ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oríṣi Pàto Fáírọ́ọ̀sì HIV ní India
  • Ìṣètò Ìrànwọ́ Nítorí Ọ̀dá ní Zimbabwe
  • Wọ́n Ní Orísun Kan Náà Kẹ̀?
  • A Pa Iná Tí Ó Jó fún 100 Ọdún
  • Ẹ̀jẹ̀ Ríru àti Ìpàdánù Agbára Ìrántí
  • Àlàfo Nínú Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀
  • Ìjàm̀bá Ọkọ̀—Èé Ṣe?
  • Pípiyẹ́ Òkun
  • A Ṣèèṣì Ṣàwári Pílánẹ́ẹ̀tì Kan
  • A Kò Fojú Rere Wo Ìsìn àti Ìṣèlú
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Oríṣi Pàto Fáírọ́ọ̀sì HIV ní India

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Ẹ̀ka Orílẹ̀-Èdè fún Ìwádìí Àrùn AIDS ní Pune, India, ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwùjọ àwọn olùwádìí tí Dókítà Max Essex, ti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Nípa Àrùn AIDS ní Harvard ṣíwájú fún, ti ṣàwárí oríṣi pàto fáírọ́ọ̀sì HIV tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ní India. Òun ni fáírọ́ọ̀sì HIV-1C, tí a gbà gbọ́ pé ó rọrùn láti tàn kálẹ̀ ní ìlọ́po márùn-ún sí mẹ́wàá ju fáírọ́ọ̀sì HIV-1B, tí ó wọ́pọ̀ ní Europe àti America lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Indian Express ṣe sọ, Dókítà Essex sọ pé, ó ṣeé ṣe kí ìwọ̀n tí fáírọ́ọ̀sì HIV fi ń tàn kálẹ̀ ní India pọ̀ gan-an ju ti apá púpọ̀ míràn lágbàáyé lọ. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, Dókítà V. Ramalingaswami, ṣàkíyèsí pé kò sí ọ̀kan lára àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí a nírètí pé yóò kẹ́sẹ járí láti dènà àrùn AIDS, tí ó gbéṣẹ́ fún fáírọ́ọ̀sì HIV-1C.

Ìṣètò Ìrànwọ́ Nítorí Ọ̀dá ní Zimbabwe

Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sábà máa ń pèsè ìrànwọ́ ní àwọn àdúgbò tí ìjábá bá kọ lù. Ẹ̀mí Kristẹni wọn ni a nílò ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà bíi Zimbabwe, níbi tí ọ̀dá ti kọ lu ọ̀pọ̀ ẹkùn ilẹ̀ orílẹ̀-èdè náà. Tìfẹ́tìfẹ́, a dá ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ àti aṣọ jọ fún iṣẹ́ yìí, ẹ̀ka ọ́fíìsi Watch Tower Society ní Zimbabwe sì ṣàṣeyọrí ní pípín àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn ní àwọn agbègbè jíjìnnà orílẹ̀-èdè náà. Ní àfikún sí oúnjẹ àti aṣọ, àwọn Ẹlẹ́rìí ará Zimbabwe fi 7,500 dọ́là ilẹ̀ United States ṣètọrẹ, Watch Tower Society sì ná 20,500 dọ́là míràn láti bójú tó iṣẹ́ ìrànwọ́ náà. Society àti àwọn Ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn kàn fi ìmọrírì wọn jíjinlẹ̀ hàn fún ìfẹ́ ọlọ́làwọ́ tí àwọn Kristẹni arákùnrin wọn fi hàn.

Wọ́n Ní Orísun Kan Náà Kẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ti Paris ṣe sọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan nínú gbajúgbajà ìwé ìròyìn ẹgbẹ́ Jesuit náà, La Civiltà Cattolica, sọ pé “Ọlọ́run lè ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìwé yíyàtọ̀ síra bíi Kùránì ti àwọn Mùsùlùmí, Vedas àti Bhagavad-Gita ti àwọn Hindu àti àwọn ìwé mímọ́ ìsìn Tao ti China àti ti ìsìn Shinto ti Japan.” Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà dámọ̀ràn pé, ìwọ̀nyí àti àwọn àkọsílẹ̀ ìsìn míràn “kì í ṣe ìwé ìtàn tàbí ọgbọ́n èrò orí lásán, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ ‘ìṣípayá’—bí Ọlọ́run ṣe sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ènìyàn.” Nítorí pé àwọn aṣelámèyítọ́ ní Vatican máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn yìí, a ti gbé ìbéèrè dìde lórí bóyá ojú ìwòye wọ̀nyí dọ́gba pẹ̀lú èrò inú póòpù fúnra rẹ̀ lórí ọ̀ràn náà. Ìwé agbéròyìnjáde Tribune ṣàkíyèsí pé, nínú ìwé rẹ̀, Crossing the Threshold of Hope, John Paul Kejì sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì náà ń wá ohun kan tí ó jẹ́ irú orísun àjùmọ̀ní kan pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà nínú àwọn ìsìn míràn.

A Pa Iná Tí Ó Jó fún 100 Ọdún

Èédú ilẹ̀ tí a kò tí ì wà jáde ní China gbiná ní èyí tí ó lé ní 100 ọdún sẹ́yìn, ó sì ti ń jó láti ìgbà náà títí di àìpẹ́ yìí. Iná náà gba nǹkan bíi kìlómítà mẹ́fà lóròó níbùú, ó sì ń jó 300,000 tọ́ọ̀nù èédú ilẹ̀ lọ́dọọdún. Àwọn ìsapá láti pa iná ńlá náà ti kùnà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, a ròyìn pé àwọn panápaná ti ṣàṣeyọrí ní pípa iná náà nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Láti pa ìjófòfò náà, àwọn panápaná lo àwọn ohun abúgbàù láti gbẹ́ àwọn ihò, wọ́n sì da iyanrìn, òkúta, àti omi sí ọ̀wọ́ iná náà.

Ẹ̀jẹ̀ Ríru àti Ìpàdánù Agbára Ìrántí

Ìwé ìròyin Psychology Today ròyìn pé: “Ìwádìí tuntun kan fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ọkùnrin àgbàlagbà tí wọ́n ní ẹ̀jẹ̀ ríru ní agbára ìrántí, agbára ìṣèpinnu, àti agbára ìpọkànpọ̀ tí a pa lára, nígbà tí wọ́n bá ti lè wọ àwọn ìbẹ̀rẹ̀ 70 ọdún ìgbésí ayé wọn.” Àwọn olùwádìí rí i pé, fún ìlọsókè ìwọ̀n mẹ́wàá kọ̀ọ̀kan nínú ìtújáde ẹ̀jẹ̀ láti inú ọkàn-àyà, ìdínkù tí ó ṣeé ṣe nínú ìṣiṣẹ́ ọpọlọ jẹ́ ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún. Ọ̀mọ̀wé Lenore Launer, olùdarí ìwádìí náà, sọ pé: “A mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ ríru ní ìbátan pẹ̀lú àrùn ẹ̀gbà àti àrùn ọkàn-àyà,” ní fífi kún un pé: “Èyí wulẹ̀ jẹ́ ìdí mìíràn láti dín in kù.”

Àlàfo Nínú Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀

Ìwé agbéròyìnjáde The Courier-Mail ti Brisbane, Australia, ròyìn pé, ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ kan rí i pé àwọn ọ̀dọ́langba akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga kì í sábà ní ìfikùnlukùn pẹ̀lú àwọn bàbá wọn, bí wọ́n bá tilẹ̀ ń ní in rárá. Ìwádìí náà fi hàn pé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́langba kì í lò tó ìṣẹ́jú 15 pẹ̀lú àwọn bàbá wọn lóòjọ́, síbẹ̀, wọ́n ń bá àwọn ìyá wọn sọ̀rọ̀ fún nǹkan bíi wákàtí kan lóòjọ́. Agbára káká ni àwọn òbí fi máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìwà híhù tàbí kí wọ́n wádìí nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tàbí fídíò tí wọ́n ń wò. Ìjíròrò èyíkéyìí láàárín àwọn ọmọkùnrin àti àwọn bàbá ṣeé ṣe kí ó jẹ́ lórí àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì, bíi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti eré ìdárayá. Ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ìyá sábà máa ń jẹ́ nípa àwọn ọ̀rẹ́, ilé ẹ̀kọ́, àti ìwéwèé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, agbára káká ni ó fi máa ń jẹ́ nípa àwọn ọ̀ràn tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Nínú àwọn ọ̀ràn púpọ̀, ìjíròrò láàárín àwọn ọmọbìnrin àti àwọn bàbá máa ń mọ sórí àwàdà tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ láàárín ara wọn lásán.

Ìjàm̀bá Ọkọ̀—Èé Ṣe?

Ìròyìn ìwádìí kan tí ilé iṣẹ́ ìgbòkègbodò ọkọ̀ ilẹ̀ Brazil gbé jáde fi hàn pé nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìjàm̀bá ọkọ̀ ń ṣẹlẹ̀ nítorí àṣìṣe tàbí àìfiǹkanpè awakọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, àwọn awakọ̀ sábà máa ń dá ara wọn lójú jù bí wọ́n bá ń wakọ̀ lábẹ́ ipò ojú ọjọ́ tí ó dára tàbí ní ojú títì tó tọ́ rangbọndan. Ìròyìn náà tún ṣí i payá pé ojú ọ̀nà tí kò dára àti àwọn àbùkù ara ọkọ̀ ń yọrí sí ikú 25,000 ènìyàn àti 350,000 ènìyàn tí ń fara pa lọ́dọọdún ní Brazil.

Pípiyẹ́ Òkun

Ìwé ìròyin New Scientist sọ pé: “Nínú eré àsápajúdé láti ṣàwárí àwọn egbòogi tuntun tí ó lè mérè rẹpẹtẹ wọlé, ‘àwọn olùṣàwárí àwọn ẹ̀dá tí a lè lò fún ìṣòwò’ tí ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ilé iṣẹ́ ìpoògùn ń kó iye ẹ̀dá púpọ̀ jù jáde láti inú òkun láìka àwọn àbájáde rẹ̀ sí.” Gẹ́gẹ́ bí Mary Garson, onímọ̀ nípa ohun alààyè inú omi ní Yunifásítì Queensland, Australia, ṣe wí, ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àfiṣàpẹẹrẹ tí a kó jáde ni a ń kó dà nù láìsí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé kíkún. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan 450 kìlógíráàmù aràn acorn, àti 2,400 kìlógíráàmù sponge ń mú mìlígíráàmù 1 èròjà tí ń gbógun ti àrùn jẹjẹrẹ jáde, 1,600 kìlógíráàmù ehoro òkun ń mú mìlígíráàmù 10 oríṣi èròjà peptide tí a fi ń wo àrùn kókó ọlọyún dúdú jáde, a sì nílò 847 kìlógíráàmù ẹ̀dọ moray eel láti yọ kìkì 0.35 mìlígíráàmù èròjà ciguatoxin fún àyẹ̀wò. Garson sọ pé: “A kò wulẹ̀ lè máa kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹ̀dá láti inú agbami òkun—bí ó ti wù kí wọ́n wúlò tó—láìṣe pé ó dá wa lójú pé, kì í ṣe pé a ń pa wọ́n run.”

A Ṣèèṣì Ṣàwári Pílánẹ́ẹ̀tì Kan

Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ onímọ̀ ìjìnlẹ sánmà, George Sallit, ti Bradfield, abúlé kan ní England, ti fi awò awọ̀nàjíjìn kan tí ń bẹ nínú ahéré kan nínú ọgbà rẹ̀ ṣàwári pílánẹ́ẹ̀tì kékeré kan láìpẹ́ yìí. Ó gbà pé: “Èèṣì pátá gbáà ni. Mo ya fọ́tò kan, nígbà tí mo sì wò ó fínnífínní, mo rí i pé pílánẹ́ẹ̀tì kan, tí ó rọra ń rìn la ojú ilẹ̀ tí a yà náà já ni.” Pílánẹ́ẹ̀tì tuntun náà tí a ń pè ní Sallit One báyìí jẹ́ 30 kìlómítà ní ìwọ̀n ìdábùú òbírí, ó sì jìn tó 600 mílíọ̀nu kìlómítà sí ilẹ̀ ayé. Òpó rẹ̀ mú un gba àárín Mars àti Júpítà. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ròyìn pé, awò awọ̀nàjíjìn tí a lò náà fẹ̀ ní 30 sẹ̀ǹtímítà, ó jẹ́ irú èyí tí a ń fi kọ̀m̀pútà darí tí iye rẹ̀ tó 7,000 dọ́là, ṣùgbọ́n tí ó ń lo ohun èlò àgbékalẹ̀ tí a wéwèé fún lílò lórí awò awọ̀nàjíjin Hubble. Ìgbékalẹ̀ ìṣètò oòrùn wa lè ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, tàbí asteroid, kéékèèké bẹ́ẹ̀ nínú.

Ìyàlẹ́nu Fún Àwọn Àgbẹ̀ Onírẹsì

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn àgbẹ̀ onírẹsì ní Éṣíà máa ń fún ọ̀pọ̀ oògùn apakòkòrò sórí irè oko wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ àsìkò ọ̀gbìn láti pa àwọn mùkúlù àwọn àfòpiná tí ń ká ewé kò, tí wọ́n máa ń jẹ púpọ̀ ewé orí igi ìrẹsì run. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àyẹ̀wò lọ́ọ́lọ́ọ́ dábàá pé àwọn igi ìrẹsì lè pàdánù tó ìdajì ewé wọn láìṣèpalára kankan fún bí wọ́n ṣe ń so tó. A fi dá àwọn àgbẹ̀ ará Vietnam mélòó kan lójú débi tí wọ́n fi gbin irè wọn láìlo oògùn apakòkòrò ní ìbẹ̀rẹ̀ àsìkò ọ̀gbìn—èyí tí ó jẹ́ nǹkan bí ìpín 30 sí 50 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo oògùn apakòkòrò tí àwọn àgbẹ̀ ará Éṣíà ń lò—wọ́n sì rí i pé kò ní ipa búburú kankan lórí irè tí ohun ọ̀gbìn wọn mú jáde.

A Kò Fojú Rere Wo Ìsìn àti Ìṣèlú

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Australian ṣe sọ, “àmúṣàpẹẹrẹ àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà ọmọ ilẹ̀ Australia” kò ní ìfẹ́ gidi sí ìṣèlú tàbí ìsìn. Ó gbé ìparí èrò yìí ka orí ìwádìí tí olùdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì Sydney, Ọ̀mọ̀wé Jennifer Bowes, ṣe láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún 13 sí 16. A to àwọn ohun àkọ́múṣe àwọn èwe náà lẹ́sẹẹsẹ láti orí èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ báyìí: “níní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, níní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yíyè kooro, níní iṣẹ́ jíjọjú, mímú ẹ̀bùn mi dàgbà, wíwà sún mọ́ ìdílé mi, dídáàbò bo ilẹ̀ ayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, dídáàbò bo àwọn ẹranko, níní ilé tó jíire, rírin ìrìn àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míràn, pípa owó rẹpẹtẹ wọlé, ṣíṣe nǹkan kan láti fòpin sí ìbàyíkájẹ́, ṣíṣègbeyàwó, ríran àwọn tí kò rìnnà kore tó bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ríran orílẹ̀-èdè mi lọ́wọ́, ṣíṣe ohun kan tí ó tóó tun fún àwùjọ, nínípa lórí àwọn ẹlòmíràn lọ́nà kan ṣáá.” Méjì tí ìjẹ́pàtàkì wọn kéré jù lọ lára àwọn ohun 18 tí a tò sílẹ̀ ni “títẹ̀ lé àwọn ìlànà ìsìn mi” àti “kíkópa nínú ìṣèlú.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́