ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g17 No. 1 ojú ìwé 16
  • Kòkòrò Saharan Silver

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kòkòrò Saharan Silver
  • Jí!—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2017
  • Ọrùn Èèrà
    Jí!—2016
  • Ògbóǹkangí Olùtọ́jú Ọgbà
    Jí!—1997
  • Bí Eèrà Talamọ́ Ṣe Ń Nu Ìdọ̀tí Ara Rẹ̀
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Àwọn Míì
Jí!—2017
g17 No. 1 ojú ìwé 16
Kòkòrò Saharan silver

Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Kòkòrò Saharan Silver

KÒKÒRÒ kan wà tí wọ́n ń pè ní Saharan Silver Ant tàbí Cataglyphis bombycina. Àrà ọ̀tọ̀ ni kòkòrò yìí jẹ́ lára àwọn ẹranko tó lè fara da ooru gbígbóná tó máa ń mú ní aṣálẹ̀. Nígbà tí oòrùn ọ̀sán gangan bá yọ ní aṣálẹ̀, tí ooru gbígbóná sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú, gbogbo ẹranko á wá ibi tó tutù forí pa mọ́ sí, àmọ́ kòkòrò yìí kì í sá. Ó lè jẹ́ ìgbà yẹn gan-an lá bẹ̀rẹ̀ sí wá oúnjẹ kiri. Kódà, lára ohun tó máa ń jẹ ni àwọn kòkòrò míì tí oòrùn ajónigbẹ ti pa.

Irun ara kòkòrò Saharan silver wà lára ohun tí kì í jẹ́ kí oòrùn jó o gbẹ

[50] μm

Rò ó wò ná: Kí ló mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀? Kòkòrò yìí ní awọ kan tó yi àti irun fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó bo gbogbo ẹ̀yìn àti ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ara rẹ̀, èyí ni kì í jẹ́ kí ooru mú un. Àmọ́, kò sí irun ní igbáàyà rẹ̀. Irun rẹ̀ tá à ń wò nínú àwòrán 1 àti 2 ló máa ń jẹ́ kí ara rẹ̀ máa dán bọ̀rọ́bọ̀rọ́. Lábẹ́ ẹ̀rọ tó ń sọ nǹkan di ńlá, irun yẹn tún rèé nínú àwòrán 3 tó dà bí ọ̀pá gbọọrọ tó ní igun mẹ́ta. Ara rẹ̀ rí wúruwùru níta àmọ́ ó ń dán nínú. Iṣẹ́ méjì ni èyí ń ṣe. Apá tó wà níta ló ń dá àwọn ìtànṣán olóró tó ń wá láti ara oòrùn pa dà kí ó má bàa jó kòkòrò náà gbẹ, apá kejì tó wà nínú ló ń jẹ́ kí kòkòrò náà lè tú ooru tó gba abẹ́ ilẹ̀ wọlé síta.a

Lábẹ́ ẹ̀rọ tó ń sọ nǹkan di ńlá, irun ara kòkòrò Saharan silver dà bí ọ̀pá gbọọrọ tó ní igun mẹ́ta.

[10] μm

Awọ ara kòkòrò yìí máa ń jẹ́ kó lè fara da ibi tó móoru gan-an kódà títí dé ìwọ̀n 53.6°C. Àyẹ̀wò nípa kòkòrò yìí ti mú kí àwọn olùṣèwádìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí ohun tó lè mú ara tutu yàtọ̀ sí ẹ̀rọ amúlétutù àti fáànù.

Kí lèrò rẹ? Ṣé kòkòrò Saharan silver yìí kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

a Kòkòrò yìí tún ní àwọn nǹkan míì tó mú kó yàtọ̀. Ó ní èròjà protein kan tí ooru gbígbóná kò lè tètè bà jẹ́. Ẹsẹ̀ rẹ̀ tó gùn tún jẹ́ kó ga nílẹ̀ kí ooru inú ilẹ̀ má bàa mú un, ó sì tún jẹ́ kó lè yára sáré. Paríparí rẹ̀, ó mọ ọ̀nà dáadáa, èyí sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè tètè dé inú ihò rẹ̀ pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́