ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/8 ojú ìwé 8-9
  • Yóò Ṣẹ́ Ku Ìsìn Kan Ṣoṣo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yóò Ṣẹ́ Ku Ìsìn Kan Ṣoṣo
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orísun Ìgboyà tí Kìí Ṣákìí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/8 ojú ìwé 8-9

Yóò Ṣẹ́ Ku Ìsìn Kan Ṣoṣo

FINÚ ro bí ì bá ti rí, ká ní gbogbo ènìyàn orí ilẹ̀ ayé wà ní ìṣọ̀kan nínú ìsìn kan ṣoṣo, nínú ìjọsìn mímọ́ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run tòótọ́. Ẹ wo irú orísun ìṣọ̀kan tí ìyẹn ì bá jẹ́! Kì bá tí sí asọ̀, gbọ́nmisi-omi-òto, tàbí ogun ìsìn mọ́. Àlá lásán nìyí bí? Ó tì o. Ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nípa ìparun aṣẹ́wó náà, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tọ́ka sí i pé yóò ṣẹ́ ku irú ìjọsìn kan lẹ́yìn ìparun rẹ̀. Èwo ni?

Ohùn tí Jòhánù gbọ́ láti ọ̀run wá fún wa ní amọ̀nà kan pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:4) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ níhìn-ín. Ṣàkíyèsí pé, kò pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ aṣẹ́wó náà nínú ìgbìyànjú àjọṣepọ̀ yíká ayé kan láti gbà á là nípa ríràn án lọ́wọ́ láti mú ara rẹ̀ bá ipò ìgbésí ayé yíyẹ mu. Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àtúnṣe kankan fún un. Nítorí náà, Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn láti jáde kúrò nínú rẹ̀, kí wọ́n sì ta kété sí i, kí wọ́n lè yẹra fún jíjẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ púpọ̀ jaburata kó àbàwọ́n bá wọn, kí wọ́n sì yẹra fún gbígba ìdájọ́ àti ìparun pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Ìkìlọ̀ àtọ̀runwá náà láti “jáde kúrò nínú rẹ̀” tún ṣèrànwọ́ fún àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ń wá òtítọ́ kiri láti dá àwọn ènìyàn Ọlọ́run mọ̀. Wọ́n lè bi ara wọn pé, ‘Àwọn ènìyàn wo lórí ilẹ̀ ayé lónìí ni wọ́n ti ṣègbọràn sí àṣẹ yìí nípa yíyọwọ́ kúrò nínú ìsìn, àjọ, tàbí ẹgbẹ́ àwọn olùjọsìn èyíkéyìí tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú “Bábílónì Ńlá”? (Ìṣípayá 18:2) Àwọn ènìyàn wo lórí ilẹ̀ ayé lónìí ni wọ́n ti tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn dòmìnira lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀kọ́, ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́, àṣà, àti òfin àtọwọ́dọ́wọ́ Bábílónì?’ Ta ni ì bá tún jẹ́ bí kò ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Lára iye tí ó lé ní mílíọ̀nù 5.2 àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ orílẹ̀-èdè tí ó pọ̀ tó 230, gbogbo àwọn tí wọ́n ti ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìsìn Bábílónì kan tẹ́lẹ̀ rí, yálà nípasẹ̀ ìbí tàbí ìyípadà, ti yọwọ́ kúrò nínú rẹ̀ ní kedere—nígbà míràn, láìka ìṣàtakò àti ìlòdìsí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àti àwọn aṣáájú ìsìn sí.

Àpẹẹrẹ kan ni ti Henry, ọkùnrin ará Gúúsù Áfíríkà kan, tí ó jẹ́ akápò ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, tí ó sì rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà. Ṣùgbọ́n ó ń wá òtítọ́ kiri, ó sì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́jọ́ kan. Bí àkókò ti ń lọ, nígbà tí ó pinnu láti di Ẹlẹ́rìí, ó sọ fún pásítọ̀ rẹ̀, tí ó tún jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọn gan-an, pé òún fẹ́ẹ́ kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà.

Pásítọ̀ náà wárìrì, ó sì pe alága ṣọ́ọ̀ṣì náà àti àwọn mẹ́ḿbà míràn láti bẹ Henry wò. Wọ́n béèrè ìdí tí ó fi fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ìsìn kan tí, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ ọ́, kò ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Henry sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ̀rù bà mí láti dá wọn lóhùn, nítorí pé wọ́n ti fìgbà gbogbo máa ń ní agbára ìdarí lórí mi. Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ó sì mú kí n lè gbèjà ara mi báyìí pé: ‘Nínú gbogbo ìsìn tí ń bẹ lágbàáyé, ẹyọ kan ṣoṣo wo ní ń fìgbà gbogbo lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà? Kì í ha í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni bí? Ẹ̀yín ha rò pé Ọlọ́run yóò gbà wọ́n láyè láti máa jẹ́ orúkọ rẹ̀, kí ó má sì fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ bí?’” Àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà kò lè já ìrònú yìí ní koro, Henry sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí.

Nítorí náà, nígbà tí ohùn tí ó wá láti ọ̀run náà pàṣẹ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀,” a ní ibi tí a óò lọ. (Ìṣípayá 18:4) Àwọn ènìyàn, àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà, tí o lè sá lọ bá, wà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti sá. A mọ̀ wọ́n bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni kárí ayé, tí a ṣètò sí iye ìjọ tí ó lé ní 78,600, wọ́n sì ń nírìírí ìgbòòrò di púpọ̀ nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn wọn. Ó lé ní 1,200,000 tí wọ́n ti rì bọmi láàárín ọdún mẹ́rin tí ó kọjá yìí! Ṣáájú ìrìbọmi, gbogbo àwọn wọ̀nyí ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ń tani jí kúrò nínú ìdágunlá tẹ̀mí, tí ó mú kí wọ́n lè ṣe ìpinnu ara ẹni, tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, láti yọwọ́ kúrò nínú gbogbo ìsopọ̀ tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìsìn èyíkéyìí mìíràn.—Sefanáyà 2:2, 3.

Bí o kò bá tí ì lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ọ̀kan lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn rí, o kò ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ yìí? Ó ṣeé ṣe kí àwọn ohun tí o bá rí, tí o bá sì gbọ́, wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. Bí o bá sì ń fẹ́ láti lóye Bíbélì, o kò ṣe béèrè pé kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn ti ṣe? Bí àdúrà rẹ bá jẹ́ láti ní òye tòótọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó bá Ọ̀rọ̀ yẹn mu, ìwọ yóò rí ìdáhùn sí àdúrà rẹ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń yíjú sí ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́