Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ikú Àwọn Ọmọdé Ẹ ṣeun fún apá tí ó wà nínú “Wíwo Ayé,” tí ẹ pè ní “A So Sìgá Mímu Pọ̀ Mọ́ Ikú Àwọn Ọmọdé.” (January 22, 1997) Mo lérò pé gbogbo àwọn ìyá yóò ṣàyẹ̀wò apá yẹn gidigidi. SIDS (Ikú Òjijì Àwọn Ọmọdé), fẹ́rẹ̀ẹ́ pa ọmọkùnrin mi jòjòló nítorí pé mo ń mu sìgá nígbà tí mo lóyún. Fún ọdún kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní láti máa wọ ìhùmọ̀ aṣàkíyèsí ìṣiṣẹ́ ọkàn àyà nígbàkúùgbà tó bá ń rẹjú nítorí kí ìhùmọ̀ aṣàkíyèsí ìṣiṣẹ́ ọkàn àyà náà lè pariwo tí ọkàn àyà rẹ̀ kò bá ṣiṣẹ́ mọ́. Mo wulẹ̀ dàníyàn pé kí n ti mọ Jèhófà nígbà yẹn. Ǹ bá ti jáwọ́ sìgá mímú, bóyá èmi àti ọmọkùnrin mi ì bá má ti ní ìrírí bíbanilẹ́rù yí.
A. C. A., United States
Alárùn Oríkèé Ríro Mo fẹ́ láti dúpẹ́ fún ìrírí Luretta Maass, tí ó ní àkọlé náà, “Nígbà Tí Èmi Bá Jẹ́ Aláìlera, Nígbà Náà Ni Mo Di Alágbára.” (January 22, 1997) Ẹni ọdún 27 ni mí, èmi pẹ̀lú ní àrùn làkúrègbé oríkèé ara. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtọ́jú elégbòogi ń mú ìrora náà rọ̀, nígbà míràn, mo máa ń nímọ̀lára ìjákulẹ̀ àti ìrẹ̀wẹ̀sì díẹ̀ nítorí pé àìsàn mi ti fipá mú mi láti fi iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún sílẹ̀. Ìpinnu Luretta Maass láti sin Jèhófà, láìka àìlera rẹ̀ sí, ń fúnni níṣìírí. N kò ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì ṣẹ́gun mi; mo fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù.
A. B., Ítálì
Ó ti lé ní 30 ọdún tí ìyá mi ti ní àrùn làkúrègbé oríkèé ara. Ó ń bani nínú jẹ́ láti mọ̀ pé agbára káká ni a fi ń rí ìdẹ̀rùn lọ́wọ́ ìrora náà. Mo ń fi ìyá mi yangàn, nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìpàdé ìjọ ló ń gbìyànjú láti lọ. Ní jíjókòó sórí àga arọ rẹ̀, ó máa ń nípa nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ó sì ń lè lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù síbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àrùn, kò ṣàròyé rí.
S. M., Germany
Ìkún Omi Ọjọ́ Nóà Àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ìkún Omi Náà—Òtítọ́ Tàbí Àròsọ?” (February 8, 1997), ràn mí lọ́wọ́ gidigidi láti fojú pàtàkì wo ìtàn yẹn. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn, ìgbà tí mo wà lọ́mọdé ni wọ́n ti kọ́ mi nípa Ìkún Omi náà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, n kò fìgbà kan mọ̀ pé àwọn kan ka àkọsílẹ̀ nípa Ìkún Omi náà sí ìtàn àròsọ lásán. Òtítọ́ náà pé Jésù fi àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wé ọjọ́ Nóà fi hàn pé Ìkún omi náà ṣẹlẹ̀ lótìítọ́.
S. M., United States
Kíkojú Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Mo ti ní ọ̀pọ̀ àdánwò léraléra lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Mo kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ kan, mo sì kọ díẹ̀ lára àwọn àdánwò wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ, mo sì ṣàyọlò Orin Dáfídì 126:5 pé: “Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.” Ẹ finú wòye bí ìmọ̀lára mi ti rí lẹ́yìn tí mo kọ lẹ́tà náà tán, tí mo sì gba ìtẹ̀jáde February 8, 1997, tí ó ní àpilẹ̀kọ náà, “Fífomijé Fúnrúgbìn, Fífìdùnnú Kórè” nínú, tí a gbé karí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà yẹn. Ìrírí Raymond Kirkup ń fún ìgbàgbọ́ lókun gan-an.
P. B., Jamaica
Ṣíṣètọ́jú Àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ṣíṣètọ́jú—Kíkojú Ìpèníjà Náà” (February 8, 1997), ti jẹ́ ohun ìtùnú gidigidi fún mi ní àkókò tí nǹkan ti le koko fún mi jù lọ. Ìyá mi ọ̀wọ́n, tí ó ti jẹ́ ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ti Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ní àrùn ọpọlọ tí ń sọni di aláìlókun. Ó tún ní àrùn Parkinson àti akọ oríkèé ríro. Inú mi bà jẹ́, ẹ̀rù sì bà mí nípa bí ó ṣe ń yára joro. Gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí, gbígbé ẹrù ìtọ́jú rẹ̀ wọ̀ mí lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ àgbàyanu náà kún fún òye! Ó wá bí ẹ̀bùn gidi láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Ẹ ṣeun gan-an fún ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ yìí.
R. H., England