ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/8 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Ìsìn Ayé Ha Ń sún Mọ́ Òpin Wọn Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìsìn Ayé Ha Ń sún Mọ́ Òpin Wọn Bí?
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ̀sìn Èké Kò Ṣojú fún Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/8 ojú ìwé 3-4

Àwọn Ìsìn Ayé Ha Ń sún Mọ́ Òpin Wọn Bí?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SWEDEN

ÀKỌLÉ yìí ha mú ọ ṣe kàyéfì pé: ‘Ó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Àwọn ìsìn ayé kò ha lágbára, tí wọ́n sì ń lo agbára ìdarí gidigidi jákèjádò ayé lónìí bí?’

Dájúdájú, láìka ti pé wọ́n ń la alagbalúgbú ìṣòro kọjá sí, ó jọ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀rúndún ogún yìí, a ti ṣiyè méjì gidigidi nípa ìsìn, tí a sì tú àṣírí rẹ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ti fi àwọn awò awọ̀nàjíjìn ràgàjìràgàjì wọn wo àgbáyé, àwọn arìnrìn àjò ojúde òfuurufú sì ti lọ káàkiri gbalasa òfuurufú; bí arìnrìn àjò ojúde òfuurufú kan tí ó jẹ́ ará Soviet sì ṣe sọ, wọn kò tí ì rí “Ọlọ́run tàbí áńgẹ́lì kankan.” Àwọn onímọ̀ físíìsì ti fọ́ àwọn ohun tí a lè fojú rí sí kéékèèké láìṣàwárí nǹkan àtọ̀runwá èyíkéyìí tí ó bẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè àti àwọn tí ń fi ẹ̀kọ́ ohun àkẹ̀kù àtijọ́ mọ̀ nípa ayé láéláé sọ pé àwọ́n ti ṣàtúntò ìsokọ́ra gígùn ti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n nípa ìwàláàyè láti orí ohun alààyè tínńtínní, amoeba, títí dé orí ènìyàn, láìrí ẹ̀rí kíkéré jù lọ kan pé a dá sí ọ̀ràn náà nípasẹ̀ ìṣẹ̀dá níbikíbi láàárín ìsokọ́ra náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọgbọ́n ayé àti ọgbọ́n èrò orí onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ti kùnà láti mú èrò ìmọ̀lára ìsìn kúrò lórí pílánẹ́ẹ̀tì yìí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn agbára ìṣèlú àti ọgbọ́n èrò orí aláìgbọlọ́rungbọ́ kò tí ì múná dóko jù bẹ́ẹ̀ lọ. Fún èyí tí ó lé ní 70 ọdún, ètò ìjọba Kọ́múníìsì bóofẹ́bóokọ̀, aláìgbọlọ́rungbọ́, tọ́ka sí ìsìn gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti “oògùn tí ń pa àwọn ènìyàn lọ́bọ̀ọ́lọ̀,” ó yọ àwọn aṣáájú ìsìn nípò ó sì fòfin de àwọn ìgbòkègbodò wọn, ó ba àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti tẹ́ḿpìlì jẹ́ tàbí piyẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó yí àwọn olùjọsìn lérò padà, tí ó sì pa wọ́n. Síbẹ̀, irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò mú èrò ìmọ̀lára ìsìn kúrò. Bíi kí ni irú àwọn ìjọba bẹ́ẹ̀ ń dojú bolẹ̀ sí ni, ìsìn tún ń gbéra sọ láti ibi tí a tẹ̀ ẹ́ rì sí pẹ̀lú okun tí ó jọ pé a sọ dọ̀tun. Ní àwọn ilẹ̀ Kọ́múníìsì nígbà kan rí, àwọn ènìyàn tún ń gbára jọ sí àwọn tẹ́ḿpìlì wọn àtijọ́, wọ́n ń kúnlẹ̀ nínú ìjọsìn tọkàntọkàn bí àwọn babańlá wọn ti ṣe ṣáájú wọn.

Iná èrò ìmọ̀lára ìsìn ṣì ń jó geere ní àwọn apá ibòmíràn nínú ayé. Lọ́dọọdún, ìlú Mecca, ní Saudi Arabia, ń gbàlejò àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Mùsùlùmí arìnrìn àjò ìsìn láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Ẹsẹ̀ kì í gbèrò ní Ojúde St. Peter ní Vatican, pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ Kátólíìkì tí ń fẹ́ẹ́ fojú gán-ánní póòpù, tí wọ́n sì ń retí láti gba ìre lẹ́nu rẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn onísìn Híńdù ń bá a lọ láti máa dà gìrìgìrì lọ sí àwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibi ìrìn àjò ìsìn ní eteetí àwọn odò “mímọ́” ní Íńdíà. Àwọn Júù onítara ń dà lọ síbi Ògiri Ìsunkún ní Jerúsálẹ́mù láti gbàdúrà, kí wọ́n sì fi àwọn àdúrà tí wọ́n ti kọ sínú ìwé há àárín àwọn àlàpà ògiri náà.

Bẹ́ẹ̀ ni, o jọ pé ìsìn kò ṣeé mú kúrò lọ́dọ̀ ìran ènìyàn. Àgbà òṣèlú Edmund Burke, tí a bí ní Ireland, sọ pé: “Ènìyàn jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́mìí ìsìn lọ́nà tí a gbà dá a.” Ìsọfúnni oníṣirò fi hàn pé ìpín 5 nínú 6 ènìyàn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsìn lọ́nà kan ṣáá. Gẹ́gẹ́ bí àwọn iye tí a gbé jáde láìpẹ́ yìí ṣe fi hàn, nǹkan bíi bílíọ̀nù 4.9 ènìyàn jẹ́ mẹ́ḿbà àwọn ìsìn fífìdí múlẹ̀ lágbàáyé, nígbà tí kìkì nǹkan bí 842 mílíọ̀nù ènìyán jẹ́ aláìnísìn.a

Lójú ìwòye èyí, ó ha bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé àwọn ìsìn ayé ń sún mọ́ òpin wọn bí? Bí wọ́n bá sì ń ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà wo ni wọn yóò dópin, báwo ni yóò sì ṣe ṣẹlẹ̀? Ìsìn kankan yóò ha ṣẹ́ kù bí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì tí ó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Àwọn aláìnísìn” ní nínú: “Àwọn tí kò jẹ́wọ́ ìsìn kankan, àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀, àwọn asẹ́gbàgbọ́ ìsìn, àwọn aláìṣèsìn tí wọ́n ti wà nínú ìsìn kan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ń dágunlá sí gbogbo ìsìn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ojúde St. Peter, Ìlú Ńlá Vatican

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́