ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/8 ojú ìwé 18-19
  • Ó Ha Yẹ Kí O Bẹ̀rù Òkú Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí O Bẹ̀rù Òkú Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀rù Òkú Wà Káàkiri
  • Àwọn Òkú Ha Lè Pa Ọ́ Lára Bí?
  • Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?
    Jí!—2009
  • Ìbẹ́mìílò
    Jí!—2014
  • Ó Ha Yẹ Kí A Bọlá fún Òkú Bí?
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/8 ojú ìwé 18-19

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Yẹ Kí O Bẹ̀rù Òkú Bí?

MẸ́NU kan ọ̀rọ̀ nípa òkú, ọ̀pọ̀ ènìyàn kì yóò fẹ́ẹ́ jíròrò nípa rẹ̀ mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ náà wulẹ̀ ń ni àwọn kan lára ni; ẹ̀rú máa ń bà wọ́n gidigidi. Nítorí náà, kò ṣàjèjì láti rí àwọn àṣà àti ààtò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rù òkú nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ jákèjádò ayé. Fún àpẹẹrẹ, jẹ́ kí a wo àwọn àṣà tí a rí ní apá ìsàlẹ Sahara ní Áfíríkà.

Obìnrin kan ní ìlú ńlá kan ní Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà rántí dáadáa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀ kan kú. Ó wí pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹbí máa ń gbọ́ oúnjẹ sínú abọ́ kan wá fún òkú náà déédéé, yóò sì rọra gbé e sínú iyàrá rẹ̀. Nígbà tí kò bá sí nítòsí, èmi yóò yára lọ fi oúnjẹ náà lánu. Nígbà tí ẹbí náà bá dé, inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an! Ó gbà gbọ́ pé òkú náà ti tẹ́wọ́ gba oúnjẹ aládùn náà. Èyí ń bá a lọ títí tí mo fi ṣàìsàn. N kò ní ìyánnu fún oúnjẹ mọ́, n kò sì lè jẹ oúnjẹ èyíkéyìí rárá. Èyí fa ìpayà fún mi! Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹbí parí ọ̀rọ̀ sí pé ẹbí wa tó kú ló fa àìsàn mi. Wọ́n ronú pé, ó ní láti jẹ́ pé ó ń bínú sí ẹnì kan nínú ìdílé ni.”

Nínú ìlú ńlá yẹn kan náà, bí ìdílé kan bá bí ìbejì, tí ọ̀kán bá sì kú, kò sí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó kú náà nínú ilé yẹn. Bí ẹnì kan bá béèrè nípa ọmọ kejì tí ó kú náà, ìdílé náà yóò dáhùn lọ́nà àṣà pé: “Ó lọ ra iyọ̀.” Wọ́n gbà gbọ́ gan-an pé èkejì tí ó wà láàyè yóò kú bí a bá sọ òtítọ́.

Lẹ́yìn náà, finú wòye ìran yìí: Ọkùnrin kan tí ó ní ìyàwó mẹ́ta kú. Lọ́jọ́ kejì ìsìnku rẹ̀, wọ́n dá àkànṣe aṣọ funfun fún àwọn ìyàwo rẹ̀. Lákòókò kan náà, wọ́n fi pákó àti koríko kọ́ àkànṣe balùwẹ̀ kan sí ìtòsí ilé náà, níbi tí àwọn obìnrin wọ̀nyí yóò ti máa wẹ̀, tí wọn yóò sì máa wọ aṣọ funfun náà. Kò sí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ wọ ibẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn àti obìnrin kan tí a yàn láti máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí wọ́n bá ṣe ń jáde láti inú àkànṣe balùwẹ̀ yìí ni wọ́n yóò máa ta aṣọ bojú. Àwọn obìnrin náà tún máa ń lo sebe, gbẹ̀dẹ̀ ọrùn tí a fi okùn ṣe fún “ààbò.” Gbogbo ọjọ́ Friday àti Monday ni wọn yóò máa wẹ ìwẹ̀ àkànṣe yìí fún 100 ọjọ́. Láàárín àkókò yìí, wọn kò lè fúnra wọn gba ohunkóhun láti ọwọ́ ọkùnrin. Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ẹ́ fún wọn ní nǹkan, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀ tàbí sóri tábìlì kan. Ìgbà yẹn ni obìnrin náà yóò wá mú un. Kò sí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ jókòó tàbí sùn lórí ibùsùn àwọn obìnrin wọ̀nyí. Ìgbàkigbà tí wọ́n bá jáde nílé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n gbọ́dọ̀ mú àkànṣe ọ̀pá kan dání. Wọ́n ronú pé níní ọ̀pá yìí lọ́wọ́ kò níí jẹ́ kí ọkọ wọn tó ti kú gbéjà kò wọ́n. Bí wọn kò bá tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ó wà lókè yìí, wọ́n lérò pé inú lè bí ọkọ tó ti kú náà, kí ó sì ṣèpalára fún wọn.

Irú àwọn ìrírí báwọ̀nyí wọ́pọ̀ ní apá ibẹ̀ yẹn lágbàáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe ilẹ̀ Áfíríkà nìkan ni irú àṣà báwọ̀nyí wà.

Ìbẹ̀rù Òkú Wà Káàkiri

Ìwe gbédègbẹ́yọ̀ kan, Encarta, sọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí nípa ojú tí ọ̀pọ̀ ènìyán fi ń wo àwọn baba ńlá wọn tí wọ́n ti kú, pé: “Àwọn ẹbí tí wọ́n ti kú . . . ni a gbà gbọ́ pé wọ́n ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tàbí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, pé wọ́n ti dé ipò àwọn ọlọ́run. [Èròǹgbà yìí] ni a gbé karí èrò ìgbàgbọ́ pé àwọn baba ńlá jẹ́ mẹ́ḿbà àwùjọ tí ó wà lójúfò, tí wọ́n ṣì lọ́kàn ìfẹ́ nínú àwọn àlámọ̀rí àwọn ẹbí wọn tó wà láàyè. A ti kọ àwọn àkọsílẹ̀ jàn-ànràn-jan-anran nípa rẹ̀ ní àwùjọ Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà (àwọn ẹ̀ya Bantu àti Shona), ní Polynesia àti Melanesia (àwọn ará Dobu àti Manus), láàárín àwọn Indo-European bíi mélòó kan (àwọn ará Scandinavia àti Germany ìgbàanì), àti ní pàtàkì ní China àti Japan. Lápapọ̀, wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn baba ńlá ń lo agbára ńlá, pé wọ́n ní agbára àrà ọ̀tọ̀ láti darí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí láti darí ire àwọn ẹbí wọ́n tó wà láàyè. Ààbò ìdílé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn lájorí àníyàn wọn. A kà wọ́n sì alárinà láàárín ọlọ́run gíga jù lọ, tàbí àwọn ọlọ́run, àti àwọn ènìyàn, wọ́n sì lè bá àwọn alààyè sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àlá àti nípasẹ̀ gbígbé wọn dè. Ìmọ̀lára tí a ń ní fún wọn jẹ́ àpapọ̀ ẹ̀rù àti ọ̀wọ̀. Bí a bá pa àwọn baba ńlá náà tì, wọ́n lè fa àrùn àti àwọn àgbákò míràn. Ètùtù, ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà, àti ìrúbọ ni àwọn oríṣiríṣi ọ̀nà tí àwọn alààyè lè gbà ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn.”

Ní tòótọ́, a lè lo owó tí ń wọlé fún ìdílé gbẹ nítorí ìbẹ̀rù òkú. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ayẹyẹ ńlá tí ń béèrè fún oúnjẹ àti ọtí, ààyè ẹran fún ìrúbọ, àti aṣọ olówó ńlá ni àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ gan-an pé ó yẹ kí a bẹ̀rù òkú máa ń béèrè fún.

Ṣùgbọ́n, ṣé àwọn ẹbí tàbí baba ńlá tó ti kú wà ní ipò kan tí ń béèrè fún ẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ ní tòótọ́ bí? Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, sọ?

Àwọn Òkú Ha Lè Pa Ọ́ Lára Bí?

Ó lè dùn mọ́ ọ nínú láti mọ̀ pé Bíbélì jẹ́rìí sí ìjótìítọ́ irú àwọn èrò ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Nínú ìwe Diutarónómì, a mẹ́nu kan àwọn àṣà tí ó jẹ mọ́ ìbẹ̀rù òkú. Ó wí pé: “Kí a má ṣe rí nínú yín . . . atujú, tàbí abá-iwin-gbìmọ̀, tàbí oṣó, tàbí abókùúlò. Nítorí pé gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ìríra ni sí OLÚWA.”—Diutarónómì 18:10-12.

Ṣàkíyèsí pé Jèhófà Ọlọ́run dẹ́bi fún irú àwọn ààtò bẹ́ẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé a gbé wọn karí irọ́. Irọ́ gíga jù lọ nípa àwọn òkú ni pé ọkàn ń wà láàyè lọ. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyin The Straight Path sọ èyí nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú pé: “Ikú wulẹ̀ jẹ́ ìjádelọ ọkàn. . . . Ibi ìtọ́júpamọ́ ara nìkan, kì í ṣe ti ọkàn, ni sàréè jẹ́.”

Bíbélì kò gbà bẹ́ẹ̀. Ka Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4 fúnra rẹ: “Kíyè sí i, gbogbo ọkàn ni tèmi; gẹ́gẹ́ bí ọkàn bàbá ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni tèmi ni ọkàn ọmọ pẹ̀lú; ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” Bákan náà, a sọ ipò tí àwọn òkú wà jáde kedere nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Oníwàásù 9:5 pé: “Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan.” Èyí ṣàlàyé ìdí tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ loúnjẹ òkú ń gbé, àyàfi bí alààyè kan bá jẹ ẹ́.

Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì fún wa ní ìrètí nípa àwọn tí wọ́n wà nínú sàréè. Wọ́n tún lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i! Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “àjíǹde.” (Jòhánù 5:28, 29; 11:25; Ìṣe 24:15) Èyí yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run. Ní báyìí ná, àwọn òkú wà nínu sàréè láìmọ nǹkan kan, ‘wọ́n ń sùn,’ títí di ìgbà tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n “jí.”—Jòhánù 11:11-14; Orin Dáfídì 13:3.

Àwọn ènìyàn níbi gbogbó máa ń bẹ̀rù ohun tí wọn kò mọ̀. Ìmọ̀ pípéye lè sọ ẹnì kan di òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ìgbàgbọ́ tí kò fìdí múlẹ̀ nínú ohun asán. Bíbélì sọ òtítọ́ fún wa nípa ipò àwọn tí wọ́n wà nínú sàréè. Láìfọ̀rọ̀ lọ́ko lọ́jù, kò yẹ kí o bẹ̀rù òkú!—Jòhánù 8:32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́