Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ Mo bá ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan, tí ó ti kó àwọn ọmọ mélòó kan tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe tira, pàdé. Mo fi ìtẹ̀jáde October 8, 1993, tí ó ní ọ̀wọ́ “Dáàbòbo Awọn Ọmọ Rẹ!” lọ̀ ọ́. Nígbà tí mo tún padà bẹ̀ ẹ́ wò, ó wí pé: “Àwọn àpilẹ̀kọ náà ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ipò tuntun yìí. Mo mú ìwé ìròyìn náà dání nígbà tí mo ń lọ fún ìgbẹ́jọ́ kan ní ilé ẹjọ́ àwọn màjèṣín, mo sì fi han agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́. Àwọn àpilẹ̀kọ náà wú òun àti adájọ́ náà lórí, wọ́n sì fẹ́ láti pín wọn fún àwọn amòfin mìíràn.” Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin yìí béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí i, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa báyìí.
E. T. V., Brazil
Àwọn Àdìtú Ọlọ́rọ̀ Títò Ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, èmi àti ọmọ-ọmọ mi obìnrin ń yẹ Jí!, December 8, 1995 (Gẹ̀ẹ́sì), wò, nígbà tí a rí àdìtú ọlọ́rọ̀ títò nínú rẹ̀. Ó ké jáde pé, “Mo fẹ́ràn àwọn àdìtú ọlọ́rọ̀ títò!” Nítorí náà, a jùmọ̀ yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà wò, mo sì jẹ́ kí ó ronú kan àwọn ìdáhùn náà fúnra rẹ̀. A lo nǹkan bí ìdajì wákàtí alárinrin náà pọ̀. Ẹ máa bá a nìṣó! A ń fojú sọ́nà fún àdìtú ọlọ́rọ̀ títò tí ń bọ̀.
M. G., Kánádà
Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí. Mo fẹ́ràn àwọn ìwé ìròyìn yín, ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo fẹ́ràn àwọn àdìtú ọlọ́rọ̀ títò nítorí tí wọ́n máa ń mú kí n máa rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ènìyàn inú Bíbélì. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún apá fífani mọ́ra yìí.
J. M. T., Brazil
Àwọn Àrùn Panipani Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ pípéye, tí ó ṣe kedere, tí ó sì kúnjú ìwọ̀n náà, “Àwọn Àrùn Panipani—Ogun Tí Ènìyàn Ń Bá Kòkòrò Àrùn Jà.” (February 22, 1996) N kò fìgbà kankan mọ bí kòkòrò àrùn ṣe díjú púpọ̀ tó àti bí ó ṣe lè ṣèpalára ti ara ìyára tó.
C. L., United States
Ìwé ìròyìn náà bọ́ sásìkò gan-an, níwọ̀n bí mo ti kó àrùn otútù àyà, tí mo sì ní láti máa lo àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn. Àwọn àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí àrùn náà fi le sí i dípò kí ó sàn lẹ́yìn tí mo lo egbòogi náà fún ìgbà àkọ́kọ́. Mo dúpẹ́ fún kókó ọ̀rọ̀ yìí tí ẹ pèsè lọ́nà tí ó rọrùn láti lóye bẹ́ẹ̀.
I. W., Germany
Etiopia Lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ “Etiopia Fífani Mọ́ra” (February 22, 1996), ọkàn àyà mi kún fún ọpẹ́. Mo ní ọ̀pọ̀ ẹbí, tí wọ́n jẹ́ ará Etiopia, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí dára gan-an débi pé mo ní ìdánilójú pé yóò ru ọkàn ìfẹ́ wọn sókè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run wa títóbi, Jèhófà.
J. R., Luxembourg
Afọ̀jọ̀jọ̀-Àlejò-Ṣiṣẹ́ṣe Nígbà Kan Rí Àpilẹ̀kọ “Ọmọ Àkèré” (February 22, 1996) ru mí sókè gidigidi. Nítorí ipá tí ìyá mi ní lórí mi, mo kọ́ ijó alálọ̀ọ́yípo ti ìbílẹ̀ láti ìgbà ọmọdé pínníṣín. Nígbà tí mo di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo pinnu láti fi ijó alálọ̀ọ́yípo sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo kúndùn rẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí fún mi níṣìírí. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé àwọn Kristẹni mìíràn wà, tí wọ́n ti ṣe irú ìrúbọ kan. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín tọkàntọkàn.
Y. S., Japan
Omijé bọ́ lójú mi nígbà tí mo wo àwòrán Sawako Takahashi pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ aláyọ̀, tí ń tẹ̀ lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwọn ìjìyà tí mo ti fojú winá sẹ́yìn ti jẹ gàba lórí ìgbésí ayé mi, ìmọ̀lára ìfìyà jẹni sì ti mú mi ṣàìláyọ̀ gidigidi. Mímọ̀ pé Jèhófà yóò dárí àwọn ìkùnà mí àtijọ́ jì mí ti fún mi ní ìgboyà láti gbìyànjú láti di Kristẹni tí a batisí.
M. K., Japan
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìtàn akọ́ni lọ́gbọ́n tí ó sì dùn mọ́ni jù lọ tí mo tí ì kà rí. Ó tún ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ìjọsìn àwọn baba ńlá ní nínú. Kò tí ì ṣeé ṣe fún mi láti lóye irú ìjọsìn yìí ṣáájú kí n tóó ka ìtàn ìgbésí ayé ara ẹni yìí.
P. Y., United States