ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Ọlọ́kàn-Fífúyẹ́—Kí Ara Rẹ sì Túbọ̀ Le! 
  • Àwọn Ẹyẹ Wà Nínú Ewu Lọ́wọ́ Àwọn Olùfẹ́ Ẹyẹ Bí?
  • Ibùgbé Àdánidá Títura fún Àwọn Yọ̀rọ̀
  • Bí A Ṣe Lè Kojú Àwọn Abúmọ́ni Nílé Ẹ̀kọ́
  • Ohun Tí Àwọn Ọmọdé Fẹ́ àti Ohun Tí Wọn Kò Fẹ́
  • Kádínà Dámọ̀ràn Ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí
  • Sísọ Òkun Di Mímọ́ Tónítóní
  • Àwọn Ọkọ̀ Abẹ́ Omi Onírunlára
  • Àwọn Ọmọdé Tí Ń Bá Àwọn Ọmọdé Ṣèṣekúṣe
  • Ọtí Líle Nígbà Tí Oyún Wà Nínú
  • Fífòòró Ẹni—Díẹ̀ Lára Ohun Tó Ń Fà Á Àtàwọn Ohun Tó Ń Yọrí Sí
    Jí!—2003
  • Fífòòró Ẹni—Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2003
  • Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀?
    Jí!—1997
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Jẹ́ Ọlọ́kàn-Fífúyẹ́—Kí Ara Rẹ sì Túbọ̀ Le! 

Ọ̀jọ̀gbọ́n Sueli Damergian láti Yunifásítì São Paulo sọ pé: “Nípasẹ̀ ìdẹ́rìn-ínpani, àwọn ènìyàn túbọ̀ ń rára gba nǹkan sí, wọ́n ń kápá ìjákulẹ̀ lọ́nà tí ó dára, wọ́n sì ń ní ìlera ti ara ìyára àti ti èrò orí.” Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde O Estado de S. Paulo, ti ilẹ̀ Brazil, ṣe wí, a lè kọ́ bí a ṣeé dẹ́rìn-ín pani—lọ́nà kan náà tí a fi ń kọ́ bí a ṣeé kàwé àti bi a ṣeé kọ̀wé. Ó ṣe kedere pé èyí ń béèrè pé kí abínúfùfù kan yí ìrònú rẹ̀ pa dà. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìrònú òun ìhùwà, Raquel Rodrigues Kerbauy, sọ pé: “Bí ẹnì kan bá rò pé, àfi ìgbà tí ayé bá rójú ni òun yóò tóó láyọ̀, yóò jẹ́ oníkanra títí láé. Ó ṣe tán kò sí ibi tí ayé ti rójú.” Ìròyìn náà sọ pé, kódà pẹ̀lú ìṣètò tí ó há gádígádí, àwọn atúraká ènìyàn ń gbádùn àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wọn. Wọ́n mọyì àwọn nǹkan kéékèèké bí “àwàdà kan, dáyá kan, tàbí gbígbọ́ orin rere kan fún ìwọ̀n àkókò díẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, Damergian kìlọ̀ pé: “Kò yẹ kí a ṣi ìdẹ́rìn-ínpani yíyẹ mú fún ìwà òmùgọ̀ àti àìní ìwà rere.”

Àwọn Ẹyẹ Wà Nínú Ewu Lọ́wọ́ Àwọn Olùfẹ́ Ẹyẹ Bí?

Ìwé agbéròyìnjáde Sunday Times ti London sọ pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn olùfẹ́ ẹyẹ máa ṣe ibi púpọ̀ ju ire lọ nípa fífi oúnjẹ sínú àwọn ọgbà wọn fún àwọn ẹyẹ láti jẹ. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ẹyẹ tí ń jẹun lọ́gbà nílẹ̀ Britain ni májèlé oúnjẹ tí bakitéríà salmonella, àwọn kòkòrò àfòmọ́, àti oríṣi ẹ̀dá tí kò ṣeé fojú lásán rí kan tí a kò dá mọ̀ fà, ti pa ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. James Kirkwood, ọ̀gá àgbà olùtọ́jú ẹranko ní Ọgbà Ẹranko ti London, dàníyàn pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn irú ọ̀wọ́ kan kú àkúrun ní àwọn àgbègbè kan. Àwọn bakitéríà àti kòkòrò àfòmọ́ náà, tí ń yára kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn àjálù, lè gbé ọ̀pọ̀ ọjọ́ lórí ìyàgbẹ́ ẹyẹ tí ó bá wà lára ohun tí a fi ń gbé oúnjẹ ẹyẹ sí tàbí lórí ilẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Chris Perrins, láti Yunifásítì Oxford, kìlọ̀ pé, àwọn kóró èso tí ó ní èèhù léwu ní pàtàkì. Ó sọ pé: “Ìjọba fòfin de títa àwọn kóró èso tí ó ní èèhù fún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n wọ́n fàyè gbà wọ́n nínú oúnjẹ àwọn ẹyẹ,” ó fi kún un pé: “Wọ́n ń pa ọ̀pọ̀ ẹyẹ.”

Ibùgbé Àdánidá Títura fún Àwọn Yọ̀rọ̀

Ojú ọjọ́ ìgbà òtútù adánilágara máa ń pa àwọn yọ̀rọ̀ nígbà kan rí. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ilẹ̀ Britain ṣe sọ, nǹkan ti yí pa dà. John Maunder, láti Ibùdó Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Kòkòrò ní Cambridge, sọ pé: “Láàárín ẹ̀wádún tí ó kọjá, àwọn yọ̀rọ̀ ológbò pọ̀ sí i gan-an ni.” Àwọn ilé ìgbàlódé jẹ́ ibùgbé títura fún àwọn yọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n tún ń gbé ara àwọn ajá. Látijọ́ rí, ojú ọjọ́ tútù máa ń mú kí ooru inú ilé lọ sílẹ̀—ohun kan tí ń fa ikú àwọn kògbókògbó yọ̀rọ̀. Maunder ṣàkíyèsí pé: “Ní báyìí, ìfẹ́lọfẹ́bọ̀ afẹ́fẹ́ nínú ọ̀pọ̀ ilé burú débi pé ó ń mú kí ooru inú ilé pọ̀ síbẹ̀, tí ó sì jẹ́ pé ojú ọjọ́ títutù fún ìgbà pípẹ́ pàápàá kò lè pa àwọn yọ̀rọ̀ náà.”

Bí A Ṣe Lè Kojú Àwọn Abúmọ́ni Nílé Ẹ̀kọ́

Nítorí ìpolongo lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa ìbúmọ́ni ní àwọn ilé ẹ̀kọ́, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Japan ṣe ìwádìí kan láàárín 9,420 àwọn ọmọdé àti àwọn òbí àti olùkọ́ wọn. Àwárí náà fi hàn pé, ó tó ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a ń bú mọ́, láti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé ẹ̀kọ́ girama kékeré, tí kò mọ̀ nípa ìṣòro náà, tàbí tí kò fọwọ́ dan-indan-in mú àròyé àwọn ọmọ wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tí a ń bú mọ́ náà kò sọ fún olùkọ́ kankan nítorí ìbẹ̀rù pé a lè gbẹ̀san lára àwọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwádìí náà fi hàn pé, nígbà tí olùkọ́ kan bá fọwọ́ líle mú ọ̀ràn náà, kìkì ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òjìyà náà ni a ń gbẹ̀san lára wọn, tí ìbúmọ́ni náà sì ń dáwọ́ dúró ní ti nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yoji Morita, láti Yunifásítì Ìlú Ńlá Osaka, sọ pé: “Ó dá mi lójú ju ti ìgbàkigbà rí lọ pé a lè tọwọ́ ìbúmọ́ni bọlẹ̀ bí àwọn òjìyà bá fẹjọ́ sun àwọn olùkọ́ wọn, tí àwọn olùkọ́ sì ń ṣe ohun tí ó yẹ sí i.”

Ohun Tí Àwọn Ọmọdé Fẹ́ àti Ohun Tí Wọn Kò Fẹ́

Kí ni àwọn ọmọdé ń ṣe, tí ń fún wọn ní ìgbádùn kíkéré jù lọ? Nínú ìwádìí kan nípa àwọn ọmọ ọlọ́dún 6 sí 11 tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Gustavo Pietropolli Charmet, láti Yunifásítì Milan, Ítálì, ṣe, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé sọ pé: “Jíjókòó máa wo tẹlifíṣọ̀n nílé,” tàbí “Gbígbélé máa bá Mọ́mì ṣe iṣẹ́ ilé.” Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica, sọ pé, ohun tí wọ́n ń ṣe, tí kò gbádùn mọ́ wọn jù lọ ni, “níní àdéhùn láti pàdé ẹnì kan,” ìyẹn ni lílọ láti ibi ẹ̀kọ́ kan dé òmíràn bí ijó jíjó, èdè Gẹ̀ẹ́sì, títẹ dùùrù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tí wọ́n tún kórìíra ní gbogbogbòò ni “dídáwà.” Ní ìdà kejì, ìpín 49 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin ń fẹ́ kí àwọn òbí “máa jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn máa lọ ṣeré níta,” nígbà tí àwọn ọmọbìnrin ń fẹ́ kí àwọn òbí “ní ìmóríyá nípa bíbá àwọn ọmọ wọn ṣeré.” Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé: ‘Nígbà tí Mọ́mì bá ń bá mi ṣeré, ó ní láti ṣeré ní ti gidi. O lè mọ̀ bí kò bá ní ìmóríyá, èmi náà kò sì níí ní ìmóríyá bákan náà.’

Kádínà Dámọ̀ràn Ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí

Kádínà Suenens, ti Belgium, agbátẹrù àwọn àjọ ìlépa ìṣọ̀kan àti agbára mẹ́mìímẹ́mìí ti Kátólíìkì, kú láìpẹ́ yìí ni ẹni ọdún 91. Ìwé agbéròyìnjáde ti Belgium náà, Het Belang van Limburg, ṣàlàyé pé, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé Suenens ṣàṣeparí ọ̀pọ̀ nǹkan, àlá rẹ̀ nínú ìgbésí ayé kò ṣẹ. Àtẹ̀lé rẹ̀, Kádínà Danneels, sọ pé, Suenens “ti sábà ń fẹ́ kí àwọn Kristẹni túbọ̀ gbé kánkán. Ó . . . bi ara rẹ̀ bóyá a gbọ́dọ̀ máa lọ láti ilé dé ilé, bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe. Ó sì rí i níkẹyìn pé, ọ̀nà ìṣeǹkan yẹn kò burú. Gbólóhùn kan tí a sábà máa ń gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ ni pé: ‘Ìwọ jẹ́ Kristẹni tòótọ́, kìkì bí o bá ti sọ ẹlòmíràn kan di Kristẹni bákan náà.’”

Sísọ Òkun Di Mímọ́ Tónítóní

Kódà, lọ́jọ́ tójò kò rọ̀ pàápàá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ gálọ́ọ̀nù omi eléèérí àti pàǹtírí láti ojú òpópó ìlú ń ṣàn lọ sínú àwọn omi etíkun ní àyíká Los Angeles, California. Lọ́jọ́ tójò bá rọ̀, àwọn omi tí ń ṣàn lọ bẹ́ẹ̀ lè tó ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù gálọ́ọ̀nù! Ìjọba ìlú ńlá náà ṣonígbọ̀wọ́ ètò kan láti jẹ́ kí àwọn olùgbé mọ̀ pé gbogbo ohun tí wọ́n bá jù sílẹ̀ ní títì, èyí tí wọ́n fọ̀ sí títì, tàbí èyí tí wọ́n gbá sí títì ń lọ sínú òkun ní tààràtà nípasẹ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ń fa omi kúrò lórí ilẹ̀—láìsí àtúnṣe kankan tí a ṣe sí i! Èyí kan àwọn epo àti àwọn ohun olómi mìíràn láti ara ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn koríko tí a gé, pàǹtírí, àti àwọn ìyàgbẹ́ ohun ọ̀sìn. Láti yẹra fún bíba àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn jẹ́ nínú Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Santa Monica, a ń fún àwọn olùgbé ní ìṣírí pé: Má ṣe da pàǹtírí sí títì; gbá ilẹ̀ ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé dípò kí o fẹ́ pàǹtírí wọn dà nù; palẹ̀ ìyàgbẹ́ àwọn ohun ọ̀sìn mọ́; ṣàtúnṣe àwọn ibi tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bá ti ń jò; sì pààrọ̀ epo ọkọ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal ròyìn pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn tí ń lúwẹ̀ẹ́ nítòsí ibi tí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ń fa omi kúrò lórí ilẹ̀ ti ń tú omi rẹ̀ dà sókun ní àfikún ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ibà, èébì, àrùn èémí, tàbí etí ríro, ju àwọn tí ń lúwẹ̀ẹ́ níbi tí ó jìn ní ó kéré tán, 360 mítà sí ibẹ̀ lọ.

Àwọn Ọkọ̀ Abẹ́ Omi Onírunlára

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ṣe sọ, Ilé Iṣẹ́ Jagunjagun Ojú Omi Ilẹ̀ Sweden ní ìgbékalẹ̀ alásokọ́ra ẹ̀rọ gbohùngbohùn abẹ́ omi láti ṣàwárí ìró ìsọpùtù inú omi tí àwọn àjẹ̀ ayíbírí inú àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi ń fà. Ní ṣíṣe àyẹ̀wò 6,000 ìròyìn “ìgbòkègbodò ṣíṣàjèjì lábẹ́ omi,” tí a gbé karí ìgbékalẹ̀ gbohùngbohùn náà àti ìfojúrí àwọn ará ìlú, ìgbìmọ̀ kan tí ìjọba gbé kalẹ̀ rí ẹ̀rí ìgbòkègbodò ọkọ̀ abẹ́ omi tí ó fìdí múlẹ̀ nínú ọ̀ràn mẹ́fà péré. Ìròyìn náà sọ pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìdágìrì náà ti lè wáyé nítorí “ìjusẹ̀ kéékèèké pẹ̀lú ìbínú.” Ó jọ pé àwọn ẹranmi mink àti ẹranmi otter ń mú ìró tí ó jọra pẹ̀lú ti àwọn àjẹ̀ ayíbírí inú àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi jáde, nígbà tí wọ́n bá ń lúwẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ da àwọn olùgbọ́ròó abẹ́ omi náà lọ́kàn rú.

Àwọn Ọmọdé Tí Ń Bá Àwọn Ọmọdé Ṣèṣekúṣe

Ìwé agbéròyìnjáde Saturday Star ti Johannesburg ròyìn pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èwe ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà ni àwọn ọmọdé mìíràn ń bá ṣèṣekúṣe. Evanthe Schurink, ti Ìgbìmọ̀ Ìwádìí Sáyẹ́ǹsì Nípa Ẹ̀dá Ènìyàn, so ìṣekúṣe yìí pọ̀ mọ́ kókó náà pé, àwọn ọ̀dọ́ tí ń ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn tí a ń rorò mọ́ fúnra wọn. Marilyn Donaldson, olùgbani-nímọ̀ràn àwọn ọmọdé kan ní Ibùdó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìtọ́jú Ìrírí Agbonijìgì ti Ìwà Ipá àti Ìlàjà, fara mọ́ ọn ní wíwí pé: “Nínú ọ̀pọ̀ . . . ilé, a ń ṣí àwọn ọmọ wọ̀nyí payá sí ìwà ipá abẹ́lé bíbanilẹ́rù, àwọn tí ó sì sábà máa ń jìyà lọ́wọ́ wọn máa ń jẹ́ àwọn ìbátan wọn.” Ó tún di ẹ̀bi ọ̀pọ̀ ìbáṣèṣekúṣe náà ru ìkáàárẹ̀ àti àìsí ìtọ́jú òbí. Ó ṣàkíyèsí pé: “Kì í sí ẹnikẹ́ni nílé pẹ̀lú àwọn ọmọ náà nígbà tí àwọn òbí bá lọ síbi iṣẹ́, nítorí náà, wọ́n wà lábẹ́ agbára àwọn tí ń bá wọn ṣèṣekúṣe.” Nígbà tí ó ń tọ́ka sí àfikún ewu mìíràn sí i, Donaldson sọ pé, òun rí i pé púpọ̀ sí i “àwọn ọmọ ọlọ́dún 6 sí 10 ń ní àrùn AIDS, tí wọ́n ti kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo.”

Ọtí Líle Nígbà Tí Oyún Wà Nínú

Ìwé agbéròyìnjáde The Medical Post, ti Kánádà, ròyìn pé: “Ìwádìí tuntun ti fìdí ìsopọ̀ tí ó wà láàárín kí ìyá máa mu ọtí líle nígbà tí ó lóyún sínú àti ìbísí ewu àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun ọmọ ọwọ́ múlẹ̀.” Ìwádìí aláfiwéra náà kan àwọn ọmọ 302 tí wọ́n ní àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun, tí wọ́n jẹ́ ọmọ oṣù 18 tàbí tí kò tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣàwárí àrùn náà lára wọn, àti àwùjọ àfiwéra àwọn ọmọ ọwọ́ 558 mìíràn. Ní ti àwọn ọmọ tí ìyá wọn ń mu ọtí líle láàárín ìgbà tí oyún ti pé oṣù mẹ́ta sí mẹ́sàn-án, ewu níní àrùn àpọ̀jù kògbókògbó sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun líle koko fi nǹkan bí ìlọ́po mẹ́wàá pọ̀ ju ti àwọn tí ìyá wọn kì í mu ọtí líle lọ. A gbọ́ pé ìwádìí tuntun náà dọ́gba pẹ̀lú àwọn ìwádìí mìíràn nípa àwọn aboyún tí ń mu ọtí líle àti bí ewu níní àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun ṣe ń pọ̀ sí i fún àwọn ọmọ wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́