Orílẹ̀-Èdè Wo Ló Lè Jẹ́?
Àwọn ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà sábà máa ń wo gbígba rìbá, ìwà ìbàjẹ́, àti ipò òṣì gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó jẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà àti Latin America. Nítorí náà, orílẹ̀-èdè wo ni àyọkà tí ó tẹ̀ lé e yìí bá wí?
“Àwọn mínísítà ìjọba ń parọ́, a ń fi àwọn oníṣòwò sẹ́wọ̀n nítorí ìwà ìbàjẹ́, a ká àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí ń gba rìbá mọ́, a kò ka ìṣèlú kún, a sì rí [àwọn òṣèlú] gẹ́gẹ́ bí aláìníyì, tí ọtí líle sọ dìdàkudà, tí ìbálòpọ̀ sì ti gbà lọ́kàn. . . . Jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, olè jíjà lójú pópó tún ti di lemọ́lemọ́. . . . Ìlọsókè ìwà ìbàjẹ́ ní àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, ètò ìṣúnná owó, àti ti ibi iṣẹ́ ìjọba ti bá ìwà ọ̀daràn wíwọ́pọ̀ rìn. . . . Lónìí, mílíọ̀nù 11 ènìyàn ni kò ní mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé, . . . iye àwọn tí wọ́n sì ń gbé nínú ipò òṣì paraku—tí wọn kò ní méje tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun kòṣeémánìí náà—sì ti ròkè láti 2.5 mílíọ̀nù sí 3.5 mílíọ̀nù.”—Phillip Knightley, ìwé ìròyin The Australian Magazine.
Ǹjẹ́ ìméfò rẹ tọ̀nà bí? Britain ni ìdáhùn náà. Àmọ́, èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó bani nínú jẹ́ nípa sànmánì wa pé ohun tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí lè jẹ́ òtítọ́ nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹ wo bí gbogbo wa ti nílò ìṣàkóso rere, tí kò lábòòsí, tí ó dúró ṣinṣin tó! Bẹ́ẹ̀ ni, a nílò ìṣàkóso Ọlọ́run nípasẹ̀ Ìjọba tí Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún pé, “Kí ìjọba rẹ dé.”—Mátíù 6:10.