Ògbóǹkangí Olùtọ́jú Ọgbà
ÀWỌN ọ̀nà dídíjú tí kòkòrò jáwéjáwé ti Gúúsù America ń gbà ṣiṣẹ́ ìtọ́jú ọgbà rẹ̀ ń ya àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè lẹ́nu. Láti pèsè oúnjẹ, kòkòrò kóńkóló yìí yóò já àwọn àjákù ewé, yóò sì kó pàǹtírí ilẹ̀ inú igbó jọ, yóò sì kó ìwọ̀nyí pa dà sínú ìtẹ́ rẹ̀ lábẹ́ ilẹ̀. Lẹ́yìn náà ni kòkòrò náà yóò lọ pàǹtírí wọ̀nyí lúbúlúbú láti ṣe ajílẹ̀ ọgbà olú rẹ̀. Lọ́nà àdánidá, jáwéjáwé yìí mọ bí ó ṣe lè mú kí àwọn irúgbìn rẹ̀ wà ní ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù àti ìwọ̀n ọ̀rinrin tí ó bójú mu láti rí àbájáde tí ó dára jù lọ. Láti ṣẹ̀dá àwọn àyè tuntun, yóò kó àwọn ègé láti ìdí àwọn irúgbìn tí ó ti fìdí múlẹ̀ lọ sórí àwọn ọ̀tọ̀rọ́ ewé tuntun. Kòkòrò jáwéjáwé náà tilẹ̀ ti mọ ọ̀nà ìtúlẹ̀ láti mú kí iye olú tí ń hù pọ̀ dunjú. Àwọn olùṣèwádìí tí ń sẹ́ ọ̀rọ̀ wọn yìí ti ṣàkíyèsí pé onímọ̀ nípa ewéko yìí máa ń ṣàtúnṣe àwọn ìsapá rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn oúnjẹ tí ó nílò nínú ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣún àkókò àti agbára lò.
Àbójútó ọgbà jẹ́ iṣẹ́ àṣekára, kòkòrò jáwéjáwé náà sì ṣeni ní kàyéfì lọ́nà yí. Kò yani lẹ́nu pé Bíbélì sọ pé: “Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹ: kíyè sí iṣẹ́ rẹ̀, kí ìwọ kí ó sì gbọ́n: Tí kò ní onídàájọ́, alábòójútó, tàbí alákòóso. Tí ń pèsè oúnjẹ rẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, tí ó sì ń kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní ìgbà ìkórè.” (Òwe 6:6-8) Ní tòótọ́, ọgbọ́n àdánidá kòkòrò jáwéjáwé náà jẹ́rìí sí ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.—Òwe 30:24, 25.