máa ń mú ara rọlẹ̀ lójú ẹsẹ̀.” Àwọn kan dábàá pé kí ènìyàn de ìgbànú onírọ́bà mọ́ ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Nígbà tí àwọn èrò alájàálù bá yọjú, fà á pàtì, kí o sì sọ fún ara rẹ pé: “Ó tó!” Já lu àníyàn kí ó tó rí àyè láti peléke di ìpayà.

Mú híhùwà padà rọlẹ̀. Bí ìpayà bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, má ṣe bá a jà. Ìmọ̀lára lásán ni, kò sì yẹ kí ìmọ̀lára ṣe ọ́ ní jàm̀bá. Finú wòye pé o wà ní etíkun tí o ti ń wo ìgbì rẹ̀. Ó ń gbéra, ó ń ga sókè, lẹ́yìn náà, yóò sì fọ́n ká. Ìpayà máa ń tọ ipa kan náà. Dípò bíbá ìgbì náà wọ̀dìmú, máa bá a yí. Yóò kọjá lọ. Bí ó bá ti lọ, má ṣe hùwà padà pẹ̀lú àṣejù tàbí sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ jù. Ó ti lọ, bíi ti sísín tàbí ẹ̀fọ́rí.

Ìpayà dà bí abúmọ́ni. Yọ ọ́ lẹ́nu, yóò sì gbógun tì ọ́; má ṣe yọ ọ́ lẹ́nu, ó sì lè máa lọ. Dókítà R. Reid Wilson ṣàlàyé pé àwọn ìlànà ìmúrọlẹ̀ “ni a kò pète kí o baà lè ‘gbógun ti’ ìpayà dáradára tàbí kí o ‘lé’ ìpayà ‘dànù’ níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, kà wọ́n sí ọ̀nà àtiré àkókò náà kọjá, nígbà tí ìpayà ń gbìyànjú láti bá ọ jà.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìbẹ̀rùbojo, Ìbẹ̀rù Ìpayà

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ìpayà ń ṣe máa ń ní ìbẹ̀rùbojo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti túmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rù wíwà ní ibi ojútáyé, lọ́nà tí ó túbọ̀ péye, a lè pe ìbẹ̀rùbojo ní ìbẹ̀rù ìpayà. Àwọn oníbẹ̀rùbojo máa ń bẹ̀rù ìpayà gan-an tí wọ́n fi máa ń yẹra fún gbogbo ibi tí ìkọlù náà bá ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí. Láìpẹ́ láìjìnnà, ibì kan ṣoṣo ló ṣẹ́ kù tí ó “láàbò”—lọ́pọ̀ ìgbà, inú ilé.

Òǹkọ̀wé Melvin Green sọ pé: “Finú wòye pé o ń jáde kúrò nínú ilé rẹ. Ọkùnrin títóbi fìrìgbọ̀n jù lọ tí o tí ì rí rí yọ sí ọ lójijì. Ó ní abẹ̀bẹ̀ ìgbátẹníìsì orí kọnkéré, ó kó o bò ọ́ lórí láìnídìí. O pògìrá padà sínú ilé, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yẹn yà ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí ojú rẹ wálẹ̀ díẹ̀, o yọjú lẹ́nu ilẹ̀kùn, ó sì jọ pé kò sí ìṣòro mọ́. O tún mọ́nà pọ̀n. Ó tún yọ lójijì, ó sì tún kó o bò ọ́. O padà sínú ilé níbi tí ààbò wà fún ọ. O yọjú lẹ́nu ilẹ̀kùn ẹ̀yìnkùlé . . . ó wà níbẹ̀. O yọjú lójú fèrèsé . . . ó wà níbẹ̀. O mọ̀ pé bí o bá kúrò lábẹ́ ààbò àbẹ́ ilé rẹ, yóò tún kó o bò ọ́. Ìbéèrè náà wa ni pé: Ìwọ yóò ha jáde síta bí?”

Ọ̀pọ̀ àwọn oníbẹ̀rùbojo fi ìmọ̀lára wọn wé tí inú àpèjúwe yẹn, wọ́n sì ronú pé àwọ́n wà láìní ọ̀nà àbájáde. Àmọ́ Dókítà Alan Goldstein pèsè ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí pé: “O kò dá yàtọ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan ló ń ṣẹlẹ̀ sí. . . . O lè ran ara rẹ lọ́wọ́.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́