Iwọ Ha Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Lati Ọ̀dọ̀ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni Wa Bí?
JULIO ṣàlàyé pé, “Mo kẹ́kọ̀ọ́ nipa òfin fún ọdún márùn-ún ní ọkàn lára awọn yunifásítì tí ó dára jùlọ ní Spain. Ṣugbọn ohun tí mo kọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ga fíìfíì jù ìyẹn lọ. Yunifásítì kọ́ mi bí mo ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́; Bibeli kọ́ mi bí mo ṣe lè gbé ìgbésí-ayé.”
Nípasẹ̀ Bibeli a ni àǹfààní sí ìrònú Ọlọrun, awọn ìlànà rẹ̀, ati awọn ìtọ́ni rẹ̀. Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe Jehofa gẹ́gẹ́ bí “Atóbilọ́lá Olùkọ́ni” nitori pé oun ní olùkọ́ni tí ó jáfáfá jùlọ lágbàáyé. (Isaiah 30:20, NW) Ní olówuuru, ìwé mímọ́ lédè Heberu pè É ní “awọn olùkọ́ni”—ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tí ń fí ìtayọlọ́lá hàn. Èyí níláti rán wa létí pé jíjẹ́ ẹni tí Jehofa kọ́ ga fíìfíì ju kíkẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ olùkọ́ni èyíkéyìí lọ.
Ọgbọ́n Ṣíṣeémúlò Lati Ọ̀dọ̀ Jehofa
Èéṣe tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá fi ṣàǹfààní tóbẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó jẹ́ nitori awọn ohun tí kò ṣeédíyelé tí ó ní ninu. Ẹ̀kọ́ Jehofa ń fún wa ní “ọgbọ́n ṣíṣeémúlò.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọgbọ́n tí Ọlọrun fi fúnni “fi ìyè fún” awọn wọnnì tí wọ́n bá fisílò.—Owe 3:21, 22, NW; Oniwasu 7:12.
Olùṣàkójọ Orin Dafidi 119 mọ̀ pé ọgbọ́n Jehofa tì dáàbòbo oun jálẹ̀ gbogbo ìgbésí-ayé oun. Fún àpẹẹrẹ, ó kọrin pé: “Òfin ẹnu rẹ dára fún mi ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà ati fàdákà lọ. Bí kò ṣe pé bí òfin rẹ ti ṣe inúdídùn mi, èmi ì bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú mi. Nipa àṣẹ rẹ iwọ mú mi gbọ́n ju awọn ọ̀tá mi lọ: nitori tí o wà pẹlu mi láéláé. Emi ní iyè ninu ju gbogbo awọn olùkọ́ mi lọ, nitori pé ẹ̀rí rẹ ni ìṣàrò mi.”—Orin Dafidi 119:72, 92, 98, 99.
Kìí ṣe onipsalmu naa nìkan ni kìbá ‘ṣègbé ninu ìpọ́njú rẹ̀’ bí kìí bá ṣe ti òfin Jehofa. Rosa, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan lati Spain, ni ó dálójú pé a dá ìgbésí-ayé oun sí nitori pé oun fi awọn ìlànà Ọlọrun sílò. Ó rántí pé, “Ní ẹni ọdún 26, mo ti gbìyànjú lati pa araàmi nígbà méjì.”
Rosa ti kó wọnú iṣẹ́ aṣẹ́wó, bẹ́ẹ̀ sì ni ọtí àmujù ati oògùn ìlòkulò pẹlu. Ó sọ pé, “Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo wà láìnírètí pátápátá, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan bá mi sọ̀rọ̀ nipa bí Bibeli ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lati yanjú awọn ìṣòro wa. Mo bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, èyí tí ó fà mí lọ́kàn mọ́ra gidigidi. Láàárín oṣù kan mo ní okun lati bẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé mímọ́ tónítóní, tí ó sì jẹ́ titun. Nísinsìnyí tí mo ti ní ète ninu ìgbésí-ayé, nkò nílò ìrànlọ́wọ́ ọtí ati oògùn mọ́. Níwọ̀n bí mo sì ti fẹ́ gidigidi lati jẹ́ ọ̀rẹ́ Jehofa, mo pinnu lati máa gbé ní ìbámu pẹlu awọn ọ̀pá ìdíwọ̀n rẹ̀. Bí kìí bá ṣe tí ọgbọ́n ṣíṣeémúlò ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni, ó dá mi lójú pé ǹ bá ti fòpin sí ìwàláàyè mi nísinsìnyí.”
Ní tòótọ́, ọgbọ́n tí ó wá lati ọ̀dọ̀ Jehofa ń gbẹ̀mílà. Nitori naa, a lè jàǹfààní kìí ṣe kìkì lati inú awọn ohun aláìṣeédíyelé tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ninu ṣugbọn lati inú ọ̀nà tí Jehofa ń lò lati kọ́ awọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Níwọ̀n bí Jesu Kristi, Ọmọkùnrin Ọlọrun, ti pàṣẹ fún wa lati jẹ́ olùkọ́ ati olùsọni di ọmọ-ẹ̀yìn, a fẹ́ lati kọ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jùlọ lati gbin ẹ̀kọ́ síni lọ́kàn.—Matteu 28:19, 20.
Bí Jehofa Ṣe Ń Lo Àkàwé
Ìhìnrere Marku sọ pé “oun [Jesu] kìí bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí òwe.” (Marku 4:34) Apá-ẹ̀ka híhàn gbangba yii ninu ẹ̀kọ́ Jesu kò yanilẹ́nu. Oun wulẹ̀ ṣàfarawé ọ̀kan lára awọn ọ̀nà tí a gbà jẹ́ ìhìn-iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ Jehofa fún orílẹ̀-èdè Israeli ni. Èyí ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn àkàwé ṣíṣe kedere.—Isaiah 5:1-7; Jeremiah 18:1-11; Esekieli 15:2-7; Hosea 11:1-4.
Fún àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí bí Jehofa ṣe lo àpèjúwe lílágbára lati kọ́ wa pé awọn òrìṣà kò níláárí. Isaiah 44:14-17 sọ pé: “Ó bẹ́ igi kédárì lulẹ̀ fún araarẹ̀, ó sì mú igi kipressi ati oaku, . . . ó gbin igi aṣi, . . . nígbà naa ni yoo jẹ́ ohun ìdáná fún ènìyàn: nitori yoo mú ninu wọn, yoo sì fi yá iná; lóòótọ́, ó da iná, ó sì dín àkàrà, lóòótọ́, ó ṣe Ọlọrun fún araarẹ̀, ó sì ń sìn ín; ó gbẹ́ ẹ ní ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún ún. Apákan ninu rẹ̀ ni ó sì fi dá iná, apákan ninu rẹ̀ ní ó fi jẹ ẹran: ó sun sísun, ó sì yó, . . . Ìyókù rẹ̀ ni ó fi ṣe ọlọrun, àní ère gbígbẹ́ rẹ̀, ó foríbalẹ̀ fún un, ó sìn ín, ó gbàdúrà sí i, ó sì wí pé, Gbà mi; nitori iwọ ní ọlọrun mi.” Awọn àkàwé báwọ̀nyí jẹ́ irin-iṣẹ́ lílágbára ní ríran awọn olótìítọ́ ọkàn lọ́wọ́ lati kọ ìbọ̀rìṣà ati ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀.
Awọn Ìbéèrè tí Ń Wádìí Ọkàn
Bibeli tún ní awọn àpẹẹrẹ bí Jehofa ṣe tún ojú-ìwòye awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan ṣe nípasẹ̀ awọn ìbéèrè arùrònúsókè. Baba olórí ìdílé naa Jobu jẹ́ ọ̀kan lára awọn wọ̀nyí. Jehofa fi pẹlu sùúrù ràn án lọ́wọ́ lati gbé àìjámọ́ nǹkankan rẹ̀ yẹ̀wò ní ìfiwéra pẹlu Ọlọrun. Èyí ni oun ṣe nípasẹ̀ ọ̀wọ́ awọn ìbéèrè, tí Jobu kò tóótun rárá lati dáhùn.
Jehofa bi Jobu pé, “Níbo ni iwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Ta ni ó fi ilẹ̀kùn sé omi òkun mọ́? . . . Iwọ lè í fi ọ̀já de awọn ìràwọ̀ méje Pleyade tabi iwọ lè túdìí ìràwọ̀ Orionu? . . . Iwọ ní apá bí Ọlọrun?” Ìfìbéèrè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń rẹnisílẹ̀ yii ní ìbéèrè ṣíṣe pàtàkì naa ninu pé: “Iwọ ó sì dá mi [Jehofa] lẹ́bi, kí iwọ kí ó lè í ṣe olódodo?”—Jobu 38:4, 8, 31; 40:8, 9.
Awọn ìbéèrè tí ń wádìí ọkàn wọnyii mú kí Jobu mọ̀ pé oun ti sọ̀rọ̀ láìní òye. Nitori èyí, ó kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ó sì ronúpìwàdà. (Jobu 42:6) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu ọ̀ràn yii, awọn ìbéèrè tí a yàn dáradára lè ṣèrànlọ́wọ́ lati ṣàtúnṣe ìrònú tí kò tọ̀nà tí awọn ọmọ tabi akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa lè ní.
Gbígbé Ìgbọ́kànlé Ró
Bí a bá níláti ṣèrànlọ́wọ́ fún ẹnìkan tí ó nímọ̀lára pé oun kò kúnjú ìwọ̀n tabi tóótun ńkọ́? Ìjíròrò kan láàárín Jehofa ati wòlíì rẹ̀ Mose lè ṣèrànlọ́wọ́ níhà yii. Nígbà tí Ọlọrun yan Mose lati jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún un níwájú Farao ati awọn ọmọ Israeli, wòlíì naa nímọ̀lára àìtóótun lati ṣe iṣẹ́ naa. Ó sọ pé, “olóhùn wúwo ni mí, ati aláhọ́n wúwo.” Ṣugbọn, Ọlọrun fèsì pé: “Ta ni ó dá ẹnu ènìyàn? . . . Emi OLUWA ha kọ́? Ǹjẹ́ lọ nísinsìnyí, emi ó sì pẹlu ẹnu rẹ, emi ó sì kọ́ ọ ní èyí tí iwọ óò wí.”—Eksodu 4:10-12.
Jehofa yan Mose arákùnrin Aaroni gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, wọn sì tẹ̀síwájú lati lọ jíṣẹ́ tí a rán wọn ní Egipti. (Eksodu 4:14-16) Awọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí wọn ti nímọ̀lára àìkúnjú ìwọ̀n bí ti Mose nígbà tí wọn kọ́kọ́ lọ́wọ́ ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé tabi ninu ìjẹ́rìí òpópónà kò kéré níye. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu ọ̀ràn Mose, mímọ̀ pé a ní ìtìlẹ́yìn Jehofa ati pé òjíṣẹ́ kan tí ó nírìírí yoo tẹ̀lé wa lè mú kí ó ṣeéṣe fún wá lati borí ìlọ́tìkọ̀ wá. Àní gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣeéṣe fún Mose lati mú ìgbọ́kànlé dàgbà títí dé orí sísọ awọn ọ̀rọ̀ lílágbára tí a rí lati ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí ninu ìwé Deuteronomi tí ó wà ninu Bibeli, pẹlu ìrànlọ́wọ́ Jehofa awa pẹlu lè mú agbára ọ̀rọ̀ sísọ wa dàgbà síi.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Kan
Ìfẹ́-ọkàn àtọkànwá lati ran awọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ tún jẹ́ èyí tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ànímọ́ tí wòlíì Jona kò ní nìyẹn. Jehofa yan Jona lati kìlọ̀ fún awọn ará Ninefe nipa ìparun tí ń bọ̀ wá sórí ìlú-ńlá naa. Lọ́nà yíyanilẹ́nu, awọn ara Ninefe ronúpìwàdà. (Jona 3:5) Gẹ́gẹ́ bí àbájáde èyí, Jehofa sún ìjábá naa síwájú. Ṣugbọn dípò kí ayọ̀ kún inú rẹ̀ látàrí àṣeyọrí ìgbétásì ìwàásù rẹ̀, Jona bínú gidigidi pé àsọtẹ́lẹ̀ oun kì yoo ní ìmúṣẹ. Bawo ní Jehofa ṣe ràn án lọ́wọ́ lati ní ojú-ìwòye tí ó tọ̀nà?
Jehofa lo ìtàkùn kan lati kọ́ Jona lẹ́kọ̀ọ́ ìjẹ́pàtàkì bíbìkítà nipa awọn ẹlòmíràn. Irúgbìn naa dàgbà lọ́nà ìyanu lóru ọjọ́ kan ó sì pèsè ìbòji títunilára fún Jona, ẹni tí ó ti pa àtíbàbà kan sí ẹ̀yìn òde Ninefe. Jona bẹ̀rẹ̀ sí “yọ ayọ̀ ńlá” nitori irúgbìn rírẹlẹ̀ yii. Ṣugbọn Jehofa mú kí kòkòrò kan jẹ́ ìtàkùn naa kí ó baà lè rọ. Nígbà tí oòrùn pa á tí ẹ̀fúùfù gbígbóná sì fẹ́ lù ú, inú bí Jona tí ó fi sọ pé: “Ó sàn fún mi lati kú ju ati wàláàyè lọ.” (Jona 4:5-8) Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ ninu gbogbo ìwọ̀nyí?
Jehofa bá Jona sọ̀rọ̀ ó sì wí pé: “Iwọ kẹ́dùn ìtàkùn naa nitori èyí tí iwọ kò ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ní iwọ kò mú un dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ní òru kan. Kí èmi kí ó má sì dá Ninefe sí, ìlú-ńlá nì, ninu èyí tí ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà ènìyàn wà tí kò lè mọ ọ̀tún mọ òsì ninu ọwọ́ wọn, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ọ̀sìn?”—Jona 4:9-11.
Ẹ wo irú ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí ìyẹn jẹ́! Jona ní ọkàn-ìfẹ́ ninu ìtàkùn naa ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dídàníyàn fún èyíkéyìí lara ìṣẹ̀dá Ọlọrun yẹ ní gbígbóríyìn fún, ṣíṣèrànlọ́wọ́ lati gba ẹ̀mí awọn ènìyàn là ní iṣẹ́ wa ṣiṣe pàtàkì jùlọ.
Fífi Sùúrù Kọ́ni
Gẹ́gẹ́ bí Jona ti rí i, kìí fìgbà gbogbo rọrùn lati ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa. (2 Timoteu 4:5) Bí ó ti wù kí ó rí, ìwà sùúrù sí awọn ẹlòmíràn yoo ṣèrànlọ́wọ́.
Bawo ní o ṣe ń hùwàpadà bí ọ̀kan lára awọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ ba ń lọ́ra tabi tí kìí yára lóye nǹkan? Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa kọ́ wa bí a ṣe lè kojú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Ó fi sùúrù àrà-ọ̀tọ̀ hàn nígbà tí Abrahamu da ìbéèrè bò ó nipa ìdájọ́ tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀ sórí Sodomu ati Gomorra. “Iwọ óò ha run olódodo pẹlu ènìyàn búburú?” ní Abrahamu béèrè. Abrahamu bẹ̀bẹ̀ pé: “Bóyá àádọ́ta olódodo yoo wà ninu ìlú naa: Iwọ ó ha run ún, iwọ kì yoo ha dá ibẹ̀ naa sí nitori àádọ́ta olódodo tí ó wà ninu rẹ̀?” Ìdáhùn Jehofa sún Abrahamu lati máa bẹ̀bẹ̀ nìṣó títí tí iye naa fi dínkù sí mẹ́wàá. Jehofa mọ̀ pé ìdílé Loti nìkan ṣoṣo ni ó yẹ fún dídásí, ó sì ti ṣètò nipa tiwọn. Ṣugbọn Ọlọrun fi sùúrù fàyègba Abrahamu lati máa bi oun ní ìbéèrè títí tí ó fí lóye bí àánú Jehofa ṣe pọ̀ tó.—Genesisi 18:20-32.
Jehofa fàyè sílẹ̀ fún ibi tí òye Abrahamu mọ ati fún ìmọ̀lára àníyàn rẹ̀. Bí awa pẹlu bá lóye ibi tí agbára akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ, yoo ràn wá lọ́wọ́ lati fi àánú hàn nígbà tí oun bá ń tiraka lati lóye ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ kan pàtó tabi lati borí ìwà kan tí ó ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù.
Máa Báa Nìṣó Ní Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lati Ọ̀dọ̀ Jehofa
Kò sí tabi-ṣugbọn pé Jehofa Ọlọrun ni Atóbilọ́lá Olùkọ́ni. Oun ń gbin òye sí wa lọ́kàn, nípasẹ̀ irú awọn ọ̀nà bí àkàwé, ìbéèrè, ati ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n. Bí a bá ṣe ṣàfarawé ọ̀nà ìgbà kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ naa ní awa fúnraawa yoo ṣe di olùkọ́ni tí ó jáfáfá tó.
Níwọ̀n bí awọn tí ń kọ́ awọn ẹlòmíràn kò ti níláti ṣàìnáání kíkọ́ araawọn, a gbọ́dọ̀ máa báa nìṣó lati jẹ́ ẹni tí ‘Oluwa ń kọ́.’ (Isaiah 54:13) Isaiah kọ̀wé pé: “Ojú rẹ yoo rí [Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, NW] rẹ. Etí rẹ óò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, Èyíyìí ni ọ̀nà, ẹ máa rìn ninu rẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin bá yí sí apá ọ̀tún, tabi nígbà tí ẹ̀yin bá yí sí apá òsì.” (Isaiah 30:20, 21) Nipa bíbá a nìṣó ní rírìn ní ọ̀nà Jehofa ati ríran awọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lati ṣe bẹ́ẹ̀, awa lè ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti kíkẹ́kọ̀ọ́ títíláé lati ọ̀dọ̀ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jehofa bi Jobu pé: “Ńjẹ́ nipa àṣẹ rẹ ni idì fi ń fò lọ sókè tí ó sì ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí orí òkè téńté?”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jehofa kọ́ Jona lati jẹ́ ẹni tí ó túbọ̀ ń dàníyàn nipa awọn ènìyàn, nipa lílo ìtàkùn kan