“Nígbà Tí Èmi Bá Jẹ́ Aláìlera, Nígbà náà ni Mo Di Alágbára”
MO DÀGBÀ ní ìlú kékeré kan, tí ń jẹ́ Petaluma, ní ìhà àríwá San Francisco, California. Mọ́mì mi jẹ́ ẹlẹ́mìí ìsìn lọ́nà kan, àmọ́ èrò nípa ìsìn kò sí lọ́kàn dádì mi. Mo gbà gbọ́ nínú ẹlẹ́dàá—n kò mọ ẹni tí ó jẹ́ gan-an.
Mo jẹ́ ọmọ tí ó láyọ̀ bí mo ti ń dàgbà. Ẹ wo bí mo ti fẹ́ràn láti máa rántí bí mo ṣe gbádùn àwọn ọjọ́ aláìníṣòro wọ̀nyẹn tó! N kò mọ̀ pé àwọn nǹkan kan, tí yóò gba púpọ̀ nínú òmìnira mi, ń ṣẹlẹ̀ nínú ara mi. Ní ọdún 1960, ọdún tí mo lò kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ni mo rántí pé mo bá ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìka mélòó kan tí ń ro mí.
Kò pẹ́ tí ẹsẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dùn mí gan-an débi pé mọ́mì mi mú mi lọ sí ilé ìwòsàn ní San Francisco, níbi tí mo ti lo nǹkan bí ọjọ́ mẹ́fà. Ọmọ ọdún 18 ni mí nígbà yẹn, èsì àyẹ̀wò sì fi hàn pé àrùn làkúrègbé oríkèé ara ló ń ṣe mí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba abẹ́rẹ́ gold sodium thiosulfate, lẹ́yìn náà, abẹ́rẹ́ prednisone, àti lẹ́yìn náà, oríṣi abẹ́rẹ́ cortisone míràn. Lápapọ̀, mo lo àwọn oògùn yẹn fún ọdún 18, nígbà tí mo bá sì ń lo ọ̀kan, yóò dín ìrora náà kù fún ọdún bíi mélòó kan, àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, kò ní ṣiṣẹ́ mọ́, n óò sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn míràn. A kò lè gbójú fo ìrora tí kò dáwọ́ dúró náà dá, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìgbékútà wá irú àrànṣe ìṣègùn míràn. Mo ti rí àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò kan tí ó ti ṣèrànwọ́ lọ́nà kan. Pẹ̀lú ọpẹ́, ara ríro mi kò pọ̀ tó bí ó ti rí nígbà tí àrùn náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìdààmú púpọ̀ gan-an bí ó ti ń lọ kiri nínú ara mi.
Lọ́jọ́ kan ní 1975, ọmọkùnrin mi ṣèèṣì rí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí mọ́mì mi kọ nípa mi nígbà tí mo wà ní ọmọ ọwọ́. Mo rí i pé nígbà tí mo wà lọ́mọ oṣù mẹ́fà, dókítà kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìtọ́jú fọ́tò X-ray fún mi nítorí ìwúlé ẹṣẹ́ omira lymph. Mo gbà gbọ́ pé ìtọ́jú onítànṣán tí wọ́n júwe fún mi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọwọ́ lè jẹ́ ìdí tí mo ṣe wà ní ipò yí lónìí. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ wo irú àṣìṣe ńláǹlà tí ìyẹn jẹ́!
Mo ṣègbéyàwó ní 1962. Ní 1968, nígbà tí àrùn náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, èmi àti ọkọ mi, Lynn, ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ilé búrẹ́dì kan tí a ní. A máa ń jí ní agogo mẹ́rin ìdájí, ọkọ mi máa ń po àwọn èròjà búrẹ́dì pọ̀, lẹ́yìn náà yóò máa rẹjú lórí àpò ìyẹ̀fun nígbà tí búrẹ́dì ṣì wà nínú ààrò. A óò gé e, a óò sì dì í, lẹ́yìn náà ni Lynn yóò kó wọn lọ fún àwọn oníbàárà. Nígbà kan, olùpolówó ọjà ìbánigbófò kan yà ní ilé búrẹ́dì wa, ó sì bá wa sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba tí Ọlọ́run ṣèlérí. A nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí a gbọ́, àmọ́ ọwọ́ wa dí gan-an. Ibi tí a ń gbé búrẹ́dì wa lọ ń pọ̀ sí i, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ sì ń dí wa lọ́wọ́ lọ́nà púpọ̀. Sí ìdùnnú wa, ilé búrẹ́dì míràn ra òwò búrẹ́dì wa! Lynn ń lọ bá wọn ṣiṣẹ́, èmi sì ń lọ ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀bù ìṣaralóge kan. Síbẹ̀síbẹ̀, bí oríkèé ríro náà ti ń burú sí i, mo lè ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ mẹ́ta péré láàárín ọ̀sẹ̀, mo sì ní láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ pátápátá, nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Láàárín àkókò yẹn, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sí ilé wa déédéé, ó sì fún mi ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Mo sábà máa ń fún un ní ọrẹ owó, tí n óò sì gba àwọn ìwé ìròyìn náà, pẹ̀lú èrò pé mo ń ṣe é lóore ni. Lẹ́yìn tí ó bá ti lọ, n óò kó wọn sórí pẹpẹ ìkówèésí láìṣí wọn wò fún ọjọ́ bíi mélòó kan, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá sì yá, ọ̀kan nínú wa máa ń dà wọ́n nù. Ìyẹn kò dára rárá, nítorí pé nísinsìnyí, a mọyì ìníyelórí tẹ̀mí tí wọ́n ní. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lákòókò yẹn, àwọn ọ̀ràn ìsìn kò wulẹ̀ jọ bí èyí tí ó ṣe pàtàkì gan-an.
Àìní Tẹ̀mí Wa Jẹ Wá Lọ́kàn
Èmi àti ọkọ mi ń jíròrò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nípa bí ìgbésí ayé ṣe yẹ kí ó ní ìtúmọ̀ ju jíjẹun àti sísùn àti ṣíṣiṣẹ́ kára lọ. A bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò tẹ̀mí tí kò sí nínú ìgbésí ayé wa kiri. A darí àfiyèsí wa sí ṣọ́ọ̀ṣì kékeré kan tí ó wà nísàlẹ̀ òpópónà náà, àmọ́ a kò rí ohun tí a retí pé yóò mú ipò tẹ̀mí wa sunwọ̀n sí i. Àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì náà sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro àdúgbò wọn.
Ẹlẹ́rìí tí ó mú àwọn ìwé ìròyìn náà wá ti ń dé ọ̀dọ̀ wa fún nǹkan bí ọdún kan, àmọ́ mo ṣì ń ṣe bí mo ṣe máa ń ṣe àyàfi ìgbà tí mo ka ìtẹ̀jáde Jí!, October 8, 1968 (Gẹ̀ẹ́sì), tí ó ní àkọlé náà, “O Ha Ti Pẹ́ Ju Bí O Ṣe Rò Lọ Bí?” nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Mo nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mo kà, lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ó ní ipa kan náà lórí ọkọ mi. A bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, a sì ń yára fi ara fún òtítọ́. A ń fi ìháragàgà gba gbogbo ohun àgbàyanu tí a ń kọ́. Ní 1969, a ṣèrìbọmi.
Bí àkókò ti ń lọ, ó ń ṣòro fún mi láti dìde jókòó, ó sì túbọ̀ ń le koko sí i láti rìn. Ńṣe ni mo ń fipá ká orúnkún mi kò kí n baà lè wọlé, kí n sì jáde nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Mo ti kọ́ láti máa fara mọ́ àwọn ààlà tí mo lè dé àti ìrora tí ń mú kí n máa sunkún lọ́pọ̀ ìgbà. Nítorí náà, n óò tún èròjà ìṣaralóge mi tọ́, a óò sì gbọ̀nà ìpàdé lọ tàbí kí a jáde lọ fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Mo máa ń rìn láti ẹnu ilẹ̀kùn dé ẹnu ilẹ̀kùn fún ìwọ̀n àkókò tí mo fi lè ṣe bẹ́ẹ̀. Mo máa ń gbìyànjú láti jáde lọ fún iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, títí dìgbà tí àìṣeékákò àti ìrora orúnkún òun ẹsẹ̀ mi kò fi jẹ́ kí ó ṣeé ṣe mọ́. Mo sábà máa ń dààmú nípa ṣíṣubú, kí n sì má lè dìde mọ́. Ó máa ń ṣàǹfààní nígbà tí mo bá bá Jèhófà sọ̀rọ̀. Nígbà míràn, mo máa ń ké pè é pẹ̀lú omijé púpọ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, fífàbọ̀ sórí omijé kì í fìgbà gbogbo ṣeé ṣe. Ẹnì kan tí àrùn làkúrègbé oríkèé ara ń ṣe tún lè máà lómi lójú. Ó ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí tí ìgbẹfúrúfúrú náà le koko gan-an débi pé ó ṣòro fún mi láti kàwé. Nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, mo máa ń tẹ́tí sí àwọn téèpù Bíbélì. Mo sábà máa ń rìn kiri ní pípa ojú mi dé nítorí pé ṣíṣẹ́jú máa ń ha mí lójú. Ó sì lè sọ mí di afọ́jú pẹ̀lú. Nígbà míràn, mo ní láti máa da àgbílẹ̀rọ omijé sínú ojú mi ní ìṣẹ́jú márùn-ún-márùn-ún. Èyí tí ó tún burú jù, n óò ní láti fi oògùn ra ojú mi, tí n óò sì fi báńdéèjì dì í fún ọjọ́ márùn-ún tàbí mẹ́fà títí wọn óò fi sàn díẹ̀. Jíjẹ́ afìmoorehàn kò rọrùn nígbà tí ẹnì kan bá ń jìjàkadì pẹ̀lú àrùn tí ó ti pẹ́ lára tí a kò lè fi ọgbọ́n inú retí pé yóò yí pa dà nínú ètò ìgbékalẹ̀ yí.
Ní 1978, mo ní láti fàbọ̀ sórí kẹ̀kẹ́ arọ. Ṣíṣe ìpinnu yẹn ṣòro. Mo ti ń sún lílo kẹ̀kẹ́ arọ síwájú tipẹ́tipẹ́ gan-an, àmọ́ kò sí ohun tí mo lè ṣe mọ́. Mo ti mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí n óò nílò rẹ̀, àmọ́ ìrètí mi ni pé ayé tuntun Ọlọ́run yóò kọ́kọ́ dé. Lynn ra àga ayàwòrán-ilé, tí ń yí bírí, gíga kan tí ìsàlẹ̀ rẹ̀ ní ẹsẹ̀ márùn-ún. Mo ń ti ara mi káàkiri ilé lórí rẹ̀.
Láti nawọ́ gbé nǹkan jẹ́ ohun tí ń tánni ní sùúrù, nítorí pé n kò lè na apá mi jìnnà, tí n kò sì lè fi àwọn ìka mi tí ó ká, tí ó sì lọ́, gbá nǹkan mú dáadáa tó. Nítorí náà, n óò wá lo ọ̀pá “ìgbáǹkanmú” mi. Mo lè fi mú nǹkan ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, mo lè fi ṣí kọ́bọ́ọ̀dù, kí n sì mú àwo, tàbí kí n gbé nǹkan jáde láti inú fìríìjì. Bí mo ti ń mú àwọn òye iṣẹ́ tuntun dàgbà ní lílo ọ̀pá “ìgbáǹkanmú” mi, mo lè bójú tó àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan. Mo lè gbọ́únjẹ, mo lè fọbọ́ kí n sì nù ún, mo lè lọ aṣọ kí n sì ká a, mo sì lè fọ ilẹ̀. Mo nímọ̀lára ìyangàn kan bí agbára ìtóótun mi ti ń sunwọ̀n sí i, inú mi sì dùn pé mo ṣì lè kópa nínú díẹ̀ lára àwọn ohun tí agboolé nílò. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun tí mo máa ń fi ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣe tẹ́lẹ̀ ti ń gbà mí ní ọ̀pọ̀ wákàtí.
Wíwàásù Lórí Tẹlifóònù
Ó gba àkókò, àmọ́ mo mọ́kàn le láti gbìyànjú wíwàásù lórí tẹlifóònù. N kò ronú pé mo lè ṣe é, àmọ́ nísinsìnyí, mo ń gbádùn rẹ̀ gidigidi, mo sì ti ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí rere. Sí ìyàlẹ́nu mi, ó rí bákan náà pẹ̀lú lílọ láti ilé dé ilé, ní ti èrò pé mo lè bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀.
Ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí mo máa ń lò bẹ̀rẹ̀ lọ́nà yí pé: “Ẹ ǹlẹ́ o, ṣé ẹ̀yin ni Ọ̀gbẹ́ni——? Ìyáàfin Maass ni mo ń jẹ́. Mo ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ní ṣókí, bí ẹ bá sì ní àyè díẹ̀, ǹjẹ́ mo lè bá yín sọ̀rọ̀? (Èsì tí ó wọ́pọ̀ ni pé: “Nípa kí ni?”) Rírí ohun tí ń lọ ní ayé lónìí ń dẹ́rù bani, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? (Mo máa ń jẹ́ kí wọ́n fèsì) Mo fẹ́ kí a jùmọ̀ ṣàjọpín èrò tí ó bá Bíbélì mu yìí, tí ń fún wa ní ìrètí tòótọ́ nípa ọjọ́ iwájú.” Lẹ́yìn náà, ni n óò wá ka Àdúrà Olúwa àti bóyá Pétérù Kejì 3:13. Mo ti fa àwọn ìpadàbẹ̀wò díẹ̀ lé àwọn arábìnrin Kristẹni míràn tàbí Lynn lọ́wọ́ láti máa lọ ṣe wọ́n fún mi.
Ní àwọn ọdún tó ti kọjá, mo ti ní ọ̀pọ̀ àwọn ìjíròrò dáradára, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn, àti ìwé ńlá ránṣẹ́ sí àwọn tí wọ́n fi ìfẹ́ hàn. Àwọn díẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí tẹlifóònù. Obìnrin kan tí mo bá sọ̀rọ̀ ní òun rò pé dídá kẹ́kọ̀ọ́ fúnra òun yóò tó. Àmọ́ lẹ́yìn ìjíròrò bíi mélòó kan, ó gbà láti wá sí ilé wa láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí pé mo sọ ipò tí mo wà fún un.
Ní ìgbà kan tí mo ń tẹ àwọn ènìyàn láago, ohùn kan tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ pe nọ́ńbà tuntun kan fún mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí wọ́n wà nítòsí ni mo máa ń tẹ̀ láago, èyí kò sí nítòsí, mo nímọ̀lára ìsúnniṣe láti pe nọ́ńbà náà lọ́nàkọnà. Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ fún àkókò díẹ̀ pẹ̀lú mi, obìnrin tí ó gbé tẹlifóònù náà sọ pé òun àti ọkọ òun ń fẹ́ láti kàn sí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ Kristẹni gidi. Nítorí náà, èmi àti Lynn lọ sí ilé wọn, tí ó gba wákàtí kan láti ilé wa, láti bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́.
Mo ṣì ń rí ìdùnnú àti ayọ̀ nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti ìlérí rẹ̀ nípa àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun kan, níbi tí òdodo yóò máa gbé. Láìpẹ́ yìí, obìnrin kan tí mo ti ń bá sọ̀rọ̀ fún oṣù bíi mélòó kan sọ fún mi pé: “Ìgbàkigbà tí mo bá ti bá ọ sọ̀rọ̀, mo ń rí i pé mo ń gba ìmọ̀ púpọ̀ sí i.” Mo mọ̀ pé ìmọ̀ tí mo ń ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ń ṣamọ̀nà sí ìyè ayérayé, ó sì ń ṣèmújáde ìdùnnú tí ó lè mọ́lẹ̀ jáde láti inú arọ bíi tèmi pàápàá. Ní àwọn ìgbà míràn, mo lè ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn ju àwọn ìgbà míràn lọ, àmọ́ mo dàníyàn kí n lè máa ṣe èyí tí ó pọ̀ gan-an ní gbogbo ìgbà! Mo mọ̀ pé Jèhófà mọ ipò tí olúkúlùkù wà àti pé ó mọyì ohun tí a lè ṣe, láìka bí ó bá ṣe jọ pé ó kéré sí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ronú nípa Òwe 27:11 pé: “Ọmọ mi, kí ìwọ kí ó gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn; kí èmi kí ó lè dá ẹni tí ń gàn mí lóhùn,” mo sì ń fẹ́ láti wà lára àwọn tí wọ́n ń fi Sátánì hàn ní òpùrọ́.
Wíwà ní àwọn ìpàdé sábà máa ń jẹ́ ohun ìṣírí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dídé ibẹ̀ ṣòro fún mi. Jèhófà ti ṣe ìpèsè àgbàyanu púpọ̀ gan-an fún wa láti jẹ́ ẹni tí a bọ́ dáradára nípa tẹ̀mí débi tí mo fi fẹ́ láti jàǹfààní wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ẹ wo bí a ti láyọ̀ tó pé àwọn ọmọ wa méjèèjì ti sọ òtítọ́ di tiwọn! Ọmọbìnrin wa, Terri, ti fẹ́ arákùnrin dáradára kan, wọ́n sì bí ọmọ mẹ́rin tí mo nífẹ̀ẹ́ gidi gan-an. Ẹ wo bí ó ti ń mú ọkàn wa yọ̀ tó láti rí i pé àwọn ọmọ-ọmọ wa pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ Jèhófà! Ọmọkùnrin wa, James, àti ìyàwó rẹ̀, Tuesday, ti yàn láti máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn, orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní New York.
Párádísè Lórí Ilẹ̀ Ayé Nípasẹ̀ Agbára Jèhófà
Mo ń gbìyànjú láti fi ìlérí àgbàyanu Jèhófà nípa párádísè orí ilẹ̀ ayé kan sọ́kàn. Kódà, nísinsìnyí pàápàá, àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tí wọ́n lè jẹ́ orísun ìdùnnú fúnni pọ̀ yanturu. Mo máa ń gbádùn ẹwà wíwọ̀ oòrùn. Inú mi máa ń dùn nípa àwọn onírúurú òdòdó àti òórùn dídùn wọn. Mo fẹ́ràn àwọn òdòdó rose! N kò lè máa jáde nílé lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ nígbà tí mo bá lè jáde, mo máa ń gbádùn ìtànṣán oòrùn lílọ́wọ́ọ́wọ́ lára gidigidi. Mo dijú mi, mo sì finú wòye ipò ẹlẹ́wà kan láàárín àwọn òkè ńlá níbi tí ìdílé mi ti ń gbádùn ara wọn lórí ilẹ̀ eléwéko tútù tí ó kún fún àwọn òdòdó ẹgàn. Omi odò kékeré tí ń pariwo àti ọ̀pọ̀ omi èso watermelon aládùn wà fún olúkúlùkù! Nígbà tí ó bá ṣeé ṣe fún mi, mo máa ń ya àwòrán àwọn ohun tí ń jẹ́ kí n lè máa ronú nípa Párádísè tí yóò dé sórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí mo bá ń yà á, mo máa ń finú wòye pé mo wà níbẹ̀. Mo mọ̀ pé Jèhófà lè sọ àwọn àwòrán ohun ọ̀wọ́n ṣíṣeyebíye tí mo ń fọkàn ṣìkẹ́ di nǹkan gidi.
Mo fẹ́ láti fi ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó wà ní Jákọ́bù 1:12 sọ́kàn. Ó wí pé: “Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà òun yóò gba adé ìyè, èyí tí Jèhófà ṣèlérí fún àwọn wọnnì tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Pọ́ọ̀lù fi àìlera rẹ̀ wé ‘áńgẹ́lì Sátánì kan tí ń gbá a ní àbàrá.’ Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà mú àbùkù ara òun kúrò, àmọ́ a wí fún un pé ńṣe ni a sọ agbára Ọlọ́run di pípé nínú àìlera rẹ̀. Nítorí náà, àṣeyọrí tí Pọ́ọ̀lù ṣe lójú pé ó ní àìlera yìí jẹ́ ẹ̀rí agbára Ọlọ́run lórí rẹ̀. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (Kọ́ríńtì Kejì 12:7-10) Mo nímọ̀lára pé ìwọ̀nba iṣẹ́ ìsìn tí mo bá lè ṣe nísinsìnyí lójú pé mo ní àwọn ààlà tí mo lè dé, wulẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run lórí mi.
Jòhánù ṣe àkọsílẹ̀ kan tí ń fún mi níṣìírí gidi. Ó jẹ́ nípa ọkùnrin kan tí wọ́n ti gbé dùbúlẹ̀ sórí àkéte fún ọdún 38. Òun pẹ̀lú àwọn aláìsàn míràn máa ń dùbúlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ odò adágún kan tìrètítìrètí, ó sì ní ìfẹ́ àtọkànwá gan-an láti tu ara rẹ̀ lára nínú rẹ̀. Kò lè dé inú omi tí ó ronú pé yóò wo òun sàn. Lọ́jọ́ kan, Jésù rí i, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ ha fẹ́ láti di alára dídá bí?” Ẹ wo bí n óò ṣe fi omijé ayọ̀ dáhùn ìbéèrè yẹn! “Jesu wí fún un pé: ‘Dìde, gbé àkéte rẹ kí o sì máa rìn.’” (Jòhánù 5:2-9) Àwa púpọ̀ ni a ń fi ìháragàgà dúró láti gbọ́ irú ìpè yẹn!—Gẹ́gẹ́ bí Luretta Maass ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Mo ronú nípa ọmọdé kan tí ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn, òun sì nìyí, tí ń ré ilẹ̀ eléwéko tútù kan kọjá tayọ̀tayọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Nígbà tí ara mi bá yá gágá, mo máa ń finú wòye ọmọkùnrin olófìn-íntótó kan tí ó gun àgéré, tí ajá rẹ̀ sì wà nísàlẹ̀
[Àwọn Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ṣíṣàkójọ àwọn nọ́ńbà fóònù fún iṣẹ́ ìsìn pápá
Títẹ nọ́ńbà lórí fóònù