ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/8 ojú ìwé 10-13
  • Kí N Lè Bá Ọmọ Mi Sọ̀rọ̀, Mo Kọ́ Èdè Míràn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí N Lè Bá Ọmọ Mi Sọ̀rọ̀, Mo Kọ́ Èdè Míràn
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọkàn Mi Dà Rú
  • Kí Ni Yóò Dára Jù fún Spencer?
  • Àkókò Ìyípadà Ńlá Kan fún Mi
  • Àkókò Láti Pa Ilé Dà
  • “A Lè Sọ̀rọ̀ Nípa Ohunkóhun”
  • Bí Mo Tilẹ̀ Dití tí Mo Tún Fọ́jú, Mo Rí Ààbò
    Jí!—2001
  • Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • ‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/8 ojú ìwé 10-13

Kí N Lè Bá Ọmọ Mi Sọ̀rọ̀, Mo Kọ́ Èdè Míràn

ÌBÍ ọmọkùnrin wa, Spencer, ní August 1982, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkókò ìdùnnú jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Ọmọ ọwọ́ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni! Èmi àti ọkọ mi ti wéwèé láti dúró fún ọdún márùn-ún kí a tóó bí àkọ́bí wa. Ẹ wó bi a ti láyọ̀ tó láti rí i tí ó ń dàgbà sí i bí oṣù ti ń gorí oṣù lẹ́yìn tí a bí i! Àbájáde àyẹ̀wò oṣooṣù ní iyàrá iṣẹ́ dókítà máa ń dára. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún irú ìbùkún àgbàyanu bẹ́ẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí Spencer fi di ọmọ oṣù mẹ́sàn-án, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fura pé nǹkan kan kù díẹ̀ káà tó. Kì í yíra padà sí ohùn tàbí àwọn ìró kan. Láti dán agbára ìgbọ́ròó rẹ̀ wò, n óò dúró sí ibi tí kò ti níí rí mi, n óò sì lu páànù tàbí nǹkan mìíràn wò. Nígbà kọ̀ọ̀kan, ó ń yíra padà, ṣùgbọ́n kì í ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Nígbà àyẹ̀wò rẹ̀ ti oṣù kẹsàn-án, mo jíròrò àníyàn mi pẹ̀lú dókítà rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mú un dá mi lójú pé ara ọmọkùnrin mi dá ṣáṣá, kò sì sí ohun kankan láti páyà lé lórí. Síbẹ̀síbẹ̀, bí àwọn oṣù ṣe ń kọjá lọ, kì í yíra padà sí ohùn tàbí kí ó sọ̀rọ̀ síbẹ̀.

Nígbà àyẹ̀wò rẹ̀ ti ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún kan, mo tún bá dókítà náà jíròrò àníyàn mi. Lẹ́ẹ̀kan sí i, kò rí ohun kankan tí ó kù díẹ̀ káà tó, ṣùgbọ́n ó darí wa sọ́dọ̀ onímọ̀ nípa ìgbọ́ròó kan fún àyẹ̀wò. Mo gbé Spencer lọ síbẹ̀ fún àyẹ̀wò, ṣùgbọ́n àwọn àbájáde náà kò bára mu délẹ̀. Mo padà lọ fún àyẹ̀wò lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta, kìkì láti gbọ́ pé àwọn àbájáde náà kò bára mu délẹ̀ síbẹ̀. Dókítà náà rò pé, bí Spencer bá ṣe ń dàgbà sí i, àbájáde àyẹ̀wò rẹ̀ yóò máa dára sí i. Ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé ọmọ kan ṣe pàtàkì púpọ̀ fún lílóye èdè. Àníyàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i. Mo ń tẹ̀ síwájú láti máa wádìí lọ́wọ́ onímọ̀ nípa ìgbọ́ròó náà nípa àyẹ̀wò tí ó lè fúnni ní àbájáde tí ó dáni lójú. Níkẹyìn, ó sọ fún mi nípa àyẹ̀wò apá ìgbọ́ròó nínú ọpọlọ, tí a lè ṣe ní Ilé Ìwòsàn Tojútetí ní Massachusetts.

Ọkàn Mi Dà Rú

Ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, a lọ sí ilé ìwòsàn náà ní Boston. Mo gbàdúrà sí Jèhófà láti fún mi ní okun tí n óò lè fi gbé àbájáde náà, ohun yòó wù tí ó lè jẹ́. Nínú ọkàn-àyà mi, mo rò pé Spencer ní ìṣòro àìlègbọ́ròó dáadáa ni, àti pé ìhùmọ̀ ìgbọ́ròó kan ni gbogbo ohun tí a óò nílò. Ẹ wo bí n kò ti jánà tó! Lẹ́yìn àyẹ̀wò náà, onímọ̀ iṣẹ́ náà pè wá sí ọ́fíìsì rẹ̀. Àbájáde náà kò ní tàbí ṣùgbọ́n rárá: Spencer ní ìṣòro agbára ìgbọ́ròó tí kò ṣeé tún ṣe. Nígbà tí mo sì béèrè ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ní pàtó, ó ṣàlàyé pé ọmọkùnrin mi kò lè gbọ́ ohùn àti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìró mìíràn. Èyí kọ́ ni ohun tí mo retí láti gbọ́; ọkàn mi dà rú.

Lọ́gán, mo ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni èyí ti ṣe lè ṣẹlẹ̀? Kí ló ti lè fà á?’ Mo ronú padà sígbà tí mo lóyún rẹ̀ àti ìgbà ìbímọ. Ohun gbogbo ló lọ létòlétò. Spencer kò tí ì fìgbà kankan ní àrùn etí tàbí àmódi ńlá kankan. Ìmọ̀lára mi pòrúurùu! Kí ni mo ní láti ṣe báyìí? Mo tẹ ìdílé mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mélòó kan láago, mo sì sọ àbájáde àyẹ̀wò náà fún wọn. Ọ̀rẹ́ kan, tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, fún mi níṣìírí láti wo èyí gẹ́gẹ́ bí ìpèníjà kan; mo wulẹ̀ ní láti kọ́ Spencer lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yíyàtọ̀ kan. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún okun ti mo nílò náà.

Kí Ni Yóò Dára Jù fún Spencer?

N kò mọ ohunkóhun nípa títọ́ ọmọ tí ó dití, tàbí nípa ohun tí jíjẹ́ adití túmọ̀ sí. Báwo ni mo ṣe lè tọ́ ọmọkùnrin mi, kí n sì bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó nítumọ̀? Ọ̀pọ̀ èrò àti àníyàn ló gbà mí lọ́kàn.

Ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, a padà lọ sí ilé ìwòsàn náà, onímọ̀ iṣẹ́ náà sì bá wa jíròrò àwọn yíyàn tí a ní. Ó ṣàlàyé pé ọ̀nà kan, ọ̀nà ti ẹnu, darí àfiyèsí sí lílóye ọ̀rọ̀ sísọ àti wíwo ẹnu. Ọ̀nà míràn ni lílo èdè àwọn adití. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan ń bẹ tí yóò pèsè ìtọ́ni lórí ìfàmìsọ̀rọ̀, tí yóò sì mú lílóye wíwo ẹnu àti ọ̀rọ̀ sísọ wọ̀ ọ́ lẹ́yìn náà. Onímọ̀ iṣẹ́ náà tún dámọ̀ràn lílo àwọn ìhùmọ̀ ìgbọ́ròó láti túbọ̀ mú kí ìwọ̀n agbára ìgbọ́ròó tí ọmọkùnrin mí ní yè kooro sí i. A wáá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ onímọ̀ nípa ìgbọ́ròó tí ó wà ládùúgbò, òun ni ó fi ìhùmọ̀ ìgbọ́ròó ti inú etí sí àyè rẹ̀ fún Spencer, tí ó sì fún un ní àwọn ìhùmọ̀ ìgbọ́ròó tó kù. Nígbà ìbẹ̀wò wa, onímọ̀ nípa ìgbọ́ròó náà dámọ̀ràn pé Spencer yóò gbéṣẹ́ gan-an ní ọ̀nà ti ẹnu.

Kí ni yóò dára jù fún Spencer? Mo ronú nípa ohun tí ó ṣe pàtàkì ní tòótọ́. Jèhófà ń fẹ́ kí a máa bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀; èyí ṣe pàtàkì bí a bá fẹ́ẹ́ ní ìgbésí ayé ìdílé tí ó kẹ́sẹ járí. A lè gbìyànjú ọ̀nà ti ẹnu, kí a sì pàfiyèsí sórí lílóye ọ̀rọ̀ sísọ àti wíwo ẹnu. Ó lè ṣeé ṣe kí Spencer mú agbára ọ̀rọ̀ sísọ rẹ̀ dàgbà débi tí àwọn ẹlòmíràn lè lóye rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kì yóò lè mọ ìyẹn fún ọ̀pọ̀ ọdún! Kí ni kí a wáá ṣe báyìí? A pinnu láti lo èdè àwọn adití.

Ní oṣù tí ó tẹ̀ lé e, a fi orúkọ Spencer sílẹ̀ fún ohun tí a ń pè ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìbánisọ̀rọ̀ pátápátá nígbà náà. Àtèmi àti Spencer ń kẹ́kọ̀ọ́ ìpìlẹ̀ nínú èdè àwọn adití, wọ́n sì tún ń kọ́ Spencer ní sísọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti wíwo ẹnu. Wọ́n fi bí mo ṣe lè máa kọ́ ọmọkùnrin mi hàn mí. Àwọn oṣù ń kọjá lọ, Spencer sì ń tẹ̀ síwájú dáradára. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ṣì máa ń ní àwọn àkókò kan nígbà náà, tí ọkàn mi máa ń pòrúurùu. Mo rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí mo kíyè sí àwọn ọmọ mìíràn tí ń pe “Mọ́mì” tàbí tí wọ́n ń kọ́ láti sọ pé “Jèhófà.” Ṣùgbọ́n nígbà náà ni mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ń nímọ̀lára báyìí? Ọmọkùnrin mi láyọ̀, ara rẹ̀ sì dá ṣáṣá.’ Mo gbàdúrà sí Jèhófà láti jẹ́ kí n mọyì níní irú ọmọ dáradára bẹ́ẹ̀.

Nígbà tí Spencer di ọmọ ọdún méjì, a ṣètò láti lọ sí àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan níbi tí a óò ti túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí èdè àwọn adití. Mo jíròrò ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì mi pẹ̀lú àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú awọn adití Ẹlẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wọ́n sọ fún mi nípa ìpàdé olóṣooṣù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a ń ṣe ní Massachusetts, níbi tí a ti ń lo èdè àwọn adití, wọ́n sì fún mi níṣìírí láti lọ síbẹ̀.

Mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn, èmi àti Spencer sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ. A ní àǹfààní láti pàdé àwọn àgbàlagbà tí wọ́n dití níbẹ̀, a sì lè fara rora pẹ̀lú wọn. Nínú ìjọ wa tí a ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìwọ̀nba àǹfààní díẹ̀ ni Spencer rí jẹ nínú àwọn ìpàdé. Yóò jókòó tì mí tímọ́tímọ́, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èmi nìkan ni ó lè bá sọ̀rọ̀. Ìjákulẹ̀ rẹ̀ nínú irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀ ń pọ̀ sí i bí ó ti ń dàgbà sí i, ìhùwàsí rẹ̀ sì jó rẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn kì í rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá lọ sí ìpàdé tí a ti ń lo èdè àwọn adití. Ó ṣeé ṣe fún un láti fara rora fàlàlà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ láìní láti fi ìyá rẹ̀ ṣògbufọ̀. Ó ní ipò ìbátan tí ó nílò gan-an pẹ̀lú àwọn ènìyàn nínú ìjọ náà. Àwa méjèèjì túbọ̀ sunwọ̀n sí i nínú ìmọ̀ wa nínú èdè àwọn adití, mo sì kọ́ bí mo ṣe le túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó! Ní báyìí, fún ìgbà àkọ́kọ́, mo lè wà nípàdé pẹ̀lú ọmọkùnrin mi, kí n sì wulẹ̀ jẹ́ MỌ́MÌ rẹ̀, dípò jíjẹ́ ògbufọ̀ rẹ̀!

Àkókò Ìyípadà Ńlá Kan fún Mi

Pẹ̀lú ìfọwọ́sí ọkọ mi, nígbà tí Spencer di ọmọ ọdún mẹ́ta, mo fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan fún àwọn ọmọ tí ó dití àti àwọn tí wọ́n ní ìṣòro agbára ìgbọ́ròó tí kò ṣeé tún ṣe, tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba kan. Wọ́n máa ń ṣe ìpàdé ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ láti kọ́ àwọn òbí lẹ́kọ̀ọ́, mo sì lo àǹfààní yìí láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Ní ìpàdé kan, àwọn olùjíròrò kan, tí ó ní àwọn àgbàlagbà àti ọ̀dọ́langba adití nínú, bá ẹgbẹ́ náà sọ̀rọ̀. Àwọn olùjíròrò náà ṣàlàyé pé àwọn kì í ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí tàbí mọ̀lẹ́bí àwọn, bí ó bá tilẹ̀ wà rárá. Nígbà tí mo bi wọ́n léèrè ìdí rẹ̀, wọ́n fèsì pé àwọn òbí àwọn kò fìgbà kankan kọ́ èdè àwọn adití, nítorí náà, kò ṣeé ṣe fún àwọn nígbà kankan láti bá àwọn òbí àwọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó nítumọ̀ nípa ìgbésí ayé, ìmọ̀lára, tàbí ìfẹ́ ọkàn àwọn. Ó jọ pé wọn kò rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí apá kan ìdílé wọn.

Èyí jẹ́ àkókò ìyípadà ńlá kan fún mi. Mo ronú nípa ọmọkùnrin mi. N kò lè fara da ríronú pé kí ó dàgbà tán, kí ó sì kúrò nílé, láìní ipò ìbátan kan pẹ̀lú àwa òbí rẹ̀. Mo túbọ̀ pinnu ju ti àtẹ̀yìnwá lọ láti sunwọ̀n sí i nínú ìlò èdè àwọn adití. Bí àkókò ti ń lọ, mo túbọ̀ mọ̀ síwájú sí i pé ìpinnu tí ó dára jù lọ fún wa ni láti lo èdè àwọn adití. Ìlò èdè rẹ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i, a sì lè jọ jíròrò kókó ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, bí, “Ibo ni a ti fẹ́ẹ́ lọ lo ìsinmi?” tàbí “Iṣẹ́ wo ni o fẹ́ẹ́ ṣe bí o bá dàgbà?” Mo wáá mọ bí ǹ bá ti pàdánù tó, ká ní mo ti gbára lé ọ̀rọ̀ sísọ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.

Ní ọmọ ọdún márùn-ún, wọ́n fi Spencer sí kíláàsì kan náà pẹ̀lú àwọn ọmọ tí kò dití, àti olùkọ́ kan tí ó lè lo èdè àwọn adití. Ó ṣe èyí fún ọdún mẹ́ta, tí ó jọ pé kò níí tán mọ́ lójú wa. Kò fẹ́ràn ilé ẹ̀kọ́, kò sì rọrùn láti rí i bí ó ti ń la irú àwọn ìṣòro ńlá bẹ́ẹ̀ kọjá. Ọpẹ́ ni pé mo lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bí a ti ń gbìyànjú onírúurú ọ̀nà tí a fi lè kojú ìjákulẹ̀ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, níkẹyìn, mo pinnu pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba kò dára fún iyì ara ẹni rẹ̀ tàbí fún ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ìgbéyàwó mi dópin ní 1989. Mo wáá di òbí anìkàntọ́mọ kan tí ó ní ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́fà kan tí agbára rẹ̀ láti lo èdè àwọn adití ń yára pọ̀ sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo lè bá a sọ̀rọ̀, mo mọ̀ pé mo ní láti túbọ̀ mú òye mi nínú lílo èdè àwọn adití sunwọ̀n sí i, kí n lè máa bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ àárín wa nìṣó, kí n sì túbọ̀ fún un lókun sí i.

Àkókò Láti Pa Ilé Dà

Mo ṣèwádìí nípa ọ̀pọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó wà fún àwọn adití ọmọ ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀, mo sì rí ilé ẹ̀kọ́ kan ní Massachusetts níbi tí a ti ń lo èdè àwọn adití àti èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́nà kan tí a kà sí elédè méjì. Ní àfikún, mo gbọ́ pé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, tí ń lo èdè àwọn adití yóò wà ní agbègbè Boston láìpẹ́, ọ̀rẹ́ kan sì dábàá pé kí a kó lọ síbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òbí anìkàntọ́mọ kan, èrò kíkó lọ kúrò nílé wa, lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ wa ní àrọko New Hampshire lọ sí agbègbè àárín ìlú ṣòro láti gbà. Spencer pẹ̀lú gbádùn gbígbé ní àrọko. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ní ohun méjì láti gbé yẹ̀ wò. Ó yẹ kí Spencer wà ní ilé ẹ̀kọ́ kan tí gbogbo olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ti ń jùmọ̀ lo èdè àwọn adití fàlàlà, mo sì rò pé ì bá dára kí a wà nínú ìjọ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí ó dití.

A palé dà ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, nígbà tí Spencer jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, a dá Ìjọ Sign Language, tí ń lo èdè àwọn adití ní Malden, Massachusetts, sílẹ̀, láti ìgbà náà wá sì ni Spencer ti ń tẹ̀ síwájú lọ́nà àgbàyanu. Ìhùwàsí rẹ̀ sunwọ̀n sí i gan-an, ó sì ń gbádùn wíwà ní àwọn ìpàdé. Mo ń ní ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí mo bá rí i tí ó ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀, tí ó sì ń ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú wọn. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n dití nínú ìjọ náà jẹ́ àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe aláìlẹ́gbẹ́ fún ọmọkùnrin mi, tí wọ́n ń ràn án lọ́wọ́ láti mọ̀ pé òun pẹ̀lú lè lé àwọn góńgó tẹ̀mí bá. Ó sì ti ṣe èyí. Ó ti ń níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ó sì ń ṣiṣẹ́ sìn bí akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi. Ó ti sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ jáde láti ṣe ìrìbọmi.

Ẹ wo bí mo ṣe máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, bí mo bá ń wò ó, tí ó ń fi èdè àwọn adití sọ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún àwọn adití mìíràn! Iyì ara ẹni rẹ̀ ti pọ̀ rẹpẹtẹ. Spencer sọ ìmọ̀lára rẹ̀ nípa ìjọ náà fún mi. Ó wí pé: “Ibí ló yẹ wá. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin lè bá mi sọ̀rọ̀.” Ọmọkùnrin mi kò tún máa rọ̀ mí láti lọ sílé kété tí ìpàdé bá ti parí mọ́. Èmi ni mo tún ń ní láti sọ fún un pé ó tó àkókò láti kúrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nísinsìnyí!

Ní ilé ẹ̀kọ́ tí ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́, Spencer lè fìrọ̀rùn bá àwọn ọmọ mìíràn tí ó dití sọ̀rọ̀. Àwọn ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú wọn ti ràn án lọ́wọ́ láti rí ìyàtọ̀ tí ó wà nínú ojú tí ayé fi ń wo àwọn ọmọdé àti ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n. Èmi àti Spencer jọ ń sọ̀rọ̀ pọ̀ fàlàlà, a sì ní ipò ìbátan tímọ́tímọ́, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Nígbà tí ó bá darí wálé ní ọ̀sán, a jọ ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀. A máa ń lọ sí àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé pa pọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, Spencer lè rí i pé kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló ní irú ìbátan tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn.—Kólósè 3:20, 21.

“A Lè Sọ̀rọ̀ Nípa Ohunkóhun”

Ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn, mo kíyè sí i pé Spencer ń wò mí bíi pé ó fẹ́ẹ́ sọ nǹkan fún mi. Mo bi í bóyá ó ń fẹ́ ohunkóhun ni. Ó dáhùn pé: “Rárá.” Mo bi í léèrè àwọn ìbéèrè díẹ̀ nípa bí gbogbo nǹkan ṣe rí nílé ẹ̀kọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Mo mọ̀ pé ó ní ohun kan tí ó fẹ́ẹ́ sọ fún mi. Lẹ́yìn náà, nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ìdílé wa, ó wí pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn mélòó kan lára àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ mi kò lè lo èdè àwọn adití?” Mo wò ó tìyanutìyanu. Ó wí pé: “N kò fi ṣeré o. Àwọn òbí tí kò lè bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ pọ̀ wà.” Ó ṣàlàyé pé àwọn òbí kan ṣèbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà, òún sì rí wọn tí wọ́n ń nàka, tí wọ́n sì ń fara ṣàpèjúwe ohun tí wọ́n fẹ́ẹ́ sọ, nínú ìgbìyànjú láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. “Olúwa ló bá mi ṣe é pé o kọ́ èdè àwọn adití. A lè bá ara wa sọ̀rọ̀ pọ̀. O kò wulẹ̀ máa nàka; a lè sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun.”

Ẹ wo bí èyí ti wọ̀ mí lọ́kàn tó! Púpọ̀ nínú wa kì í mọyì ìsapá àwọn òbí wa títí di ìgbà tí a bá dàgbà. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin mi nìyí, lọ́mọ ọdún 12, tí ó ń sọ fún mi bí ó ṣe kún fún ọpẹ́ tó pé a lè máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó nítumọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìyá kan, ọ̀kan nínú àwọn góńgó mi ni láti ni ìbátan gbígbámúṣé pẹ̀lú ọmọkùnrin mi, kí n sì sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́. Bóyá èyí kì bá tí ṣẹlẹ̀ bí n kò bá ti kọ́ èdè àwọn adití. Ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà sún mi láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹrù iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí òbí ní gírímọ́káyì; èyí sì mú kí ṣíṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rọrùn. Àwọn ìpinnu wọ̀nyí ti mú kí àwa méjèèjì jàǹfààní nípa tẹ̀mí. Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ní Diutarónómì 6:7 ti ṣe pàtàkì tó, níbi tí a ti fún àwọn òbí nítọ̀ọ́ni láti máa fi àwọn àṣẹ Jèhófà kọ́ àwọn ọmọ wọn ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé wọn àti nígbà tí wọ́n bá ń rìn lọ ní ọ̀nà àti nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.’ Mo dúpẹ́ pé èmi àti Spencer lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ fàlàlà nípa “awọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:11)—Bí Cindy Adams ṣe sọ ọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

‘N kò lè fara da ríronú pé kí ó dàgbà láìní ipò ìbátan kan pẹ̀lú àwa òbí rẹ̀’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́