ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/8 ojú ìwé 6-9
  • Lílà Á Já Nínú Ayé Oníwọra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílà Á Já Nínú Ayé Oníwọra
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣe Ohun Tí O Lè Ṣe Lábẹ́ Ipò Náà
  • Yẹra fún Dídi Ẹni Tí Ìwọra Sọ Dìbàjẹ́
  • Má Ṣe Bọ́hùn Nínú Ìrètí Ìdásílẹ̀
  • Ṣaṣeyọri Ninu Yiyẹra fun Ìdẹkùn Ìwọra
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìwọra—Kí Ló Ń Ṣe fún Wa?
    Jí!—1997
  • O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdẹkùn Èṣù!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/8 ojú ìwé 6-9

Lílà Á Já Nínú Ayé Oníwọra

“BÁWO ni mo ṣe lè là á já?” James Scott dojú kọ ìbéèrè yẹn nígbà tí ó sọ nù láìnírètí ní Òkè Ńlá Himalaya. Ó wà nínú ewu ńlá ti kí ó gan tàbí kí ebi pa á kú. Ó sọ pé òun ti rí àwọn ènìyàn tí ń díje nínú eré kàréètì “tí wọ́n ń pàdánù okun wọn díẹ̀díẹ̀, tí ìpá òun ìkúùkù kọ̀ọ̀kan ń tán wọn lókun, títí tí . . . wọn kò fi ní lè ṣe nǹkan kan mọ́.” Ó sọ pé: “Bí ìmọ̀lára mi ṣe rí nìyẹn nígbà tí mo ń de àpò ìfisùn mi, tí mo sì fẹnu kó òjò dídì díẹ̀ nítorí àìlókun. Ẹ̀mí mi ti pò rúurùu, gbogbo ìfẹ́ àtọkànwá mi láti wà láàyè ti kúrò lára mi. N kò nímọ̀lára ìjákulẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí.”—Lost in the Himalayas.

Lọ́nà kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí dà bíi tirẹ̀—tí a sé mọ́ inú ayé kan tí ìwọra ń jọba lé. O lè nímọ̀lára pé o ń pàdánù okun rẹ díẹ̀díẹ̀, tí a sì ń borí rẹ. Ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ lè yè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ipa tí ìwọra ń ní ní tààràtà. Ó sinmi lórí ibi tí o ń gbé ní ayé, ìṣòro tí o ń kojú yóò yàtọ̀ gidigidi—ìwọra ń kan àwọn ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lọ́nà yíyàtọ̀ gan-an sí àwọn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun yòó wù kí àwọn ìṣòro náà jẹ́, bóyá ìwọ lè kọ́ bí o ṣe lè máa wà nìṣó ní ti ara ìyára, èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí títí ti ìdásílẹ̀ yóò fi dé. Báwo? Nípa títẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn ṣíṣe kókó tí àwọn ògbógi nípa lílà á já pèsè.

Àwọn kókó méjì fara hàn nínú ìmọ̀ràn wọn. Àkọ́kọ́ ni láti yẹra fún mímú kí ipò tí ó ti ṣòro tẹ́lẹ̀ burú sí i. Ìwé ìléwọ́ The Urban Survival Handbook sọ pé: “Ìwéwèé àfìṣọ́raṣe rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ láti yẹra fún àwọn ewu tí kò pọn dandan . . . kí o sì dín ìbàjẹ́ tí àwọn tí o kò lè yẹra fún ń ṣe kù.” Èkejì—bóyá èyí tí ó sì ṣe pàtàkì jù—ní í ṣe pẹ̀lú ìṣarasíhùwà. Ìwé ìléwọ́ The SAS Survival Handbook sọ pé: “Lílà á já jẹ́ ọ̀ràn ẹ̀mí èrò orí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìfaradà ti ara ìyára àti ìmọ̀ ti jẹ́.”

Ṣe Ohun Tí O Lè Ṣe Lábẹ́ Ipò Náà

Ìwé Staying Alive—Your Crime Prevention Guide ròyìn pé: “Wọ́n ń pa ènìyàn kan láàárín ìṣẹ́jú 22 ní United States, wọ́n ń ja ẹnì kan lólè láàárín ìṣẹ́jú àáyá 47, wọ́n sì ń fipá kọ lu ẹnì kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá 28 lọ́nà líléwu gan-an.” Nínú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, kí ni o lè ṣe? Ó kéré tán, o lè gbìyànjú láti yẹra fún sísọ ara rẹ di ohun àfojúsùn híhàn gbangba tàbí ẹni tí ó rọrùn láti pa lára. Wà lójúfò, kí o sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ṣe ohun tí o bá lè ṣe láti dín ewu kù.a

Fún àpẹẹrẹ, má ṣe mú kí ipò rẹ burú sí i nípa jíjẹ́ ẹni tí a lè tètè tàn jẹ. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ará America ni wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn ti jìyà ìpalára jìbìtì—tí àwọn aláìtẹ̀lé-lànà tí ń ṣọdẹ àwọn tí wọ́n lè pa lára tí wọ́n ṣíra payá sí ìjàǹbá fi ìtànjẹ gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là lọ́wọ́ wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òjìyà ìpalára náà máa ń jẹ́ àwọn àgbàlagbà bí opóbìnrin ẹni ọdún 68 kan tí wọ́n fipá jí 40,000 dọ́là lọ́wọ́ rẹ̀. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i ló fa àkọlé ìròyìn náà pé: “Ewú Ì Báà Wà Lórí Rẹ, Àwọ̀ Ewé [tí ó túmọ̀ sí èèpo aláwọ̀ ewé, tàbí dọ́là] Ni Àwọn Atannijẹ Ń Rí.”

Ṣùgbọ́n o kò ní láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀, òjìyà ìpalára mìíràn tí kò lólùgbèjà, tí ń dúró de kí a kó òun nífà. Ìwé Staying Alive kìlọ̀ fún wa pé: “Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀tá afojújọ̀rẹ́.” Ìyá àgbà kan tí ó jẹ́ ẹni 70 ọdún lo ìmọ̀ràn yí. Wọ́n fi àròpọ̀ dọ́là 10 péré lóṣù fún kíkájú ìbánigbófò owó ìtọ́jú ìṣègùn lọ̀ ọ́. Ìròyìn náà sọ pé: “Kìkì ohun tí Ìyá Àgbà ní láti ṣe ni pé kí ó sàsan-ánlẹ̀ 2,500 dọ́là fún olùtajà náà.” Kò san án. Nípa títẹ ilé iṣẹ́ ìbánigbófò náà láago, ó rí i pé oníjìbìtì ni ọkùnrin náà. “Bí ó ti ń bu ife tíì kejì fún olùtajà náà, àwọn ọlọ́pàá dé, wọ́n sì mú ọkùnrin náà lọ.”

Ṣíṣe ohun tí o bá lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ ṣe kedere láti inú ìmọ̀ràn tí a fúnni nínú Bíbélì. “Òpè ènìyàn gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́: ṣùgbọ́n amòye ènìyàn [ṣọ́] ọ̀nà ara rẹ̀.” (Òwe 14:15; 27:12) Ọ̀pọ̀ ènìyàn fọwọ́ rọ́ Bíbélì sẹ́yìn bí èyí tí kò bágbà mu, tí kò sì wúlò. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn rẹ̀ wíwúlò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa wà nìṣó. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ààbò ni ọgbọ́n [irú èyí tí a rí nínú Bíbélì], àní bí owó ti jẹ́ ààbò: ṣùgbọ́n èrè ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n fi ìyè fún àwọn tí ó ní in.”—Oníwàásù 7:12.

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ń ka Jí! ti rí i pé òtítọ́ ni èyí jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ti jèrè ìwọ̀n ààbò nípa kíké rara nígbà tí a bá fi ìfipábáni-lòpọ̀ tàbí ìwà ipá halẹ̀ mọ́ wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a mẹ́nu kàn nínú Diutarónómì 22:23, 24. Àwọn mìíràn ti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì láti yẹra fún ohunkóhun “tí ń sọ yálà ara tàbí ẹ̀mí di eléèérí.” (Kọ́ríńtì Kejì 7:1, The Twentieth Century New Testament) Wọ́n ti tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn tí ń kiri tábà àti oògùn líle, tí ń sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀ nípa fífi ìlera àwọn ènìyàn sínú ewu. Ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé pẹ̀lú ti yẹra fún ìdẹkùn àwọn oníwàásù orí tẹlifíṣọ̀n tí ń wá owó àti àwọn òṣèlú tí ń yán hànhàn fún agbára. (Wo àpótí, ojú ìwé 7.) Ka Bíbélì. Bí ìrànlọ́wọ́ wíwúlò tí ó ń fúnni ṣe pọ̀ tó lè yà ọ́ lẹ́nu.

Yẹra fún Dídi Ẹni Tí Ìwọra Sọ Dìbàjẹ́

Dájúdájú, ewu mìíràn ń ti inú ìwọra wá—ìwọ fúnra rẹ lè di oníwọra. Èyí yóò fi àwọn ànímọ́ ìwà rere dídára jù tí ń fìyàtọ̀ hàn láàárín ìwọ àti ẹranko dù ọ́. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ìṣòwò ṣe-bóo-ti-fẹ́, níbi tí àwọn oníṣòwò ti ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti jèrè, a fa ọ̀rọ̀ ògbógi alákìíyèsí kan yọ tí ó sọ pé: “Àwọn wọ̀bìà ń fi ìwàǹwára lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti kó èrè jọ. Apá kò kàn ká ìwọ̀n ìwọra . . . náà ni.” Ìyẹn jọ ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ju bí ó ti jẹ́ sí àwọn oníṣòwò akóninífà lọ! Ó jọ pé wọ́n kọtí ikún sí ìmọ̀ràn rere tí Jésù Kristi fúnni pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.”—Lúùkù 12:15.

Jésù Kristi fúnni ní ìmọ̀ràn yẹn nítorí ó mọ̀ bí o ṣe lè ṣèjàǹbá fún ara rẹ tó bí ìwọra bá kì ọ́ mọ́lẹ̀. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì—dájúdájú, bákan náà sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fún agbára tàbí ìbálòpọ̀—lè di ohun àìníjàánu tí ó gba gbogbo ìgbésí ayé rẹ, tí ń fi àkókò àti ìtẹ̀sí ọkàn èyíkéyìí tí ó ṣeé ṣe kí o ní láti bìkítà fún àwọn ènìyàn tàbí tí o ní fún àwọn ìlànà tẹ̀mí dù ọ́. Anthony Sampson sọ nínú ìwé rẹ̀, The Midas Touch, pé: “Owó” ti “gba ọ̀pọ̀ lára àwọn ànímọ́ tí ìsìn ní.” Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Owó ti di ọlọ́run kan. Wọ́n ti fi ìwọra àti èrè rọ́pò ohun gbogbo. Kókó pàtàkì kan tí ó jẹ́ ìdí abájọ ni èrè. Bí ó bá ṣe pọ̀ tó ni ó ṣe dára tó. Ní gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láìka iye àkókò tí a lò lórí rẹ̀ sí, a kò lè tẹ́ ìwọra fún ọrọ̀ àlùmọ́nì lọ́rùn pátápátá. Oníwàásù 5:10 sọ pé: “Ẹni tí ó bá fẹ́ fàdákà, fàdákà kì yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fẹ́ ọrọ̀, kì yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn.” Lọ́nà kan náà, “ẹni tí ó bá fẹ́” agbára, ohun ìní, tàbí ìbálòpọ̀ kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn láé, bí ó ti wù kí ó ní tó.

Má Ṣe Bọ́hùn Nínú Ìrètí Ìdásílẹ̀

Kọ́kọ́rọ́ pátákì kan sípa wíwà nìṣó ni dídi ojú ìwòye tí ó kún fún ìrètí, tí ó sì wà déédéé mú. Nígbà míràn, ìwọ̀nba ni o lè ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ ipa tí àwọn oníwọra ń ní lórí ẹni. Fún àpẹẹrẹ, lọ́pọ̀ ìgbà, ìwọ̀nba ni àwọn ènìyàn tí ebi ń pa ń lè ṣe láti bọ́ nínú ipò búburú tí wọ́n wà. Bí ó ti wù kí ó rí, má ṣe bọ́hùn; má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Ìwé ìléwọ́ The SAS Survival Handbook sọ pé: “Ó rọrùn láti juwọ́ sílẹ̀, láti jura nù, kí o sì máa dá kẹ́dùn” nígbà tí o bá wà nínú ipò àyíká aláìníwà-bí-ọ̀rẹ́ tàbí tí ó léwu. Má ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn èrò àti èrò ìmọ̀lára òdì. Ìwọ̀n tí o lè fara dà á dé lè ṣe ọ́ ní kàyéfì. Ìwé ìléwọ́ kan náà sọ pé: “Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti fi hàn pé àwọn lè máa wà nìṣó láàárín àwọn ipò tí kò bára dé.” Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Ó sọ pé ìdí tí wọ́n fi lè máa wà nìṣó jẹ́ “nítorí ìpinnu wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ètò ìgbékalẹ̀ oníwọra yìí borí rẹ.

James Scott, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, ni a yọ, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nínú ewu ohun tí ì bá ti jẹ́ sàréè rẹ̀ ní Himalaya. Ó wí pé ìjàkadì òun láti máa wà nìṣó ti kọ́ òun ní, ó kéré tán, ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Kí ni ẹ̀kọ́ náà? Ó sọ pé: “Kò sí ìpèníjà kan nínú ìgbésí ayé tí ó le jù láti kò lójú.” Tim Macartney-Snape, tí ó jẹ́ onírìírí nínú òkè pípọ́n, tí ó ṣe kàyéfì pé James Scott lè fara dà á títí di ìgbà tí wọ́n rí i lóòyẹ̀, pẹ̀lú kọ́ ẹ̀kọ́ kan. Ó sọ pé: “Níwọ̀n bí àmì ìrètí èyíkéyìí bá ti wà, o kò gbọ́dọ̀ bọ́hùn láé.” Nítorí náà, láìka bí ipò nǹkan bá ṣe fara hàn bí èyí tí ó dá gùdẹ̀ tó sí, bí o bá sọ̀rètí nù, o wulẹ̀ ń mú kí ọ̀ràn náà burú sí i ni. Má ṣe bọ́hùn nínú ìrètí ìdásílẹ̀.

Ṣùgbọ́n “àmì ìrètí” kankan, àǹfààní èyíkéyìí tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé fún ìdásílẹ̀ lọ́wọ́ ayé tí ó kún fọ́fọ́ fún ìwọra ha wà bí? A óò ha mú àwọn oníwọra tí wọ́n ń tẹ pílánẹ́ẹ̀tì yí rẹ́, tí wọ́n sì ń ba ìwàláàyè àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn jẹ́ kúrò bí? Ní tòótọ́, ìfojúsọ́nà gidi kan wà fún ìdásílẹ̀. Yẹ àwọn ìdáhùn Bíbélì tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e wò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ “Ìwà-Ipá—Iwọ Lè Daabobo Araàrẹ,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde ti October 22, 1989, ojú ìwé 7 sí 10.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ìkìlọ̀ Bíbélì Tí Ó Bágbà Mu

Òwe 20:23 “Ìwọ̀n míràn, àti òṣùwọ̀n míràn, ìríra ni lójú Olúwa; ìwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì dára.”

Jeremáyà 5:26, 28 “Nítorí láàárín ènìyàn mi ni a rí ènìyàn ìkà, wọ́n wò káàkiri, bíi bíba ẹni tí ń dẹ ẹyẹ, wọ́n dẹ okùn wọn mú ènìyàn. Wọ́n sanra, wọ́n ń dán, pẹ̀lúpẹ̀lù wọ́n ré kọjá ní ìwà búburú, wọn kò ṣe ìdájọ́, wọn kò dájọ́ ọ̀ràn aláìníbaba, kí wọ́n lè rí rere; wọn kò sì dájọ́ àre àwọn tálákà.”

Éfésù 4:17-19 “Nítorí náà, èyí ni mo ń wí tí mo sì ń jẹ́rìí sí nínú Olúwa, pé kí ẹ má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn, bí wọ́n ti wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan tí ń bẹ nínú wọn, nítorí yíyigbì ọkàn àyà wọn. Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.”

Kólósè 3:5 “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́ ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”

Tímótì Kejì 3:1-5 “Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn-sí-òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúró-ṣinṣin, aláìní-ìfẹ́ni-àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra ẹni níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀-pẹ̀lú-ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.”

Pétérù Kejì 2:3 “Pẹ̀lú ojúkòkòrò wọn yóò fi àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó yín nífà. Ṣùgbọ́n ní tiwọn, ìdájọ́ náà láti ìgbà láéláé kò falẹ̀, ìparun wọn kò sì tòògbé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́