ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 26-27
  • Ṣíṣẹ́pá Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Pẹ̀lú Okun Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣẹ́pá Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Pẹ̀lú Okun Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Máa Tu Ara Yín Nínú Lẹ́nì Kíní Kejì”
  • Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Ń Mú Ìrètí Wá
  • Ìrẹ̀lẹ́kún Láti Ọ̀dọ̀ “Ọlọrun Ìtùnú Gbogbo”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • “Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • ‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 26-27

Ṣíṣẹ́pá Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Pẹ̀lú Okun Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ

NÍ February ọdún yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn láti Ìjọ Bailén ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sípéènì gbádùn ọjọ́ alárinrin kan pa pọ̀ ní Òkè Ńlá Sierra Nevada tí ń bẹ̀ nítòsí. Nígbà tí ó ku kìkì kìlómítà márùn-ún kí wọ́n padà délé, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ń bọ̀ yà bàrá sí ọ̀nà wọn, ó sì forí sọ orí pẹ̀lú bọ́ọ̀sì tí wọ́n wọ̀. Iná là, ọ̀wọ́ iná sì bo bọ́ọ̀sì náà. Àwọn èrò ọkọ̀ mélòó kan lè sá jáde kó tóó pẹ́ jù, ṣùgbọ́n èéfín bo ọ̀pọ̀ àwọn tó wà lẹ́yìn nínú bọ́ọ̀sì náà, wọ́n sì kú.

Lápapọ̀, Ẹlẹ́rìí 26 pàdánù ẹ̀mí wọn, ó ní àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mẹ́rin àti ọ̀pọ̀ ọmọ wẹ́wẹ́ nínú—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rin Ìjọ Bailén. Ọba ilẹ̀ Sípéènì, Juan Carlos, gbẹnu sọ fún ìmọ̀lára ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Sípéènì nígbà tí ó tẹ wáyà ránṣẹ́ sí olórí ìlu Bailén pé: “Ìjàm̀bá náà kó jìnnìjìnnì báni gidigidi. Ní ìdánilójú ìbánikẹ́dùn wa àtọkànwá. Jọ̀wọ́ fi ìbánikẹ́dùn àti ìtìlẹ́yìn wa ní àkókò ìṣòro yìí jíṣẹ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tí ọ̀ràn náà kàn.”

Ìbéèrè tí ó wá sọ́kàn àwọn kan lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó lọ síbi ìsìn ìsìnkú ni pé, Èé ṣe tí irú ọ̀ràn ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀? Ní kedere, àwọn ìjàm̀bá tí “ìgbà àti èṣe” ń fà lè kan àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́nà tí ó fi ń kan ẹnikẹ́ni mìíràn. (Oníwàásù 9:11, 12) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé láìpẹ́, irú ọ̀ràn ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ kì yóò sí mọ́.—Ìṣípayá 21:4, 5.

Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sípéènì àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè náà rìnrìn àjò lọ sí Bailén láti fún àwọn arákùnrin àdúgbò náà nítùnú àti ìtìlẹ́yìn. Àwọn ènìyàn ìlu Bailén, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìlú àti ti ẹkùn ìpínlẹ̀ pẹ̀lú ṣàjọpín ẹ̀dùn ọkàn àwọn ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Okun inú àwọn Ẹlẹ́rìí tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà wọ ọ̀pọ̀ àwọn alákìíyèsí lọ́kàn.

Antonio Gómez, olórí ìlú Bailén, sọ pé: “Mo ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ ọdún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èmi fúnra mi gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀, ìgbàgbọ́ yín jẹ́ ìyanu fún mi. Nígbà tí ìjàm̀bá náà ṣẹlẹ̀, mo ronú lọ́gán pé ìṣọ̀kan ìsìn àti ti ẹ̀dá ènìyàn yín yóò mú kí ẹ lè ṣẹ́pá ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà dáradára ju àwọn àwùjọ mìíràn lọ. Mo ti rí bí gbogbo ìlú ṣe ti àwọn ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lẹ́yìn. Bóyá tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ènìyàn ṣi irú ẹni tí ẹ jẹ́ lóye, ṣùgbọ́n ó dùn mọ́ mi láti sọ pé, àwọn àṣìlóye wọ̀nyí ti pò ó rá. Ẹ ní okun inú tí ó ṣòro fún ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí láti lóye.”

José Borrell, alábòójútó ètò iṣẹ́ òde, tí ó lọ síbi ìsìnkú náà gẹ́gẹ́ bí aṣojú ìjọba ilẹ̀ Sípéènì, jẹ́wọ́ pé: “Irú ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni o lè sọ fún àwọn tí wọ́n ti pàdánù gbogbo ìdílé wọn lọ́wọ́ kan? Kò sí èyí tí ó lè sàn ju èyí tí àwọn fúnra wọ́n ti rí nínú ìgbàgbọ́ wọn lọ. . . . Ìgbàgbọ́ àgbàyanu ni ẹ ní.”

“Ẹ Máa Tu Ara Yín Nínú Lẹ́nì Kíní Kejì”

Kí ni wọ́n “rí nínú ìgbàgbọ́ wọn”? Ju ohun gbogbo lọ, wọ́n rí ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4) Láìka ẹ̀dùn ọkàn wọn sí, wọ́n ní okun láti tu ẹnì kíní kejì nínú, ní fífi àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Tẹsalóníkà sọ́kàn pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kíní kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kíní kejì.”—Tẹsalóníkà Kíìní 5:11.

Ó jẹ́ ìrírí wíwọni lọ́kàn láti rí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin, tí díẹ̀ lára wọ́n ti pàdánù ìbátan bíi mẹ́jọ, tí wọ́n ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà míràn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú ìjọ. Francisco Saez, alábòójútó olùṣalága, tí òun fúnra rẹ̀ pàdánù ọmọ rẹ̀ méjèèjì, ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a bá rí ara wa, a ń sunkún. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú omi náà lójú, a ń rán ara wa létí ìrètí àjíǹde, a sì ń ní ìtùnú.

“A kò pa iṣẹ́ ìwàásù wa tì, a sì fi í ṣe ìsapá àrà ọ̀tọ̀ láti bẹ àwọn ìbátan àwọn tí wọ́n kú, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí wò, ní lílo ìwé pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú.” Francisco ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ń fẹ́ láti wàásù, nítorí mo mọ̀ pé nípa wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn, ara mi yóò túbọ̀ yá gágá sí i. Ó sì dájú pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń jáde lọ pẹ̀lú omi lójú, mo ń padà sílé pẹ̀lú ìtùnú.”

Àwọn ará ìlu Bailén hùwà padà lọ́nà rere sí iṣẹ́ ìwàásù yìí. Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìjàm̀bá náà, Encarna, tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọbìnrin rẹ̀ méjì àti ọmọ-ọmọ mẹ́rin, ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Encarna ti ń fún obìnrin yìí, tí ọkọ rẹ̀ kú ní oṣù mẹ́rin ṣáájú, ní ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́. Bí wọ́n ti ń bá ìjíròrò wọn lọ nínú ìwé pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, ó wí pé: “Nísinsìnyí, àwa méjèèjì ní láti máa tu ara wa nínú.”

Lọ́gán ni ìtìlẹ́yìn tún ń wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé. Francisco Capilla, akọ̀wé ìjọ náà, ṣàlàyé pé: “Ìjọ lódindi nímọ̀lára ìṣírí gidigidi nípasẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn lẹ́tà àti wáyà tí a ti rí gbà. Ńṣe ni ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ń fi ọkọ̀ kan kó wọn wá sílé wa ní tààràtà lójoojúmọ́. A dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́ àwọn ará.”

Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Ń Mú Ìrètí Wá

Ire kankan ha lè wá láti inú irú ọ̀ràn ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ bí? Ọba Sólómọ́nì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Àyà ọlọgbọ́n ń bẹ ní ilé ọ̀fọ̀.” (Oníwàásù 7:4) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà yìí, ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà ní Bailén ti mú kí àwọn ènìyàn díẹ̀ túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Faustino, ọkọ kan tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́, tí ó pàdánù méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà nínú ìjàm̀bá náà, sọ fún aya rẹ̀, Dolores, pé: “Mo ní ìhìn rere kan láti sọ fún ọ. N óò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí pé mo fẹ́ láti rí àwọn ọmọ mi nínú ayé tuntun.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Bailén kì yóò tètè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn, wọ́n ń tu àwọn mìíràn nínú, a sì ń tu àwọn náà nínú. Jèhófà ń fún wọn lókun pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀ àti pẹ̀lú ìtìlẹyìn ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́. Àdúrà wa fún wọn ń bá a lọ sí Bàbá wa ọ̀run.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mẹ́rin lára àwọn tó ṣègbé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́