ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/8 ojú ìwé 12-15
  • Òpin Sànmánì kan—Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òpin Sànmánì kan—Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìlàna Glasnost àti Perestroika
  • Bíbẹ̀rẹ̀ Sí Í Káàárẹ̀
  • Perestroika Ètò Ìṣèlú Ṣamọ̀nà sí Ìyípadà Tegbòtigaga
  • Òpin Ogun Tútù Náà
  • Ìfojúsọ́nà Ọjọ́ Ọ̀la Kò Dán Mọ́rán
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Awọn Nǹkan Ha Nsunwọn Sii Nitootọ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ilẹ̀ Soviet Gbógun Ti Ìsìn
    Jí!—2001
  • Ìsìn Tí Ilẹ̀ Soviet Dojú Àtakò Kọ
    Jí!—2001
Jí!—1996
g96 7/8 ojú ìwé 12-15

Òpin Sànmánì kan—Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ GERMANY

LÁÀÁRÍN 1987 sí 1990, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó wọn 6.9 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lórí òṣùwọn Richter mi àwọn apá ilẹ̀ Armenia, China, Ecuador, Iran, Philippines, àti United States jìgìjìgì. Nǹkan bí 70,000 ènìyán kú tí ẹgbẹẹgbàárùn-ún sì fara pa, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún sì di aláìnílé lórí. Iye àwọn ohun tí ó bà jẹ́ ń lọ sí ọ̀pọ bílíọ̀nu dọ́là.

Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí tí ó mi ọ̀pọ̀ ènìyàn tìtì, tàbí lọ́nà líle koko, tó bí ìsẹ̀lẹ̀ míràn tí ó mi ayé tìtì ní àkókò kan náà ti ṣe. Ìsẹ̀lẹ̀ ìṣèlú ni, ọ̀kan tí ó mú sànmánì kan wá sí òpin. Bí ó ti wù kí ó rí, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó yí ọjọ́ ọ̀la àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn padà.

Kí ní ṣamọ̀nà sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ kíkàmàmà bẹ́ẹ̀? Kí ni àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́?

Ìlàna Glasnost àti Perestroika

Mikhail Gorbachev di akọ̀wé àgbà Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ti Soviet Union ní March 11, 1985. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Soviet, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ alákìíyèsí kárí ayé, kò retí ìyípadà sàn-án kankan nínú ètò ìṣèlú láàárín ìgbà ìṣàkóso rẹ̀.

Kò pé ọdún kan lẹ́yìn náà, Arkady Shevchenko, olùgbaninímọ̀ràn ọ̀ràn ìṣèlú tẹ́lẹ̀ fún alábòójútó ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè fún ilẹ̀ Soviet nígbà kan rí, tí ó tún ti fi ọdún márùn-ún jẹ́ akọ̀wé àgbà onípò kejì fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìwòyemọ̀ àrà ọ̀tọ̀ nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ilẹ̀ U.S.S.R. wà ní oríta ìṣèpinnu. Bí a kò bá mú àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé àti ti ẹgbẹ́ àwùjọ fẹ́ri láìpẹ́, ìyìnrìnsíwájú ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, tí, nígbẹ̀yìngbẹ́yín rẹ̀, ó sì ń wu ìlàájá rẹ̀ léwu. . . . Gorbachev ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọ̀nà tuntun kan . . . Ṣùgbọ́n a óò ṣì máa wò ó, bóyá àkókò rẹ̀ lórí àlééfà yóò ṣí sànmánì tuntun kan sílẹ̀ fún U.S.S.R. . . . Ó ń dojú kọ àwọn ìṣòro tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé borí.”

Ipò Gorbachev nígbà náà fún un láǹfààní ìṣèlú tí ó nílò láti ṣàgbékalẹ̀ ìpinnu ìjọba tí ó ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1971, nínú àwùjọ ilẹ̀ Soviet. Ó jẹ́ ìlàna glasnost, tí ó túmọ̀ sí “ìsọfúnni fún ará ìlú” tí ó sì ṣojú fún ìpinnu ìjọba láti má ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa àwọn ìṣòro ilẹ̀ Soviet. Ó ṣalágbàwí àwùjọ aláìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, nínú èyí tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ àti ilé iṣẹ́ ìròyìn ilẹ̀ Soviet yóò ti ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ púpọ̀ gan-an. Ní àbárèbábọ̀, ìlàna glasnost ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ará ìlú láti ṣe lámèyítọ́ ìjọba àti àwọn kan lára àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Èdè ọ̀rọ̀ míràn tí Gorbachev tún ti ń lò tipẹ́ ni “perestroika,” ọ̀rọ̀ kan tí ó túmọ̀ sí “ìṣàtúntò.” Nínú àròkọ kan tí a tẹ̀ jáde ní 1982, ó sọ̀rọ̀ nípa “àìní fún ìṣàtúntò yíyẹ ní ti ìrònú òun ìhùwà” nínú apá ẹ̀ka iṣẹ́ àgbẹ̀.

Lẹ́yìn tí Gorbachev di olórí ilẹ̀ Soviet Union, ó wá dá a lójú pé àtúntò ìṣàbójútó ètò ọrọ̀ ajé jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe pẹ̀lú. Ó mọ̀ pé kì yóò rọrùn láti ṣàṣeparí rẹ̀—bóyá kí ó má tilẹ̀ ṣeé ṣe rárá, bí ìyípadà ọ̀ràn ìṣèlú kò bá bá a rìn.

Ìtara Gorbachev láti ṣàmúlò àwọn ìlàna glasnost àti perestroika kò túmọ̀ sí pé ó fẹ́ láti pa ètò ìjọba Kọ́múníìsì run. Ó yàtọ̀ gédégédé sí ìyẹn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Ète rẹ̀ ni láti bẹ̀rẹ̀ ìyípadà tegbòtigaga kan tí ìjọba ń darí. Kò fẹ́ láti jin ètò ìgbékalẹ̀ ilẹ̀ Soviet lẹ́sẹ̀, ó wulẹ̀ fẹ́ láti mú un túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i ni.”

Àwọn ìkálọ́wọ́kò tí àwọn ìpinnu ìjọba wọ̀nyí mú dẹrùn fa àìfararọ láàárín àwọn aṣáájú kan ní ilẹ̀ Soviet Union. Ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn aṣáájú díẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrùn. Nígbà tí púpọ̀ lára wọ́n mọ àìní fún ìṣàtúntò ètò ọrọ̀ ajé lámọ̀jẹ́wọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló fara mọ́ ọn pé ìyípadà èto ìṣèlú pọn dandan tàbí pé ó yẹ ní fífẹ́.

Láìka ìyẹn sí, Gorbachev jẹ́ kí àwọn alájọṣepọ̀ rẹ̀ ní Ìlà Oòrun Europe mọ̀ pé, wọ́n lómìnira láti fi ìlàna perestroika tiwọn dánra wò. Bí ó ti wù kí ó rí, Gorbachev ṣèkìlọ̀ fún Bulgaria—àti ní gidi, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrùn lápapọ̀—pé nígbà tí ìṣàtúnṣebọ̀sípò pọn dandan, ó gba ìṣọ́ra láti má ṣe dín ipa iṣẹ́ híhàn gbangba jù lọ ti Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì kù.

Bíbẹ̀rẹ̀ Sí Í Káàárẹ̀

Ṣíṣe lámèyítọ́ ètò ìjọba Kọ́múníìsì, ní Soviet Union àti ní àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrùn, ti pọ̀ sí i bí ọdún ti ń gorí ọdún. Fún àpẹẹrẹ, láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, ìwé ìròyin HVG (Heti Világgazdaság) ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ilẹ̀ Hungary ti ń pe àwọn ojú ìwòye Kọ́múníìsì tí gbogbogbòó tẹ́wọ́ gbà níjà lọ́nà líle koko, bí ó tilẹ̀ ti yẹra fún ṣíṣe lámèyítọ́ Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì fúnra rẹ̀ ní tààràtà.

A dá ẹgbẹ́ Solidarity, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kìíní tí ó dá dúró ní ìhà Ìlà Oòrùn, sílẹ̀ ní Poland ní 1980. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè tọpa ìbẹ̀rẹ rẹ̀ sẹ́yìn dé 1976, nígbà tí àwùjọ àwọn oníyapa kán dá Ìgbìmọ̀ Olùgbèjà Àwọn Òṣìṣẹ́ sílẹ̀. Nígbà tí ó fi di apá ìbẹ̀rẹ̀ 1981, ẹgbẹ́ Solidarity ti ní nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá ọmọ ẹgbẹ́. Ó béèrè fún àtúntò ètò ọrọ̀ ajé àti ìdìbò ojútáyé, ó sì ń tẹnu mọ́ àwọn ìbéère rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìyanṣẹ́lódì. Ní jíjuwọ́ sílẹ̀ fún ìhalẹ̀mọ́ni pé ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ Soviet dá sí i, ìjọba ilẹ̀ Poland tú ẹgbẹ́ náà ká níkẹyìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì ń gbéṣẹ́ ṣe lábẹ́lẹ̀. Àwọn ìdaṣẹ́sílẹ̀ nítorí kí ìjọbá lè ka ẹgbẹ́ náà sí tún ṣamọ̀nà sí fífi òfin gbé e kalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní 1989. Wọ́n ṣe ìdìbò ojútáyé ní June 1989, wọ́n sì dìbò yan ọ̀pọ̀ lára àwọn olùdíje láti inú ẹgbẹ́ Solidarity. Nígbà tí ó di August, fún ìgbà àkọ́kọ́ láàárín nǹkan bí 40 ọdún, olórí ìjọba kan tí kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsí wà lórí àlééfà ní Poland.

Ó ṣe kedere pé, ìlàna glasnost àti perestroika, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣòro tí a ń dojú kọ ní ilẹ̀ ìṣàkóso Kọ́múníìsì, ní ń ṣàtúnṣe bọ̀ sípò àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrùn lódindi.

Perestroika Ètò Ìṣèlú Ṣamọ̀nà sí Ìyípadà Tegbòtigaga

Martin McCauley ti Yunifásítì London kọ̀wé pé: “Títí di July 1987, ó jọ pé ohun gbogbo ń lọ bí Mikhail Gorbachev ṣe pète rẹ̀.” Àní ní apá ìparí June 1988, níbi Àpérò Kọkàndínlógún Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ní Moscow, ìròyín sọ pé, Gorbachev jèrè “ìfọwọ́sí gbígbòòrò fún àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ ṣe lọ́nà kò gbóná kò tutù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” Ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé ó ń dojú kọ ìṣòro nínu ṣíṣàtúntò Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì àti ìjọba ilẹ̀ Soviet.

Ní 1988, ìyípadà nínú àkọsílẹ̀ òfín fàyè gba fífi Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kékeré ní U.S.S.R., tí a yan àwọn 2,250 mẹ́ḿbà rẹ̀ nínú ìdìbò ojútáyé kan lọ́dún kan lẹ́yìn náà, rọ́pò Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jù Lọ ní Ilẹ̀ Soviet. Lẹ́yìn náà, àwọn aṣòfin kékeré wọ̀nyí ṣàgbékalẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin alábala méjì láàárín ara wọn, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ yóò sì ní mẹ́ḿbà 271. Boris Yeltsin wáá di mẹ́ḿbà títayọ lọ́lá kan nínú ìgbìmọ̀ aṣòfin yìí. Láìpẹ́, ó ń tọ́ka sí àìkẹ́sẹjárí ìlàna perestroika náà, ó sì ń pe àfiyèsí sí àwọn àtúnṣe tí òún rò pé ó pọn dandan. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti gbé Gorbachev ga sí ipò ààrẹ ní 1988, ipò tí ó fẹ́ láti sọ jí kí ó sì fún lókun, àtakò ń pọ̀ lòdì sí i.

Nígbà kan náà, àwọn alágbára ńlá méjèèjì náà, ilẹ̀ Soviet Union àti United States, ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì nínú dídín àwọn ọmọ ogun kù àti dídín ìbẹ̀rù ohun ìjà átọ́míìkì kù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àdéhùn tí wọ́n ń ṣe ń tanná ran ọ̀tun ìrètí pé ọwọ́ lè tẹ àlàáfíà àgbáyé—tó bẹ́ẹ̀ tí òǹkọ̀wé John Elson fi sọ ní September 1989 pé: “Lójú ọ̀pọ̀ olùṣàkíyèsí, apá ìkẹyìn àwọn ọdún 1980 ń ṣojú fún oríṣi ìdágbére kan fún ohun ìjà ogun. Ó jọ pé ogun tútù náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí tán; ó jọ pé àlàáfíà ti ń gbèrú ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé.”

Lẹ́yìn náà ni November 9, 1989 wọlé dé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà lóòró gangan, a ṣí Ògiri Berlin sílẹ̀ lẹ́yìn nǹkan bí ọdún 28, lójijì ni ó sì dẹ́kun jíjẹ́ ìdènà ìṣàpẹẹrẹ láàárín Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn. Lọ́kọ̀ọ̀kan, ní ìtẹ̀léra yíyá kánkán, àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrun Europe pa ìṣàkóso ìjọba àjùmọ̀ní tì. Nínú ìwe rẹ̀, Death of the Dark Hero—Eastern Europe, 1987-90, David Selbourne pè é ní “ọ̀kan lára ìyípadà tegbòtigaga títóbi jù lọ nínú ìtàn: ìyípadà tegbòtigaga oníjọba tiwantiwa, tí ó sì lòdì sí ìjọba afẹ́nifẹ́re, èyí tí ipa rẹ̀ yóò sì máa bá a lọ fún àkókò gígùn lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ṣokùnfa rẹ̀, àti àwọn tí ó ṣojú wọn bá ti ṣàìsí láyé mọ́.”

Kété tí ó dé ògógóró àṣeyọrí rẹ̀, ìyípadà tegbòtigaga onípẹ̀lẹ́tù náà kò gba àkókò gígùn. Pátákó àfiyèsí kan tí a rí ní Prague, Czechoslovakia, ṣàkópọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí: “Poland—Ọdún 10; Hungary—Oṣù 10; Ìlà Oòrun Germany—Ọ̀sẹ̀ 10; Czechoslovakia—Ọjọ́ 10. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan, Rumania—Wákàtí 10.”

Òpin Ogun Tútù Náà

Òǹkọ̀wé Selbourne sọ pé: “Ìrísí ìwólulẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ìlà oòrun Europe bára mu délẹ̀ lọ́nà pípàfiyèsí.” Ó fi kún un lẹ́yìn náà pé: “Ohun tí ó mú un yá kánkán ní kedere ni ìgorí-àlééfà Gorbachev ní Moscow ní March 1985 àti bí ó ṣe mú ‘Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Brezhnev’ wá sópin, èyí tí ó fi ìdánilójú ìrànwọ́ àti ìdásí ilẹ̀ Soviet nígbà tí rìgbòrìyẹ̀ ará ìlú bá ṣẹlẹ̀ du àwọn ìṣàkóso ìhà ìlà oòrun Europe, lọ́nà tí ń ṣekú pani.”

Ìwe gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica pe Gorbachev ní “olùdápète pàtàkì jù lọ fún ọ̀wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apá ìparí 1989 sí 1990 tí ó yí ìgbékalẹ̀ olóṣèlú ilẹ̀ Europe padà, tí ó sì sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ òpin Ogun Tútù náà.”

Dájúdájú, Gorbachev kò ti lè dá mú Ogun Tútù náà wá sópin. Ní títọ́ka sí ohun tí ń bọ̀ wáá ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, olórí ìjọba ilẹ̀ Britain, Margaret Thatcher sọ, lẹ́yìn tí ó kọ́kọ́ bá a pàdé pé: “Mo fẹ́ràn Ọ̀gbẹ́ni Gorbachev. A lè jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ dáadáa.” Síwájú sí i, àjọṣepọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ tí Thatcher ní pẹ̀lú ààrẹ Reagan ti ilẹ̀ America, mú kí ó lè yí Reagan lérò padà pé ipa ọ̀nà ọgbọ́n ni láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Gorbachev. Òǹkọ̀wé ìwe Gorbachev—The Making of the Man Who Shook the World, Gail Sheehy, parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Thatcher lè lura rẹ̀ lọ́gọ ẹnu fún jíjẹ́, ‘ní èrò ìtumọ̀ ogidì gan-an, igi lẹ́yìn ọgbà àjọṣepọ̀ láàárín Reagan òun Gorbachev.’”

Bí ó ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn, àwọn ẹni yíyẹ ti wà nípò ní àkókò tí ó rọgbọ láti ṣàṣeyọrí àwọn ìyípadà tí kì bá tí ṣeé ṣe lọ́nà míràn.

Ìfojúsọ́nà Ọjọ́ Ọ̀la Kò Dán Mọ́rán

Àní bí Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrún ṣe ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pé Ogun Tútù náà ń parí lọ, dùgbẹ̀dùgbẹ̀ ń fì lókè níbòmíràn. Ayé kò fi bẹ́ẹ̀ fiyè sí i nígbà tí ó ń gbọ́ ìròyìn láti Áfíríkà ní 1988 pé a ti pa ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ènìyàn nínú ìwà ipá ẹ̀yà ìran tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní Burundi. Àfiyèsí díẹ̀ ni ó sì pè sí ìròyìn láti Yugoslavia ní April 1989, pé ìwà ipá ẹ̀yà ìran tí ó burú jù lọ láti 1945 ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Láàárín àkókò náà, òmìnira púpọ̀ sí i tí ó hàn gbangba ní ilẹ̀ Soviet Union ń yọrí sí rìgbòrìyẹ̀ aráàlú tí ń gbilẹ̀ sí i. Àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira mélòó kan tilẹ̀ ń ṣèfilọ́lẹ̀ ìgbìdánwò láti dá dúró.

Ní August 1990, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Iraq ya wọ Kuwait, wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ láàárín wákàtí 12. Nígbà tí àwọn ará Germany ń ṣayẹyẹ ìsọdọ̀kan ilẹ̀ Germany, ní èyí tí kò tó ọdún kan lẹ́yìn ìwólulẹ̀ Ògiri Berlin, ààrẹ ilẹ̀ Iraq ń dánnu pé: “Ilẹ̀ Iraq ló ni ilẹ̀ Kuwait, a kì yóò sì fi sílẹ̀, àní bí a bá tilẹ̀ ní láti jà nítorí rẹ̀ fún 1,000 ọdún.” Ní November, Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé ìgbésẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì halẹ̀ mọ́ Iraq pé, bí kò bá kó kúrò ní Kuwait, òun yóò bá a gbé ìgbésẹ̀ ológun. Ayé tún ṣẹ̀ẹ́ fa tẹ̀ẹ̀tẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i ní bèbè ipò kan tí ó sún mọ́ ìjábá tí ó lè ṣẹlẹ̀, tí gbogbo rẹ̀ sì dá lérí ìpèsè epo.

Nítorí náà, àwọn ìrètí àlàáfíà àti ààbò tí a tanná ràn nípa òpin Ogun Tútù náà ha gbọ́dọ̀ ṣíwọ́, kí wọ́n tóó ní ìmúṣẹ bí? Kà nípa èyí nínú ìtẹ̀jáde wa tí ń bọ̀, nínú ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà, “‘Ètò Ayé Tuntun’—Ó Bẹ̀rẹ̀ Lọ́nà Àìfararọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Lójijì ni Ògiri Berlin ṣíwọ́ jíjẹ́ ìdènà ìṣàpẹẹrẹ láàárín Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]

Gorbachev (lápá òsì) àti Reagan: Robert/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́