ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/1 ojú ìwé 3-4
  • Awọn Nǹkan Ha Nsunwọn Sii Nitootọ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Nǹkan Ha Nsunwọn Sii Nitootọ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fifi Iha Titun Kan Kún un
  • Itilẹhin Atọrunwa Ha Ni Bi?
  • Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?
    Jí!—2000
  • Òpin Sànmánì kan—Kí Ni Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la?
    Jí!—1996
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/1 ojú ìwé 3-4

Awọn Nǹkan Ha Nsunwọn Sii Nitootọ Bi?

“Ogiri [Berlin] le tubọ dáhòlu sii gẹgẹ bi isopọ Ila-oorun ati Iwọ-oorun ti ndi pupọ. Ṣugbọn yoo gba ọpọlọpọ ọdun, ani ọpọlọpọ iran paapaa, ki o tó wólulẹ̀. Germany mejeeji naa ki yoo pada di ọkan lae.” Bẹẹ ni iwe irohin America ti o gbayi kan ṣe sọ ni March 1989.

Ni ohun ti o din sí 250 ọjọ—kii ṣe awọn ọdun, ki a má tilẹ sọ nipa ọpọlọpọ iran, ogiri naa bẹrẹ sii wó. Laaarin ọsẹ melookan, ẹgbẹẹgbẹrun èkúfọ́ rẹ̀, tí ó ti wá di awọn ohun iranti nisinsinyi, ti di awọn ohun ìfiṣọ̀ṣọ́ ori tabili kárí aye.

IBOJU IRIN kan ti ó ti dipẹta gidigidi ti ṣẹ́ kuro nikẹhin, ni fifunni ni ireti pe alaafia ati ailewu yika aye sunmọtosi nígbẹ̀hìngbẹ́hín. Ani Ogun Gulf ni Aarin Ila-oorun Aye paapaa ko ṣokunkun bo ireti naa pe idije ti ó ti wà tipẹ laaarin Ila-oorun ati Iwọ-oorun ti dopin, ati pe eto aye titun kan ti sunmọle.

Fifi Iha Titun Kan Kún un

Lati igba ogun agbaye keji, itẹsiwaju siha isopọṣọkan Europe ti hàn gbangba. Ni 1951, awọn orilẹ-ede apa Iwọ-oorun Europe dá European Coal and Steel Community silẹ. Eyi ni European Common Market tẹle ni 1957. Ni 1987 awọn mẹmba 12 ti wọn jẹ ti awujọ agbaye yii (ti wọn tó 342 million nisinsinyi) gbé gongo isopọṣọkan jalẹjalẹ ninu ọrọ̀-ajé bi o ba fi maa di 1992 ka iwaju. Ani isopọṣọkan kikun ti oṣelu farahan nisinsinyi bi ohun ti o ṣeeṣe gan an. Iru iyipada atunilara wo ni eyi jẹ́ si itan Europe ti ọdun aipẹ yii ti o ni itajẹsilẹ ninu!

Bi o ti wu ki o ri, nitori irukerudo oṣelu ti ẹnu aipẹ yii, 1992 ti ńní ijẹpataki pupọ sii. Ìméfò ti pọ sii pe awọn orilẹ-ede Kọmunist ti apa Ila-oorun Europe tẹlẹri ni a tun le fikun Europe ti a sopọṣọkan nígbẹ̀hìngbẹ́hín.

Itilẹhin Atọrunwa Ha Ni Bi?

Awọn awujọ isin kan, laika ilana aidasi tọtun tosi Kristẹni sí, yọọda ki ìtẹ̀rì isin fun ọpọlọpọ ẹwadun ni apa Ila-oorun Europe tí wọ́n wọnu dídásí ọran oṣelu loju mejeeji. Ni sisọrọ lori eyi, iwe irohin ojoojumọ Frankfurter Allgemeine Zeitung ti Germany ṣakiyesi pe “itilẹhin awọn Kristẹni ninu mimu awọn iyipada ni Ila-oorun jade ni a ko le jiyan otitọ rẹ,” ni fifi kun un pe “ipa tiwọn ni a ko nilati fojubu kere dajudaju.” O ṣalaye siwaju sii pe: “Fun apẹẹrẹ, ni Poland, isin nso araarẹ pọ mọ orilẹ-ede, ṣọọṣi si di ọta lile kan lodisi ẹgbẹ ti nṣakoso; ni GDR [Ila-oorun Germany tẹlẹri] ṣọọṣi pese àyè ọfẹ fun awọn oniyapa wọn si yọnda fun wọn lati lo awọn ile ṣọọṣi fun awọn ete ti eto-ajọ; ni Czechoslovakia, awọn Kristẹni ati awọn alatilẹhin ijọba apawọpọṣe pade ninu ẹwọn, wọn wa mọriri araawọn ẹnikinni keji, ati nikẹhin, ẹgbẹ ogun wọn darapọ.” Ani ni Romania paapaa, nibi ti “awọn ṣọọṣi ti fẹ̀rí han lati jẹ olusinru olootọ fun ijọba Ceauşescu,” fifaṣẹ ọba mu alufaa Laszlo Tökes ti o ṣeeṣe ki o ṣelẹ ni o gún iyipada tegbotigaga naa ni kẹṣẹ.

O ni Vatican pẹlu ninu. Iwe irohin Time sọ ni December 1989 pe: “Nigba ti o jẹ pe ilana ìdáṣèpinnu funra ẹni lati ọwọ Gorbachev ni o jẹ́ okunfa akọkọ fun idasilẹ alasokọra ti o ṣẹlẹ lojiji ni apa Ila-oorun Europe ni awọn oṣu diẹ ti o kọja, John Paul lẹtọọsi ọpọjulọ ninu iyin ńláǹlà naa. . . . La awọn ọdun 1980 já leralera ni awọn ọrọ rẹ̀ tẹnumọ èrò imupadaṣọkan Europe lati Atlantic si Urals a si fun un niṣiiri nipasẹ igbagbọ Kristẹni.” Nipa bayii gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, nigba ti o nṣebẹwo si Czechoslovakia ni April 1990, pope nireti pe ibẹwo oun yoo ṣí awọn ilẹkun titun silẹ laaarin Ila-oorun ati Iwọ-oorun. O ṣefilọ apejọ awọn biṣọọbu Europe ti o ti wewee lati ṣeto ọna ti wọn lè gbà mu iwoye rẹ ṣẹ nipa “Europe kan ti a sopọṣọkan nitori ipilẹ rẹ̀ ti ó jẹ ti Kristẹni.”

Njẹ Germany ti a sopọṣọkan ninu igbekalẹ Europe ti a sopọṣọkan ki yoo ha jẹ́ ami ọjọ iwaju kan fun Europe ti a sopọṣọkan patapata, ati lẹhin naa aye kan ti a sopọṣọkan paapaa bi? Njẹ lilọwọ ti isin lọwọ ninu rẹ̀ ko ha fihan pe eyi ni ohun ti Bibeli ṣeleri bi? Dajudaju, bi awọn alufaa ni Ila-oorun ati Iwọ-oorun ti nṣiṣẹ laaarin igbekalẹ oṣelu fun alaafia ati ailewu nisinsinyi, njẹ kò ha yẹ ki a reti pe ki eyi di otitọ gidi laipẹ? Ẹ jẹ ki a wò ó.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣọọṣi ti Protẹstanti Nikolai ni Leipzig—ami irukerudo oṣelu ní Germany

Awọn orilẹ-ede ti wọn jẹ́ mẹmba European Common Market

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́