ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/1 ojú ìwé 10-15
  • Ṣaṣeyọri Ninu Yiyẹra fun Ìdẹkùn Ìwọra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣaṣeyọri Ninu Yiyẹra fun Ìdẹkùn Ìwọra
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jehofa Kilọ fun Wa Nipa Ewu
  • A Dẹkùn Mú Wọn Nipasẹ Ìwọra fun Ọrọ̀ Tabi Awọn Ohun-ìní
  • Ìwọra Ninu Awọn Apá Ìhà Igbesi-Aye Miiran
  • Maa Baa Lọ Lati Jẹ Onipinnu Lati Yẹra fun Ìwọra
  • O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdẹkùn Èṣù!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìwọra—Kí Ló Ń Ṣe fún Wa?
    Jí!—1997
  • Máa Gbọ́ Ohùn Jèhófà Níbikíbi Tó O Bá Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/1 ojú ìwé 10-15

Ṣaṣeyọri Ninu Yiyẹra fun Ìdẹkùn Ìwọra

“Awọn ti ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a maa bọ́ sinu idanwo ati ìdẹkùn.”—1 TIMOTEU 6:9.

1. Eeṣe ti a fi nilati ni aniyan-ọkan nipa awọn ìdẹkùn?

Ọ̀RỌ̀ naa “ìdẹkùn” lè mú ki o ronu nipa ọlọ́dẹ kan tí ń dẹ ohun-ẹ̀rọ awúrúju kan lati mú ẹran-ọdẹ ti kò fura. Bi o ti wu ki o ri, Ọlọrun mú un ṣe kedere pe fun wa, awọn ìdẹkùn ti o léwu julọ, kìí ṣe iru awọn ohun-ẹ̀rọ gidi bẹẹ, ṣugbọn ohun ti o lè dẹkùn mú wa nipa tẹmi tabi nipa ti iwarere ni. Eṣu jẹ́ ìjìmì ninu dídẹ iru awọn ìdẹkùn bẹẹ.—2 Korinti 2:11; 2 Timoteu 2:24-26.

2. (a) Bawo ni Jehofa ṣe ń ràn wá lọwọ lati yẹra fun awọn ìdẹkùn eléwu? (b) Iru ìdẹkùn wo ní pataki ni a ń yiju afiyesi si nisinsinyi?

2 Jehofa ń ràn wá lọwọ nipa fifi diẹ lara ọpọlọpọ ati oniruuru ìdẹkùn Satani hàn. Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun kilọ pe ètè, tabi ẹnu wa, lè jẹ́ ìdẹkùn bi a bá sọrọ lọna ailọgbọn, lọna ainironu, tabi nipa ohun tí kò yẹ ki a sọ. (Owe 18:7; 20:25) Igberaga lè jẹ́ ìdẹkùn, gẹgẹ bi bíbá awọn eniyan ti wọn ní ìtẹ̀sí siha ibinu kẹgbẹ ṣe lè jẹ. (Owe 22:24, 25; 29:25) Ṣugbọn ẹ jẹ ki a yiju si ìdẹkùn miiran: “Awọn ti ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a maa bọ́ sinu idanwo ati ìdẹkùn, ati sinu wèrè ifẹkufẹẹ pipọ tíí panilára, iru eyi tíí maa ri eniyan sinu iparun ati ègbé.” (1 Timoteu 6:9) Ohun ti ó wà lẹhin ìdẹkùn yẹn tabi ti ó jẹ́ ipilẹ fun un ni a lè ṣàkópọ̀ rẹ̀ ninu ọ̀rọ̀ naa “ìwọra.” Bi o tilẹ jẹ pe ìwọra ni a sábà maa ń fẹ̀rí rẹ̀ hàn nipa ipinnu lati di ọlọ́rọ̀, ìwọra nitootọ jẹ́ ìdẹkùn ti ó ní ọpọlọpọ apá ìhà.

Jehofa Kilọ fun Wa Nipa Ewu

3, 4. Ọ̀rọ̀-ìtàn igbaani ti ẹda-eniyan ní ẹkọ wo ninu nipa ìwọra?

3 Ni ipilẹ, ìwọra jẹ́ ìfẹ́-ọkàn aláìníwọ̀n tabi àníjù lati ní pupọ sii, yala iyẹn jẹ́ owó, ohun-ìní, agbara, ibalopọ takọtabo, tabi awọn ohun miiran. Awa kọ́ ni ẹni akọkọ ti ìdẹkùn ìwọra maa fi sinu ewu. Tipẹ sẹhin ninu ọgbà Edeni, ìwọra dẹkùn mú Efa ati lẹhin naa Adamu. Ẹnikeji Efa ninu igbeyawo, ti o niriiri pupọ ninu igbesi-aye ju bi oun ti ní lọ, ni Jehofa ti fun ni itọni ni taarata. Ọlọrun ti pese ile paradise kan. Wọn lè gbadun ọpọ yanturu ounjẹ didara ati oniruuru, ti a mú jade lori ilẹ ti a kò sọ di ẹlẹ́gbin. Wọn lè reti lati ní awọn ọmọ pípé, ti wọn lè bá gbé ki wọn sì jọ ṣiṣẹsin Ọlọrun lailopin. (Genesisi 1:27-31; 2:15) Iyẹn kò ha ní jọ bi eyi ti o pọ̀ tó lati tẹ́ eniyan eyikeyii lọ́rùn bi?

4 Sibẹ, pe ẹnikan ní ànító kò dí ìwọra lọwọ lati maṣe jẹ́ ìdẹkùn. Efa ni a dẹkùn mú nipa ifojusọna fun dídàbí Ọlọrun, níní ominira pupọ sii ati gbigbe awọn ọpa-idiwọn tirẹ̀ funraarẹ kalẹ. Ó dabi pe Adamu fẹ́ ipo-ibakẹgbẹ ti ń baa lọ pẹlu ẹnikeji rẹ̀ rírẹwà, laika ohun ti iyẹn ná an sí. Niwọn bi awọn eniyan pípé wọnyi paapaa ti lè di ẹni ti a dẹkùn mú nipasẹ ìwọra, iwọ lè mọriri idi ti ìwọra fi lè jẹ́ ewu kan fun wa.

5. Bawo ni o ti ṣe pataki fun wa tó lati yẹra fun ìdẹkùn ìwọra?

5 A gbọdọ ṣọra fun dídi ẹni ti a dẹkùn mú nipasẹ ìwọra nitori pe aposteli Paulu kilọ fun wa pe: “Ẹyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣootọ ki yoo jogun ijọba Ọlọrun? Ki a ma tàn yin jẹ: kìí ṣe awọn àgbèrè, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti ń fi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, tabi awọn olè, tabi awọn [oníwọra, “NW”] . . . ni yoo jogun ijọba Ọlọrun.” (1 Korinti 6:9, 10) Paulu tun sọ fun wa pe: “Àgbèrè, ati gbogbo ìwà-èérí, tabi [ìwà-ìwọra, NW], ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ laaarin yin mọ́.” (Efesu 5:3) Nitori naa ìwà-ìwọra ni kò tilẹ nilati jẹ́ akori-ọrọ fun ijumọsọrọpọ fun ète títẹ́ ẹran-ara aipe wa lọ́rùn.

6, 7. (a) Awọn apẹẹrẹ Bibeli wo ni o tẹnumọ bi ìwọra ti lè jẹ́ alagbara tó? (b) Eeṣe ti awọn apẹẹrẹ wọnni fi nilati jẹ́ ikilọ fun wa?

6 Jehofa ti ṣe akọsilẹ awọn apẹẹrẹ lati mú wa wà lojufo si ewu ìwọra. Ranti ìwọra Akani. Ọlọrun sọ pe Jeriko ni a nilati parun, ṣugbọn wúrà, fadaka, bàbà, ati irin rẹ̀ wà fun ilé-ìṣúra Rẹ̀. Akani lè ti ní i lọ́kàn lati tẹle itọsọna yẹn ni ibẹrẹ, ṣugbọn ìwọra dẹkun mú un. Gbàrà ti ó dé Jeriko, ńṣe ni ó dabi ẹni pe ó wà ninu irin-ajo ọjà rírà kan nibi ti ó ti rí ìdúnàándúrà ti o yà á lẹnu gan-an, pẹlu ẹ̀wù mèremère ti o wulẹ ṣe rẹ́gí fun un. Ni ṣíṣa wúrà ati fadaka ti iye wọn tó ẹgbẹẹgbẹrun owó dọ́là, ó ti lè ronu pe, ‘Ẹ wo iru ìrìnnàkore ti eyi jẹ́! Àfi bi ẹni pe mo jí i.’ Nitootọ olè jíjà ni! Nipa ṣiṣojukokoro si ohun ti a nilati parun tabi fi lélẹ̀, ó ja Ọlọrun lólè, iyẹn sì ná Akani ni iwalaaye rẹ̀. (Joṣua 6:17-19; 7:20-26) Tun ṣagbeyẹwo, apẹẹrẹ Gehasi ati Judasi Iskariotu pẹlu.—2 Ọba 5:8-27; Johannu 6:64; 12:2-6.

7 A kò nilati gbójúfo otitọ naa dá pe awọn mẹta ti a mẹnukan loke yii kìí ṣe abọriṣa ti wọn kò mọ awọn ọpa-idiwọn Jehofa. Kaka bẹẹ, wọn wà ninu ipo-ibatan oniyasimimọ si Ọlọrun. Gbogbo wọn ti rí awọn iṣẹ-iyanu tí ìbá ti tẹ agbara Ọlọrun ati ijẹpataki bíbá a lọ lati ní ojurere rẹ̀ mọ́ wọn lọ́kàn. Sibẹ, ìdẹkùn ìwọra ni iṣubu wọn. Awa pẹlu lè pa ipo-ibatan wa run pẹlu Ọlọrun bi a bá jẹ ki ìwọra ní iru eyikeyii dẹkùn mú wa. Ẹ̀yà tabi iru ìwọra wo ni ó lè léwu fun wa ni pataki?

A Dẹkùn Mú Wọn Nipasẹ Ìwọra fun Ọrọ̀ Tabi Awọn Ohun-ìní

8. Bibeli funni ni ikilọ wo nipa ọrọ̀?

8 Ọpọ julọ awọn Kristian ti gbọ́ awọn ikilọ kedere lati inu Bibeli lodisi mimu ifẹ fun ọrọ̀, òòfà-ọkàn fun owó dagba. Eeṣe ti o kò fi ṣatunyẹwo diẹ ninu iwọnyi, gẹgẹ bi a ti rí i ni Matteu 6:24-33; Luku 12:13-21; ati 1 Timoteu 6:9, 10? Nigba ti o lè nimọlara pe o fohunṣọkan ti o sì tẹle iru imọran bẹẹ, kò ha ṣeeṣe pe Akani, Gehasi, ati Judasi yoo ti sọ pe awọn fohunṣọkan pẹlu rẹ̀ pẹlu bi? Ni kedere, a gbọdọ lọ rekọja ifohunṣọkan ti ọgbọ́n-òye. A nilati kiyesara pe ìdẹkùn ìwọra fun ọrọ̀ tabi awọn ohun-ìní kò nipa lori igbesi-aye wa ojoojumọ.

9. Eeṣe ti a fi nilati ṣayẹwo iṣarasihuwa wa siha lílọ rajà?

9 Ninu igbesi-aye ojoojumọ, a sábà nilati rajà—ounjẹ, aṣọ, ati awọn ohun-eelo fun ile. (Genesisi 42:1-3; 2 Ọba 12:11, 12; Owe 31:14, 16; Luku 9:13; 17:28; 22:36) Ṣugbọn ayé iṣowo ń ru ìfẹ́-ọkàn soke fun pupọ sii ati fun awọn ohun titun. Ọpọlọpọ ipolowo-ọja ti o kún inu awọn iwe-agberohinjade, iwe-irohin, ati gọgọwú tẹlifiṣọn jẹ́ isapa ọlọ́gbọ́n-ẹ̀tàn lati ru ìwọra soke. Iru awọn ifanimọra bẹẹ tún lè wà ni awọn ile-itaja ti o kun fun ẹ̀wù àwọ̀lékè obinrin, kóòtù, awọn aṣọ, ati súẹ́tà ti a kó sori ìkọ́, pẹlu apoti awọn bàtà titun, ohun-eelo oníná, ati kamẹra. Awọn Kristian lè fẹ́ lati beere lọwọ araawọn pe, ‘Lílọ rajà ha ti di ohun pataki kan tabi olori igbadun ninu igbesi-aye mi bi?’ ‘Nitootọ ni mo ha nilo awọn ohun-eelo titun ti mo rí, tabi ńṣe ni ayé iṣowo wulẹ ń bu ajílẹ̀ si irugbin ìwọra ninu mi bi?’—1 Johannu 2:16.

10. Ìdẹkùn ìwọra wo ni o jẹ ewu fun awọn ọkunrin ni pataki?

10 Bi lílọ rajà bá dabi ìdẹkùn kan ti o wọ́pọ̀ fun awọn obinrin, níní owó pupọ sii jẹ́ ọ̀kan fun ailonka awọn ọkunrin. Jesu ṣakawe ìdẹkùn yii pẹlu ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan ti owó gegere ń wọle fun sibẹ ti ó pinnu lati ‘wó àká rẹ̀ palẹ̀ ki ó sì kọ́ eyi ti o tubọ tobi lati kó gbogbo ọkà ati awọn ohun rere rẹ jọ sí.’ Jesu kò fi iyemeji kankan silẹ niti ewu naa: “Kiyesara ki ẹ sì maa ṣọra nitori ojukokoro” tabi ìwọra. (Luku 12:15-21) Yala a jẹ́ ọlọ́rọ̀ tabi bẹẹkọ, a nilati kọbiara si imọran yẹn.

11. Bawo ni a ṣe lè dẹkùn mú Kristian kan nipasẹ ìwọra fun owó pupọ sii?

11 Ìwọra fun owó pupọ sii, tabi awọn ohun ti owó lè rà, ni a sábà maa ń mú dagba labẹ awúrúju. Ihumọ lati di ọlọ́rọ̀ kiakia ni a lè gbekalẹ—boya anfaani ẹẹkan-laaarin-gbogbo igbesi-aye fun aabo iṣunna-owo nipasẹ okòwò ti o léwu. Tabi a lè dán ẹnikan wò lati wá owó nipasẹ awọn àṣà ti o ṣeé gbébèéèrè dide sí tabi iṣẹ́-ajé ti kò bá ofin mu. Ìfẹ́-ọkàn olojukokoro yii lè jẹ alagbara juni lọ, adẹkùn múni. (Orin Dafidi 62:10; Owe 11:1; 20:10) Awọn kan laaarin ijọ Kristian ti bẹrẹ awọn iṣẹ́-ajé pẹlu ireti naa pe awọn arakunrin wọn ti o gbẹkẹle wọn ni yoo jẹ́ oníbàárà. Bi gongo-ilepa wọn kìí bá wulẹ ṣe lati pese ohun amujade tabi iṣẹ-ipese ti a nilo nipasẹ ‘iṣẹ́ àṣekára, ní fifi ọwọ́ araawọn tikaraawọn ṣiṣẹ ohun ti o dara,’ ṣugbọn lati gba owó ní kiakia si ìyànjẹ awọn Kristian ẹlẹgbẹ wọn, nigba naa wọn ń huwa lati inu ìwọra. (Efesu 4:28; Owe 20:21; 31:17-19, 24; 2 Tessalonika 3:8-12) Ìwọra fun owó ti ṣamọna awọn kan sinu tẹ́tẹ́ títa nipasẹ títa nọmba, iyàn kíkọ́, tabi lọ́tìrì. Awọn miiran, ní fifoju tín-ín-rín igbatẹniro ati ilọgbọn-ninu, ti fi kanjukanju bẹrẹ ẹjọ́ pẹlu ireti fun ẹbun tabi owó-ìtanràn ńlá.

12. Eeṣe ti a fi mọ̀ pe a lè bori ìwọra fun ọrọ̀?

12 Awọn ti o ṣaaju yii jẹ́ awọn agbegbe ninu eyi ti iṣayẹwo ara-ẹni ti bojumu ki a baa lè rí i lọna ailabosi yala ìwọra lè maa ṣiṣẹ ninu wa. Àní bi o bá ń ṣiṣẹ, a lè yipada. Ranti pe Sakeu yipada. (Luku 19:1-10) Bi ẹnikẹni bá rí ìwọra fun owó tabi awọn ohun-ìní gẹgẹ bi iṣoro kan, ó nilati jẹ́ onipinnu gẹgẹ bi Sakeu ti jẹ́ lati jàbọ́ lọwọ ìdẹkùn naa.—Jeremiah 17:9.

Ìwọra Ninu Awọn Apá Ìhà Igbesi-Aye Miiran

13. Orin Dafidi 10:18 pe ìdẹkùn ìwọra miiran wo si afiyesi wa?

13 Awọn kan rí i pe ó rọrùn jù lati rí ewu ìwọra nipa owó tabi awọn ohun-ìní ju awọn ọ̀nà miiran ti ó gbà farahan lọ. Iwe atumọ-ede Griki kan sọ pe awujọ awọn ọ̀rọ̀ ti a tumọ si “ìwọra” tabi “ojukokoro” ní ero-itumọ “‘fífẹ́ sii,’ niti ọ̀ràn agbara ati bẹẹ bẹẹ lọ ati ohun-ìní bakan naa.” Bẹẹni, a lè dẹkùn mú wa nipa fifi ìwọra fẹ́ lati lo agbara lori awọn ẹlomiran, boya lati jẹ ki wọn maa gbọ̀n labẹ ọla-aṣẹ wa.—Orin Dafidi 10:18.

14. Ni awọn agbegbe wo ni ifẹ fun agbara ti jẹ eléwu?

14 Lati awọn ìgbà ijimiji ni awọn eniyan alaipe ti gbadun níní agbara lori awọn miiran. Ọlọrun rí eyi ṣaaju pe iyọrisi ẹṣẹ eniyan yoo jẹ pe ọpọlọpọ ọkọ yoo “jẹ gàba lori” awọn aya wọn. (Genesisi 3:16) Bi o ti wu ki o ri, ikuna yii, ti gbooro kọja sakaani igbeyawo. Ẹgbẹẹgbẹrun ọdun lẹhin naa, òǹkọ̀wé Bibeli kan ṣakiyesi pe “ẹnikan ń ṣe olórí ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.” (Oniwasu 8:9) O ṣeeṣe ki o mọ bi eyi ti jẹ́ otitọ tó ninu awọn ọ̀ràn iṣelu ati ti ológun, ṣugbọn ó ha lè jẹ́ pe ni sakaani ayika tiwa, a ń lakaka fun agbara àdáni tabi idari pupọ sii bi?

15, 16. Ni awọn ọ̀nà wo ni Kristian kan lè gbà di ẹni ti a dẹkùn mú nipasẹ ìfẹ́-ọkàn fun agbara pupọ sii? (Filippi 2:3)

15 Gbogbo wa ni a ni isopọ pẹlu awọn eniyan miiran—ninu idile tiwa gan-an tabi ti amẹ́bímúbàátan, ni ibi iṣẹ ounjẹ oojọ wa tabi ni ile-ẹkọ, laaarin awọn ọ̀rẹ́, ati ninu ijọ. Lóòrèkóòrè, tabi niye ìgbà, a lè lóhùn si ohun ti a o ṣe, ati bi a o ti ṣe é tabi ìgbà ti a o ṣe é. Iyẹn funraarẹ kò ṣaitọ tabi buru. Bi o ti wu ki o ri, ǹjẹ́ awa, lọna àṣejù ha ń gbadun lilo ọla-aṣẹ eyikeyii ti a lè ní bi? Ó ha lè jẹ́ pe a nifẹẹ si ṣiṣe ipinnu ikẹhin ti a sì tubọ ń fẹ́ sii bi? Awọn mọ́níjà tabi ọ̀gá ninu ayé sábà maa ń fi iṣarasihuwa yii hàn nipa fifi awọn ti ń ṣe yẹsà-yẹsà yi araawọn ká, awọn ti kìí fi oju-iwoye ti o lodi hàn ti wọn kìí sìí gbe ipenija dide si ilepa (ìwọra) ti ayé ti o jẹ́ ti awọn aṣaaju wọn.

16 Ìdẹkùn kan tí a nilati yẹra fun ninu bíbá awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa lò ni eyi jẹ́. Jesu sọ pe: “Ẹyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a maa lo agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a maa fi ọlá tẹrí wọn ba. Ṣugbọn kì yoo rí bẹẹ laaarin yin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o bá fẹ́ pọ̀ ninu yin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ yin.” (Matteu 20:25, 26) Iru ẹmi irẹlẹ bẹẹ nilati hàn kedere bi awọn Kristian alagba ti ń bá araawọn ẹnikinni keji, awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ, ati agbo lò. Ifẹ fun agbara ni a ha lè fihàn, fun apẹẹrẹ, nipasẹ alaboojuto oluṣalaga ti ń gbìmọ̀ pẹlu awọn alagba ẹlẹgbẹ rẹ̀ kìkì lori awọn ọ̀ràn keekeeke ṣugbọn ti ń ṣe gbogbo awọn ipinnu pataki funraarẹ bi? Oun ha muratan nitootọ lati yan iṣẹ funni bi? Awọn iṣoro lè jẹyọ bi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan tí ń dari ipade kan fun iṣẹ-isin pápá bá ń fi ailọgbọn-ninu beere ohun pupọ jù ninu awọn iṣeto rẹ̀, ti o sì tilẹ ń ṣe awọn ofin paapaa.—1 Korinti 4:21; 9:18; 2 Korinti 10:8; 13:10; 1 Tessalonika 2:6, 7.

17. Eeṣe ti o fi bojumu lati gbé ọ̀ràn ounjẹ yẹwo nigba ti a bá ń jiroro ìdẹkùn ìwọra?

17 Ounjẹ ni agbegbe miiran ninu eyi ti a ń dẹkùn mú ọpọlọpọ nipasẹ ìwọra. Nitootọ, ó bá ìwà-ẹ̀dá mu lati rí igbadun ninu jíjẹ ati mímu; Bibeli sọrọ nipa iyẹn lọna itẹwọgba. (Oniwasu 5:18) Sibẹ, kò ṣàìwọ́pọ̀ fun ìfẹ́-ọkàn ti o jẹ mọ́ ounjẹ lati dagba laaarin sáà akoko kan, ni gbigbooro rekọja ohun ti o gbadun mọni lọna ti o lọ́gbọ́n-nínú ti o sì pọ̀ tó. Bi eyi kìí bá ṣe agbegbe ti o bojumu fun idaniyan-ọkan lọdọ awọn iranṣẹ Ọlọrun, eeṣe ti Ọ̀rọ̀ Jehofa yoo fi sọ ni Owe 23:20 pe: “Maṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn tí ń ba ẹran-ara awọn tikaraawọn jẹ”? Sibẹ, bawo ni a ti ṣeéyẹra fun ìdẹkùn yii?

18. Ayẹwo ara-ẹni wo nipa ounjẹ ati ohun mímu ni a lè ṣe?

18 Ọlọrun kò damọran pe ki awọn eniyan oun maa jẹ iru awọn ounjẹ alaiwulo kan. (Oniwasu 2:24, 25) Ṣugbọn bẹẹ ni oun kò fọwọsi pe ki a sọ ohun jíjẹ ati mímu di apa ajọbabori ninu ijumọsọrọpọ ati iwewee wa. A lè beere lọwọ araawa pe, ‘Mo ha sábà maa ń di onitara-ọkan àníjù nigba ti mo bá ń ṣapejuwe ounjẹ kan ti mo ti jẹ tabi ti mo ń wewee lati jẹ bi?’ ‘Mo ha maa ń sọrọ nipa ounjẹ ati ohun mímu ninu ijumọsọrọpọ mi bi?’ Ohun miiran ti ó lè fihàn lè jẹ́ bi a ti ń huwapada nigba ti a bá ń jẹ ounjẹ ti a kò wá tabi sanwo fun, boya nigba ti a bá jẹ́ alejo kan ninu ile ẹlomiran tabi nigba ti ounjẹ bá wà larọọwọto ni apejọ Kristian kan. Ó ha lè jẹ́ pe awa nigba naa ní itẹsi lati jẹ rekọja bi a ti sábà maa ń ṣe bi? A ranti pe Esau yọọda ki ounjẹ di pataki laiyẹ, si ipalara ainipẹkun rẹ̀.—Heberu 12:16.

19. Bawo ni ìwọra ṣe lè jẹ́ iṣoro nigba ti ọ̀ràn bá kan igbadun ibalopọ takọtabo?

19 Paulu fun wa ni ìjìnlẹ̀-òye sinu ìdẹkùn miiran pe: “Àgbèrè, ati gbogbo ìwà-èérí, tabi [ìwà-ìwọra, NW], ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ laaarin yin mọ́, bi o ti yẹ awọn eniyan mimọ.” (Efesu 4:17-19; 5:3) Nitootọ, ìwọra fun igbadun ibalopọ takọtabo lè gbèrú. Igbadun yii, niti tootọ, ní a ń fihàn lọna ti o ṣetẹwọgba laaarin ìdè igbeyawo. Ifẹni timọtimọ ti o sopọ pẹlu igbadun yii ń kó ipa kan ninu ríran ọkọ ati aya lọwọ lati dìjọ wà pọ gẹgẹ bi oluṣotitọ si araawọn ẹnikinni keji fun ọpọlọpọ ọdun igbeyawo. Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan diẹ yoo sẹ́, pe ayé ode-oni ti fi itẹnumọ ti o rekọja ààlà sori ibalopọ takọtabo, ni gbígbé ohun ti o jẹ́ òjìji ìwà-ìwọra tí Paulu mẹnukan niti gasikiya kalẹ bi ohun ti ó wà deedee. Ni pataki iru oju-iwoye òdì bẹẹ nipa igbadun ibalopọ takọtabo ni awọn wọnni ti wọn ṣí araawọn kalẹ si iwapalapala ati wíwà níhòhò goloto ti o wọ́pọ̀ lonii ninu awọn sinima, fidio, ati awọn iwe-irohin, ati ni awọn ibi eré-ìnàju bakan naa maa ń fìrọ̀rùn tẹwọgba.

20. Bawo ni awọn Kristian ṣe lè fi araawọn hàn ni ẹni ti o wà lojufo si ewu ìwà-ìwọra ninu awọn ọ̀ràn ibalopọ takọtabo?

20 Akọsilẹ nipa ẹṣẹ Dafidi pẹlu Batṣeba fihàn pe ọ̀kan lara awọn iranṣẹ Ọlọrun ni a lè kẹ́dẹ mú nipasẹ ìdẹkùn ìwọra ibalopọ takọtabo. Bi o tilẹ jẹ pe ó lominira lati jẹ ìgbádùn laaarin igbeyawo tirẹ̀ funraarẹ, Dafidi jẹ́ ki ifẹ fun ibalopọ takọtabo tí kò bofinmu dagba. Ni kikiyesi bí aya Uriah ti fanimọra tó, o fi ainijaanu fun èrò—ati iṣe—ti wíwá igbadun ti kò bofinmu pẹlu rẹ̀. (2 Samueli 11:2-4; Jakọbu 1:14, 15) Dajudaju awa gbọdọ sára fun iru ìwọra yii. Àní laaarin igbeyawo paapaa ó yẹ lati sára fun ìwọra. Eyi yoo ní ninu ṣíṣá awọn iṣe ibalopọ takọtabo àṣerégèé tì. Ọkọ kan ti o pinnu lati yẹra fun ìwọra ni agbegbe yii yoo ní ojulowo ọkàn-ìfẹ́ ninu ẹnikeji rẹ̀ ninu igbeyawo, ki o baa lè jẹ́ pe yíyàn eyikeyii ti awọn mejeeji bá ṣe nipa ìfètòsọ́mọbíbí kò ní gbé igbadun rẹ̀ ga gẹgẹ bi ohun ti o ṣe pataki ju ilera isinsinyi ati ti ọjọ-iwaju aya rẹ̀ lọ.—Filippi 2:4.

Maa Baa Lọ Lati Jẹ Onipinnu Lati Yẹra fun Ìwọra

21. Eeṣe ti ijiroro wa nipa ìwà-ìwọra kò fi nilati kó irẹwẹsi bá wa?

21 Jehofa kò pese awọn akiyesi tabi ikilọ nitori ainigbẹkẹle eyikeyii. Ó mọ̀ pe awọn iranṣẹ oun onifọkansin ń fẹ́ lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin oun, ó sì ní igbọkanle pe ọpọ julọ yoo maa baa lọ lati ṣe iyẹn. Nipa awọn eniyan rẹ̀ lodindi, oun lè sọ ọ̀rọ̀ kan ti o jọra pẹlu oun ti o sọ nipa Jobu nigba ti ó ń bá Satani sọrọ pe: “Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò sí ekeji rẹ̀ ni ayé, ọkunrin tíí ṣe oloootọ, ti o sì duro ṣinṣin, ẹni ti o bẹru Ọlọrun, ti o sì koriira iwa buburu”? (Jobu 1:8) Baba wa ọ̀run onifẹẹ, ti o ṣeé gbẹkẹle mú wa wà lojufo si awọn ewu ìdẹkùn, bi iru awọn wọnni ti o sopọ mọ́ oriṣiriṣi ìwọra, nitori pe ó ń fẹ́ ki a maa baa lọ láìlábàwọ́n ati ni olotiitọ sí oun.

22. Ki ni a nilati ṣe bi ikẹkọọ wa bá ṣipaya agbegbe ewu ara-ẹni tabi ailera kan?

22 Ẹnikọọkan wa ti jogun itẹsi siha ìwà-ìwọra, a sì ti lè mú eyi dagba siwaju sii labẹ agbara-idari ayé buburu yii. Ki ni bi o bá jẹ pe laaarin ikẹkọọ wa nipa ìwà-ìwọra—niti ọrọ̀, awọn ohun-ìní, agbara ati ọla-aṣẹ, ounjẹ, tabi igbadun ibalopọ takọtabo—o rí awọn agbegbe ailera kan? Nigba naa fi amọran Jesu sọkan pe: “Bi ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ, ké e kuro: ó sàn fun ọ ki o ṣe akéwọ́ lọ si ibi ìyè, ju ki o ni ọwọ́ mejeeji ki o lọ si [Gehenna, NW].” (Marku 9:43) Ṣe awọn iyipada eyikeyii ti o pọndandan ninu iṣarasihuwa tabi ọkàn-ìfẹ́. Yẹra fun ìdẹkùn ti o lè ṣekupani ti ìwọra. Nipa bayii pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, iwọ lè “wọ inu ìyè.”

Ki Ni Mo Ti Kẹkọọ?

◻ Eeṣe ti a fi nilati ni aniyan-ọkan nipa ìdẹkùn ìwọra?

◻ Ni awọn ọ̀nà wo ni ìwọra fun ọrọ̀ tabi awọn ohun-ìní lè gbà dẹkùn mú wa?

◻ Bawo ni ìwọra ni awọn agbegbe miiran ninu igbesi-aye ṣe lè gbé ewu gidi kalẹ?

◻ Ki ni o nilati jẹ́ iṣarasihuwa wa siha ailera eyikeyii ti a ní nipa ìwọra?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́