Irè Oko Gbogboǹṣe, Tí Ó Jojú Ní Gbèsè
KÍ NI epo rọ̀bì, oúnjẹ màlúù, ọṣẹ, àti margarine jùmọ̀ ní pọ̀? Ní àwọn ilẹ̀ kan, gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a ń mú jáde pẹ̀lú ìrànwọ́ irúgbìn rape, pẹ̀lú òdòdo rẹ̀ aláwọ̀ òfefèé títàn yòò.
Ìbátan irúgbìn músítádì tí ó jojú ní gbèsè yìí, tí a máa ń gbìn ní àwọn apá kan ilẹ̀ Europe, Éṣíà, àti Àríwá America, ni a mọrírì ní pàtàkì, nítorí àwọn hóró èso rẹ̀ olóròóró. Èyí tí ó tó ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún hóró èso rape jẹ́ òróró, tí a lè lò ní oríṣiríṣi ọ̀nà.
Ọ̀pọ̀ jù lọ òróró hóró èso rape—bóyá tí ó pọ̀ tó ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún—ni a fi ń ṣe ohun jíjẹ. A fi ń ṣe margarine, bisikíìtì, ọbẹ̀, ice cream, àti àwọn dáyá. Ṣùgbọ́n, a tún lè fi òróró hóró èso rape ṣe ìmújáde epo rọ̀bì tí ìbafẹ́fẹ́jẹ́ rẹ̀ dín kù, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ń pààlà sí ìbàyíkájẹ́. Nígbà tí a bá fọ̀ ọ́ tán, a tún lè máa kán epo náà sí àwọn ẹ̀rọ ẹlẹgẹ́ láti mú kí wọ́n máa yí geere, lẹ́yìn tí a bá sì ti yọ òróró náà tán, a lè ṣu fùlùfúlù irè oko náà pọ̀ di ìdìpọ̀ ọlọ́pọ̀ èròja protein kan tí ó sì wúlò bí oúnjẹ ẹran.
Ẹ wo bí irè oko náà ti jẹ́ gbogboǹṣe tó! Lóòótọ́, a lè sọ bí onísáàmù náà ti sọ pé: “[Jèhófà], iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ti pọ̀ tó! nínú ọgbọ́n ni ìwọ́ ṣe gbogbo wọn.”—Orin Dáfídì 104:24.