Ìwọra—Kí Ló Ń Ṣe fún Wa?
ÌWỌRA ń ba ìwàláàyè ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́. Ó ń fi àwọn àkópọ̀ ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn du àwọn oníwọra, ó sì ń fa ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn tí ń jìyà ìpalára tí wọ́n ń ṣe. Ìwọ lè máa nímọ̀lára ipa tí ìwọra ní gan-an nínú ìgbésí ayé rẹ. Kódà, jíjí ọjà lórí àtẹ ń mú kí iye owó ọjà tí o ń rà pọ̀ sí i. Bí owó ọ̀yà rẹ bá kéré, tí iye àwọn kòṣeémánìí ojoojúmọ́ sì kọjá ohun tí o lè rà, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìyà ìpalára ìwọra ẹnì kan lò ń jẹ.
Àwọn Tí Ebi Ń Pa àti Àwọn Tí Ń Kú Lọ
Fífi ìwọra wá ire ara ẹni fún orílẹ̀-èdè ń dojú ìsapá ìjọba láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́ délẹ̀. Láti 1952 ni onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ògbógi nípa oúnjẹ náà, Alàgbà John Boyd Orr, ti sọ pé: “Àwọn ìjọba múra tán láti mú àwọn ènìyàn àti ohun èèlò ṣọ̀kan fún ogun àgbáyé kan ṣùgbọ́n Àwọn Alágbára Ńlá kò múra tán láti fìmọ̀ ṣọ̀kan láti lé ebi àti àìní kúrò ní ayé.”—Food Poverty & Power, láti ọwọ́ Anne Buchanan.
A gbà pé wọ́n pèsè àwọn àfijọ àrànṣe kan. Ṣùgbọ́n kí ní ń ṣẹlẹ̀ ní gidi sí àwọn aláìní, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tí a ṣá tì lágbàáyé? Ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ kan sọ pé lójú pé oúnjẹ tí a ń mú jáde ń pọ̀ sí i ní àwọn àgbègbè kan, “ebi àti àìjẹunre-kánú ṣì ń gbá ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aláìní láyé mú . . . Ìdá márùn-ún [tí ó lé ní bílíọ̀nù kan] àwọn ènìyàn ayé ni ebi ń pa lójoojúmọ́.” Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Ní àfikún, àwọn bílíọ̀nù 2 ènìyàn ń jìyà lọ́wọ́ ‘àìjẹunre-kánú’ nítorí . . . àìní [oúnjẹ] tó, èyí tí ó lè yọrí sí àrùn líle koko.” (Developed to Death—Rethinking Third World Development) Ó yẹ kí àwọn àkójọ ìṣirò wọ̀nyí jẹ́ kókó inú àwọn ìròyìn!
Àwọn Tí A Mú Lẹ́rú
Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀daràn ń sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀ nípa ṣíṣèpalára fún àwọn òjìyà ìpalára tí wọ́n ń ṣe àti àwọn aráàlú lápapọ̀. Oògùn líle, ìwà ipá, ìṣaṣẹ́wó, àti ìkóninífà nínú ọ̀ràn ìnáwó ti sọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn dẹrú. Bákan náà, Gordon Thomas sọ nínú ìwé rẹ̀, Enslaved, pé: “Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Agbógunti Òwò Ẹrú ti sọ, 200 mílíọ̀nù ẹrú ni a fojú díwọ̀n pé ó wà láyé. Ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù lára wọ́n jẹ́ ọmọdé.” Kí ni lájorí okùnfà rẹ̀? Ìròyìn náà ṣàlàyé pé: “Ìrọni láti sọ ènìyàn dẹrú ṣì jẹ́ apá dídágùdẹ̀ nípa àbùdá ènìyàn . . . [Òwò ẹrú ni] ìmújáde ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìwọra àti ìfẹ́ fún agbára.”
Àwọn alágbára ń lé àwọn aláìlera, tí wọ́n rọrùn láti kọ lù kúrò, wọ́n sì ń pa púpọ̀ lára wọn. “Bóyá ọ̀kẹ́ mẹ́wàá ló là á já nísinsìnyí lára àwọn ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ ará Íńdíà tí wọ́n ń gbé Brazil nígbà tí àwọn òyìnbó kọ́kọ́ dé.” (The Naked Savage) Kí ló fà á? Ìwọra ni lájorí okùnfà rẹ̀.
Àlàfo Tí Ń Pọ̀ Sí i Láàárín Ọlọ́rọ̀ àti Aláìní
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé James Gustave Speth, alákòóso kan nínú Ètò Ìdàgbàsókè Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ pé “àwùjọ àwọn ọ̀tọ̀kùlú kan tí wọ́n wà káàkiri àgbáyé . . . ń kó ọrọ̀ àti agbára púpọ̀ jọ fún ara wọn, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ó lé ní ìdajì aráyé ṣaláìní gan-an.” Àlàfo líléwu tí ó wà láàárín ọlọ́rọ̀ àti aláìní yìí túbọ̀ hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “A ṣì ní iye tí ó pọ̀ ju ìdajì àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lórí pílánẹ́ẹ̀tì yí, tí owó tí ń wọlé fún wọn lójúmọ́ kò tó dọ́là 2—àwọn ènìyàn tí iye wọ́n lé ní bílíọ̀nù 3.” Ó fi kún un pé: “Fún àwọn aláìní, ayé ẹlẹ́gbẹ́ méjì yí jẹ́ ibi mímú àìnírètí, ìbínú, ìjákulẹ̀ dàgbà.”
Òkodoro òtítọ́ náà pé ó jọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọlọ́rọ̀ ni kò ní ẹ̀rí ọkàn, wọn kò sì ní ìyọ́nú kankan fún ipò ìṣòro àwọn gbáàtúù tí wọ́n ṣaláìní, tí ebi sì ń pa, ló ń mú kí àìnírètí yìí máa pọ̀ sí i.
Àwọn òjìyà ìpalára ìwọra wà níbi gbogbo. Fún àpẹẹrẹ, wo ìbẹ̀rùbojo tí ó hàn lójú àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n há sínú ìjìjàdù fún agbára ní Bosnia, Rwanda, àti Liberia. Wo ìrísí àìjanpata lójú àwọn tí ebi ń pa láàárín ayé tí ó kún fún ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan. Kí ló wà lẹ́yìn gbogbo rẹ̀? Onírúurú ìwọra ni!
Báwo ni o ṣe lè máa wà nìṣó bí àwọn akóninífà oníwọra bá yí ọ ká nínú irú àyíká aláìníwà-bí-ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ méjì tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé ìbéèrè yí yẹ̀ wò.