Orísun Ìgboyà tí Kìí Ṣákìí
“OHÙN kan tí ń dún bí ẹni pòṣé mú kí a dúró lójijì. Lẹ́yìn naa, lati inú igbó kan lápá òsì wa, awọn ẹyẹ méjì tí wọn na ìyẹ́ wọn yẹbẹyẹbẹ sáré sí ìhà ọ̀dọ̀ wa. Níwájú wa, awọn ẹyin méjì wà ninu ihò kékeré kan ninu ilẹ̀. Awọn ẹyẹ naa ni wọn kò jẹ́ kí a ṣèèṣì tẹ ìtẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Gbogbo ìgbà tí a bá ti gbìyànjú lati túbọ̀ súnmọ́ ọn kí a sì ya awọn ẹyin aláwọ̀ rúsúrúsú tóótòòtó fífanimọ́ra wọnyi ní fọ́tò, awọn ẹyẹ naa tún pakuuru mọ́ wa. A ronú pé, ‘ìgboyà wọn mà pọ̀ o.’”
Oun tí awọn àgbàlagbà mẹ́rin kan nírìírí rẹ̀ nìyẹn bí wọn tí ń súnmọ́ ìtẹ́ ẹyẹ dikkop kan tí wọn ti fojúsùn. Ẹyẹ blacksmith plover jẹ ẹyẹ kékeré. Ninu ìwé naa Everyone’s Guide to South African Birds, Sinclair ati Mendelsohn onímọ̀ nipa awọn ẹyẹ ṣàlàyé pé: “Takọtabo tí ń pamọ ń dáàbòbo ìtẹ́ wọn ati awọn ọmọ wọn pẹlu gbogbo agbára wọn tí wọn sì máa ń ṣetán lati wọ̀yá ìjà bí ọ̀yọjúràn kan bá ti ń súnmọ́tòsí. Wọn kò bẹ̀rù bí agbabẹ̀kọjá láìlẹ́tọ̀ọ́ yii ṣe tó wọn á fò mọ́ ọn pẹẹrẹpẹ, wọn tilẹ̀ máa ń ràbàbà ni fífi àìbẹ̀rù fò mọ́ ènìyàn látòkè ninu ìgbìyànjú wọn lati lé wọn dànù.”
Awọn kan ti wo bí awọn erin ńlá kan ṣe fi àìmọ̀ọ́mọ̀ rìn lọ sí apá ibi tí ìtẹ́ ẹyẹ blacksmith plover wà, èyí wulẹ̀ mú kí ẹyẹ naa bẹ̀rẹ̀ ìtapẹẹrẹ rẹ̀. Awọn erin naa ni ó máa ń di dandan fún lati pẹ̀yìndà.
Níbo ní awọn ẹyẹ ti rí irú ìgboyà híhàn gbangba bẹ́ẹ̀? Ó wá lati ọ̀dọ̀ Ẹni naa tí ó dá wọn. Jehofa Ọlọrun ti dá awọn ìṣètò agbára ìsúnniṣe mọ́ awọn ẹ̀dá kékeré wọnyi lati dènà awọn ẹranko tí ó tóbi jù wọn lọ kúrò lọ́wọ́ ṣíṣe ìpalára fún ìtẹ́ tabi awọn òròmọ wọn.
Ẹ̀kọ́ kan fún Awọn Kristian
Awọn Kristian lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára èyí, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn lè nilati lọ rékọjá ìgboyà ti agbára ìsúnniṣe lásán. A késí wọn lati ṣe àfarawé Ọ̀gá wọn, Jesu Kristi, ẹni tí ó ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọrun láìbẹ̀rù. (Heberu 12:1-3) Bibeli dẹ́bi fún awọn ojo tí ń fàsẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun. (Heberu 10:39; Ìfihàn 21:8) Bákan naa pẹlu, Jehofa lóye ipò àìpé wa ó sì mọ̀ pé a lè dẹ́ṣẹ̀ nígbà mìíràn tabi kí a ṣaláìní ìgboyà tí a nílò lati ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. (Orin Dafidi 103:12-14) Kí ni ẹnìkan lè ṣe bí ìbẹ̀rù bá ń mú kí ó fawọ́ sẹ́yìn lati ṣe ohun tí ó tọ́?
Kristian kan gbọ́dọ̀ yíjúsí Ọlọrun tàdúrà-tàdúrà fún okun lati kojú àdánwò kí ó sì máa báa nìṣó ní ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Bibeli ní awọn ìlérí afúnni nídàánilójú yii fún ìrànlọ́wọ́ Jehofa ninu: “Ó ń fi agbára fún aláàárẹ̀; ó sì fi agbára kún awọn tí kò ní ipá. Àní àárẹ̀ yoo mú awọn ọ̀dọ́mọdé, yoo sì rẹ̀ wọn, ati awọn ọ̀dọ́mọkùnrin yoo tilẹ̀ ṣubú pátápátá: ṣugbọn awọn tí ó bá dúró de Oluwa yoo tún agbára wọn ṣe; wọn ó fi ìyẹ́ gun òkè bí idì; wọn óò sáré, kí yoo sì rẹ̀ wọn; wọn ó rìn, àárẹ̀ kì yoo sì mú wọn.” (Isaiah 40:29-31) Ọ̀pọ̀ awọn ènìyàn aláìpé ti nírìírí awọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ‘a sì sọ wọn di alágbára ninu àìlera.’ (Heberu 11:34) Kristian aposteli Paulu jẹ́ àpẹẹrẹ dídára, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Oluwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù naa ní àwàjálẹ̀, ati pé kí gbogbo awọn Keferi kí ó lè gbọ́.”—2 Timoteu 4:17.
Awọn ẹni tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́hàn pàápàá lati di ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi lè nírìírí irú ìrànwọ́ afúnnilókun bẹ́ẹ̀. Gbé ọ̀ràn ọkùnrin ara South Africa kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Henry yẹ̀wò, ẹni tí ó jẹ́ akápò ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní yàrá kejì sí ti pásítọ̀. Henry ń wà òtítọ́ kiri. Láìka ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ rẹ̀ pẹlu ṣọ́ọ̀ṣì naa sí, lọ́jọ́ kan ó tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láìpẹ́, ó sọ ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ lati di Ẹlẹ́rìí jáde ó sì béèrè awọn ìgbésẹ̀ tí ó yẹ kí oun gbé kí ọwọ oun baà lè tẹ góńgó yẹn. A ṣàlàyé fún un pe ó kọ́kọ́ níláti kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. (Ìfihàn 18:4) Níwọ̀n bí pásítọ̀ naa ti jẹ́ aládùúgbò ati ọ̀rẹ́ rẹ̀, Henry ronú pé oun kò wulẹ̀ níláti kọ lẹ́tà ìfiṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ ṣugbọn oun níláti ṣàlàyé ọ̀ràn naa lójúkorojú. Èyí ni oun fi tìgboyà-tìgboyà ṣe.
Jìnnìjìnnì dàbo pásítọ̀ naa lẹ́yìn naa ni ó késí alága ìpàdé ìjíròrò ìlànà ìsìn naa ati awọn mẹ́ḿbà mìíràn ninu ṣọ́ọ̀ṣì lati lọ bẹ Henry wò. Wọn fẹ́ lati mọ ìdí tí ó fi fi ṣọ́ọ̀ṣì wọn sílẹ̀ lati di mẹ́ḿbà ìsìn kan, tí kò ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ. Henry ṣàlàyé pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ̀rú bà mí lati dá wọn lóhùn, nitori pé wọn ti máa ń fi ìgbà gbogbo ní agbára ìdarí ńláǹlà lórí mi. Ṣugbọn mo gbàdúrà sí Jehofa fún ìrànwọ́, ó sì mú kí ó ṣeéṣe fún mi lati sọ awọn ọ̀rọ̀-ìgbèjà yii jáde pé: ‘Ninu gbogbo ìsìn tí ń bẹ lágbàáyé, èwo ni ọ̀kan ṣoṣo tí ń lo orúkọ Ọlọrun, Jehofa? Kìí ha ṣe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni bí? Ẹ ha rò pé Ọlọrun yoo gbà wọn láyè lati máa jẹ́ orúkọ rẹ̀ tí kì yoo sì tún fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?’” Awọn ìjòyè-òṣìṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì naa kò lè bi irú ìrònú bẹ́ẹ̀ ṣubú. Ọpẹ́ ni fún ìmọ̀ ati okun tí Ọlọrun ń pèsè, ní bayii Henry ń fi tìgboyà-tìgboyà nípìn-ín ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Bẹ́ẹ̀ni, jíjẹ́ Kristian tòótọ́ ń béèrè fún ìgboyà. Bí òpin ayé yii ti ń súnmọ́lé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yoo máa pọ̀ síi. Satani fẹ́ lati ja awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lólè ìrètí àgbàyanu wọn ti ìyè ayérayé nipa gbígbìyànjú lati ba ìwàtítọ́ wọn sí Jehofa jẹ́. (Fiwé Ìfihàn 2:10.) Ṣugbọn a kò gbọdọ̀ juwọ́sílẹ̀ láé. Kódà bí a bá tilẹ̀ jìyà ìfàsẹ́yìn fún ìgbà díẹ̀ nitori ìbẹ̀rù, Jehofa lè ràn wá lọ́wọ́ lati jèrè okun padà. Túbọ̀ máa yíjú sí i fún okun lati máa bá ṣíṣe ìfẹ́-inú rẹ̀ lọ. Rántí pé, ẹni naa tí ó dá awọn ẹyẹ tí kìí bẹ̀rù ni Orísun ìgboyà tí kìí ṣákìí. Ní tòótọ́, awọn Kristian tòótọ́ níláti “jẹ́ onígboyà gidi gan-an kí [wọn] sì wí pé: ‘Jehofa ní olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yoo fòyà. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?’”—Heberu 13:6, NW.