ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/8 ojú ìwé 3-6
  • Yíya Àwọn Obìnrin Sọ́tọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíya Àwọn Obìnrin Sọ́tọ̀
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpín Kékeré
  • Àwọn Ìyá àti Olùpèsè
  • Kí Ló Dé Tí Ìṣòro Yìí Fi Ń peléke Sí I?
    Jí!—2003
  • Mímọyì Àwọn Obìnrin àti Iṣẹ́ Wọn
    Jí!—1998
  • Ìṣòro Tí Àwọn Obìnrin Ń Bá Yí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àwọn Wo Lẹrú Lóde Òní?
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/8 ojú ìwé 3-6

Yíya Àwọn Obìnrin Sọ́tọ̀

NÍ Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ọkùnrin oníṣòwò kan ra ọmọ ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan. Ní Éṣíà, wọ́n sin ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí kan lóòyẹ̀ sínú iyanrìn aṣálẹ̀ náà. Ní orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn kan, ebi pa ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ kan kú nílé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí—a kò fẹ́ ẹ, a kò sì bójú tó o. Ohun kan dọ́gba nípa gbogbo ọ̀ràn ìbànújẹ́ wọ̀nyí: Gbogbo àwọn tí ọ̀ràn náà ṣẹlẹ̀ sí jẹ́ obìnrin. Jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ obìnrin túmọ̀ sí pé a kà wọ́n sí aláìjámọ́-ǹkan.

Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀ràn aláìlẹ́gbẹ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọbìnrin àti ọ̀ṣọ́ọ́rọ́bìnrin ni wọ́n ń tà lẹ́rú ní Áfíríkà, wọ́n ń ta àwọn kan ní iye owó tí kò ju dọ́là 15 lọ pàápàá. A sì gbọ́ pé lọ́dọọdún ni wọ́n ń ta ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọ̀dọ́bìnrin tàbí tí wọ́n ń fipá sọ wọ́n di aṣẹ́wó, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ní Éṣíà. Èyí tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ ni pé, iye ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ń fi hàn pé iye ọmọbìnrin tó pọ̀ tó 100 mílíọ̀nù “ń sọ nù.” Ní kedere, èyí jẹ́ nítorí ìṣẹ́yún, ìṣekúpọmọdé, tàbí wíwulẹ̀ pa àwọn obìnrin tì.

Láti ìgbà pípẹ́—láti ọ̀rọ̀ọ̀rúndún—ni a ti ń fojú báyìí wo àwọn obìnrin ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni a ṣì ń wò wọ́n ní àwọn ibì kan. Èé ṣe? Nítorí pé ní àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀, a ka àwọn ọmọkùnrin sí gan-an. Níbẹ̀, a rò pé ọmọkùnrin kan lè máa bá ìlà ìdílé nìṣó, kí ó jogún dúkìá, kí ó bójú tó àwọn òbí nígbà tí wọ́n bá darúgbó, nítorí pé lọ́pọ̀ ìgbà, kò sí àbójútó kankan láti ọ̀dọ̀ ìjọba fún àwọn arúgbó ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí. Òwe ilẹ̀ Éṣíà kan sọ pé, “títọ́ ọmọbìnrin kan dà bí bíbomirin-irúgbìn kan nínú ọgbà ọ̀gbìn aládùúgbò rẹ.” Nígbà tó bá dàgbà, yóò fi ọ́ sílẹ̀ gba ilé ọkọ lọ tàbí kí wọ́n tà á fún iṣẹ́ aṣẹ́wó, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣàìwúlò tó láti bójú tó àwọn òbí tó ti darúgbó tàbí kí ó tilẹ̀ máà wúlò rárá.

Ìpín Kékeré

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ipò òṣì ń bá fínra, ìwà yìí ń yọrí sí àìtó oúnjẹ, àìtó àbójútó ìṣègùn, àti àìkàwé púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin nínú ìdílé. Àwọn olùwádìí ní orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà kan rí i pé ìpín 14 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin ni kì í jẹun kánú ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 5 péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin. Ìròyìn kan tí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) ṣe fi hàn pé, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, iye ọmọkùnrin tí a ń mú lọ gbàtọ́jú nílé ìwòsàn jẹ́ ìlọ́po méjì ti ọmọbìnrin. Iye tí ó sì lé ní ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní Áfíríkà àti ní ìhà gúúsù òun ìhà ìwọ̀ oòrùn Éṣíà ni wọ́n jẹ́ púrúǹtù. Olóògbé Audrey Hepburn, ikọ̀ àjọ UNICEF nígbà kan rí, kédàárò pé: “Ìpààlà-ẹ̀yà bíbanilẹ́rù kan ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.”

“Ìpààlà-ẹ̀yà” yìí kì í kásẹ̀ nílẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà bá dàgbà. Lápapọ̀, ipò òṣì, ìwà ipá, àti làálàá àìlópin sábà máa ń jẹ́ ìpín obìnrin kan, ní pàtó, nítorí pé ó jẹ́ obìnrin. Ààrẹ Báńkì Àgbáyé wí pé: “Àwọn obìnrin ní ń ṣe ìdá méjì nínú mẹ́ta gbogbo iṣẹ́ tí a ń ṣe lágbàáyé. . . . Síbẹ̀, ìdá kan nínú mẹ́wàá gbogbo owó tí ń wọlé fúnni lágbàáyé ní ń wọlé fún wọn, wọn kò sì ní tó ìpín kan nínú ọgọ́rùn-ún nínú ohun ìní àgbáyé. Wọ́n wà lára àwọn tó tálákà jù lọ nínú àwọn tálákà àgbáyé.”

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe ṣe wí, lára àwọn bílíọ̀nù 1.3 ènìyàn tí ń gbé nínú ipò ìṣẹ́ paraku lágbàáyé, àwọn obìnrin lé ní ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìròyìn náà fi kún un pé: “Ńṣe ló sì ń burú sí i. Iye àwọn obìnrin tí ń gbé àrọko, tí ìṣẹ́ ń bá fínra pọ̀ sí i ní iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ẹ̀wádún méjì tó kọjá. Lọ́nà tí ń pọ̀ sí i, bí a bá ń sọ̀rọ̀ ìṣẹ́, ó jọ pé ọ̀rọ̀ obìnrin la ń sọ.”

Èyí tó túbọ̀ ń ṣèpalára ju ipò òṣì tí ń poni mọ́lẹ̀ náà lọ ni ìwà ipá tí ń ba ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ obìnrin jẹ́. Àwọn ọmọbìnrin tí a fojú bu iye wọn sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáta ọ̀kẹ́, tí ọ̀pọ̀ wọn wá láti Áfíríkà, ti fojú winá dídábẹ́. Ìfipábáni-lòpọ̀ jẹ́ ìṣekúṣe tó gbilẹ̀, tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní àkọsílẹ̀ ní àwọn àdúgbò kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwádìí fi hàn pé ní àwọn ilẹ̀ kan, obìnrin kan nínú mẹ́fà ni a ń fipá bá lò nígbà ìgbésí ayé wọn. Ogun ń pọ́n àtọkùnrin-àtobìnrin lójú lọ́gbọọgba, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí a ń fipá lé kúrò nílé wọn jẹ́ obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Àwọn Ìyá àti Olùpèsè

Ẹrù àbójútó ìdílé sábà máa ń wà léjìká ìyá jù. Ó ṣeé ṣe kí àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ ju ti àwọn tó kù lọ tàbí kí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun nìkan ló ń pèsè ohun tí ìdílé nílò. Ní àwọn àgbègbè àrọko kan ní Áfíríkà, àwọn ìdílé tí obìnrin ti jẹ́ olórí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì. Ní àwọn àdúgbò kan ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ìdílé tí àwọn obìnrin ti jẹ́ olórí pọ̀ jọjọ.

Síwájú sí i, ní pàtàkì, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn obìnrin ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó gbagbára jù mélòó kan gẹ́gẹ́ bí àṣà, bí omi pípọn àti igi ṣíṣẹ́. Ìpagbórun àti ìfẹranjẹkojù ti túbọ̀ mú kí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ṣòro sí i. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí ọ̀dá ti dá gan-an, àwọn obìnrin ń lo wákàtí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lójúmọ́ láti ṣẹ́ igi, wọ́n sì ń lo wákàtí mẹ́rin lóòjọ́ láti pọn omi. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe iṣẹ́ tí ń fàárẹ̀ múni yìí tán ni wọ́n tó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ tí a retí kí wọ́n ṣe nínú ilé tàbí lóko.

Ní kedere, tọkùnrin-tobìnrin ní ń jìyà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ipò òṣì, ebi, tàbí gbọ́nmisi-omi-òto ti jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́. Ṣùgbọ́n àwọn obìnrin ní ń jìyà náà jù. Ǹjẹ́ ipò yìí yóò yí padà láé bí? Ǹjẹ́ ìrètí gidi kankan wà pé ìgbà kan yóò dé tí a óò fi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò hùwà sí àwọn obìnrin níbi gbogbo bí? Ǹjẹ́ ohun kan wà tí àwọn obìnrin lè ṣe nísinsìnyí láti mú kí ipò wọn sunwọ̀n sí i bí?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Aṣẹ́wó Ọmọbìnrin—Ta Ló Lẹ̀bi?

Lọ́dọọdún, a ń fipá ti àwọn ọmọdé tí a fojú bu iye wọn sí àádọ́ta ọ̀kẹ́—tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn jẹ́ ọmọbìnrin—sí iṣẹ́ aṣẹ́wó, tàbí kí a tà wọ́n sí i. Araya,a tó wá láti ìhà Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà, rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ mélòó kan. “Kulvadee di aṣẹ́wó lọ́mọ ọdún 13 péré. Ọmọbìnrin dáadáa ni, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ sábà máa ń mutí yó, ó sì máa ń ta káàdì poker, nítorí náà, kò ráyè bójú tó ọmọbìnrin rẹ̀. Ìyá Kulvadee rọ̀ ọ́ láti máa bá àwọn ọkùnrin ròde kí ó lè máa pawó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó láìpẹ́.”

“Sivun, akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn ní kíláàsì mi, wá láti ìhà àríwá orílẹ̀-èdè náà. Ọmọ ọdún 12 péré ni nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rán an lọ ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Ó ní láti ṣiṣẹ́ ọdún méjì kó tó kájú àdéhùn tí àwọn òbí rẹ̀ fọwọ́ sí. Ọ̀ràn Sivun àti Kulvadee kì í ṣe àrà ọ̀tọ̀—5 lára ọmọbìnrin 15 tó wà ní kíláàsì mi ló daṣẹ́wó.”

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èwe bí Sivun àti Kulvadee ló wà. Wassyla Tamzali, ti àjọ UNESCO (Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè) kédàárò pé: “Òwò ìbálòpọ̀ jẹ́ ọjà ńlá tó ní agbára ìsúnniṣe tirẹ̀. Títa ọmọbìnrin ọlọ́dún 14 kan ti wọ́pọ̀ gan-an, kì í ṣe ohun tuntun.” Ní gbàrà tí wọ́n bá sì ti ta àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí sí oko ẹrú ìbálòpọ̀, sísan owó náà padà lè di ohun tí kò ṣeé ṣe mọ́. Manju, tí baba rẹ̀ tà nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún 12, ṣì jẹ gbèsè 300 dọ́là (owó U.S.) lẹ́yìn ọdún méje tó ti fi ṣe aṣẹ́wó. Ó wí pé: “Kò sí ohun tí mo lè ṣe—mo ti há.”

Bíbọ́ lọ́wọ́ àrùn AIDS lè fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣòro fún àwọn ọmọbìnrin náà tó bí ó ṣe ṣòro fún wọn láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn tí ń báṣẹ́wó wá oníbàárà tó mú wọn lẹ́rú. Ìwádìí kan tí a ṣe ní ìhà Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà fi hàn pé ìpín 33 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé aṣẹ́wó wọ̀nyí ló ní fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS. Bí òwò aṣẹ́wó oníbílíọ̀nù-márùn-ún-dọ́là náà bá ṣe ń gbilẹ̀ pẹ́ tó ni ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí máa jìyà nìṣó pẹ́ tó.

Ta ló lẹ̀bi àṣà tí ń múni gbọ̀n rìrì yìí? Ó dájú pé àwọn tí ń ta àwọn ọmọbìnrin sí iṣẹ́ aṣẹ́wó àti àwọn tí ń rà wọ́n jẹ púpọ̀ nínú ẹ̀bi náà. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí a dá àwọn ọkùnrin aláìníláárí tí ń fi àwọn ọmọbìnrin náà tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìbálòpọ̀ wọn lọ́rùn lẹ́bi pẹ̀lú. Nítorí pé, bí kò bá sí irú àwọn tí ń sọ ìṣekúṣe dàṣà bẹ́ẹ̀, sísọ àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí di aṣẹ́wó kì bá tí sí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

[Àwòrán]

Lọ́dọọdún, a ń fipá ti nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé sí iṣẹ́ aṣẹ́wó

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àpèjúwe Ọjọ́ Tí Obìnrin Kan Fi Ń Ṣiṣẹ́ ní Àáríngbùngbùn Áfíríkà

Obìnrin náà ń jí ní agogo mẹ́fà, ó sì ń gbọ́únjẹ tí òun àti ìdílé rẹ̀ yóò jẹ lọ́wọ́ ìyálẹ̀ta. Lẹ́yìn tí ó bá pọnmi láti odò ìtòsí, yóò forí lé oko rẹ̀—ó lè jìn tó ìrìn wákàtí kan.

Títí di nǹkan bí agogo mẹ́rin ọ̀sán, ó ń túlẹ̀, ó ń ṣáko, ó sì lè máa fomi fún oko náà, ó ń ṣíwọ́ fún àkókò ráńpẹ́ kan láti jẹ oúnjẹ tó wù kó gbé wá láti ilé. Ó ń fi wákàtí méjì tó kù kí ilẹ̀ ṣú ṣẹ́ igi, kí ó máa wa pákí tàbí kí ó máa fẹ́ ẹ̀fọ́ mìíràn tí ìdílé yóò jẹ—ó ń ru gbogbo rẹ̀ lọ sílé.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ń délé nígbà ti oòrùn ń wọ̀. Iṣẹ́ wá wà láti ṣe ní báyìí láti gbọ́únjẹ alẹ́, iṣẹ́ kan tó lè gba wákàtí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ń fi ọjọ́ Sunday fọ aṣọ ní odò àdúgbò, ní gbàrà tí àwọn aṣọ náà bá sì ti gbẹ, ó ń lọ̀ wọ́n.

Kò wọ́pọ̀ pé kí ọkọ rẹ̀ mọyì gbogbo iṣẹ́ àṣekára yìí tàbí kí ó fetí sí àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀. Kò ni ọkọ náà lára láti gégi lulẹ̀ tàbí kí ó dáná sun pápá kí obìnrin náà lè dáko tí yóò fi gbin irúgbìn, ṣùgbọ́n kì í ṣe nǹkan jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọkọ náà ń mú àwọn ọmọ lọ sódò láti lọ wẹ̀, ó sì lè ṣọdẹ díẹ̀ tàbí kí ó pẹja díẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ń lo àkókò tó pọ̀ jù lójúmọ́ láti máa bá àwọn ọkùnrin tó kù lábúlé rojọ́.

Bí ọkọ náà bá lè ṣe é, lẹ́yìn ọdún mélòó kan, yóò mú ìyàwó kékeré wálé, tí yóò wá di ààyò rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, a retí pé kí ìyáálé rẹ̀ ṣì máa ṣiṣẹ́ nìṣó bó ti ń ṣe bọ̀, títí di ìgbà tí ara rẹ̀ kò bá le mọ́ tàbí tí ó kú.

Àwọn obìnrin Áfíríkà ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́