ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/8 ojú ìwé 31
  • Ìwà Ipá Tí Àwọn Obìnrin Ń Jìyà Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Ipá Tí Àwọn Obìnrin Ń Jìyà Rẹ̀
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífìyà Jẹ Àwọn Obìnrin Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2008
  • Irú Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Ipá?
    Jí!—2002
  • Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ipá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Yíya Àwọn Obìnrin Sọ́tọ̀
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/8 ojú ìwé 31

Ìwà Ipá Tí Àwọn Obìnrin Ń Jìyà Rẹ̀

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

GẸ́GẸ́ bí ìwé Human Development Report 1995 tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde ṣe sọ, àwọn obìnrin ń jìyà ìwà ipá láti inú oyún títí dé ọjọ́ ikú. Àwọn ìwádìí kárí ayé fi ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí hàn:

Ṣáájú ìbí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a ń ṣe àyẹ̀wò láti mọ̀ bóyá ọmọ inú ọlẹ̀ kan jẹ́ akọ tàbí abo. Wọ́n sábà máa ń ṣẹ́ oyún àwọn abo.

Nígbà ọmọdé. Ní Barbados, Kánádà, Netherlands, New Zealand, Norway, àti United States, ìpín 1 nínú 3 àwọn obìnrin ròyìn pé wọ́n bá àwọn ṣèṣekúṣe nígbà ọmọdé tàbí nígbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà. Ní Éṣíà àti àwọn ibòmíràn, nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé—tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ ọmọbìnrin—ni wọ́n ń fipá sọ di aṣẹ́wó lọ́dọọdún. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọbìnrin kárí ayé ń jìyà abẹ́ dídá.

Nígbà àgbàlagbà. Ní Chile, Mexico, Papua New Guinea, àti Ilẹ̀ Olómìnira Korea, ìpín 2 nínú 3 gbogbo abilékọ ní ń jìyà ìwà ipá abẹ́lé. Ní Kánádà, New Zealand, United Kingdom, àti United States, wọ́n ti fipá bá ìpín 1 nínú 6 àwọn obìnrin lò.

Lọ́jọ́ alẹ́. Ó lé ní ìdajì lára àwọn obìnrin tí wọ́n ṣìkà pa ní Bangladesh, Brazil, Kenya, Papua New Guinea, àti Thailand, tí ó jẹ́ pé, àwọn ọkọ wọn látijọ́ tàbí lọ́wọ́lọ́wọ́ ló pa wọ́n. Ní Áfíríkà, Gúúsù America, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ erékùṣù òkun Pacific, àti United States, ìwà ipá tí ó jẹ mọ́ ìgbéyàwó ni ìdí títayọ fún ìpara-ẹni láàárín àwọn obìnrin.

Ìwà ipá tí àwọn obìnrin ń jìyà rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò jẹ́ “abúni,” “aláìní ìgbatẹnirò,” àti “òkú òǹrorò.” (Tímótì Kejì 3:1-5, New American Bible) Ó yẹ kí a dúpẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé lẹ́yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” onídààmú yìí, òun yóò gbé ayé tuntun alálàáfíà kan kalẹ̀ níbi tí àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé “yóò wà ní àlàáfíà, ẹnikẹ́ni kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:28; Pétérù Kejì 3:13) Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, Jésù Kristi yóò “gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò ra ọkàn wọn pa dà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti [ìwà ipá, NW].”—Orin Dáfídì 72:12, 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́