Ayé Kan Láìsí Ìwọra
“LÁÌSÍ ìyípadà tegbòtigaga nínú ìrònú ẹ̀dá ènìyàn jákèjádò ayé, kò sí ohun tí yóò túbọ̀ sunwọ̀n nípa wíwà wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tí ayé wa sì ń forí lé . . . kì yóò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.”—Václav Havel, ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech.
Àwọn ènìyàn púpọ̀ mọ̀ pé ètò ayé ìsinsìnyí kò lè máa wà nìṣó. Àwọn kan, bíi Václav Havel, rí ìyípadà ìrònú àti ìhùwà ẹ̀dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ojútùú kan ṣoṣo tí ó wà. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan tí ń ṣàkíyèsí ìṣẹ̀lẹ̀ ayé, sọ pé: “Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn tí àìní rìn mọ́lẹ̀ dan-indan-in, ìfojúsọ́nà fún oúnjẹ àti àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé mìíràn kò lè sunwọ̀n sí i . . . àyàfi bí àwọn orílẹ̀-èdè ayé bá gbégbèésẹ̀ tìpinnutìpinnu láti yí ìtẹ̀sí lọ́ọ́lọ́ọ́ pa dà.”—Food Poverty & Power.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ha bọ́gbọ́n mu láti gbé ìrètí wa láti máa wà nìṣó karí àwọn ìyípadà pàtàkì kan nínú àbùdá ẹ̀dá ènìyàn bí? A ha lè fi ìdánilójú gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìjọba láti “gbégbèéṣẹ̀ tìpinnutìpinnu láti yí ìtẹ̀sí lọ́ọ́lọ́ọ́ pa dà” bí? Àwọn kan ronú bẹ́ẹ̀. Wọ́n sọ pé: ‘Ọlọ́run fún wa ní ìdánúṣe fàlàlà, ó sì kù sọ́wọ́ wa láti yí àwọn nǹkan pa dà.’ Ṣùgbọ́n òkodoro òtítọ́ inú ìtàn ní gidi gbé àwọn ìbéèrè gbígbàrònújinlẹ̀ dìde nípa ìfẹ́-ọkàn ènìyàn àti ìtóótun rẹ̀ láti ṣe àwọn ìyípadà tí a nílò. Èròǹgbà yí kì í ṣe èyí tí kò fojú sọ́nà fún ire, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó ṣeé fojú gidi wò. Ìwọ yóò ha fi ẹ̀mí rẹ lé oníṣẹ́ abẹ kan lọ́wọ́ bí o bá mọ̀ pé gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ti tọ́jú rí ni wọ́n kú bí?
Ìṣòro Ẹ̀kọ́
Ted Trainer sọ nínú ìwé Developed to Death—Rethinking Third World Development pé: “Ìṣòro náà jẹ́ ti ẹ̀kọ́.” Ó sọ pé àyàfi bí a bá lè kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ láti rí i pé a nílò ìyípadà pàtàkì, “a kò lè retí láti ṣàṣeyọrí ìrékọjá lọ sínú ètò ayé kan tí ó lè gbéṣẹ́.” Kò sí iyè méjì pé àìní wà láti kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìjẹ́pàtàkì ìyípadà ìṣarasíhùwà àti ìgbésẹ̀ bí ayé yìí yóò bá ní láti máa wà nìṣó. Ní tòótọ́, ó pọn dandan, Bíbélì sì sọ nípa irú ìṣètò ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé ilẹ̀ ayé yóò “kún fún ìmọ̀ Olúwa.” Nígbà náà, ẹnikẹ́ni kì yóò “pani lára, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò pani run” níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 11:9.
Àmọ́ kò sí bí ẹ̀kọ́ ṣe lè pọ̀ tó, kódà kò sí ìṣètò ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pàápàá, tí ó lè dá tìkara rẹ̀ gbá àwọn oníwọra tí ń ṣèpalára ńláǹlà, tí wọ́n sì ń fa ìparun níbi gbogbo, kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ̀kọ́ yóò mú ìyípadà wá nínú kìkì àwọn ẹni tí wọ́n fẹ́ láti yí pa dà, àwọn ẹni tí wọ́n fẹ́ láti mú ara wọn bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. Gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ti sọ, wọn kò tó nǹkan. (Mátíù 7:13, 14) Nítorí náà, Bíbélì kò gbé ìlérí ìyípadà rẹ karí àwọn ìrètí ẹlẹ́tàn kan pé lọ́jọ́ kan, gbogbo aráyé yóò mọ bí ìṣòro náà ṣe tóbi tó, wọn óò sì yí àwọn ọ̀nà wọn pa dà. Ó sọ pé Ọlọ́run yóò gbé ìgbésẹ̀ tààràtà láti mú àwọn oníwọra kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
Ìdásí Ọlọ́run
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ka èrò nípa ìdásí tààràtà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yìí sí àlá tàbí ìrújú. Ìwé World Hunger: Twelve Myths sọ pé: “Àwọn ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún fipá mú wa sọ̀rètí nù nínú èrò atuninínú nípa Ọlọ́run olùdásí-ọ̀ràn kan, tí yóò tún ibùgbé aráyé ṣe.” Àmọ́, ó ha yẹ kí àwa gba ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n èrò orí àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú “Ọlọ́run olùdásí-ọ̀ràn kan” gbọ́ bí? Àwọn ojútùú tí wọ́n ń mú wá kì í ha ṣe ìrújú bí?
Ó bọ́gbọ́n mu jù láti gbé ìrètí wa fún wíwà nìṣó karí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí kì í ṣìnà, tí a rí nínú Bíbélì, tí ó tọ́ka sí ìdásí ní ìhà ti Ọlọ́run. Kì í ṣe “èrò atuninínú” lásán láti gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́—òun ni ìrètí tí ó ṣeé fojú gidi wò kan ṣoṣo tí a ní fún wíwà nìṣó!
“Mú Àwọn Wọnnì Tí Ń Run Ayé Bà Jẹ́ Wá sí Ìrunbàjẹ́”
Kí ni Ọlọ́run ṣèlérí ní gidi? Ó dára, fún ohun kan, ó ṣèlérí láti mú àwọn tí ń sọ ayé deléèérí, tí wọ́n sì ń ba àyíká jẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ìṣípayá 11:18 polongo pé ó ní “àkókò tí a yàn kalẹ̀” láti “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.” Kí ni ìyẹn yóò túmọ̀ sí? Yóò túmọ̀ sí òpin gbogbo àwọn tí ń ni àwọn aláìní àti àwọn aláìlera lára ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ọlọ́run yóò ‘ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà ènìyàn, yóò gba àwọn ọmọ àwọn aláìní, yóò sì fa aninilára ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.’ Yóò mú àwọn oníwọra kúrò, yóò sì jẹ́ kí àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tí ń jìyà ìpalára tí wọ́n ń ṣe gbilẹ̀. “Òun yóò gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: . . . Òun óò ra ọkàn wọn pa dà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà agbára.”—Orin Dáfídì 72:4, 12-14.
Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti yàtọ̀ tó! Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ti sọ, ìyípadà yí yóò jẹ́ pátápátá gan-an débi pé yóò ṣèmújáde “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan.” (Pétérù Kejì 3:13) Nínú “ayé tuntun” yìí, olúkúlùkù yóò gbádùn èyí tí ó tó láti inú ohun tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde. (Míkà 4:4) Kódà, nísinsìnyí, oúnjẹ tí ó pọ̀ wà fún olúkúlùkù. Àìpín in dọ́gba ni ìṣòro. Anne Buchanan sọ nínú ìwé rẹ̀, Food Poverty & Power, pé: “A ti fojú díwọ̀n pé a lè ṣèmújáde ohun tí ó pọ̀ tó láti gbọ́ bùkátà bílíọ̀nù 38 sí 48 ènìyàn lórí àgbègbè àgbáyé tí ó ṣeé fi ṣọ̀gbìn.”
Pílánẹ́ẹ̀tì yí yóò là á já. Ẹlẹ́dàá rẹ̀ “kò dá a lásán, [ṣùgbọ́n] ó mọ ọ́n kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Ìgbésẹ̀ Ọlọ́run lòdì sí àwọn oníwọra yóò túmọ̀ sí àkókò kúkúrú tí “ìpọ́njú ńlá” yóò fi ṣẹlẹ̀. (Mátíù 24:21) Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n la ìpọ́njú yẹn já yóò wá gbádùn párádísè ilẹ̀ ayé kan, tí ó kún fún àwọn ènìyàn tí kò ní ìwọra rárá. (Orin Dáfídì 37:10, 11; 104:5) Yóò dà bí Bíbélì ti ṣèlérí pé: “Jèhófà yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.
Ìwọ pẹ̀lú lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aláyọ̀ olùjàǹfàní ìgbésẹ̀ Ọlọ́run láti fọ ìwọra kúrò nínú ayé. Bí o bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní gidi, mú ara rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí a pèsè láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa wà nìṣó nísinsìnyí nínú ayé oníwọra. Gbé ìgbésẹ̀ láti la “ìpọ́njú ńlá” náà já. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí o nílò láti mọ̀. Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti kàn sí wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5.