Oríkèé Ara Ríro Àrùn Tó Ń Sọni Di Akúrẹtẹ̀
“O KÒ LÈ MỌ BÍ ÌRORA YẸN ṢE MÁA Ń PỌ̀ TÓ ÀFI TÓ BÁ ṢE Ọ́. Ọ̀NÀ KAN ṢOṢO TÍ MO RÒ PÉ MO LÈ GBÀ RÍ ÌTURA NI PÉ KÍ N KÚ.”—SETSUKO, JAPAN.
“ÀRÙN YÌÍ KÒ JẸ́ KÍ N GBÁDÙN ÌGBÀ ÈWE MI, NÍTORÍ ÀTÌGBÀ TÍ MO TI WÀ LỌ́MỌ ỌDÚN MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN LÓ TI Ń BÁ MI JÀ.”—DARREN, ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ.
“MI Ò GBÁDÙN ODIDI ỌDÚN MÉJÌ NÍNÚ ÌGBÉSÍ AYÉ MI NÍTORÍ PÉ MI Ò LÈ RÌN.”—KATIA, ÍTÁLÌ.
“TÍ ÌRORA NÁÀ BÁ TI BẸ̀RẸ̀ BÁYÌÍ NÍ GBOGBO ORÍKÈÉ ARA MI, GBOGBO ARA PÁTÁ LÁÁ MÁ A RO MÍ.”—JOYCE, GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ.
ÌRORA tí kò láàlà táwọn alárùn oríkèé-ara-ríro ń jẹ lẹ gbọ́ yẹn o. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń bá jà ló ń lọ sọ́dọ̀ dókítà wọn lọ́dọọdún tí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi bọ́ lọ́wọ́ ìrora, àìlèrìn àti àléébù ara tí àrùn náà lè fà.
Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan, iye èèyàn tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń ṣe lé ní mílíọ̀nù méjìlélógójì, ó sì ń sọ ọ̀kan nínú èèyàn mẹ́fà tó ń ṣe di akúrẹtẹ̀. Kódà, àrùn oríkèé-ara-ríro ni àrùn tó ń sọ àwọn èèyàn di akúrẹtẹ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè yẹn. Àwọn Ibùdó fún Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé ọṣẹ́ tí àrùn yìí ti ṣe ètò ọrọ̀ ajé “kúrò ní díẹ̀,” nítorí ó ń ná àwọn ará Amẹ́ríkà lóhun tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́ta dọ́là lọ́dọọdún lórí egbòogi àti àìlèṣiṣẹ́ bó ti yẹ. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà bíi Brazil , Chile, China, Íńdíà, Indonesia, Malaysia, Mẹ́síkò, Pakistan, ilẹ̀ Philippines àti Thailand fi hàn pé, ìṣòro tí àrùn oríkèé-ara-ríro àtàwọn oríṣi làkúrègbé mìíràn ń fà fún wọn níbẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ “jẹ́ bákan náà pẹ̀lú tàwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà.”
Irọ́ gbáà lohun táwọn kan ń sọ pé àwọn arúgbó nìkan ni àrùn oríkèé-ara-ríro máa ń ṣe o. Lóòótọ́, béèyàn bá ṣe ń dàgbà sí i ló túbọ̀ máa ń yọ èèyàn lẹ́nu sí i. Àmọ́ ọ̀kan lára oríṣi tó wọ́pọ̀ nínú àrùn yìí, ìyẹn èyí tó ń mú oríkèé ara wú sábà máa ń bá àwọn tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti àádọ́ta ọdún jà. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ mẹ́ta nínú èèyàn márùn-ún tó ní àrùn oríkèé-ara-ríro ni wọ́n ò tíì tó ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́ta. Bákan náà, ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nínú mílíọ̀nù mẹ́jọ èèyàn tí àrùn náà ń bá jà, mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá ni kò tíì pé ọmọ ọdún márùnlélógójì. [1,200,000] Àwọn tó jẹ́ ọmọdé nínú wọn sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àtààbọ̀ [14,500].
Lọ́dọọdún, ńṣe ni iye àwọn tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń ṣe ń pọ̀ sí i. Ní Kánádà, wọ́n fojú bù ú pé láàárín ọdún mẹ́wàá tó ń bọ̀, iye àwọn tó ní àrùn oríkèé-ara-ríro máa fi mílíọ̀nù kan pọ̀ sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àrùn oríkèé-ara-ríro pọ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù ju ní Éṣíà àti Áfíríkà lọ, àrùn ọ̀hún kò yéé pọ̀ sí i láwọn ilẹ̀ méjì tá a dárúkọ kẹ́yìn yìí. Bí àrùn oríkèé-ara-ríro ṣe wá ń pọ̀ sí i yìí ti mú kí Àjọ Ìlera Àgbáyé pe ọdún 2000 sí 2010 ní Ẹ̀wádún Egungun àti Àwọn Oríkèé Ara. Láàárín àkókò yìí, àwọn dókítà àtàwọn tó mọ̀ nípa ètò ìlera kárí ayé yóò pòbìrìkòtò láti wá bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ mú káyé dẹrùn fún àwọn tí àrùn tó jẹ mọ́ eegun àti iṣan ara ń ṣe.
Kí la mọ̀ nípa àrùn tó ń roni lára yìí? Àwọn wo ló lè ní i? Báwo làwọn tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń yọ lẹ́nu ṣe lè fara da sísọ tó ń sọni di akúrẹtẹ̀? Ṣé ìwòsàn á wà lọ́jọ́ iwájú? Àwọn àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e á jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
X ray: Lọ́lá àṣẹ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àrùn Oríkèé-Ara-Ríro, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (www.arc.org.uk)