Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àmúdá Ẹlẹ́wọ̀n ni mí, ó sì ku ọdún méjì kí n parí àkókò mi lẹ́wọ̀n. Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Wọ́n Mú Wa Ní Àmúdá Nígbà Ìrúkèrúdò Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Kan.” (November 8, 1996) Nígbà kọ̀ọ̀kan, omijé ayọ̀ ń wá sí ojú mi, ọ̀fun mi máa ń há. Nígbà gbogbo ni mo ń fojú sọ́nà fún ìbẹ̀wò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n yí. Wọ́n ń tuni lára gan-an ni!
J. K., United States
N kò fìgbà kankan kọ̀wé sí yín nípa àpilẹ̀kọ kankan rí, ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ nípa àwọn tí wọ́n mú ní àmúdá náà ń fún ìgbàgbọ́ lókun gan-an ni. Ó fún mi ní ìdánilójú lọ́tun pé Jèhófà ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ lókun nígbà tí wọ́n bá wà nínú wàhálà.
K. D., United States
Ìtọ́sọ́nà Mo gbádùn àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ìtọ́sọ́nà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?” gidigidi. (November 8, 1996) Ó tù mí nínú, ó sì fún mi níṣìírí gan-an. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn, mo ti ní ìjákulẹ̀ gidigidi sẹ́yìn nígbà tí àwọn tí mo dara dé fún ìtọ́sọ́nà ti já mi kulẹ̀. Àkàwé ọmọ kan tí ń di ọwọ́ bàbá rẹ̀ mú wulẹ̀ mú kí omijé dá lójú mi ni. Ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti mọ̀ pé Jèhófà sọ nínú Aísáyà 41:13 pé, òun yóò ‘di ọwọ́’ àwọn ènìyàn òun ‘mú.’
M. S., United States
Ọmọ ọdún 17 ni mí, mo sì ti ń ní ọ̀pọ̀ ìṣòro lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ọ̀rẹ́ mi kan sọ pé kí n gbàdúrà, kí n sì ka ohun kan tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí. Lẹ́yìn kíka àpilẹ̀kọ náà, “Ìtọ́sọ́nà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?,” mo pinnu láti má sọ̀rètí nù, ṣùgbọ́n kí n túbọ̀ di ọwọ́ Bàbá mi ọ̀run mú gírígírí sí i!
C. G., United States
Èdè Àwọn Adití Mo dúpẹ́ gidigidi fún àpilẹ̀kọ náà, “Kí N Lè Bá Ọmọ Mi Sọ̀rọ̀, Mo Kọ́ Èdè Míràn.” (November 8, 1996) Mo jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ kan tí ó ní ọmọkùnrin ọlọ́dún 24 tí ó dití kan. Nítorí náà, ìrírí ara mi jẹ́ kí n mọ ohun tí Cindy Adams ti nírìírí rẹ̀, mo sì mọrírì ohun tí ó ti ṣe yọrí gidigidi.
H. B., Germany
Àpilẹ̀kọ náà mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè àwọn adití kí n lè bá àwọn adití ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Bíbélì, kí n sì bá àwọn arákùnrin tí ó dití nínú ìjọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú.
B. L., Venezuela
Mo bá ọ̀dọ́langba ọmọbìnrin kan tí ó dití ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A kọ́ ohun púpọ̀ lọ́dọ̀ ara wa, láìka òtítọ́ náà sí pé ìmọ̀ èdè àwọn adití tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní kò tó nǹkan. Kíkà nípa ìpinnu Cindy Adams láti kọ́ èdè náà nítorí ọmọkùnrin rẹ̀ fún mi níṣìírí láti mú kí ìmọ̀ tí mo ní nínú èdè títayọlọ́lá yìí pọ̀ sí i, kí n lè bá àwọn adití àwùjọ mi ṣàjọpín ìhìn rere ti ó wà nínú Bíbélì.
S. T., St. Martin, Netherlands Antilles
Èmi pẹ̀lú ní ọmọ kan tí ó dití, a sì yàn láti máa lo ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ ẹnu. Ọ̀nà yí dá lé orí ìmúdàgbà ọ̀rọ̀ sísọ àti wíwo ètè láti mọ ohun tí a ń sọ. Ó ti já sí yíyàn dídára kan fún ọmọkùnrin mi. Níbẹ̀rẹ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ jàǹfààní nínú àwọn ìpàdé ìjọ. Àmọ́ ní báyìí, ó ń fọkàn bá ìpàdé lọ dáradára, èmi àti àwọn ẹlòmíràn sì ń gbúfọ̀ fún un. Ó ń sọ̀rọ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ó sì jẹ́ akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi. Ọ̀pọ̀ ọdún tí a ti fi tiraka ti mú èso wá. Ìrírí tiwa fi hàn pé yálà Èdè Àwọn Adití tàbí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ ẹnu lè ṣàǹfààní níwọ̀n bí àwọn òbí àti ìjọ àdúgbò bá ti ń sapá láti fún ọmọ náà níṣìírí, kí wọ́n sì máa bá a sọ̀rọ̀.
M. T., United States