Ìdí Tí Koríko Fi Ní Àwọ̀ Ewé—Wíwo Ìlànà Photosynthesis Láwòfín
“ÈÉ ṢE tí koríko fi ní àwọ̀ ewé?” Bóyá o ti béèrè ìbéèrè yẹn rí nígbà tí o wà lọ́mọdé. Ṣé ìdáhùn tí wọ́n fún ọ tẹ́ ọ lọ́rùn? Irú àwọn ìbéèrè bí èyí tí àwọn ọmọdé máa ń béèrè lè lọ́gbọ́n nínú gan-an. Wọ́n lè mú kí a túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí a kò fojú bàbàrà wò, kí a sì ṣí àwọn ohun àgbàyanu tí ó fara sin tí a kò fura rí pé wọ́n wà níbẹ̀ payá.
Láti lóye ìdí tí koríko fi ní àwọ̀ ewé, finú wòye ohun kan tí ó lè jọ pé kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú koríko. Gbìyànjú láti finú wòye ilé iṣẹ́ pípé náà. Ilé iṣẹ́ pípé náà yóò pa rọ́rọ́ nígbà iṣẹ́, yóò sì fani mọ́ra láti wò, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Dípò bíba àyíká jẹ́, ilé iṣẹ́ pípé náà yóò mú kí ó sunwọ̀n sí i nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ní ti gidi ni. Dájúdájú, yóò mú ohun tí ó wúlò jáde—tí ó ṣe pàtàkì ní ti gidi—fún gbogbo ènìyàn. Irú ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa fi oòrùn ṣagbára, àbí o kò rò bẹ́ẹ̀? Lọ́nà yẹn, kò ní nílò ìsokọ́ra oníná mànàmáná tàbí jíjá èédú tàbí epo láti fún un lágbára.
Kò sí iyè méjì nípa pé ilé iṣẹ́ pípé tí ń fi oòrùn ṣagbára náà yóò lo àwọn bátìrì tí ó níye lórí gan-an ju ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti ènìyàn lọ. Wọn óò wúlò gan-an, wọn kì yóò wọ́nwó, wọn kì yóò sì máa ba àyíká jẹ́, nígbà tí a bá ń ṣe wọ́n àti tí a bá ń lò wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yóò lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ó gba iwájú jù lọ tí a lè ronú rẹ̀, ilé iṣẹ́ pípé náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí kò fara hàn gbangba, láìsí pé kò lè ṣiṣẹ́, pé ó bà jẹ́, tàbí yíyí kiri tí ó jọ pé àwọn ìmújáde ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní nílò láti lè ṣiṣẹ́ ketekete, lọ́nà tí a kò retí. A óò retí pé kí ilé iṣẹ́ pípé náà máa ṣiṣẹ́ ní lílo ìlànà ìdáṣiṣẹ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, láìsí pé ó nílò àfiyèsí ẹ̀dá ènìyàn kankan. Ní tòótọ́, yóò máa ṣàtúnṣe ara rẹ̀, yóò máa bójú tó ara rẹ̀, kódà yóò máa ṣẹ̀dà ara rẹ̀.
Àròsọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lásán ha ni ilé iṣẹ́ pípé náà bí? Àwòrán àfinúwòye, atannijẹ, tí kò lè ṣẹ lásán ha ni bí? Rárá o, láìṣe àní-àní, nítorí pé ilé iṣẹ́ pípé náà jẹ́ gidi bí koríko tí o dúró lé ti jẹ́ gan-an. Ní tòótọ́, òun ni koríko tí o dúró lé, àti ewéko tí ó wà ní ọ́fíìsì rẹ àti igi tí ó wà lójúde fèrèsé rẹ. Ní gidi, ilé iṣẹ́ pípé náà ni irúgbìn aláwọ̀ ewé èyíkéyìí! Bí ìtànṣán oòrùn ṣe ń fún àwọn irúgbìn aláwọ̀ ewé lágbára, wọ́n ń lo gáàsì carbon dioxide, omi, àti àwọn èròjà láti ṣèmújáde oúnjẹ, ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà, fún èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun abẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé. Nínú ìlànà náà, wọ́n ń sọ afẹ́fẹ́ àyíká dọ̀tun, ní fífa gáàsì carbon dioxide kúrò, kí wọ́n sì tú afẹ́fẹ́ oxygen jáde.
Lápapọ̀, àwọn irúgbìn orí ilẹ̀ ayé ń ṣèmújáde tọ́ọ̀nù ṣúgà tí a fojú díwọ̀n sí 150 bílíọ̀nù sí 400 bílíọ̀nù lọ́dọọdún—èròjà tí ó pọ̀ ju àkópọ̀ gbogbo èròjà irin líle, irin lílẹ̀, ohun ìrìnnà, àti àwọn ilé iṣẹ́ afẹ́fẹ́ àyíká òun ojúde òfuurufú tí ẹ̀dá ènìyàn ń ṣe jáde lọ. Wọ́n ń ṣe èyí nípa lílo agbára tí oòrùn ń pèsè láti mú àwọn átọ̀mù inú gáàsì hydrogen kúrò nínú molecule omi, lẹ́yìn náà, wọ́n óò so àwọn átọ̀mù gáàsì hydrogen náà pọ̀ mọ́ molecule gáàsì carbon dioxide láti inú afẹ́fẹ́, tí èyí ń sọ gáàsì carbon dioxide náà di carbohydrate tí a mọ̀ sí ṣúgà. Ìlànà arabaríbí yìí ni a ń pè ní photosynthesis. Àwọn irúgbìn náà wá lè lo ṣúgà molecule tuntun wọn láti ṣagbára tàbí kí wọ́n pa wọ́n pọ̀ dí tááṣì, fún ìtọ́júpamọ́ oúnjẹ tàbí kí wọ́n sọ wọ́n di èròjà cellulose, èròjà olókùn, líle koránkorán tí ó di fọ́nrán irúgbìn. Rò ó wò! Bí ó ti ń dàgbà, igi sequoia ńlá tí ó fi 90 mítà ga kọjá rẹ wá láti inú afẹ́fẹ́ lásán, ẹyọ kan molecule gáàsì carbon dioxide àti ẹyọ kan molecule omi ní tẹ̀ léra tẹ̀ léra, ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ‘ìlà ìtòjọ’ sẹ́ẹ̀lì tí kò ṣeé fojú lásán rí tí ń jẹ́ chloroplast. Àmọ́ lọ́nà wo?
Yíyẹ “Ìlànà Iṣẹ́” Náà Wò
Rírí i tí afẹ́fẹ́ lásán (pẹ̀lú omi àti ìwọ̀nba èròjà díẹ̀) di igi sequoia jẹ́ àgbàyanu ní tòótọ́, àmọ́ kì í ṣe idán. Ó jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ọnà àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ onílàákàyè tí ó díjú gan-an ju èyíkéyìí tí ènìyàn ní lọ. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń ṣàwárí àwọn ìlànà photosynthesis dídíjú láti tẹjú mọ́ ànímọ́ òun ìṣiṣẹ́ ohun abẹ̀mí dídíjú gan-an tí ń ṣẹlẹ̀ ní inú lọ́hùn-ún. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ “ìlànà iṣẹ́” tí ó ṣokùnfà ọ̀pọ̀ jù lọ ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀. Bóyá a óò bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìdáhùn sí ìbéèrè wa náà pé, “Èé ṣe tí koríko fi ní àwọ̀ ewé?”
Ẹ jẹ́ kí a yọ awò asọhun kékeré di ńlá wa jáde, kí a ṣàyẹ̀wò irú ewé kan. Tí a bá fi ojú lásán wò ó, ó jọ pé aláwọ̀ ewé ni látòkèdélẹ̀, àmọ́, ẹ̀tàn ni. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan inú irúgbìn kan tí a ń fi awò asọhun kékeré di ńlá wò kò kúkú fi bẹ́ẹ̀ ní àwọ̀ ewé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń fi òdìkejì hàn, àmọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan ní bóyá 50 sí 100 àmì tóótòòtó aláwọ̀ ewé. Àwọn àmì tóótòòtó yìí ni chloroplast, ibi tí a ti ń rí chlorophyll aláwọ̀ ewé tí oòrùn ń nípa lé lórí, tí ìlànà photosynthesis sì ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú chloroplast?
Chloroplast náà jọ àpò kóńkó kan tí ó ní àwọn àpò kóókòòkó pẹlẹbẹ, tí ń jẹ́ thylakoid, nínú rẹ̀. Níkẹyìn, a ti kan àwọ̀ ewé inú koríko náà. Àwọn molecule chlorophyll aláwọ̀ ewé wà lára àwọn thylakoid náà, kò ṣe gátagàta, àmọ́ lọ́nà ìtòjọ létòlétò, tí a fìṣọ́ra ṣe, tí ń jẹ́ photosystem. Oríṣi photosystem méjì ló wà nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn irúgbìn aláwọ̀ ewé, a mọ̀ wọ́n sí PSI (photosystem I) àti PSII (photosystem II). Àwọn photosystem náà ń ṣiṣẹ́ bí ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ aṣèmújáde ní ilé iṣẹ́ kan, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ìgbésẹ̀ pàtó nínú ìlànà photosynthesis.
Ohun “Aláìwúlò” Tí Kò Ṣòfò
Bí ìtànṣán oòrùn ti ń kan ara thylakoid, ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ àwọn chlorophyll molecule tí ń jẹ́ àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ akómọ̀ọ́lẹ̀jọ tí ó wà lára PSII ń dúró láti dẹkùn mú un. Àwọn molecule yìí fẹ́ láti gba ìmọ́lẹ̀ pupa ti ìwọ̀n gígùn ìgbì kan pàtó ní pàtàkì. Ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lára thylakoid náà, ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ àwọn PSI ń wọ̀nà fún ìmọ́lẹ̀ tí ìwọ̀n gígùn ìgbì rẹ̀ tún fi bẹ́ẹ̀ gùn jù. Láàárín àkókò náà, chlorophyll àti àwọn molecule mìíràn, bíi carotenoid, ń gba ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ búlúù àti pupa rẹ́súrẹ́sú mọ́ra.
Nítorí náà, èé ṣe tí koríko fi ni àwọ̀ ewé? Lára gbogbo ìwọ̀n gígùn ìgbì tí ń bọ́ sórí irúgbìn, ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ ewé nìkan ni kò wúlò fún wọn, nítorí náà, ó wulẹ̀ ń tàn dà nù pa dà sójú wa àti ti àwọn kámẹ́rà wa ni. Rò ó wò! Àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewé ti ìgbà ìrúwé, bí àwọn ewé dídán gbinrin ti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, jẹ́ àbáyọrí ìwọ̀n gígùn ìgbì tí àwọn irúgbìn kò nílò, àmọ́ tí àwa ẹ̀dá ènìyàn mọyì! Láìdà bíi ti ìbàyíkájẹ́ àti ìfiṣòfò láti àwọn ilé iṣẹ́ ènìyàn, ìmọ́lẹ̀ “aláìwúlò” yí kò ṣòfò nígbà tí a bá wo ilẹ̀ eléwéko tútù tàbí ẹgàn kan tí ó jojú ní gbèsè, tí àwọn àwọ̀ ewé gbígbádùnmọ́ni rẹ̀ ń tu ọkàn wa lára.
Nínú chloroplast lọ́hùn-ún, nínú ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ àwọn PSII, agbára tí ń wá láti ibi tí ó pupa nínú ìtànṣán oòrùn ni a ti gbé lọ sínú àwọn electron tí ó wà nínú molecule chlorophyll títí di, ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, tí electron kan bá tóó gbagbára tó bẹ́ẹ̀, tàbí “tí a ru ú sókè,” tí ó fi fò láti inú ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà lódindi, lọ sọ́wọ́ molecule agbéǹkankiri nínú abala thylakoid tí ó ti ń dúró dè é. Bí ìgbà tí a ń gbé oníjó kan lọ láti ọ̀dọ̀ alábàájó kan sí òmíràn, electron náà ni a ń gbé lọ láti ọ̀dọ̀ molecule agbéǹkankiri kan sí òmíràn bí ó ti ń pàdánù agbára rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Nígbà tí agbára rẹ̀ bá ti lọ sílẹ̀ tó, a lè lò ó láti pààrọ̀ electron kan nínú photosystem kejì, PSI.—Wo àwòrán 1.
Láàárín àkókò náà, ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ PSII náà ti pàdánù electron kan, tí ó mú kí ó lágbára, kí ó sì máa wọ̀nà fún electron míràn láti rọ́pò èyí tí ó pàdánù. Bí ọkùnrin kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé wọ́n ti jáwó lápò òun, àgbègbè PSII tí a mọ̀ sí àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ ìtújáde afẹ́fẹ́ oxygen yóò máa ṣe wọ́nranwọ̀nran. Ibo ni a ti lè rí electron kan? Tóò! Molecule omi kan ń lọ gbéregbère nítòsí. Ohun ìyanu kan yóò ṣẹlẹ̀ sí i.
Fífọ́ Molecule Omi Yángá
Molecule omi ní átọ̀mù afẹ́fẹ́ oxygen tí ó pọ̀ díẹ̀ àti átọ̀mù gáàsì hydrogen méjì tí ó kéré díẹ̀ nínú. Àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ ìtújáde afẹ́fẹ́ oxygen ti PSII ní èròjà ion mẹ́rin tí ó jẹ́ ti mẹ́táàlì manganese tí ń mú àwọn electron kúrò nínú àwọn átọ̀mù gáàsì hydrogen nínú molecule omi. Àbáyọrí ibẹ̀ ni pé molecule omi náà ni a pín sí ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen (proton) agbaǹkanmọ́ra méjì, átọ̀mù afẹ́fẹ́ oxygen kan, àti electron méjì. Bí a ti ń gé ọ̀pọ̀ àwọn molecule omi, àwọn átọ̀mù afẹ́fẹ́ oxygen ń so pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi molecule gáàsì afẹ́fẹ́ oxygen, tí irúgbìn náà ń dá pa dà sínú afẹ́fẹ́ fún ìlò wa. Àwọn ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen yóò bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ pọ̀ sínú “àpò” thylakoid, níbi tí àwọn irúgbìn ti lè lò wọ́n, wọ́n sì ń lo àwọn electron láti tún pèsè àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ PSII, tí ó ti ṣe tán ní báyìí láti tún àyípoyípo náà ṣe lọ́pọ̀ ìgbà láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan.—Wo àwòrán 2.
Nínú àpò thylakoid náà, ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen tí ó kún fọ́fọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà àbájáde. Kì í ṣe pé a ń fi ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen méjì kún un nígbà kọ̀ọ̀kan tí molecule omi kan bá pín sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nìkan ni, àmọ́, àwọn ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen yòó kù ni àwọn electron PSII náà ń fà mọ́ra sínú àpò thylakoid náà, bí wọ́n ṣe ń kọjá lórí wọn lọ sínú àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ PSI. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen ń kùn yùnmùyùnmù bí àwọn oyin tí inú ń bí nínú ilé oyin tó kún jù. Báwo ni wọ́n ṣe lè jáde?
Ó ṣẹlẹ̀ pé ọlọ́gbọ́nlóye Olùṣàgbékalẹ̀ ìlànà photosynthesis ti pèsè ilẹ̀kùn ayíbírí kan tí ó ní ọ̀nà àbájáde kan ṣoṣo, gẹ́gẹ́ bí àkànṣe enzyme kan tí a ń lò láti ṣe epo onísẹ́ẹ̀lì tí ó ṣe pàtàkì gan-an tí ń jẹ́ ATP (adenosine triphosphate). Bí àwọn ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen náà ti ń ti ara wọn jáde gba ẹnu ilẹ̀kùn ayíbírí náà, wọ́n ń pèsè agbára tí ó wúlò láti tún mú àwọn molecule ATP gbé kánkán. (Wo àwòrán 3.) Àwọn molecule ATP dà bíi bátìrì onísẹ́ẹ̀lì kéékèèké. Wọ́n ń pèsè ìwọ̀nba ìmújáde agbára, nínú sẹ́ẹ̀lì náà gan-an, fún gbogbo ìṣiṣẹ́padà nínú sẹ́ẹ̀lì náà. Tí ó bá yá, àwọn molecule ATP wọ̀nyí ni yóò nílò nínú ìṣètò ìkójọpọ̀ ṣúgà inú photosynthesis.
Yàtọ̀ sí ATP, molecule kékeré mìíràn ṣe pàtàkì fún ìkójọpọ̀ ṣúgà. Ó ń jẹ́ NADPH (ìkékúrú nicotinamide adenine dinucleotide phosphate). Àwọn molecule NADPH dà bí àwọn ọkọ̀ akẹ́rù kéékèèké, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń gbé ion tí ó jẹ́ ti gáàsì hydrogen kan lọ sínú enzyme kan tí ń dúró, tí ó nílò átọ̀mù gáàsì hydrogen láti ṣèrànwọ́ láti ṣe molecule ṣúgà kan. Ṣíṣe NADPH jẹ́ iṣẹ́ àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ PSI. Nígbà tí photosystem (PSII) kan bá ń ṣiṣẹ́ ní fífọ́ àwọn molecule omi yángá, tí ó sì ń lò wọ́n láti ṣe ATP, photosystem (PSI) kejì ń gba ìmọ́lẹ̀ mọ́ra, ó sì ń ti àwọn electron tí ó wá lò nígbẹ̀yìngbẹ́yín láti ṣe NADPH jáde. Àwọn molecule ATP àti NADPH ni a tọ́jú pa mọ́ sínú àlàfo tí ó wà lóde thylakoid náà fún lílò nígbà míràn lórí ìṣètò ìkójọpọ̀ ṣúgà.
Iṣẹ́ Alẹ́
Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tọ́ọ̀nù ṣúgà ni ìlànà photosynthesis ń ṣẹ̀dá rẹ̀ lọ́dọọdún, síbẹ̀ àwọn ìṣiṣẹ́ tí ń fi ìmọ́lẹ̀ ṣagbára nínú ìlànà photosynthesis kò ṣe ṣúgà kankan ní ti gidi. Gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ni (“bátìrì”) ATP àti (“àwọn ọkọ̀ akẹ́rù”) NADPH. Láti ibí yìí lọ, àwọn enzyme tí wọ́n wà nínú stroma, tàbí àlàfo tí ó wà lóde thylakoid, ń lo ATP àti NADPH láti ṣe ṣúgà. Ní tòótọ́, irúgbìn náà lè ṣe ṣúgà nínú òkùnkùn biribiri! O lè fi chloroplast wé ilé iṣẹ́ kan tí ó ní agbo àwọn òṣìṣẹ́ méjì (PSI àti PSII) nínú thylakoid, tí wọ́n ń ṣe àwọn bátìrì àti àwọn ọkọ̀ akẹ́rù (ATP àti NADPH) tí agbo òṣìṣẹ́ kẹta (àwọn àkànṣe enzyme) nínú stroma yóò lò. (Wo àwòrán 4.) Agbo àwọn òṣìṣẹ́ kẹta yẹn ń ṣe ṣúgà nípa dída gáàsì átọ̀mù hydrogen àti molecule carbon dioxide pọ̀ ní ìtòtẹ̀léra ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà pàtó ní lílo àwọn enzyme inú stroma. Gbogbo agbo òṣìṣẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lè ṣiṣẹ́ lójúmọmọ, agbo òṣìṣẹ́ ṣúgà sì ń ṣiṣẹ́ òru bákan náà, ó kéré tán, títí tí wọn óò fi lo ATP àti NADPH tí àwọn òṣìṣẹ́ ojúmọmọ ṣe sílẹ̀ tán.
O lè ronú pé stroma jẹ́ irú ohun onísẹ́ẹ̀lì ẹ̀ka ìṣàrinà, tí ó kún fún átọ̀mù àti molecule tí a ní láti “so pọ̀” mọ́ra, àmọ́ tí wọn kò ní so pọ̀ fúnra wọn. Àwọn enzyme kan dà bí àwọn alárinà tí wọ́n kéré gan-an, tí wọ́n ń tini sí nǹkan.a Wọ́n jẹ́ molecule protein tí ó ní ìrísí àkànṣe tí ń jẹ́ kí wọ́n lè dì mọ́ àwọn átọ̀mù tàbí molecule tí ó yẹ fún ìṣiṣẹ́ pàtó kan. Bí ó ti wù kí ó rí, láti wulẹ̀ fi àwọn molecule méjì tí wọn óò so pọ̀ mọra wọn nígbà tó bá yá mọ́ra kò tẹ́ wọn lọ́rùn. Àwọn enzyme náà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn àyàfi bí wọ́n bá rí i tí ìsopọ̀ náà sẹlẹ̀, nítorí náà, wọn óò gbá àwọn méjì tí wọn óò wá so pọ̀ náà mú, wọ́n óò sì mú kí àwọn méjèèjì tí ń lọ́ra náà fara kànra ní tààràtà, tí wọn óò sì fipá ṣe ìsopọ̀ náà lọ́nà irú ìsopọ̀ tipátipá nínú ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà lára ohun abẹ̀mí. Lẹ́yìn ìsopọ̀ náà, àwọn enzyme náà yóò tú molecule tuntun náà sílẹ̀, wọn óò sì tún ìlànà náà ṣe, léraléra. Nínú stroma náà, àwọn enzyme náà ń gbé ṣúgà tí ara rẹ̀ kò pé tán káàkiri pẹ̀lú ìyára púpọ̀ jọjọ, ní ṣíṣàtúntò wọn, ní lílo ATP láti fún wọn lágbára, ní fífi carbon dioxide kún wọn, ní síso gáàsì hydrogen mọ́ wọn, àti, ní paríparí rẹ̀, ní títú ṣúgà tí ó ní carbon mẹ́ta, tí a óò tún yí pa dà di glucose àti àwọn ohun yíyàtọ̀ míràn níbòmíràn nínú sẹ́ẹ̀lì náà jáde.—Wo àwòrán 5.
Èé Ṣe Tí Koríko Fi Ní Àwọ̀ Ewé?
Ìlànà photosynthesis ju kìkì ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà lásán lọ. Ó jẹ́ ìṣètò oníṣọ̀kan ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà lára ohun abẹ̀mí ti ìlọ́júpọ̀ yíyani lẹ́nu àti ìgbọ́nféfé. Ìwé náà, Life Processes of Plants, sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Ìlànà photosynthesis jẹ́ ìlànà gbígbàfiyèsí, tí a ṣàkóso lọ́nà gíga, tí a fi ń ṣàmúlò agbára àwọn photon oòrùn. Ìgbékalẹ̀ dídíjú irúgbìn àti ìṣàkóso ìdíjúpọ̀ ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà lára ohun abẹ̀mí lọ́nà tí ó ṣòro láti gbà gbọ́ àti apilẹ̀ àbùdá tí ń darí ìgbòkègbodò ìlànà photosynthesis ni a lè wò bí ìfọ̀mọ́ àwọn ìlànà ìpìlẹ̀ ti mímú photon, kí a sì yí agbára rẹ̀ dà sí ti kẹ́míkà.”
Ní ọ̀rọ̀ míràn, láti mọ ìdí tí koríko fi ní àwọ̀ ewé sún wa láti wo iṣẹ́ ọnà àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ó ga lọ́lá ju ohunkóhun tí ẹ̀dá ènìyàn tí ì hùmọ̀ lọ—aṣàkóso ara rẹ̀, aṣàtúnṣe ara rẹ̀, “àwọn ẹ̀rọ” kíkéré jọjọ tí ń ṣiṣẹ́ ní ìwọ̀n àyípoyípo lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tàbí ìwọ̀n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ pàápàá, ní ìṣẹ́jú àáyá kan (láìsí ariwo, ìbàyíkájẹ́, tàbí àìlẹ́wà), tí ń sọ ìtànṣán oòrùn di ṣúgà. Ní tiwa, ó fún wa láǹfààní láti wo ohun kan ní èrò inú olùṣàgbékalẹ̀ àti onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ títayọ lọ́lá jù lọ kan—Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run. Ronú nípa rẹ̀ nígbà míràn tí o bá ń ṣàyẹ́sí ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ pípé, agbẹ́mìíró, tí ó lẹ́wà, ti Jèhófà, tàbí ìgbà míràn tí o bá kàn ń rìn lọ lórí koríko fífanimọ́ra aláwọ̀ ewé yẹn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn irú enzyme míràn dà bí amòfin aṣètò ìkọ̀sílẹ̀ tí ń tini sí nǹkan; iṣẹ́ wọn jẹ́ láti ya àwọn molecule nípa.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Fọ́tò àkìbọnú: Colorpix, Godo-Foto
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Báwo ni ìlànà “photosynthesis” ṣe mú kí igi yìí dàgbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwòrán 1
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwòrán 2
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwòrán 3
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwòrán 4
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwòrán 5