ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 3
  • Ìyọrísí Ìdààmú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìyọrísí Ìdààmú
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iye Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Ń Pọ̀ Sí I
    Jí!—1996
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ayé Kan Tó Máa Dẹrùn fún Gbogbo Èèyàn
    Jí!—2002
  • Àwọn Èèyàn Tó Ń Wá Ibi Ààbò Kiri
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 3

Ìyọrísí Ìdààmú

BÁWO ni jíjẹ́ olùwá-ibi-ìsádi ṣe ń rí lára? Finú wòye pé o ti ń gbé ní àlàáfíà, ṣùgbọ́n lójijì ni gbogbo ipò ìgbésí ayé rẹ yí padà. Lọ́sàn-án kan òru kan, àwọn aládùúgbò di ọ̀tá. Àwọn sójà ń bọ̀ láti piyẹ́ ilé rẹ, kí wọ́n sì sun ún. O ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá láti palẹ̀ mọ́, kí o sì sálà fún ẹ̀mí rẹ. Àpò kékeré kan péré ni o lè gbé, nítorí pé o ní láti rù ú fún ọ̀pọ̀ kìlómítà. Kí ni ìwọ yóò kó sínu rẹ̀?

O ń sá lọ láàárín ìró ìbọn àti ìró ohun ìjà ogun ràgàjìràgàjì lọ́tùn-ún lósì. O dara pọ̀ mọ́ àwọn mìíràn tí ń sá lọ. Ọjọ́ ń gorí ọjọ́; bẹ́ẹ̀ lò ń wọ́ rìn, ebi ń pa ọ́, òùngbẹ ń gbẹ ọ́, ó sì rẹ̀ ọ́ tẹnutẹnu. Láti là á já, o ní láti tiraka láti máa lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò lókun nínú. O sùn sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀. O wá ohun tí ìwọ óò jẹ kiri inú pápá kan.

O dé orílẹ̀-èdè kan tí ó láàbò, àmọ́ àwọn olùṣọ́ ibodè kò jẹ́ kí o sọdá. Wọ́n tú àpò rẹ, wọ́n sì kó gbogbo ohun ṣíṣeyebíye inú rẹ̀. O dé ọ̀gangan ibi àyẹ̀wò míràn, o sì sọdá ààlà ilẹ̀ náà. Wọ́n fi ọ́ sí àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi kan tí ó dọ̀tí, tí wọ́n fi wáyà ẹlẹ́gùn-ún ṣọgbà yí ká. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn tí wọ́n ní irú ìṣòro rẹ wà yí ọ ká, o nímọ̀lára dídá nìkan wà, ṣìbáṣìbó sì bá ọ.

Àárò ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń sọ ọ́. O rí i tí o gbára lé ìrànwọ́ láti ibòmíràn pátápátá. Kò sí iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohunkóhun láti ṣe. O ń bá ìmọ̀lára àìnírànwọ́, àìnírètí, àti ti ìbínú jà. O ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ, ní mímọ̀ pé wíwà tí o wà ní àgọ́ náà ṣeé ṣe kí ó jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Ó ṣe tán, àgọ́ náà kì í ṣe ilé—ó dà bí iyàrá ìjókòódeni tàbí ilé tí a ń kó àwọn ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́ sí. O ṣe kàyéfì bóyá a óò fipá dá ọ padà sí ibi tí o ti wá.

Ìrírí tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyán ń ní lóde òní nìyí. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àbójútó Ọ̀ràn Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR) ṣe sọ, mílíọ̀nù 27 ènìyàn yíká ayé ni wọ́n ti sá fún ogun tàbí inúnibíni. Mílíọ̀nù 23 mìíràn ni a ti yí nípò padà ní orílẹ̀-ède wọn. Tí a bá da gbogbo rẹ̀ rò, 1 nínú ènìyàn 115 lórí ilẹ̀ ayé ni a ti fipá mú fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n jẹ́ obìnrin àti àwọn ọmọdé. Nítorí pé ìyọrísí ogun àti ìdààmú ló mú wọn jáde, a fi àwọn olùwá-ibi-ìsádi sínú àìlèdáàbò bo ara ẹni pátápátá nínú ayé kan tí kò fẹ́ wọn, ayé kan tí ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀, kì í ṣe nítorí irú ẹ̀dá tí wọ́n yà, ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi.

Wíwà tí wọ́n wà jẹ́ àmì pé rúkèrúdò líle koko wà yíká ayé. Àjọ UNHCR sọ pé: “Àwọn olùwá-ibi-ìsádi ni àmì tí ó kẹ́yìn nípa ìfọ́yángá ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Dájúdájú, àwọn ni ó kẹ́yìn lára ìsokọ́ra àwọn okùnfà àti àbáyọrí tí ń pinnu bí ìwólulẹ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ètò ìṣèlú orílẹ̀-èdè kan ṣe tó. Bí a bá wo àwọn olùwá-ibi-ìsádi yíká ayé, ipò wọn ní ń tọ́ka ibi tí ọ̀làjú ènìyán bá a dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́.”

Àwọn ògbógi sọ pé ìwọ̀n tí ìṣòro náà dé kò láfiwé, ó sì ń gbèrú sí i bí èyí tí òpin rẹ̀ kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó. Kí ló ṣamọ̀nà sí irú ipò bẹ́ẹ̀? Ojútùú kankan ha wà bí? Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò U.S. Navy

Ọmọdékùnrin apá òsì: UN PHOTO 159243/J. Isaac

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́