ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/8 ojú ìwé 4-8
  • Ìsìn Èké Forí Lé Ìparun Rẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìsìn Èké Forí Lé Ìparun Rẹ̀!
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídá Aṣẹ́wó Náà Mọ̀
  • Èé Ṣe Tí Ìparun Náà Fi Sún Mọ́lé Tó Bẹ́ẹ̀?
  • Pípa Bábílónì Ńlá Run
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Ṣíṣèdájọ́ Aṣẹ́wó Burúkú Náà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Ọba naa Jà ní Armageddoni
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ohun Tí Ìwé Ìfihàn Sọ Pé Ó Máa Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Ọ̀tá Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Jí!—1996
g96 11/8 ojú ìwé 4-8

Ìsìn Èké Forí Lé Ìparun Rẹ̀!

LÁTI ṣàwárí bóyá àwọn ìsìn ayé yìí ti ń sún mọ́ òpin wọn, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ amúnijígìrì jù lọ tí ó wà nínú Bíbélì. Ó jẹ́ nípa ìjìnlẹ̀ obìnrin ìṣàpẹẹrẹ tí a júwe nínú ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì, Ìṣípayá.

Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo obìnrin kan, tí ó ti ń ṣàkóso bí ọbabìnrin lórí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ń nípa lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn, la gbogbo ìtàn já—obìnrin ọlọ́rọ̀ kan, tí ó fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò ṣe ọ̀ṣọ́ ẹ̀yẹ pàpàrẹrẹ, tí ó sì fi wúrà, òkúta ṣíṣeyebíye, àti péálì, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì? Ní iwájú orí rẹ̀, a kọ orúkọ gígùn kan, ohun ìjìnlẹ̀ kan: “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.” A mọ̀ ọ́n dunjú fún ọ̀nà ìgbésí ayé ewèlè àti oníṣekúṣe rẹ̀, níwọ̀n bí ó ti bá àwọn olùṣàkóso ayé ṣe “àgbèrè.” Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti tò jọ pelemọ dé ọ̀run. Ó ń gun ẹranko ẹhànnà kíkàmàmà kan, tí ó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò, orí méje, àti ìwo mẹ́wàá.—Ìṣípayá 17:1-6; 18:5.

Bí o bá lè fojú inú wo obìnrin yìí, o ní òye díẹ̀ nípa olórí ẹni ìtàn tí ó wà nínú ọ̀wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí àpọ́sítélì Jésù náà, Jòhánù, rí nínú ìran kan tí a fi fún un nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan. Ó ṣàpèjúwe rẹ̀ kedere nínú Ìṣípayá orí 17 àti 18. Ka orí ìwé wọ̀nyí nínú Bíbélì rẹ. Yóò ṣeé ṣe fún ọ láti tẹ̀ lé ìtòtẹ̀léra àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti bí a ṣe tú ẹni tí ìjìnlẹ̀ obìnrin yìí jẹ́ fó títí dé òpin rẹ̀ nínú ikú.

Dídá Aṣẹ́wó Náà Mọ̀

A rí amọ̀nà kan sí lílóye ẹni tí ó jẹ́ nínú àwọn ohun méjèèjì tí ọbabìnrin aṣẹ́wó náà jókòó lé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ní Ìṣípayá 17:18, a júwe rẹ̀ bí “ìlú ńlá títóbi náà tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” Èyí fàyè gbà á láti jókòó lórí “omi púpọ̀,” tí ó túmọ̀ sí “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n,” bí a ṣe fi hàn ní Ìṣípayá 17:1, 15. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 3 nínú orí kan náà ṣe sọ, a tún rí i tí ó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà kan tí ó ní orí méje—a sì sábà ń lo àwọn ẹranko nínú Bíbélì láti ṣàpẹẹrẹ àwọn agbára ìṣèlú, tàbí àwọn ètò àjọ, ti ayé.

Èyí ń tọ́ka sí i pé aṣẹ́wó náà, Bábílónì Ńlá, dúró fún ilẹ̀ ọba tí a gbé ga kan, ọ̀kan tí ń jọba lé àwọn aláṣẹ mìíràn àti àwọn ọmọ abẹ́ wọn lórí. Èyí lè jẹ́ kìkì ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé nìkan.

Agbára ìdarí tí àwọn aṣáájú ìsìn ń ní lórí àwọn ìlànà orílẹ̀-èdè àti ìṣèlú jẹ́ apá kan tí a mọ̀ dunjú dáradára nínú ìtàn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Lẹ́yìn ìṣubú Ilẹ̀ Ọba Ìwọ̀ Oòrùn Róòmù [ọ̀rúndún karùn-ún], póòpù ní ọlá àṣẹ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ ní ilẹ̀ Europe. . . . Póòpù lo ọlá àṣẹ ìṣèlú pa pọ̀ mọ́ ti ẹ̀mí. Ní ọdún 800, Póòpù Leo Kẹta dé olùṣàkóso ọmọ ẹ̀yà Franks náà, Charlemagne [Charles Ńlá] ládé bí olú ọba àwọn ará Róòmù. . . . Leo Kẹta ti fìdí ẹ̀tọ́ póòpù láti sọ ọlá àṣẹ olú ọba kan di èyí tí ó bófin mu múlẹ̀.”

Kádínà Thomas Wolsey (1475? sí 1530) pèsè àpẹẹrẹ síwájú sí i nípa irú ọlá àṣẹ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti àwọn “ọmọ aládé” rẹ̀ ń lò lórí àwọn olùṣàkóso. Wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó lágbára jù lọ ní ilẹ̀ England fún ọ̀pọ̀ ọdún.” Lábẹ́ ìṣàkóso Ọba Henry Kẹjọ, òun “ni ẹni tí ń darí gbogbo ọ̀ràn ìjọba láìpẹ́. . . . Ó ń gbé inú ọlá ńlá ọlọ́ba, ó sì ń jẹ̀gbádùn nínú agbára rẹ̀.” Ìròyìn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà ń bá a lọ pé: “Kádínà Wolsey lo agbára ńlá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣèlú àti alákòóso ní pàtàkì nínú bíbójú tó àwọn ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè ti ilẹ̀ England fún Henry Kẹjọ.”

Àpẹẹrẹ títayọ mìíràn nípa ọlá àṣẹ Kátólíìkì lórí àwọn ọ̀ràn orílẹ̀-èdè, tí kì í ṣe ti ìsìn, ni ti Kádínà Richelieu ti ilẹ̀ Faransé (1585 sí 1642), ẹni tí “ó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Faransé ní gidi gan-an . . . fún èyí tí ó lé ní ọdún 18.” Ìwé ìtọ́kasí tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ṣáájú sọ pé: “Ó ní ìfẹ́ tí ó ré kọjá ààlà sí ipò gíga, ó sì di aláìní sùúrù láìpẹ́.” Ó di kádínà ní 1622, “kò sì pẹ́ tí ó fi di abẹnugan nínú ìṣàkóso ilẹ̀ Faransé.” Ó ṣe kedere pé ó jẹ́ akíkanjú ẹ̀dá, nítorí pé “ó fúnra rẹ̀ ṣáájú ẹgbẹ́ ogun ọba nígbà ìsàgatì La Rochelle.” Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Ìfẹ́ ọkàn gíga jù lọ tí Richelieu ní wà nínú àwọn ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè.”

A ń rí bí àjọṣepọ̀ Vatican pẹ̀lú àwọn aláṣẹ òṣèlú ṣe ń bá a lọ ní kedere nínú àwọn ìkéde lemọ́lemọ́ tí ń jáde nínú ìwé ìròyìn Vatican náà, L’Osservatore Romano, nípa àwọn aṣojú ilẹ̀ òkèèrè tí ń kó àwọn ìwé ẹ̀rí wọn fún póòpù aláṣẹ. Ó ṣe kedere pé, Vatican ní ọ̀wọ́ àwọn onísìn Kátólíìkì tí wọ́n dúró ṣinṣin, tí wọ́n lè máa fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀ràn ìṣèlú àti ti àjọṣepọ̀ kárí ayé tó póòpù létí.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ sí i ni ó wà láti ṣàpèjúwe agbára ìdarí lílágbára tí àwọn aṣáájú ìsìn ní—nínú àti lóde Kirisẹ́ńdọ̀mù—nínú àwọn àlámọ̀rí ìṣèlú ayé yìí. Òtítọ́ náà pé aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ náà jókòó lórí “omi púpọ̀” (tí ó dúró fún “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè”) àti lórí ẹranko ẹhànnà náà (tí ó dúró fún gbogbo agbára ìṣèlú ayé) tún dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé agbára ìdarí rẹ̀ lórí àwọn ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè, àti àwọn aláṣẹ jẹ́ oríṣi kan tí ó yàtọ̀, tí ó sì ga lọ́lá ju ìjẹgàba ìṣèlú lásán lọ. Ẹ jẹ́ kí a wo oríṣi tí ó jẹ́.

Apá kan lára orúkọ gígùn tí ó wà níwájú orí rẹ̀ ni “Bábílónì Ńlá.” Ó jẹ́ ìtọ́ka kan sí Bábílónì ìgbàanì, tí Nímírọ́dù, ẹni tí ó wà ní “ìdojúùjàkọ Jèhófà,” Ọlọ́run tòótọ́, tẹ̀ dó ní nǹkan bí 4,000 ọdún sẹ́yìn. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8-10) Jíjẹ́ tí ó ń jẹ́ orúkọ yìí tọ́ka sí i pé ó jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ Bábílónì ìgbàanì lọ́nà títóbi, tí ó sì ní àwọn onírúurú ẹ̀ka jíjọra. Kí ni àwọn onírúurú ẹ̀ka náà? Bábílónì ìgbàanì kún fún ìsìn awo, àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ń rẹni sílẹ̀, ìbọ̀rìṣà, idán, ìwòràwọ̀, àti ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán—tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà dẹ́bi fún gbogbo wọn.

Ìwé atúmọ̀ The New International Dictionary of New Testament Theology sọ pé, ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n sọ Marduk di “òrìṣà ìlú fún Bábílónì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di olórí nínú tẹ́ḿpìlì nǹkan bí àgbájọ 1300 òrìṣà ilẹ̀ Súmérì òun Ákádì. Ó so gbogbo àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn pọ̀ di ìgbékalẹ̀ kan ṣoṣo. . . . Ní Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9, a ṣàpèjúwe ìṣètò ìkọ́lé tẹ́ḿpìlì kíkàmàmà ti Bábílónì gẹ́gẹ́ bí àfihàn ìgbéraga ẹ̀dá ènìyàn tí ń fẹ́ láti já ọ̀run gbà tipátipá.”

Nípa bẹ́ẹ̀, Bábílónì ìgbàanì ni ìkóríta ìsìn èké, èyí tí ó wáá ran gbogbo ayé bí àkókò ti ń lọ. Àwọn àṣà, ẹ̀kọ́, òfin àtọwọ́dọ́wọ́, àti àmì ìṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n jẹ́ ti Bábílónì, ti tú ká sí gbogbo apá ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ń jẹ jáde nínú àwọn onírúurú àmúlùmálà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìsìn ayé. Àwọn ìjọba olóṣèlú àti àwọn ilẹ̀ ọba ti gbérí, wọ́n sì ti ṣubú, ṣùgbọ́n ìsìn Bábílónì ti la gbogbo rẹ̀ já.

Èé Ṣe Tí Ìparun Náà Fi Sún Mọ́lé Tó Bẹ́ẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí a ti máa ń ṣàlàyé léraléra nínú àwọn ìtẹ̀jáde ìṣáájú ìwé ìròyìn yìí, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń mi ayé jìgìjìgì láti ọdún 1914 tọ́ka sí i láìsí iyè méjì pé a ń gbé ní “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” nísinsìnyí. (Mátíù 24:3) Èyí túmọ̀ sí pé òpin ìgbékalẹ̀ ayé oníwà ẹranko ń yára kánkán sún mọ́lé, bí òpin “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” tí ó ní ìwo mẹ́wàá náà, tí aṣẹ́wó náà ń gùn ní báyìí pẹ̀lú ṣe ń yára sún mọ́lé. (Ìṣípayá 17:3) Ní kedere, ẹranko yìí dúró fún àkójọpọ̀ ìṣèlú tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ti gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé—Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Òpin tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà túmọ̀ sí fífòpin sí ìṣàkóso ìṣèlú tí ń fa ìyapa, tí kì í sì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí aráyé. Ṣùgbọ́n aṣẹ́wó ọbabìnrin tí ń gun ẹranko náà ńkọ́?

Áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣàlàyé pé: “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá. Nítorí Ọlọ́run fi í sínú ọkàn-àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ, àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà ní ìjọba wọn, títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.”—Ìṣípayá 17:16, 17.

Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé gẹ́rẹ́ ṣáájú ìparun ẹranko ẹhànnà ti ìṣèlú náà, yóò bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra ẹni tí ń gùn ún, yóò sì gbógun tì í. Èé ṣe? Ní kedere, àwọn olùṣàkóso àti ìjọba yóò rò pé ìgbékalẹ̀ ìsìn tí ń ṣiṣẹ́ ní ààlà ìpínlẹ̀ àwọn ń jin agbára àti ọlá àṣẹ àwọn lẹ́sẹ̀. Lójijì, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń fipá múni kan yóò ṣe sún wọn, wọn yóò mú “ìrònú” Ọlọ́run, ìpinnu rẹ̀, ṣẹ nípa mímú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí panṣágà ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí ẹ̀jẹ̀ ti ta àbàwọ́n sí àlà rẹ̀.a—Fi wé Jeremáyà 7:8-11, 34.

Òpin àwọn ìsìn èké ayé yìí yóò dé nígbà tí ó jọ pé wọ́n ṣì lágbára, tí wọ́n sì ń lo agbára ìdarí gidigidi. Bẹ́ẹ̀ ni, àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé kété kí aṣẹ́wó náà tóó pa run, yóò ṣì máa wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í sì í ṣe opó, èmi kì yóò sì rí ọ̀fọ̀ láé.” (Ìṣípayá 18:7) Bí ó ti wù kí ó rí, òpin rẹ̀ yóò dé bí ìyàlẹ́nu sí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. Yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òjijì, tí ó sì ní ìbànújẹ́ nínú jù lọ jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn ìran ènìyàn.

Bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí Bábílónì ìgbàanì ti yọrí, àwọn ìsìn èké ti lo agbára ìdarí lórí ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà pípẹtẹrí nípasẹ̀ àwọn aṣíwájú àti alátìlẹ́yìn wọn; àwọn ẹ̀kọ́, òfin àtọwọ́dọ́wọ́, àti àṣà wọn; àwọn àìlóǹkà ilé ìjọsìn wọn títayọ lọ́lá; àti ọrọ̀ wọn tí ń múni wárìrì. Dájúdájú, ìparun wọn kò lè ṣàìgba àfiyèsí. Nítorí náà, áńgẹ́lì tí a fi ìpolongo ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ sórí aṣẹ́wó náà lé lọ́wọ́ kò fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ nígbà tí ó kéde pé: “Àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò . . . dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo a óò sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alókunlágbára.” Nítorí náà, òpin Bábílónì Ńlá yóò dé bíi sísán àrá lójijì, yóò sì ré kọjá ní kánmọ́, bíi pé “ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”—Ìṣípayá 18:8; Aísáyà 47:8, 9, 11.

Àwọn ọ̀rọ̀ lílágbára tí áńgẹ́lì náà sọ ṣamọ̀nà sí ìbéèrè náà, Yóò ha ṣẹ́ ku ìsìn kankan bí, bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀, èwo ni, èé sì ti ṣe? Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ fi hàn? A óò sọ̀rọ̀ lórí èyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àgbéyẹ̀wò kíkún lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, wo ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, orí 33, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù ní Áfíríkà

Ní Ìṣípayá 18:24, Bíbélì sọ pé nínú Bábílónì Ńlá ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn wọnnì tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” Ronú nípa àwọn ogun tí a ti jà nítorí àìdọ́gba èrò ìsìn àti nítorí ìkùnà àwọn aṣáájú ìsìn láti dènà wọn. Àpẹẹrẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan nípa èyí ṣe kedere nínú ìpalápalù ẹ̀yà tí ó wáyé ní Rwanda, nínú èyí tí a ti ṣìkà pa nǹkan bí 500,000 ènìyàn—ìdá mẹ́ta wọn jẹ́ àwọn ọmọdé.

Òǹkọ̀wé Hugh McCullum, tí ó jẹ́ ará Kánádà, ròyìn láti Rwanda pé: “Àlùfáà kan, tí ó jẹ́ Hutu, ní Kigali [Rwanda] sọ pé, ìkùnà ṣọ́ọ̀ṣì láti pèsè àpẹẹrẹ ìwà rere kò ṣeé ṣàlàyé. Ó yẹ kí ipò àwọn bíṣọ́ọ̀bù nínú àwùjọ àwọn ará Rwanda ti ṣe pàtàkì gidigidi. Wọ́n mọ̀ nípa ìjábá tí ń bọ̀ náà tipẹ́tipẹ́ kí ìpakúpa náà tóó bẹ̀rẹ̀. Láti orí àga ìwàásù, a ti lè fún èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn olùgbé láǹfààní láti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ lílágbára kan tí ì bá ti dènà ìpalápalù ẹ̀yà náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn aṣáájú náà gbẹ́nu dání síbẹ̀.”

Lẹ́yìn ìpakúpa búburú jù lọ náà ní 1994, Justin Hakizimana, tí ó jẹ́ alàgbà kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì, sọ níbi ìpàdé kékeré kan tí wọ́n ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian kan ní Kigali pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò ìṣèlú Habyarimana [ààrẹ ilẹ̀ Rwanda]. A kò dẹ́bi fún ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nítorí àwa fúnra wa ti díbàjẹ́. Kò tí ì sí ọ̀kankan lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wa, Kátólíìkì ní pàtàkì, tí ó tí ì dẹ́bi fún ìpakúpa náà.”

Nínú ìpàdé mìíràn ní Rwanda lẹ́yìn ìpalápalù ẹ̀yà náà, Aaron Mugemera, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan, sọ pé: “Ojú ti ṣọ́ọ̀ṣì. . . . Láti ọdún 1959 ni ìpakúpa ti ń ṣẹlẹ̀ níhìn-ín. Ẹnikẹ́ni kò dẹ́bi fún wọn. . . . A kò fọhùn nítorí pé ẹ̀rù ń bà wá, àti nítorí pé ara rọ̀ wá.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Aṣẹ́wó” yìí ń nípa lórí gbogbo ayé

[Credit Line]

Globe: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́